A Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre Ní Gíríìsì
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ!
NÍNÚ ọ̀kan lára àwọn ìwàásù rẹ̀, àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní abúlé Gazi ní Kírétè sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbọ̀ngàn kan ní abúlé wa níhìn-ín. Mo nílò ìtìlẹ́yìn yín láti rẹ́yìn wọn.” Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn ẹni àìmọ̀ kan fọ́ àwọn fèrèsé Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n sì yìnbọn lù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn òmìnira ìsìn tún gbé orí lẹ́ẹ̀kan sí i ní Gíríìsì.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí sún mẹ́rin lára Àwọn Ẹlẹ́rìí ládùúgbò, Kyriakos Baxevanis, Vassilis Hatzakis, Kostas Makridakis, àti Titos Manoussakis, láti kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Alákòóso Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ àti Ìsìn fún ìwé àṣẹ láti máa ṣe ìpàdé ìsìn. Ìrètí wọn ni pé gbígba ìwé àṣẹ yóò fún wọn ní ààbò àwọn ọlọ́pàá níkẹyìn. Ṣùgbọ́n, kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọrùn.
Àlùfáà náà fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí olú ilé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá aláàbò ní Heraklion, tí ó fi pe àfiyèsí àwọn aláṣẹ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀ka rẹ̀, tí ó sì béèrè pé kí a ṣe òfin lòdì sí wọn, kí a sì fòfin de àwọn ìpàdé wọn. Èyí yọrí sí kí àwọn ọlọ́pàá ṣèwádìí, kí wọ́n sì fọgbọ́n béèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn ènìyàn. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, olùpẹ̀jọ́ pe Àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́jọ́ ọ̀daràn, wọ́n sì gbé ẹjọ́ náà lọ sílé ẹjọ́.
Ní October 6, 1987, Ilé Ẹjọ́ Ọ̀daràn tí ó wà ní Heraklion dá àwọn olùjẹ́jọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sílẹ̀ láìlẹ́bi, ó sì sọ pé, “wọn kò ṣe ohun tí a torí rẹ̀ fẹ̀sùn kàn wọ́n, nítorí pé àwọn mẹ́ńbà ìsìn kan wà ní òmìnira láti ṣe àwọn ìpàdé . . . , láìnílò ìwé àṣẹ kankan.” Síbẹ̀síbẹ̀, olùpẹ̀jọ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ náà lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n sì gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ kan tí ó ga ju ìyẹn lọ. Ní February 15, 1990, ilé ẹjọ́ yìí dá ẹ̀wọ̀n oṣù méjì àti owó ìtánràn bí 100 dọ́là fún Àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Tẹ̀ lé ìyẹn, àwọn olùjẹ́jọ́ náà pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Gíríìsì.
Ní March 19, 1991, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà, ó sì fara mọ́ ìdálẹ́bi ìṣáájú. Ní èyí tí ó lé ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní September 20, 1993, nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà kéde ìdájọ́ rẹ̀, àwọn ọlọ́pàá fi àṣẹ ọba ti Gbọ̀ngàn Ìjọba náà pa. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan tí àwọn ọlọ́pàá ṣe ti fi hàn, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Kírétè ló wà nídìí ìgbésẹ̀ yí.
Ipò yí wáyé nítorí pé àwọn òfin kan, tí wọ́n ṣe ní 1938 pẹ̀lú èrò láti pààlà sí òmìnira ìsìn, ṣì ń báṣẹ́ lọ ní Gíríìsì. Àwọn òfin náà sọ pé bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ gbé ibi ìjọsìn kankan kalẹ̀, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gba ìwé àṣẹ láti Ilé Iṣẹ́ Àbójútó Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ àti Ìsìn, àti láti ọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí ó bá wà ládùúgbò. Fún àwọn ẹ̀wádún mélòó kan, àwọn òfin tí kò bágbà mu wọ̀nyí ti fa ọ̀pọ̀ ìṣòro fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Òmìnira Ìsìn, àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe gbọ́ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fara mọ́ ẹjọ́ ẹ̀bi tí wọ́n dá fún àwọn tẹ́lẹ̀, wọ́n kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ kan sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe, ní Strasbourg, ilẹ̀ Faransé, ní August 7, 1991. Àwọn olùpẹ̀jọ́ náà sọ pé ẹjọ́ ẹ̀bi tí wọ́n dá àwọn tẹ Abala 9 Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Europe lójú, èyí tí ó dáàbò bo òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn, àti ìsìn, pa pọ̀ mọ́ ẹ̀tọ́ láti dá ṣàfihàn ẹ̀sìn ẹni tàbí láti ṣàfihàn rẹ̀ ní àgbájọ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀.
Ní May 25, 1995, àwọn mẹ́ńbà 25 tí ń bẹ nínú Ìgbìmọ̀ náà dórí ìpinnu àìlálátakò pé Gíríìsì ti tẹ Abala 9 Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Europe lójú. Wọ́n dá ẹjọ́ pé ìdálẹ́bi tí a gbé wá síwájú wọn náà kò bára dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀mí òmìnira ìsìn, kò sì pọn dandan nínú àwùjọ ènìyàn oníjọba tiwa-n-tiwa. Ìdájọ́ yìí lórí bí ẹjọ́ náà ṣe ṣeé fara mọ́ sí tún sọ pẹ̀lú pé: “Àwọn olùpẹ̀jọ́ . . . jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ kan tí a mọ àwọn ààtò àti ìṣe ìsìn wọn dunjú gan-an, tí a sì gbà láyè ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Europe.” Ní àbárèbábọ̀, Ìgbìmọ̀ náà gbé ẹjọ́ ọ̀hún lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kò Ṣeé Dí Lọ́wọ́
Wọ́n fi ìgbẹ́jọ́ sí May 20, 1996. Àwọn tí ń bẹ nínú iyàrá ìgbẹ́jọ́ lé ní 200, títí kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n láti yunifásítì àdúgbò, àwọn akọ̀ròyìn, àti iye kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Gíríìsì, Germany, Belgium, àti ilẹ̀ Faransé.
Ọ̀gbẹ́ni Phédon Vegleris, ọ̀jọ̀gbọ́n-dọjọ́ọkú kan ní Yunifásítì Áténì, tí ó sì jẹ́ agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí náà, tẹnu mọ́ ọn pé, Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Europe nìkan kọ́ ni ìlànà tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà lò àti ìdájọ́ tí wọ́n ṣe tẹ̀ lójú, ṣùgbọ́n ó tún tẹ Òfin Gíríìsì lójú. “Nítorí náà, òfin orílẹ̀-èdè àti àmúlò rẹ̀ ni Ilé Ẹjọ́ náà ní láti gbé yẹ̀ wò.”
Agbẹjọ́rò ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì jẹ́ adájọ́ kan láti inú Ìgbìmọ̀ Ìjọba, ẹni tó jẹ́ wí pé, kàkà kí ó jíròrò lórí àwọn kókó náà, ó wulẹ̀ tọ́ka sí ipò Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Gíríìsì, àjọṣe tímọ́tímọ́ tí ó ní pẹ̀lú Ìjọba àti àwọn ènìyàn, àti àìní tí a fẹnu jẹ́wọ́ láti tẹrí àwọn ẹ̀sìn míràn ba. Síwájú sí i, ó sọ pé láti 1960 wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣàṣeyọrí ní mímú kí iye wọn pọ̀ sí i gidigidi. Lédè míràn, wọ́n ti ṣàṣeyọrí ní pípe àṣẹ àdáni Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì níjà!
A Gbé Òmìnira Ìsìn Lárugẹ
A óò ṣèdájọ́ ní September 26. Ọkàn gbogbo ènìyàn wà lókè, ní pàtàkì láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ààrẹ Ìgbìmọ̀ Ìdájọ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Rudolf Bernhardt, ka ìdájọ́ náà jáde pé: Ilé Ẹjọ́ náà, tí ó ní adájọ́ mẹ́sàn-án, gbà láìlálátakò kankan, pé, Gíríìsì ti tẹ Abala 9 Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Europe lójú. Ó sì tún dájọ́ pé kí olùjẹ́jọ́ san 17,000 dọ́là fún àwọn olùpẹ̀jọ́ láti kájú owó tí wọ́n ti ná sórí ẹjọ náà. Èyí tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ìdájọ́ náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ kókó agbàfiyèsí tí ń ti òmìnira ìsìn lẹ́yìn nínú.
Ilé Ẹjọ́ náà kíyè sí i pé òfin ilẹ̀ Gíríìsì fi àyè púpọ̀ jù gba “kí àwọn aláṣẹ ìṣèlú, ti ìṣàkóso àti ti ìsìn máa dá sí ọ̀ràn lílo òmìnira ìsìn jù.” Ó fi kún un pé Ìjọba ń lo àwọn ìgbésẹ̀ tí ó là sílẹ̀ láti fi gba ìwé àṣẹ kan “láti gbé àwọn ipò líle koko, tàbí, tí ọwọ́ kò lè tẹ̀ ní ti gidi, lé orí àǹfààní tí àwọn àjọ kan tí kì í ṣe ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní láti lo ìgbàgbọ́ ìsìn, ní pàtàkì, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ilé ẹjọ́ ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè yí tú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rírorò tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ń lò fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún fó.
Ilé Ẹjọ́ náà tẹnu mọ́ ọn pé “ẹ̀tọ́ òmìnira ìsìn bí Àdéhùn Àjọṣe náà ṣe fi fúnni, kò fàyè gba Ìjọba láti pinnu lórí bóyá àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn tàbí ọ̀nà tí a gbà ń fi wọ́n hàn bófin mu.” Ó tún sọ pé “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá àpèjúwe ‘ẹ̀sìn tí a mọ̀ dunjú’ mu gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú òfin ilẹ̀ Gíríìsì . . . Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ìjọba pàápàá jẹ́wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀.”
Àwàdà Lásán Kọ́
Láàárín àwọn ọjọ́ mélòó kan tí ó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé agbéròyìnjáde pàtàkì ilẹ̀ Gíríìsì ló polongo ẹjọ́ yìí. Ní September 29, 1996, ìtẹ̀jáde ìwé agbéròyìnjáde Kathimerini ti ọjọ́ Sunday gbé gbólóhùn yí jáde pé: “Bí ilẹ̀ Gíríìsì ti gbìyànjú tó láti fojú yẹpẹrẹ wo ‘àbùkù’ tí ó kàn ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe ní Strasbourg bí ‘àwàdà lásán,’ ní tòótọ́ jẹ́, òkodoro òtítọ́ kan tí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ìwọ̀n kárí ayé. Ilé Ẹjọ́ náà rán Gíríìsì létí Abala 9 Àdéhùn Àjọṣe Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn náà, ó sì pa ohùn pọ̀ láìlálátakò kankan dá ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Gíríìsì lẹ́bi.”
Ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́ ti Áténì náà, Ethnos, kọ ọ́ jáde ní September 28, 1996, pé Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe náà “dá Gíríìsì lẹ́bi, ó sì pàṣẹ fún un láti san owó àbùléni ilé ẹjọ́ fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ tí ń jìyà nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́, Ọ̀gbẹ́ni Panos Bitsaxis, lẹ́nu wò nínú ètò orí rédíò kan, ó sì wí pé: “Ọdún 1996 la wà yí, ọ̀rúndún kọkànlélógún ti ń kanlẹ̀kùn, ó sì ṣe kedere pé, ìṣàkóso kankan kò gbọ́dọ̀ ṣe ìyàtọ̀, ìfòòró, tàbí ìdásọ́ràn tí ó bá kan ṣíṣàmúlò ẹ̀tọ́ ṣíṣe kókó ti òmìnira ìsìn. . . . Àǹfààní yíyẹ kan nìyí fún ìjọba láti ṣàtúnyẹ̀wò ìlànà rẹ̀, kí ó sì fòpin sí ìyàtọ̀ tí kò bọ́gbọ́n mu yìí, tí kò ṣiṣẹ́ fún ète kankan ní àwọn àkókò òde òní.”
Ìdájọ́ ẹjọ́ Manoussakis àti Àwọn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ Lòdì sí Ilẹ̀ Gíríìsì pèsè ìrètí pé Orílẹ̀-Èdè Gíríìsì yóò mú àwọn òfin rẹ̀ bá ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe náà mu, kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gíríìsì lè máa gbádùn òmìnira ìsìn láìsí ìdásí láti ọ̀dọ̀ àwọn alákòóso, ọlọ́pàá, tàbí ṣọ́ọ̀ṣì. Síwájú sí i, èyí ni ìdájọ́ kejì tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe ṣe lòdì sí ẹ̀ka ìdájọ́ ilẹ̀ Gíríìsì lórí àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ òmìnira ìsìn.a
Káàkiri ni a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń ṣègbọràn sí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ti ìjọba nínú gbogbo ọ̀ràn tí kò bá ti forí gbárí pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 13:1, 7) Wọn kì í ṣe ewu fún ìwàlétòlétò ará ìlú lọ́nàkọnà. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn ìtẹ̀jáde wọn àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní gbangba ń fún ẹni gbogbo níṣìírí láti jẹ́ aráàlú tí ń pa òfin mọ́, kí wọ́n sì máa gbé ìgbésí ayé alálàáfíà. Wọ́n jẹ́ onísìn dídúróṣinṣin tí ó sì fìdí múlẹ̀, àwọn mẹ́ńbà wọn sì ti kópa ribiribi nínú ṣíṣe àwọn aládùúgbò wọn láǹfààní. Ìpinnu wọn aláìyẹhùn ní gbígbé ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere gíga ti Bíbélì lárugẹ, àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn aládùúgbò wọn, tí wọ́n ń fi hàn ni pàtàkì, nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe, ti ní ipa gbígbámúṣé ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 200 tí wọ́n wà.
A retí pé ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe ṣe náà yóò fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti gbogbo àwọn olùsìn kéréje mìíràn ní Gíríìsì ní òmìnira ìsìn púpọ̀ sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìdájọ́ àkọ́kọ́, tí wọ́n ṣe ní 1993, ni ẹjọ́ Kokkinakis Lòdì sí Ilẹ̀ Gíríìsì.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ tí àwọn ọlọ́pàá tì pa ní September 20, 1993
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe, Strasbourg
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn kàn: T. Manoussakis, V. Hatzakis, K. Makridakis, K. Baxevanis