Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin
LÁTI ìgbà tí ènìyàn ti ń kọ́ àwọn ìlú ńláńlá, ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi. Pàápàá ní ayé àtijọ́, àwọn odi wọ̀nyí jẹ́ ààbò. Láti orí ìdènà yìí, àwọn olùgbèjà lè jà láti dáàbò bo odi wọn kí àwọn ọ̀tá má bàa dá ihò sí i tàbí kí wọ́n gbẹ́ abẹ́ rẹ̀. Kì í ṣe kìkì pé odi náà ń dáàbò bo àwọn olùgbé ìlú náà nìkan ni ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ó tún ń dáàbò bo àwọn tí ń gbé ní àwọn ìlú tí ń bẹ nítòsí.—2 Sámúẹ́lì 11:20-24; Aísáyà 25:12.
Bákan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ odi kan—odi òfin—láti pèsè ààbò. A kò mọ odi yìí láti ya Àwọn Ẹlẹ́rìí sọ́tọ̀ kúrò lára àwùjọ yòókù, nítorí a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àwọn èèyàn tó mọ yááyì, àwọn tó kóni mọ́ra. Kàkà tí odi náà yóò fi yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣe ni ó fìdí ẹ̀rí tí ó wà fún òmìnira pàtàkì fún gbogbo ènìyàn múlẹ̀ lọ́nà òfin. Lọ́wọ́ kan náà, ó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ tí òmìnira fún Àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọn baà lè máa bá ìjọsìn wọn lọ ní fàlàlà. (Fi wé Mátíù 5:14-16.) Odi yìí ń dáàbò bo ọ̀nà ìjọsìn wọn àti ẹ̀tọ́ wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kí ni odi yìí, báwo sì ni a ṣe mọ ọ́n?
Mímọ Odi Òfin Láti Pèsè Ààbò
Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tilẹ̀ ń gbádùn òmìnira ìsìn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a ti gbéjà kò wọ́n láìnídìí. Nígbà tí a pe òmìnira ìjọsìn wọn ní ti pípéjọ pọ̀ tàbí wíwàásù láti ilé dé ilé níjà, wọ́n fi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́. Yíká ayé, àwọn ọ̀ràn òfin tí ó ní Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún.a Kì í ṣe gbogbo rẹ̀ ni wọ́n ti borí o. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn kóòtù kékeré bá dá wọn lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí àwọn kóòtù gíga. Kí wá ni ìyẹn ti yọrí sí?
Jálẹ̀ àwọn ẹ̀wádún ti ọ̀rúndún ogún, ìṣẹ́gun nínú àwọn ẹjọ́ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti fìdí àwọn ìdájọ́ tí ó ṣeé gbára lé múlẹ̀, èyí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tọ́ka sí nínú àwọn ẹjọ́ mìíràn tó wáyé lẹ́yìn náà. Gẹ́gẹ́ bí bíríkì tàbí òkúta tí ó para pọ̀ di odi, àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti dá wa láre wọ̀nyí para pọ̀ jẹ́ odi òfin tí ń pèsè ààbò. Láti orí odi àwọn ìdájọ́ yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò dáwọ́ dúró láti máa jà fómìnira ẹ̀sìn láti máa bá ìjọsìn wọn lọ.
Bí àpẹẹrẹ, gbé ẹjọ́ Murdock pẹ̀lú àjọ Commonwealth ti Pennsylvania yẹ̀ wò, èyí tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní United States dá ní May 3, 1943. Ìbéèrè tí ó wáyé nínú ẹjọ́ náà rèé: Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti gba ìwé àṣẹ ìkiri-ọjà fún pípín ìwé ẹ̀sìn wọn? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé kò yẹ kí a béèrè irú ìwé àṣẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn. Iṣẹ́ ìwàásù wọn kì í kúkú ṣe òwò—kò sì fìgbà kankan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Wíwàásù ìhìn rere náà ni góńgó wọn, kì í ṣe láti jèrè owó. (Mátíù 10:8; 2 Kọ́ríńtì 2:17) Nínú ẹjọ́ tí a dá Murdock, Ilé Ẹjọ́ náà gbà pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sọ pé bíbèèrè pé kí wọ́n kọ́kọ́ san owó ìwé àṣẹ fún pípín ìwé ẹ̀sìn ta ko òfin ilẹ̀ náà.b Ìdájọ́ yìí gbé ìpinnu tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn mọ́ kalẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí sì ti ṣàṣeyọrí nínú títọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹjọ́ láti ìgbà náà wá. Ẹjọ́ tí a dá Murdock ti jẹ́ ìpinnu tí ó lágbára nínú odi òfin tí ń pèsè ààbò.
Irú àwọn ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ti ṣèrànwọ́ gidigidi láti dáàbò bo òmìnira ẹ̀sìn fún gbogbo ènìyàn. Nípa ìrànwọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe fún jíjà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn aráàlú ní United States, ìwé University of Cincinnati Law Review wí pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti nípa pàtàkì lórí ìdàgbàsókè àgbékalẹ̀ òfin, ní pàtàkì nípa mímú kí ààbò púpọ̀ sí i wà fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ti ẹ̀sìn.”
Mímú Kí Odi Náà Lágbára Sí I
Ìṣẹ́gun nínú ẹjọ́ kọ̀ọ̀kan ń mú kí odi náà lágbára sí i. Gbé díẹ̀ lára àwọn ìdájọ́ tí ó wáyé ní àwọn ọdún 1990 yẹ̀ wò tí ó ti ṣàǹfààní fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn òmìnira jákèjádò ayé.
Gíríìsì. Ní May 25, 1993, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn gbé ẹ̀tọ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan láti fi àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀ kọ́ àwọn ẹlòmíràn lárugẹ. Ẹjọ́ náà kan Minos Kokkinakis, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láti ọdún 1938, ó ti lé ní ọgọ́ta ìgbà tí a ti fàṣẹ ọba mú Kokkinakis, a ti gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Gíríìsì nígbà méjìdínlógún, ó sì ti lo ohun tí ó ju ọdún mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. A ti dá a lẹ́bi ní pàtàkì, lábẹ́ òfin tí ilẹ̀ Gíríìsì gbé kalẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, tí ó ka ìsọnidaláwọ̀ṣe léèwọ̀—òfin kan tí ó mú kí a fàṣẹ ọba mú nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan (20,000) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láàárín ọdún 1938 sí 1992. Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì ti tẹ òmìnira ẹ̀sìn Kokkinakis lójú, ó sì ní kí wọ́n san owó gbà-máà-bínú tí ó tó 14,400 dọ́là fún un. Nínú ìdájọ́ rẹ̀, Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ “ẹ̀sìn tí a mọ̀ dunjú.”—Wo Ilé Ìsọ́nà September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31.
Mexico. Ní July 16, 1992, a gbé ìgbésẹ̀ ńlá kan nínú jíjà fún òmìnira ẹ̀sìn ní Mexico. Lọ́jọ́ yẹn, a gbé Òfin Kíkẹ́gbẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Ètò Ẹ̀sìn àti Jíjọ́sìn Ní Gbangba kalẹ̀. Nípasẹ̀ òfin yìí, ètò ẹ̀sìn kan lè di ipò kan mú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn lọ́nà òfin, nípa fíforúkọ ẹ̀sìn náà sílẹ̀ lọ́nà tí òfin béèrè. Ṣáájú àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ẹ̀sìn mìíràn tó wà ní orílẹ̀-èdè náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lóòótọ́, ṣùgbọ́n òfin ká wọn lọ́wọ́ kò. Ní April 13, 1993, Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀wé fún ìforúkọ-ẹ̀sìn-sílẹ̀. Ó dùn mọ́ni pé, ní May 7, 1993, a forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí La Torre del Vigía A. àti Los Testigos de Jehová en México, A. R., ẹgbẹ́ méjèèjì yìí sì jẹ́ ti ẹ̀sìn.—Wo Jí!, July 22, 1994, ojú ìwé 12 sí 14.
Brazil. Ní November 1990, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ààbò Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà Nílẹ̀ Brazil sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society pé a kò ní máa fojú àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn wo àwọn òjíṣẹ́ olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n wà ní Bẹ́tẹ́lì (orúkọ tí a fún àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà), nípa bẹ́ẹ̀ wọn yóò wà lábẹ́ òfin àwọn òṣìṣẹ́ ti ilẹ̀ Brazil. Àwọn Ẹlẹ́rìí pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ní June 7, 1996, Ìgbìmọ̀ Afúnni-nímọ̀ràn ti Ọ́fíìsì Adájọ́ Àgbà nílùú Brasília ṣe ìpinnu kan tí ó sọ pé àwọn ka àwọn òjíṣẹ́ tí ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sí mẹ́ńbà òjíṣẹ́ ẹ̀sìn, wọn kì í ṣe àwọn òṣìṣẹ́ tí ń gbowó oṣù.
Japan. Ní March 8, 1996, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Japan gbé ìpinnu kan kalẹ̀ lórí ọ̀ràn ètò ẹ̀kọ́ àti òmìnira ẹ̀sìn—fún àǹfààní gbogbo ènìyàn ní Japan. Ilé ẹjọ́ náà fẹnu kò pé ilé ẹ̀kọ́ Kobe Municipal Industrial Technical College tẹ òfin lójú nípa lílé Kunihito Kobayashi kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ náà, nítorí tí ó kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí eré ìgbèjà ara ẹni. Ìdájọ́ yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jú Lọ náà yóò ṣe ìpinnu kan tí a gbé karí òmìnira ẹ̀sìn tí Òfin ilẹ̀ Japan tì lẹ́yìn. Nítorí tí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí yìí tẹ̀ lé ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí a ti fi Bíbélì kọ́, ó gbà pé àwọn eré ìgbèjà ara ẹni wọ̀nyí kò bá àwọn ìlànà Bíbélì irú èyí tí a rí nínú Aísáyà 2:4 mu, èyí tí ó sọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ náà gbé ìdájọ́ kan tí ó ṣeé lò nínú ẹjọ́ mìíràn lọ́jọ́ iwájú kalẹ̀.—Wo Ilé Ìṣọ́, November 1, 1996, ojú ìwé 19 sí 21.
Ní February 9, 1998, Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Tokyo gbé ìpinnu pàtàkì mìíràn kalẹ̀, tí ó gbé ẹ̀tọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Misae Takeda lárugẹ, pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ìtọ́jú ìṣègùn tí kò bá àṣẹ Bíbélì láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’ mu. (Ìṣe 15:28, 29) Wọ́n ti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórí ọ̀ràn yìí, a ń wò ó bóyá ilé ẹjọ́ yìí yóò fara mọ́ ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga.
Philippines. Nínú ìpinnu kan tí a gbé kalẹ̀ ní March 1, 1993, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Philippines fẹnu kò pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jàre nínú ẹjọ kan tí ó kan àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí a lé kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ nítorí pé wọ́n fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ̀ láti kí àsíá.
Ìdáláre kọ̀ọ̀kan láti ilé ẹjọ́ jẹ́ òkúta tàbí bíríkì mìíràn tí ń sọ odi òfin náà di alágbára, èyí tó jẹ́ pé kì í ṣe ẹ̀tọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń dáàbò bò ṣùgbọ́n ó ń dáàbò bo ti gbogbo ènìyàn.
Dídáàbò Bo Odi Náà
A ti fi orúkọ ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní àwọn ilẹ̀ mẹ́tàléláàádọ́jọ (153), wọ́n sì ń fi ẹ̀tọ́ gbádùn òmìnira ẹ̀sìn púpọ̀ bí ti àwọn ẹ̀sìn mìíràn tí a mọ̀ lábẹ́ òfin. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún inúnibíni àti ìfòfindè ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti ní Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, a ti ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹ̀sìn tó bófin mu nísinsìnyí ní àwọn orílẹ̀-èdè bí Albania, Belarus, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, Georgia, Hungary, Kazakstan, Kyrgyzstan, Romania, àti Slovakia. Àmọ́, ní àwọn ilẹ̀ kan lónìí, títí kan àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù tí ó ti ní ètò ìdájọ́ tí wọ́n ti gbé kalẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ṣì ń pe ẹ̀tọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níjà tàbí kí a fi dù wọ́n. Àwọn alátakò ń jà fitafita láti “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjọ̀ngbọ̀n” fún Àwọn Ẹlẹ́rìí. (Sáàmù 94:20) Kí ni wọ́n wá ṣe?c
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìjọba, ṣùgbọ́n wọ́n tún fẹ́ ní òmìnira ẹ̀sìn láti lè máa bá ìjọsìn wọn lọ. Wọ́n gbà láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé, òfin èyíkéyìí tàbí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tí ó bá ní kí wọ́n má ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run—tí ó ní nínú àṣẹ láti wàásù ìhìn rere—kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Máàkù 13:10) Bí kò bá ní sí ìfohùnṣọ̀kan ní ìtùnbí-ìnùbí, ohun tó bá máa gbà lábẹ́ òfin ní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fún un, wọn yóò lo gbogbo àǹfààní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó bá pọndandan láti rí i pé àwọn gba ààbò lábẹ́ òfin fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run fún wọn láti máa bá ìjọsìn wọn lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú ìlérí Ọlọ́run pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”—Aísáyà 54:17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àkọsílẹ̀ ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, jọ̀wọ́ wo orí 30 nínú ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
b Nínú ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá Murdock, ilé ẹjọ́ náà yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí ọ̀ràn Jones pẹ̀lú Ìlú Opelika. Nínú ẹjọ́ Jones, ní ọdún 1942, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbà pẹ̀lú ìdájọ́ kóòtù kékeré tí ó dá Rosco Jones, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lẹ́bi, fún lílọ́wọ́ tí ó lọ́wọ́ nínú pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri òpópónà Opelika, Alabama, láìgba ìwé àṣẹ.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “A Kórìíra Wọn Nítorí Ìgbàgbọ́ Wọn” àti “Gbígbèjà Ìgbàgbọ́ Wa,” ní ojú ìwé 8 sí 18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Jíjà Fẹ́tọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Inúnibíni tí a ń ṣe sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yọrí sí fífà wọ́n lọ síwájú àwọn adájọ́ àti àwọn lọ́gàá lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba yíká ayé. (Lúùkù 21:12, 13) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe gudugudu méje láti rí i pé àwọn jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn lọ́nà òfin. Ìṣẹ́gun nílé ẹjọ́ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo òmìnira Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin, títí kan ẹ̀tọ́ wọn láti:
◻ wàásù láti ilé dé ilé láìjẹ́ kì òfin tí a fi de àwọn olùtajà oníṣòwò gbún wọn rárá—Murdock pẹ̀lú àjọ Commonwealth ti Pennsylvania, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti United States (1943); Kokkinakis pẹ̀lú ilẹ̀ Gíríìsì, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn (1993).
◻ lómìnira láti péjọ pọ̀ fún ìjọsìn—Manoussakis àti Àwọn Mìíràn pẹ̀lú ilẹ̀ Greece, ECHR (1996).
◻ pinnu bí ẹ̀rí-ọkàn wọn ṣe lè yọ̀ǹda fún wọn láti bọ̀wọ̀ fún àsíá tàbí àmì orílẹ̀-èdè—Ẹ̀ka Ètò Ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ West Virginia àti Barnette, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Amẹ́ríkà (1943); Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Philippines (1993); Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti India (1986).
◻ kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun tí kò bá ẹ̀rí-ọkàn Kristẹni wọn mu—Georgiadis pẹ̀lú ilẹ̀ Gíríìsì, ECHR (1997).
◻ yan ìtọ́jú àti ìṣègùn tó bá ẹ̀rí-ọkàn wọn mu—Malette pẹ̀lú Shulman, Ontario, Kánádà, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn (1990); Watch Tower pẹ̀lú E.L.A., Ilé Ẹjọ́ Gíga, San Juan, Puerto Rico (1995); Fosmire pẹ̀lú Nicoleau, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti New York, ilẹ̀ Amẹ́ríkà (1990).
◻ fi ìgbàgbọ́ tí a gbé ka Bíbélì tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, àní, nígbà tí ọ̀ràn ẹni tí ọmọ yóò máa gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ bá mú kí a ka ìgbàgbọ́ yìí sí ohun tí kò tọ́—St-Laurent pẹ̀lú Soucy, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà (1997); Hoffmann pẹ̀lú Austria, ECHR (1993).
◻ ní ẹgbẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ tí ń jàǹfààní owó orí gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn tí a mọ̀ sí ti ẹ̀sìn àti láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ yìí máa ṣojú fún wọn—People pẹ̀lú Haring, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti New York, United States of America (1960).
◻ jẹ́ kí àwọn kan tí a yàn sí oríṣi àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa jàǹfààní àjẹmọ́nú ti owó orí gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún ti ẹ̀sìn mìíràn—Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ààbò Ẹgbẹ́ Òun Ọgbà Nílẹ̀ Brazil, Brasília, (1996).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Minos Kokkinakis pẹ̀lú aya rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Kunihito Kobayashi
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck