Ebi Tẹ̀mí ní Romania
ÌRÒYÌN kan tí àjọ akóròyìnjọ Associated Press gbé jáde láti Brasov, Romania, sọ pé nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn mílíọ̀nù 23 ará Romania jẹ́ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, tí wọ́n fún láṣẹ láti máa gbéṣẹ́ ṣe lábẹ́ ìṣàkóso Kọ́múníìsì. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé agbéròyìnjáde Daily Record ti Canon City, Colorado, U.S.A., sọ pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rí i pé ṣọ́ọ̀ṣì náà kò kúnjú ìwọ̀n. Ó gbé àkọlé náà jáde pé: “Àwọn Ará Romania Rí I Pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Kò Bóde Mu.”
Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ ní October tó kọjá pé: “Alexandru Paleologu, òǹkọ̀wé àti ọlọ́gbọ́n èrò orí kan, mẹ́nu ba àìní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì sọ pé ọ̀nà ìṣeǹkan àti ànímọ́ ìpìlẹ̀ ìsìn náà ti dojú rú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn ń gbé àgbélébùú kọ́rùn, wọ́n sì ń gbààwẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí a yàn. Ṣùgbọ́n ìṣẹ́yún, tí ṣọ́ọ̀ṣì náà kà sí ẹ̀ṣẹ̀, ń gbilẹ̀ gidigidi.”
Ìwé agbéròyìnjáde Daily Record náà ṣàkíyèsí pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì mẹ́nu ba ipa tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ń ní lórí ìdílé pé: “Florentina Petrisor sọ pé ọkọ òun máa ń mutí àmuyíràá tẹ́lẹ̀, tí ó sì máa ń lu òun. Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí àwọn tọkọtaya náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ ti jẹ́ alálàáfíà.”
Ìròyìn sọ pé, Florentina, aránṣọ kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 38, “fi ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sílẹ̀ nítorí àìsí ìkọ́ni olùṣọ́ àgùntàn, àti nítorí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì tí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ń lọ ní.” Ìwé agbéròyìnjáde náà ṣàlàyé pé: “Nígbà tí bàbá ọkọ rẹ̀ kú, Petrisor sọ pé ìdílé náà ní láti lo ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní láti sanwó fún àlùfáà náà, kí wọ́n sì bọ́ ọ, kí ó lè ṣe ààtò ìsìnkú àtàtà fún wọn, kí òun tó lè rówó ra oúnjẹ fún àwọn ọmọ òun. Ó wí pé: ‘Mo rò pé kò tọ́ bẹ́ẹ̀.’”
Lórí ìpolongo ṣọ́ọ̀ṣì náà, nípa títan ìsọfúnni èké kálẹ̀ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí, ìwé agbéròyìnjáde Daily Record náà sọ pé: “Ní Romania, ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, tí ó tún ti jèrè agbára ìdarí pa dà, ṣèrànwọ́ láti darí ìjọba láti ṣí àpéjọ ọlọ́pọ̀ èrò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípò kúrò ní olú ìlú ní Bucharest lọ sí àwọn ìlú ńláńlá Brasov àti Cluj ní ẹkùn ilẹ̀ Transylvania, ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yí.”
Ìtẹ̀jáde Jí!, February 22, 1997, sọ nípa ìpolongo tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣe láti darí ìjọba láti fagi lé àpéjọpọ̀ àgbáyé tí a ṣètò sí Bucharest ní July 1996. O lè kà nípa bí a ṣe yára ṣètò fún àwọn àpéjọpọ̀ àfirọ́pò ní Cluj-Napoca àti Brasov, àti bí àròpọ̀ 34,866 ṣe lọ síbẹ̀, nínú ìwé ìròyìn yẹn. Ìsọfáyégbọ́ tí ó ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn náà jẹ́ arabarìbì. Aṣojú Àwọn Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Ohun tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Romania rò pé yóò dí wa lọ́wọ́ wá yí pa dà di ìgbélárugẹ ìhìn rere náà ní gidi.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn onípàdé tí ń kọrin ní àpéjọpọ̀ ní Brasov