Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì—Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GÍRÍÌKÌ
LÁÌSÍ àsọdùn níbẹ̀, ipò tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì wà ní ilẹ̀ Gíríìkì báyìí jẹ́ ìríra ńlá fún àwọn olótìítọ́ ọkàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun àti òtítọ́, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ìjọsìn rẹ̀. Ipò bíbani nínú jẹ́ ti àìsí ìṣọ̀kan, ìfojúkojú oníwà ipá láàárín àwọn ẹgbẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí ń bá ara wọn jà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìròyìn nípa ìjórẹ̀yìn ìwa rere lọ́nà tí ń dójú tini, àti àìtóótun ìsìn kan—tí ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìjọ tòótọ́ kan ṣoṣo ti Ọlọrun”—láti pèsè ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí, ń kó ìjákulẹ̀ àti ìríra bá ọ̀pọ̀ àwọn ará Gíríìkì.
Àwọn ènìyàn gbáàtúù ń ní ìjákulẹ̀, tí ipò àlámọ̀rí yìí tilẹ̀ ń mú ìrunú bá wọn. Nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní yunifásítì kan ń kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde kan tí ó mú ipò iwájú ní ilẹ̀ Gíríìkì, ó dárò pé: “Yánpọnyánrin kan tí kò le tó bẹ́ẹ̀ rí, tí kò pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ rí, tí ó gbé iyè méjì dìde nípa àwọn aláṣẹ [ṣọ́ọ̀ṣì náà], tí ó sì ń pa ìdíyelé àjogúnbá ìgbékalẹ̀ náà run, ti fa Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gíríìkì ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó ṣeni láàánú pé, ìpalára náà ṣì ń bá a lọ.”
Báwo ni ọ̀ràn yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ǹjẹ́ ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì ń gbádùn pẹ̀lú Ìjọba ṣàǹfààní ní tòótọ́ bí? Báwo ni ọjọ́ ọ̀la ipò ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì yìí àti Ìjọba yóò ṣe rí? Àfirọ́pò wo ni ó wà fún àwọn ènìyàn tí ń wá ìjọ tòótọ́ ti Kristi, tí ó ṣọ̀kan? Jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn òtítọ́ ibẹ̀, kí a sì rí ohun tí Bibeli ní láti sọ lórí ọ̀ràn yìí.
Ìjàkadì fún Agbára
Nígbà tí aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ kan ṣàkóso ilẹ̀ Gíríìkì láàárín 1967 sí 1974, ó kópa nínú àlámọ̀rí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì láti lè fún agbára tirẹ̀ lókun. Nínú ìsapá rẹ̀ láti gba ìṣàkóso pátápátá, ìgbìmọ̀ ológun náà tú Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́—ẹgbẹ́ olùdarí gíga jù lọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì, tí a dìbò yàn náà ká—ó sì yan ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn tí ó dá dúró kan, “ní ìbámu pẹ̀lú ìtóótun rẹ̀,” bí wọ́n ti pè é. Nígbà tí a mú ìṣàkóso dẹmọ padà bọ̀ sípò ní 1974, wọ́n tún yan ẹgbẹ́ olùdarí ṣọ́ọ̀ṣì náà padà ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ìwé àjọ rẹ̀. Lójú èyí, wọ́n yọ àwọn bíṣọ́ọ̀bù tí wọ́n jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ alákòóso ìgbìmọ̀ tí a yàn nípò dànù, wọ́n sì fi àwọn mìíràn rọ́pò wọn.
Bí ó ti wù kí ó rí, àbádòfin ìjọba kan tí a gbé jáde ní 1990 fún àwọn bíṣọ́ọ̀bù tí a lé dànù náà ní ẹ̀tọ́ láti tún gba ipò wọn nípa gbígbé ẹjọ́ wọn lọ sí ilé ẹjọ́ ìjọba, àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lọ sí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti ìjọba, Ìgbìmọ̀ Ìjọba. Ohun tí mẹ́ta lára àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, wọ́n sì borí nínú ọ̀ràn ẹjọ́ wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Lónìí, gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan ibùjókòó bíṣọ́ọ̀bù àgbà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó wà ní ilẹ̀ Gíríìkì ni bíṣọ́ọ̀bù méjì-méjì wà—ọ̀kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì nìkan kà sí lábẹ́ àṣẹ àti ọ̀kan tí àwọn Ìgbìmọ̀ Ìjọba tẹ́wọ́ gbà lábẹ́ àṣẹ.
“Àwọn Kristian Oníjà”
Àwọn bíṣọ́ọ̀bù tí a yọ nípò tẹ́lẹ̀ náà ti gba ipò wọn padà, wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti ka àwọn bíṣọ́ọ̀bù míràn, tí ṣọ́ọ̀ṣì tí a fàṣẹ sí náà yàn sípò sí. Ní àfikún sí i, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀pọ̀ “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” ọmọ ẹ̀yìn—gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde kan ṣe ṣàpèjúwe wọn—tí wọ́n ń fi tìtaratìtara sọ ìtara wọn ní ṣíṣètìlẹ́yìn fún ipa ọ̀nà àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn jáde. Ipò ọ̀ràn yìí tipa bẹ́ẹ̀ ru ìhùwàpadà gbígbóná janjan tí ó sì le sókè bí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n káàkiri orílẹ̀-èdè náà ṣe ń gbé àwọn ìran ìwà ipá jáde, tí wọ́n ń fi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ irú “àwọn Kristian oníjà” bẹ́ẹ̀, tí ń já wọnú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tipátipá, tí wọ́n ń da àwọn ère ìsìn wó, tí wọ́n sì ń kọlu àwọn àlùfáà àti àwọn tí kì í ṣe àlùfáà tí wọ́n wà lára ẹgbẹ́ òdìkejì, hàn. Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, àwọn ọlọ́pàá tí ń paná ìrúkèrúdò ní láti dá sí i kí ìlú lè tù. Ọ̀ràn náà dé òtéńté ní October àti November 1993, ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a kọ́ sí agbègbè mìnìjọ̀jọ̀ Kifisia ní Ateni, àti lẹ́yìn náà ní July àti December 1994, ní ìlú ńlá Larissa, nígbà tí sáà rúkèrúdò àwọn afọ́jú agbawèrèmẹ́sìn líle jù lọ ti dá àwọn ènìyàn ìlú níjì ní ilẹ̀ Gíríìkì.
Ìkọlura tí ó kún fún ìwà ipá jù lọ ṣẹlẹ̀ ní July 28, 1994, nígbà ìfijoyè Ignatius, bíṣọ́ọ̀bù Larissa tí Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ yàn sípò. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Ethnos gbé àkọlé ìròyìn gbàgàdà náà, “Larissa Di Pápá Ogun fún Bíṣọ́ọ̀bù Tuntun—A Mú Sànmánnì Ojú Dúdú Sọjí,” ó ròyìn pé: “Èdè ìsọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni ó bá a mu: Sànmánnì Ojú Dúdú. Báwo ni ènìyàn ṣe tún lè ṣàpèjúwe gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Larissa lánàá, . . . ìjà ìgboro, ìkọlura onírúkèrúdò, ìpanilára?”
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, àwọn akọjúùjà-síni kọ lu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Ignatius “ní lílo ọ̀pá irin àti pátákó, nígbà tí wọ́n lé e bá pẹ̀lú jàgídíjàgan.” Akọ̀ròyìn kan ṣe kàyééfì pé: “Ó ha ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti gbà pé èrò Kristian wà nínú àwọn oníjàgídíjàgan tí ọ̀rán kàn nígbà tí ó tún jẹ́ pé ìgbawèrèmẹ́sìn wọn sún wọn láti hu àwọn ìwà tí ó dọ́gba pẹ̀lú ti àwọn àjọ ìpàǹpá, pẹ̀lú ìwà ipá tí ó lè fa ikú? . . . Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n yọrí ọlá sì fún àwọn ìwà wọ̀nyí níṣìírí, wọ́n sì gbojú fún un.”
Ipò náà tilẹ̀ tún burú sí i nígbà àjọ̀dún Kérésìmesì. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Eleftherotipia ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ adaniláàmú tí ó ṣẹlẹ̀ ní December 23 sí 26, 1994, ní Larissa, ó kọ ọ́ pé: “Ó jẹ́ àkókò Kérésìmesì atinilójú ní Larissa, níbi tí, lẹ́ẹ̀kan sí i, rògbòdìyàn tí kò tán bọ̀rọ̀, tí ó nasẹ̀ jìnnà náà kó àbàwọ́n bá [àjọ̀dún] náà. . . . Bí àwọn agogo ṣọ́ọ̀ṣì ti ń kéde ìbí Kristi, kùmọ̀ àwọn ọlọ́pàá ń ró lórí ‘àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.’ Rúkèrúdò, ìforígbárí, àwọn èpè kòbákùngbé, àti ìfàṣẹmúni rọ́pò ìkíni Kérésìmesì àti àdúrà ìbùkún ní àgbàlá Church of Saint Constantine ní Larissa. . . . Ìwọ́de [ní ìdojúùjà kọ Ignatius] yára yí padà sí èébú àti lẹ́yìn náà sí ìforígbárí pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá. . . . Wọ́n sọ àgbàlá ṣọ́ọ̀ṣì náà di pápá ogun.”
Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe hùwà padà sí èyí? Ọkùnrin Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan sọ pé: “N kò mọ ìdí tí àwọn ènìyàn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristian ṣe lè hu irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀ lákòókò họlidé ìsìn mímọ́. Báwo ni mo ṣe lè lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ewu dídi ẹni tí a lù lálùbolẹ̀ níbẹ̀ wà níwájú mi?” Obìnrin Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì olùfọkànsìn kan sì sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní báyìí lẹ́yìn gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí.”
Bíi pé èyí kò tó, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun ni a tún sọ di mímọ̀ nípa ìjórẹ̀yìn ìwà rere tí ó kan Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì. Léraléra ni ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń tú àṣírí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà rere tí ń wọmi tí àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ àlùfáà kan ń hù—àwọn àlùfáà abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti abọ́mọdélòpọ̀, ìkówójẹ, àti títa àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé láìbófin mu. Èyí tí ó kẹ́yìn náà ṣeé ṣe nítorí pé, ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà ní àǹfààní fàlàlà láti dé ibi àkójọ ère ìsìn ṣíṣeyebíye àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye mìíràn láìsí ìdíwọ́.
Ẹ wo bí ipò yìí, lọ́nà híhàn gbangba, ṣe lòdì sí ìṣítí lílágbára tí aposteli Paulu fún àwọn Kristian pé, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ọmọlẹ́yìn ènìyàn nítorí pé èyí ń yọrí sí “ìjà ìyapa” àti “ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ”!—1 Korinti 1:10-13; 3:1-4.
Ipò Ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì Òun Ìjọba—Ọjọ́ Ọ̀la Wọn Ń Kọ́?
Láti ìgbà tí a ti dá Orílẹ̀-Èdè Gíríìkì sílẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì ti ń gbádùn àǹfààní ipò jíjẹ́ ìsìn tí ó yọrí jù lọ. Títí di báyìí ní ilẹ̀ Gíríìkì, kò sí ìyàsọ́tọ̀ láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba. Òfin ilẹ̀ náà fúnra rẹ̀ fúnni lẹ́rìí ìdánilójú nípa ipò Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì gẹ́gẹ́ bí “ìsìn tí ó gbòde” ní ilẹ̀ Gíríìkì. Èyí túmọ̀ sí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì wọ gbogbo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn, títí kan ìṣàbójútó ìlú, ètò òfin, ọlọ́pàá, ẹ̀kọ́ ìwé fún ara ìlú, àti ní gbogbo apá ìhà láwùjọ, lára. Wíwà tí ṣọ́ọ̀ṣì wà nínú gbogbo nǹkan yìí ti túmọ̀ sí ìnilára àti ìṣòro tí kò ṣeé ṣàpèjúwe fún àwùjọ àwọn olùjọ́sìn tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ilẹ̀ Gíríìkì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Òfin kò fi ẹ̀rí ìdánilójú òmìnira ìsìn hàn, ìgbàkígbà tí olùjọ́sìn tí kò fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní bá gbìyànjú láti jà fún ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìgbà gbogbo ni ó máa ń rí i tí òún há sínú ìtẹ̀sí ìhà kan ìsìn, ẹ̀tanú àti àtakò pé ipò ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba yìí ti wọnú ara wọn.
Àtúnṣe Òfin náà dà bí ohun kan tí ó fara hàn pé yóò ṣeé ṣe ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà, nítorí náà, a ti ń gbọ́ tí a ń béèrè fún ìpínyà Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba. Àwọn ògbógi àti àwọn olùṣètúpalẹ̀ tí a bọ̀wọ̀ fún nínú ọ̀ràn òfin ilẹ̀ Gíríìkì ti ń pe àfiyèsí sí àwọn ìṣòro tí àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ yìí dá sílẹ̀ láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba. Wọ́n tọ́ka pé ojútùú kan ṣoṣo tí ó lè ṣiṣẹ́ yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ tí a mú lógìírí fún àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí.
Ní báyìí, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ ìlòdìsí wọn jáde nípa irú ìyàsọ́tọ̀ lásẹ̀yìnwá bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde kan ń sọ nípa ọ̀ràn arùmọ̀lára sókè kan, tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun nínú ipò ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba bẹ́ẹ̀ yóò ní ìpa lé lórí, bíṣọ́ọ̀bù Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àbájáde, ṣé Ìjọba yóò jáwọ́ nínú sísan owó oṣù àwọn àlùfáà ni? . . . Ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ páríìṣì ni yóò wà láìsí àlùfáà.”—Fi wé Matteu 6:33.
Àyọrísí mìíràn láti inú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba ní ilẹ̀ Gíríìkì ni pé, òfin ilẹ̀ Gíríìkì—ní ìforígbárí tààràtà pẹ̀lú ìlànà Ìparapọ̀ Europe àti Ẹ̀ka Òfin Àpéjọpọ̀ Europe Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tí ilẹ̀ Gíríìkì wà lábẹ́ rẹ̀—béèrè pé a gbọ́dọ̀ kọ ìsìn tí ọmọ orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ń ṣe sórí káàdì ìdánimọ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì kọ̀ọ̀kan. Àwọn ènìyàn olótìítọ́ ọkàn ta ko èyí gidigidi nítorí pé àwọn mẹ́ḿbà olùjọ́sìn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sábà máa ń di òjìyà ìpalára kẹ́lẹ́sìn-mẹ̀sìn. Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ṣeé ṣe kí ó ní àwọn ìyọrísí òdì tí ó bá kan ti kí àwọn olùjọ́sìn tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lo òmìnira ìsìn tí wọ́n ní.” Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Ta Nea ń sọ̀rọ̀ lórí èyí, ó kọ̀wé pé: “Ó yẹ kí Ìjọba ṣe àwọn ìpinnu rẹ̀ kí ó sì ṣe òfin láìka àwọn ọ̀nà afipájẹgàbalénilórí àti ìhùwàpadà ṣọ́ọ̀ṣì nínú irú ọ̀ràn bíi ti títẹ ìsìn ẹni sórí káàdì ìdánimọ̀ rẹ̀.”
Nígbà tí Dimitris Tsatsos, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú òfin orílẹ̀-èdè, tí ó tún jẹ́ mẹ́ḿbà Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Europe, ń tẹnu mọ́ àìní kánjúkánjú tí ó wà fún irú ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì [Ilẹ̀ Gíríìkì] gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìfipájẹgàba lórí agbo ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìṣèlú àti ẹ̀kọ́ ìwé. Ọ̀nà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gíríìkì náà fi ń ṣiṣẹ́ ń nini lára. Òṣìkà olùṣàkóso ni ó jẹ́ lórí ètò ẹ̀kọ́ àti ẹgbẹ́ àwùjọ wa.” Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míràn, ọ̀jọ̀gbọ́n yìí kan náà sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì náà ní agbára ìkòópayàbáni ní ilẹ̀ Gíríìkì, tí ó ṣeni láàánú pé kò mọ síbi ipò ìbátan òun àti àwọn òṣèlú elérò ìtẹ̀síwájú nìkan, àmọ́, ó tilẹ̀ ti kó wọ àárín ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn òṣónú ará Gíríìkì pẹ̀lú. Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, mo fẹ́ kí Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Mo fẹ́ pé, kí àwọn mẹ́ḿbà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì rí bákan náà pẹ̀lú àwọn yòókù, kí àwọn onísìn náà sì jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú onísìn míràn ní ilẹ̀ Gíríìkì.”
Àwọn Kristian Tòótọ́ Ṣọ̀kan
Ó ṣòro ní tòótọ́ láti rí àmì ìsìn Kristian tòótọ́ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì. Jesu kò pète pé kí ìyapa àti ìṣòdì dìde nínú ìsìn Kristian. Nígbà tí ó ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, ó sọ pé kí “gbogbo” àwọn ọmọlẹ́yìn òun lè “jẹ́ ọ̀kan.” (Johannu 17:21) Àwọn ọmọlẹ́yìn wọ̀nyí sì ní láti ‘ní ìfẹ́ láàárín ara wọn,’ tí ìfẹ́ yìí yóò sì jẹ́ àmì ìdánimọ̀yàtọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́.—Johannu 13:35.
Ó jọ pé ìṣọ̀kan kò sí nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kì í ṣe ohun tí ojú kò rí rí láàárín àwọn ìsìn tí a gbé kalẹ̀ lónìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àpẹẹrẹ ìyapa tí ń da àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù láàmú.
Ó ṣòro fún àwọn olótìítọ́ ọkàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun láti mú ipò ọ̀ràn bíbani nínú jẹ́ yìí bá àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu, nínú 1 Korinti 1:10, sí àwọn Kristian tòótọ́ mu pé: “Wàyí o mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, ati pé kí ìpínyà máṣe sí láàárín yín, ṣugbọn kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.”
Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu tòótọ́ ń gbádùn ìṣọ̀kan tí kò ṣeé bì ṣubú láàárín ara wọn. Nítorí pé ìdè ìfẹ́ Kristian so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan, wọn kò yàtọ̀ ní ti ìṣèlú, ẹ̀ya, tàbí ìsìn. Jesu ṣàlàyé kedere pé, gbogbo ènìyàn yóò dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀ nípa “àwọn èso wọn,” tàbí ìgbòkègbodò wọn. (Matteu 7:16) Àwọn tí wọ́n ṣe ìwé ìròyìn yìí ń ké sí ọ láti ṣèwádìí nípa “àwọn èso” àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n ń gbádùn ìṣọ̀kan Kristian tòótọ́ ní ilẹ̀ Gíríìkì àti ní ibi gbogbo lágbàáyé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn àlùfáà forí gbárí pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Láti inú ìwé The Pictorial History of the World