ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kr orí 13 ojú ìwé 134-147
  • Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Oníjàngbọ̀n Ni Wá àbí Alágbàwí Ìjọba Ọlọ́run?
  • Ṣé À Ń Ṣọ̀tẹ̀ sí Ìjọba Ni àbí À Ń Kéde Òtítọ́?
  • Ṣé Oníṣòwò Tó Ń Kiri Ọjà Ni Wá àbí Ṣe Là Ń Fìtara Polongo Ìjọba Ọlọ́run?
  • “Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”
  • “Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”
  • Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ
    Jí!—2003
  • “Ìjà Ogun Náà Kì í Ṣe Tiyín, Bí Kò Ṣe Ti Ọlọ́run”
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
kr orí 13 ojú ìwé 134-147

ORÍ 13

Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn máa lo òfin láti ṣe àtakò sí iṣẹ́ ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀

1, 2. (a) Kí ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe sí iṣẹ́ ìwàásù? Àmọ́ kí ni àwọn àpọ́sítélì ṣe? (b) Kí nìdí tí àwọn àpọ́sítélì fi kọ̀ láti dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró?

ÌṢẸ̀LẸ̀ kan wáyé láìpẹ́ lẹ́yìn àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ìjọ tí wọ́n dá sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù kò tíì ju ọ̀sẹ̀ mélòó kan péré lọ nígbà yẹn. Ó dájú pé Sátánì wò ó pé àsìkò náà ló máa dáa jù láti gbógun ti ìjọ náà. Ṣe ló fẹ́ tú u ká kó tó di pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Kíá ni Sátánì wá ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan dá tó fi mú kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ní tiwọn kò dáwọ́ dúró, wọ́n ń fìgboyà wàásù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ló sì di “onígbàgbọ́ nínú Olúwa.”—Ìṣe 4:18, 33; 5:14.

Àwọn àpọ́sítélì Kristi ń yọ̀ bí wọ́n ṣe ń kúrò níwájú ìgbìmọ̀ Sanhedrin lẹ́yìn tí wọ́n ti nà wọ́n

Àwọn àpọ́sítélì “yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀”

2 Èyí bí àwọn alátakò nínú gan-an, ni wọ́n bá tún gbógun dìde. Lọ́tẹ̀ yìí gbogbo àwọn àpọ́sítélì ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní òru, ańgẹ́lì Jèhófà ṣí ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà, nígbà tílẹ̀ fi máa mọ́, àwọn àpọ́sítélì tún ti ń wàásù nígboro! Ni wọ́n bá tún mú wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọn kò tẹ̀ lé àṣẹ tó sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù. Àwọn àpọ́sítélì fìgboyà fèsì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” Inú bí àwọn aláṣẹ náà débi pé wọ́n ‘ń fẹ́ láti pa àwọn àpọ́sítélì.’ Àmọ́ lásìkò tíná ọ̀rọ̀ yẹn jó dórí kókó, Gàmálíẹ́lì, tó jẹ́ olùkọ́ Òfin táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gan-an sọ èrò rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fáwọn aláṣẹ náà pé: “Ẹ kíyè sí ara yín. . . Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́.” Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn aláṣẹ yìí gba ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì, wọ́n sì tú àwọn àpọ́sítélì sílẹ̀. Kí wá ni àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ṣe? Wọn kò bẹ̀rù, àmọ́ wọ́n “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:17-21, 27-42; Òwe 21:1, 30.

3, 4. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì ṣì ń lò bíi ti àtijọ́ láti ṣe àtakò sáwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Kí ni orí yìí àti orí méjì tó tẹ̀ lé e máa dá lé?

3 Ẹjọ́ tó wáyé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn alátakò máa gbógun dìde sí ìjọ Kristẹni, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò mọ síbẹ̀ rárá. (Ìṣe 4:5-8; 16:20; 17:6, 7) Lásìkò wa yìí, Sátánì ṣì ń lo àwọn alátakò ìjọsìn tòótọ́ láti mú kí àwọn aláṣẹ fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Oríṣiríṣi ẹ̀sùn làwọn alátakò ti fi kan àwa èèyàn Ọlọ́run. Lára rẹ̀ ni pé oníjàngbọ̀n ni wá. Wọ́n tún pè wá ní ọlọ̀tẹ̀. Wọ́n sì tún sọ pé oníṣòwò tó ń kiri ọjà ni wá. Àwọn ará wa máa ń lọ sílé ẹjọ́ nígbà tó bá yẹ láti járọ́ àwọn tó fẹ̀sùn kàn wá. Ibo lọ̀rọ̀ àwọn ẹjọ́ náà parí sí? Ipa wo ni àwọn ẹjọ́ tí wọ́n dá lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn lè ní lórí rẹ lónìí? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ bíi mélòó kan, ká lè rí bí wọ́n ṣe jẹ́ ká lè máa ‘gbèjà ìhìn rere, ká sì máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílí. 1:7.

4 Nínú orí yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe jà fún ẹ̀tọ́ tá a ní láti máa wàásù láìsí ìdíwọ́. Àwọn orí méjì tó kàn máa jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tá a ti gbé lọ sílé ẹjọ́ torí pé a ò fẹ́ jẹ́ apá kan ayé, a sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìjọba Ọlọ́run.

Ṣé Oníjàngbọ̀n Ni Wá àbí Alágbàwí Ìjọba Ọlọ́run?

5. Kí nìdí tí wọ́n fi mú àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ní ọdún 1937 sí 1939? Kí sì ni àwọn tó múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà?

5 Ní ọdún 1937 sí 1939 àwọn ìlú àtàwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá bí wọ́n ṣe fẹ́ fipá mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gba ìwé àṣẹ ká tó lè máa wàásù. Ṣùgbọ́n àwọn ará wa kò gba ìwé àṣe náà. Ìgbàkigbà ni ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé ìwé àṣẹ tí wọ́n bá fúnni, àwọn ará sì gbà gbọ́ pé kò sí ìjọba tó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí àwa Kristẹni má ṣe pa àṣẹ Jésù mọ́ láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 13:10) Torí náà, ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n mú. Àwọn tó múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run wá wò ó pé ó yẹ káwọn gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Wọ́n fẹ́ fi hàn pé bí ìjọba kò ṣe jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn fàlàlà kò bófin mú. Lọ́dún 1938 ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí ẹjọ́ mánigbàgbé kan wáyé. Kí lohun náà?

6, 7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìdílé Arákùnrin Cantwell?

6 Ní àárọ̀ ọjọ́ Tuesday, April 26, 1938, Arákùnrin Newton Cantwell, tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta [60] ọdún àti ìyàwó rẹ̀ Esther pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ọkùnrin mẹ́ta tó ń jẹ́ Henry, Russell àti Jesse jáde láti lọ wàásù ní ìlú New Haven, ìpínlẹ̀ Connecticut lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni àwọn márààrún. Wọ́n ti múra sílẹ̀ pé àwọn lè má pa dà wálé lọ́jọ́ yẹn. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọlọ́pàá ti mú wọn rí, torí náà wọ́n wò ó pé wọ́n tún lè mú àwọn. Àmọ́ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ yìí kò paná ìtara wọn láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ọkọ̀ méjì ni wọ́n gbé lọ sí ìlú New Haven. Arákùnrin Cantwell ló wa ọkọ̀ ìdílé wọn, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ẹ̀rọ giramafóònù sì wà nínú rẹ̀. Henry tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún [22] ló wa ọkọ̀ tí wọ́n so ẹ̀rọ gbohùngbohùn mọ́. Bí wọ́n ṣe rò ó gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí. Kò ju wákàtí mélòó kan lọ tí àwọn ọlọ́pàá dá wọn dúró.

7 Russell tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni wọ́n kọ́kọ́ mú. Lẹ́yìn náà wọ́n mú àwọn òbí wọn. Jesse tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ń wo àwọn ọlọ́pàá náà láti ọ̀ọ́kán bí wọ́n ṣe ń mú àwọn òbí rẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Apá ibòmíì ní ìlú yẹn ni Henry ti ń wàásù ní tiẹ̀, torí náà Jesse tó jẹ́ àbúrò pátápátá nìkan ló ṣẹ́ kù síbi tó wà. Àmọ́ Jesse gbé ẹ̀rọ giramafóònù rẹ̀, ó sì ń wàásù lọ. Àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì gbọ́ àsọyé Arákùnrin Rutherford látorí ẹ̀rọ giramafóònù tí Jesse gbé dání. Àkòrí rẹ̀ ni “Àwọn Ọ̀tá.” Bí wọ́n ṣe ń gbọ́ àsọyé náà lọ, inú bí wọn gan-an débi pé wọ́n fẹ́ lu Jesse. Ó sì rọra kúrò lọ́dọ̀ wọn, àmọ́ bó ṣe rìn síwájú díẹ̀, ọlọ́pàá kan dá a dúró. Bí Jesse náà ṣe wọ àtìmọ́lé nìyẹn o. Àwọn ọlọ́pàá kò fi ẹ̀sùn kankan kan Arábìnrin Cantwell, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́ ọjọ́ yẹn ni wọ́n tú wọn sílẹ̀ láti ṣe ẹjọ́ wọn nígbà tó bá yá.

8. Kí nìdí tí ilé ẹjọ́ fi dá Jesse Cantwell lẹ́bi pé ó jẹ́ oníjàngbọ̀n?

8 Ní September 1938 tí kò ju oṣù mélòó kan lọ lẹ́yìn náà, ìdílé Cantwell wá jẹ́jọ́ ní kóòtù ìlú New Haven. Ilé ẹjọ́ dá Russell, Jesse àti bàbá wọn lẹ́bi pé wọ́n ń gba ọrẹ láìní ìwé àṣẹ. Láìka ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí a pè sí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ìpínlẹ̀ Connecticut dá Jesse lẹ́bi pé ó jẹ́ oníjàngbọ̀n, ó sì ń dá wàhálà sílẹ̀. Ìdí ni pé àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí wọ́n gbọ́ àsọyé lórí giramafóònù rẹ̀ wá jẹ́rìí ní kóòtù pé àsọyé náà kan ẹ̀sìn àwọn lábùkù, ó sì mú àwọn bínú. Láti fi hàn pé àwọn kò fara mọ́ ìdájọ́ yìí, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ ilé ẹjọ́ tó láṣẹ jù lórílẹ̀-èdè náà.

9, 10. (a) Ìdájọ́ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìdílé Arákùnrin Cantwell? (b) Àwọn àǹfààní míì wo ni ìdájọ́ yìí tún ṣe fún wa?

9 Bẹ̀rẹ̀ láti March 29, ọdún 1940, Adájọ́ Àgbà Charles E. Hughes àtàwọn adájọ́ mẹ́jọ míì tẹ́tí gbọ́ àlàyé Arákùnrin Hayden Covington, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.a Nígbà tí agbẹjọ́rò ìjọba ìpínlẹ̀ Connecticut rojọ́ láti fìdí ẹ̀sùn náà múlẹ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ oníjàngbọ̀n, ọ̀kan lára àwọn adájọ́ náà bi í pé: “Ṣebí àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù Kristi Jésù nígbà tó wà láyé?” Agbẹjọ́rò náà fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, tí n bá sì rántí ohun tí Bíbélì mi sọ dáadáa, ó tún sọ ohun tí wọ́n ṣe fún Jésù torí ìwàásù tó ṣe.” Ẹ ò rí i pé ṣe ló rojọ́ mọ́ra ẹ̀ lọ́rùn! Agbẹjọ́rò náà kò fura pé ṣe ni òun ń fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló dà bí Jésù, nígbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ dà bí àwọn ọ̀tá tó dá Jésù lẹ́bi. Ní May 20, 1940, ilé ẹjọ́ náà dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń yọ̀ bí wọ́n ṣe ń kúrò nílé ẹjọ́, Hayden Covington àti Glen How, wà lára wọn

Hayden Covington (àárín níwájú), Glen How (lápá òsì), àtàwọn yòókù tí wọ́n jọ jáde nílé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn láre

10 Kí ni ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí wá mú kó ṣeé ṣe? Ó jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tá a ní láti máa ṣe ìjọsìn wa. Tó fi jẹ́ pé ìjọba àpapọ̀, ti ìpínlẹ̀ tàbí ìjọba ìbílẹ̀ èyíkéyìí kò ní lè fi òfin dí wa lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run. Ilé ẹjọ́ sì tún fi hàn pé ohun tí Jesse ṣe “kò dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́ lọ́nàkọnà.” Ìdájọ́ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fa ìdàrúdàpọ̀ láàárín ìlú. Bí ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre yìí pa àwọn alátakò àwa èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu mọ́! Àwọn àǹfààní míì wo ni ìdájọ́ yìí tún ṣe fún wa? Agbẹjọ́rò kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ẹ̀tọ́ tí a ní láti ṣe ẹ̀sìn wa láìsí ìbẹ̀rù pé wọ́n máa dí wa lọ́wọ́ láìyẹ ti mú kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní lè máa sọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìrètí fún àwọn tí a jọ ń gbé àgbègbè kan náà.”

Ṣé À Ń Ṣọ̀tẹ̀ sí Ìjọba Ni àbí À Ń Kéde Òtítọ́?

Èèpo iwájú ìwé àṣàrò kúkúrú náà Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada

Àṣàrò kúkúrú Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada tí wọ́n fi tú àṣírí ìwà àìtọ́ ní àgbègbè Quebec

11. Ìwé wo ni àwọn ará wa pín lórílẹ̀-èdè Kánádà? Kí sì nìdí?

11 Ní ọdún 1941 sí 1949, àwọn èèyàn ṣe àtakò tó gbóná janjan sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kánádà. Torí náà lọ́dún 1946, àwọn ará wa fi ọjọ́ mẹ́rìndínlógún [16] pín ìwé àṣàrò kúkúrú kan tí wọ́n fi tú àṣírí bí ìjọba ṣe fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n láti ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n fẹ́ ní àgbègbè Quebec. Àkọlé rẹ̀ ni, Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada. Ìwé àṣàrò kúkúrú olójú ewé mẹ́rin yìí tú àṣírí bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe dá rògbòdìyàn sílẹ̀, bí àwọn ọlọ́pàá ṣe hùwà ìkà sí àwọn ará àti bí àwọn èèyàn ṣe dáwọ́ jọ lu àwọn ará wa ní àgbègbè Quebec. Ìwé náà sọ pé: “Àwọn ọlọ́pàá ò yé mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìbófinmu. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ẹ̀sùn ni wọ́n fi kàn wá ní ìlú Greater Montreal.”

12. (a) Báwo ni àwọn alátakò ṣe fèsì ìwé àṣàrò kúkúrú náà? (b) Ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan àwọn ará wa? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

12 Ọ̀gbẹ́ni Maurice Duplessis tó jẹ́ olórí ìjọba àgbègbè Quebec, lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Kádínà tó ń jẹ́ Villeneuve ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti fèsì ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ó sọ pé “ogun láìsí ojú àánú” lòun máa bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jà. Kíá ni iye ọ̀ràn tó wà nílé ẹjọ́ di ìlọ́po méjì látorí ẹgbẹ̀rin [800] sí ẹgbẹ̀jọ [1,600]. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan sọ pé: “Iye ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá mú wa pọ̀ débi pé a ò lè kà á mọ́.” Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú níbi tí wọ́n ti ń pín àṣàrò kúkúrú náà pé “ìwé ọ̀tẹ̀” ni wọ́n ń pín.b

13. Àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ gbé lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀? Ìdájọ́ wo ni ilé ẹjọ́ sì ṣe?

13 Ní ọdún 1947, Arákùnrin Aimé Boucher àti ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì ni wọ́n kọ́kọ́ gbé lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀. Gisèle, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni ẹ̀gbọ́n nígbà tí Lucille, ọmọ ọdún mọ́kànlá [11] jẹ́ àbúrò. Wọ́n ti pín ìwé àṣàrò kúkúrú Quebec’s Burning Hate nítòsí oko wọn tó wà níbi àwọn òkè ní gúúsù ìlú Quebec City. Àmọ́ àwọn èèyàn kò lè pè wọ́n ní arúfin tàbí oníjàngbọ̀n. Ìdí sì ni pé, ẹni jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Arákùnrin Boucher, ó ní ilẹ̀ kékeré kan tó fi ń dáko, ó sì máa ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin lọ sí ìgboro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀síbẹ̀, òun àti ìdílé rẹ̀ wà lára àwọn tó fojú winá àwọn kan nínú ìwàkiwà tí a sọ nínú àṣàrò kúkúrú náà. Àmọ́, adájọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ náà kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà ó kọ̀ láti gbà pé ìdílé Arákùnrin Boucher kò jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó mú ẹ̀sùn wá pé àṣàrò kúkúrú náà ń dá àtakò sílẹ̀, ó sì dá ìdílé náà lẹ́bi. Ohun tí ìdájọ́ náà túmọ̀ sí ni pé: Kò bófin mú láti máa sọ òtítọ́! Ilé ẹjọ́ dá Arákùnrin Boucher àti Gisèle lẹ́bi pé wọ́n ń pín ìwé ọ̀tẹ̀, kódà wọ́n tún fi Lucille tó kéré jù sí àtìmọ́lé ọjọ́ méjì. Àwọn ará pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ tí Orílẹ̀-Èdè Kánádà, tó ní àṣẹ jù lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì gbà láti gbọ́ ẹjọ́ náà.

14. Kí ni àwọn ará wa ní Quebec ṣe ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn?

14 Ní gbogbo ìgbà yẹn, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àgbègbè Quebec ń fi ìgboyà wàásù Ìjọba Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kò yéé ṣe àtakò líle koko sí wọn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni iṣẹ́ ìwàásù wọn ń so èso rere lọ́nà tó wúni lórí. Láàárín ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tá a bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ́dún 1946, iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgbègbè Quebec pọ̀ sí i látorí ọ̀ọ́dúnrún [300] sí ẹgbẹ̀rún kan [1,000]!c

15, 16. (a) Ìdájọ́ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Kánádà ṣe lórí ẹjọ́ ìdílé Arákùnrin Boucher? (b) Kí ni ìdájọ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ará wa àti àwọn ẹlòmíì?

15 Ní oṣù June 1950, gbogbo adájọ́ mẹ́sàn-án tó wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ tí Orílẹ̀-Èdè Kánádà, gbọ́ ẹjọ́ Arákùnrin Aimé Boucher. Ní December 18, 1950, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ilé ẹjọ́ dá wa láre. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Arákùnrin Glen How, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé ilé ẹjọ́ fara mọ́ àlàyé tí a ṣe pé “ọlọ̀tẹ̀” ni ẹni tó ń sún àwọn èèyàn hùwà ipá tàbí tó ń dìtẹ̀ ìjọba. Àmọ́ “kò sí ọ̀rọ̀ tó ń múni hu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀” nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “torí náà òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé náà kò tàpá sí òfin.” Ó fi kún un pé: “Mo fojú ara mi rí bí Jèhófà ṣe mú kí wọ́n dá wa láre.”d

16 Ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí mú kí Ìjọba Ọlọ́run borí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó tún sọ àwọn ẹjọ́ méjìlélọ́gọ́fà [122] míì di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀, ìyẹn àwọn ẹjọ́ tó dá lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè Quebec pé à ń pín ìwé ọ̀tẹ̀. Síwájú sí i, ìdájọ́ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Kánádà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtijọ́ ní òmìnira láti sọ èrò wọn bí ohun tí ìjọba ṣe kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn. Yàtọ̀ síyẹn, ìdájọ́ yìí rẹ́yìn àtakò tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba àgbègbè Quebec ṣe sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.e

Ṣé Oníṣòwò Tó Ń Kiri Ọjà Ni Wá àbí Ṣe Là Ń Fìtara Polongo Ìjọba Ọlọ́run?

17. Kí ni àwọn ìjọba kan máa ń fẹ́ ṣe sí iṣẹ́ ìwàásù wa?

17 Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 2:17.) Síbẹ̀, àwọn ìjọba kan máa ń fẹ́ fi àwọn òfin tó ń darí káràkátà de iṣẹ́ ìwàásù wa. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára àwọn ẹjọ́ tó dá lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá pé ọjà là ń tà kiri, pé a kì í ṣe oníwàásù.

18, 19. Kí ni àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Denmark ṣe láti dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́?

18 Orílẹ̀-Èdè Denmark. Ní October 1, 1932, wọ́n ṣe òfin kan pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ta ìwé èyíkéyìí láìgba ìwé àṣẹ tó wà fún àwọn tó ń kiri ọjà. Àmọ́ àwọn ará wa kò gba ìwé àṣe náà. Lọ́jọ́ kejì, akéde márùn-ún lọ wàásù látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ní ìlú Roskilde, tó wà ní ọgbọ̀n [30] kìlómítà lápá ìwọ̀ oòrùn ìlú Copenhagen, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tílẹ̀ fi máa ṣú, wọ́n wá Arákùnrin August Lehmann tì. Àwọn ọlọ́pàá ti mú un pé ó ń tajà láìgba ìwé àṣẹ.

19 Ní December 19, 1932, ọ̀rọ̀ yìí dé ilé ẹjọ́. Arákùnrin August Lehmann sọ nílé ẹjọ́ pé òótọ́ ni òun lọ fi ìwé tó dá lórí Bíbélì lọ àwọn èèyàn, àmọ́ òun kò tajà. Ilé ẹjọ́ sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kan yìí . . . ń rí owó gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, kò sì gba owó ìrànwọ́ èyíkéyìí tàbí kó gbèrò láti lọ gbà á, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló tún ń náwó ara rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe.” Ilé ẹjọ́ gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sọ pé ‘kò yẹ kí wọ́n pe iṣẹ́ ìwàásù tí Arákùnrin Lehmann ń ṣe ní òwò.’ Síbẹ̀ àwọn ọ̀tá àwa èèyàn Ọlọ́run kò dáwọ́ àtakò dúró, wọ́n ṣì ń dí wa lọ́wọ́ iṣẹ́ ìwàásù ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà. (Sm. 94:20) Agbẹjọ́rò àwọn tó pè wá lẹ́jọ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Kí ni àwọn ará wá ṣe?

20. Ìdájọ́ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Denmark ṣe? Kí làwọn ará wa sì ṣe?

20 Ní ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè Denmark túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ilé ẹjọ́ náà kéde ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ Tuesday, October 3, 1933. Ó fara mọ́ ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ṣe pé Arákùnrin August Lehmann kò tẹ òfin kankan lójú. Ìdájọ́ yìí fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ láìsí ìdènà. Àwọn ará wa sì túbọ̀ koná mọ́ iṣẹ́ ìwàásù láti fi hàn pé àwọn mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n jàre ẹjọ́ yìí. Bí ilé ẹjọ́ yẹn ṣe dá wa láre ti mú kí àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Denmark lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ látìgbà yẹn láìsí pé ìjọba ń dí wọn lọ́wọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Denmark tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ pẹ̀lú páálí fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ lọ́wọ́ wọn ní ọdún 1930 sí 1939

Àwọn Ẹlẹ́rìí onígboyà ní Denmark ní 1930 sí 1939

21, 22. Ìdájọ́ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe lórí ẹjọ́ Arákùnrin Murdock?

21 Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ọlọ́pàá mú Arákùnrin Robert Murdock Kékeré tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn ará wa míì tí wọ́n jẹ́ méje ní ọjọ́ Sunday, February 25, 1940. Ẹnu iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n wà ní Jeannette nítòsí ìlú Pittsburgh, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Ilé ẹjọ́ dá wọn lẹ́bi lórí ẹ̀sùn pé wọn kò gba ìwé àṣẹ kí wọ́n tó máa fi ìwé lọ àwọn èèyàn. Nígbà tí wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbà láti gbọ́ ẹjọ́ náà.

22 Ní May 3, 1943, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kéde ìdájọ́ rẹ̀, ó sì gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilé ẹjọ́ náà kò fara mọ́ ọn pé ká gba ìwé àṣẹ torí ṣe ni ìyẹn á mú ká máa “sanwó ká tó lè lo ẹ̀tọ́ tí Òfin Ìjọba Àpapọ̀ fẹ́ kí kálùkù máa gbádùn.” Ilé Ẹjọ́ náà fagi lé àṣẹ ìlú Jeannette, ó ní “ó dí òmìnira tí àwọn òǹtẹ̀wé ìròyìn ní lábẹ́ òfin lọ́wọ́, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn lè ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n.” Nígbà tí Adájọ́ Justice William O. Douglas ń ka ìpinnu tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn adájọ́ náà fara mọ́, ó sọ pé ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe “kọjá wíwàásù; ó sì kọjá pínpín ìwé ìsìn kiri. Méjèèjì ni wọ́n ń ṣe pa pọ̀.” Ó fi kún un pé: “Bí àwọn èèyàn ṣe ka ìjọsìn ṣọ́ọ̀ṣì àti ìwàásù tí wọ́n ń gbọ́ níbẹ̀ sí pàtàkì . . . ló ṣe yẹ kí wọ́n ka ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sí pàtàkì.”

23. Kí nìdí tí a fi lè sọ pé àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀ lọ́dún 1943 ṣe wá láǹfààní lónìí?

23 Mánigbàgbé ni ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí jẹ́ fún àwa èèyàn Ọlọ́run. Ó jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ irú ẹni tí a jẹ́ gan-an, pé òjíṣẹ́ Kristẹni ni wá, a kì í ṣe oníṣòwò tó ń kiri ọjà. Ní ọjọ́ tí à ń wí yìí lọ́dún 1943, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jàre méjìlá lára ẹjọ́ mẹ́tàlá tó kàn wá ní ilé ẹjọ́ náà, títí kan ẹjọ́ Arákùnrin Murdock. Àwọn ìdájọ́ yìí ti fún wa lọ́rọ̀ sọ gan-an lórí àwọn ẹjọ́ míì tó tún wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tí àwọn alátakò tún gbógun dìde pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”

24. Kí la máa ń ṣe tí ìjọba bá fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa?

24 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń mọyì rẹ̀ gan-an tí ìjọba bá fún wa ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ká lè máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run ní fàlàlà. Àmọ́ tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, a máa ń yíwọ́ pa dà ká lè máa bá iṣẹ́ náà lọ ní ọ̀nà èyíkéyìí tí a bá lè gbé e gbà. Bíi ti àwọn àpọ́sítélì, “àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29; Mát. 28:19, 20) Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, a máa ń gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè mú ìfòfindè náà kúrò. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì.

25, 26. Kí ló ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nicaragua tó mú ká gbé ẹjọ́ lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ? Ibo lọ̀rọ̀ náà sì yọrí sí?

25 Orílẹ̀-Èdè Nicaragua. Ní November 19, 1952, Arákùnrin Donovan Munsterman tó jẹ́ míṣọ́nnárì tó sì tún jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka lọ sí Ọ́fíìsì Ìjọba Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Àlejò ní ìlú Managua, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀gágun Arnoldo García tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ọ́fíìsì náà pa àṣẹ fún un pé kó wá. Ó sì sọ fún un pé àwọn ‘kò gba gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Nicaragua láyè mọ́ láti máa wàásù ẹ̀kọ́ ìsìn wọn tàbí kí wọ́n máa ṣe ìsìn.” Nígbà tí arákùnrin náà bi Ọ̀gágun náà pé kí ló fà á, ó sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba ìwé àṣẹ látọ̀dọ̀ mínísítà ìjọba láti máa wàásù, wọ́n sì tún fẹ̀sùn kàn wá pé alátìlẹyìn ìjọba Kọ́múníìsì ni wá. Àwọn wo ló fẹ̀sùn kàn wá? Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni.

Ní nǹkan bí  ọdún 1953, àwọn ará lórílẹ̀-èdè Nicaragua ń ṣe àpéjọ àgbègbè níta

Àwọn ará lórílẹ̀-èdè Nicaragua nígbà ìfòfindè

26 Kíá ni Arákùnrin Munsterman kọ̀wé sí Ọ́fíìsì Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn, ó sì tún kọ̀wé sí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Ààrẹ Anastasio Somoza García, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Torí náà, àwọn ará wa yíwọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan pa dà. Wọ́n ti Gbọ̀ngàn Ìjọba pa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé ní àwùjọ kéékèèké, wọn ò wàásù ní gbangba mọ́, àmọ́ wọ́n ṣì ń sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Nicaragua kó lè bá wọn wọ́gi lé ìfòfindè náà. Ọ̀rọ̀ nípa ìfòfindè náà àti ìwé tá a kọ sí ilé ẹjọ́ jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sì gbà láti gbọ́ ẹjọ́ náà. Ibo ló wá yọrí sí? Ní June 19, 1953, ilé ẹjọ́ náà kéde ìdájọ́ tí wọ́n fẹnu kò lé lórí, tó sì dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ìfòfindè yìí ta ko ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti sọ èrò wọn, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà láyè àti láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́. Ó tún pàṣẹ pé kí ìjọba ilẹ̀ Nicaragua jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa dà sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀.

27. Kí nìdí tí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ṣe fi ya àwọn tó wà nílẹ̀ Nicaragua lẹ́nu? Kí ló dá àwọn ará wa lójú pé ó mú ká lè jàre ẹjọ́ náà?

27 Ó ya àwọn tó wà nílẹ̀ Nicaragua lẹ́nu pé ilé ẹjọ́ náà gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kò jẹ́ kí ilé ẹjọ́ náà rímú mí débi pé ṣe ni ilé ẹjọ́ náà ń dọ́gbọ́n yẹra fún wàhálà wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó wà nípò àṣẹ ìjọba lágbára gan-an débi pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ilé ẹjọ́ máa ń lè ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ ó dá àwọn ará wa lójú pé bí Ọba wa ṣe ń dáàbò bò wá tí a kò sì dẹwọ́ iṣẹ́ ìwàásù ló jẹ́ ká lè jàre ẹjọ́ náà.—Ìṣe 1:8.

28, 29. Kí ló ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Zaire ní ọdún 1984 sí 1986 tó mú kí nǹkan yí pa dà?

28 Orílẹ̀-Èdè Zaire. Ní ọdún 1984 sí 1986, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì [35,000] Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lórílẹ̀-èdè Zaire, tí wọ́n ń pè ní Kóńgò báyìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè náà kọ́ àwọn ilé tuntun kan láfikún, kí wọ́n lè túbọ̀ máa bójú tó àwọn akéde tó ń pọ̀ sí i níbẹ̀. A ṣe àpéjọ àgbáyé kan ní December 1985, ní ìlú Kinshasa tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] ni iye àwọn tó pésẹ̀ sí pápá ìṣeré ìlú náà láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé. Àmọ́ nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Kí ló fà á?

29 Orílẹ̀-èdè Zaire ni Arákùnrin Marce Filteau, tó jẹ́ míṣọ́nnárì láti àgbègbè Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà wà nígbà yẹn. Ó ti fojú winá inúnibíni nígbà ìjọba Ọ̀gbẹ́ni Duplessis. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ pé: “Ní March 12, 1986, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú gba lẹ́tà kan tí ìjọba fi sọ pé wọ́n ti fi òfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Zaire.” Ọ̀gbẹ́ni Mobutu Sese Seko tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, ló buwọ́ lu ìwé ìfòfindè ọ̀hún.

30. Ìpinnu tó lágbára wo ló pọn dandan pé kí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Zaire ṣe? Ibo ni wọ́n sì parí èrò sí?

30 Lọ́jọ́ kejì, wọ́n kéde lórí rédíò ìjọba ilẹ̀ náà pé: “A kò ní gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nílẹ̀ [Zaire].” Bí inúnibíni ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn! Wọ́n ba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́, wọ́n ja àwọn ará wa lólè, wọ́n mú wọn, wọ́n lù wọ́n, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n, títí kan àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Ní October 12, 1988, ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun tó jẹ́ ti ètò Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè náà, ọ̀kan lára àwùjọ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ náà sì wá ń gbé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú kọ̀wé sí Ààrẹ Mobutu, àmọ́ kò fún wọn lésì. Èyí mú kó pọn dandan fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè náà láti ṣe ìpinnu kan tó lágbára, wọ́n ń wò ó pé “Ṣé ká pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ni, àbí ká ní sùúrù?” Arákùnrin Timothy Holmes, tó jẹ́ míṣọ́nnárì, tó sì tún jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka nígbà yẹn sọ pé: “Ojú Jèhófà là ń wò pé kó tọ́ wa sọ́nà kó sì fún wa ní ọgbọ́n.” Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ náà gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n wò ó pé kò tíì yá tí àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn ará tí wọ́n á sì máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó.

“Ní gbogbo ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà wà nílé ẹjọ́, a rí bí Jèhófà ṣe lè yí nǹkan pa dà”

31, 32. Ìdájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Zaire ṣe? Ipa wo sì ni èyí ní lórí àwọn ará wa?

31 Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, inúnibíni rọlẹ̀ díẹ̀, àwọn èèyàn sì túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè náà. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka wá pinnu pé àsìkò ti tó láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Zaire kí wọ́n lè mú ìfòfindè náà kúrò. Ó dùn mọ́ wa nínú gan-an pé ilé ẹjọ́ náà gbà láti gbọ́ ẹjọ́ ọ̀hún. Nígbà tó fi máa di January 8, 1993, nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn tí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà fòfin de iṣẹ́ wa, ilé ẹjọ́ sọ pé ohun tí ìjọba ṣe fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bófin mu rárá, wọ́n sì mú ìfòfindè náà kúrò. Ronú nípa ohun tí èyí túmọ̀ sí. Àwọn adájọ́ náà fi ẹ̀mí ara wọn wewu, wọ́n wọ́gi lé àṣẹ tí ààrẹ orílẹ̀-èdè pa! Arákùnrin Holmes sọ pé: “Ní gbogbo ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà wà nílé ẹjọ́, a rí bí Jèhófà ṣe lè yí nǹkan pa dà.” (Dán. 2:21) Bí wọ́n ṣe dá wa láre yìí mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará wa túbọ̀ lágbára. Wọ́n rí bí Jésù, Ọba wa ṣe darí àwa èèyàn rẹ̀ ká lè mọ ìgbà tó yẹ ká ṣe ohun kan àti bó ṣe yẹ ká ṣe é.

Arábìnrin méjì nígbà àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Democratic Republic of Congo

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Kóńgò ń dùn nígbà tí wọ́n ní òmìnira láti máa sin Jèhófà

32 Ìfòfindè tí wọ́n mú kúrò yìí mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti pe àwọn míṣọ́nnárì wá, láti kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun, kí wọ́n sì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè.f Ẹ wo bí inú àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé ṣe dùn tó láti rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí!—Aísá. 52:10.

“Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”

33. Kí la rí kọ́ látinú àwọn ẹjọ́ díẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò yìí?

33 Àwọn ẹjọ́ díẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé Jésù mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Èmi yóò fún yín ni ẹnu [tàbí ọ̀rọ̀] àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ kì yóò lè dúró tiiri lòdì sí tàbí bá ṣe awuyewuye.” (Ka Lúùkù 21:12-15.) Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà máa ń gbé àwọn kan dìde nígbà míì bíi Gàmálíẹ́lì òde òní láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí kó mú kí àwọn adájọ́ àti agbẹjọ́rò tó nígboyà jà fún ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Jèhófà ti sọ ohun ìjà àwọn alátakò di asán. (Ka Aísáyà 54:17.) Àtakò wọn kò lè dá iṣẹ́ Ọlọ́run dúró.

34. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀? Ẹ̀rí wo nìyẹn sì fi hàn? (Tún wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Ẹjọ́ Pàtàkì Tí A Jàre Rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Tó Mú Ká Lè Túbọ̀ Máa Wàásù Ìjọba Ọlọ́run.”)

34 Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀? Rò ó wò ná: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹni ńlá, ẹnu wa ò sì fi bẹ́ẹ̀ tólẹ̀ láwùjọ. A kì í dìbò, a kì í sì í bá wọn polongo ìṣèlú tàbí ká máa wá ojúure àwọn olóṣèlú. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn tí àwọn èèyàn kà sí “àwọn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni wọ́n máa ń pè lẹ́jọ́ lára wa. (Ìṣe 4:13) Torí náà, tá a bá ní ká fojú èèyàn wò ó, ó rọrùn fún àwọn ilé ẹjọ́ láti gbè sẹ́yìn àwọn ẹlẹ́sìn àtàwọn olóṣèlú tó ń ta kò wá lójú méjèèjì ju kí wọ́n gbèjà wa lọ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ilé ẹjọ́ máa ń dá wa láre! Bí ilé ẹjọ́ ṣe ń dá wa láre jẹ́ ẹ̀rí pé à ń rìn “ní iwájú Ọlọ́run, [àti] ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.” (2 Kọ́r. 2:17) Torí náà, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwa náà ń sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”—Héb. 13:6.

a Ẹjọ́ tó wáyé láàárín Arákùnrin Cantwell àti Ìpínlẹ̀ Connecticut ni àkọ́kọ́ nínú ẹjọ́ mẹ́tàlélógójì [43] tó wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tí Arákùnrin Hayden Covington bá wa bójú tó. Ó kú ní ọdún 1978. Ìyàwó rẹ̀, Dorothy, fi tọkàntọkàn ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé títí tó fi kú ní ọdún 2015 lẹ́ni ọdún méjìléláàdọrùn-ún [92].

b Ẹ̀sùn náà dá lórí òfin kan tí wọ́n ṣe ní ọdún 1606. Ó gba àwọn adájọ́ láyè láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi tí wọ́n bá rí i pé ohun tó sọ dá rúgúdù sílẹ̀, ì báà jẹ́ òótọ́ ni onítọ̀hún sọ.

c Lọ́dún 1950, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mẹ́rìnlélọ́gọ́jọ [164] ló wà ní àgbègbè Quebec. Mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] lára wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Wọ́n gbà láti wá sí orílẹ̀-èdè náà láìka àtakò tí wọ́n máa bá pàdé níbẹ̀ sí.

d Agbẹjọ́rò tó ní ìgboyà ni Arákùnrin W. Glen How. Láti ọdún 1943 sí 2003, ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Kánádà àti láwọn orílẹ̀-èdè míì.

e Fún àlàyé síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìjà Ogun Náà Kì Í Ṣe Tiyín, Bí Kò Ṣe ti Ọlọ́run” nínú Jí! May 8, 2000, ojú ìwé 18 sí 24.

f Ẹgbẹ́ ológun yẹn kúrò nínú ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nígbà tó yá; àmọ́ a kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sí ibòmíì lẹ́yìn náà.

Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?

  • Báwo làwọn ilé ẹjọ́ ṣe fi hàn pé oníwàásù ni wá, a kì í ṣe oníjàngbọ̀n, ọlọ̀tẹ̀ tàbí oníṣòwò tó ń kiri ọjà?

  • Àwọn àǹfààní míì wo là ń rí nínú àwọn ẹjọ́ tá a ti jàre rẹ̀?

  • Kí la máa ń ṣe tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa?

  • Tá a bá fojú èèyàn wò ó, kí nìdí tó fi ṣàrà ọ̀tọ̀ pé wọ́n dá àwa èèyàn Jèhófà láre nínú ọ̀pọ̀ ẹjọ́ mánigbàgbé?

  • Báwo ni àwọn ẹjọ́ tá a gbé yẹ̀ wò yìí ṣe mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára?

Kristẹni tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Serbia ń wàásù ìhìn rere fún obìnrin kan lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀

Stara Pazova, lórílẹ̀-èdè Serbia

ÀWỌN ẸJỌ́ PÀTÀKÌ TÍ A JÀRE RẸ̀ NÍ ILÉ ẸJỌ́ GÍGA TÓ MÚ KÁ LÈ TÚBỌ̀ MÁA WÀÁSÙ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ November 11, 1927

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Switzerland

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti gba ohun tó wù wá gbọ́.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Ọlọ́pàá kan dá Arákùnrin Adolf Huber dúró lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ń dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn. Torí náà, ó gba àwọn ìwé ìléwọ́ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.

ÌDÁJỌ́ Arákùnrin Huber sọ ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-èdè Switzerland pé ohun tí ọlọ́pàá náà ṣe kò tọ̀nà. Ilé ẹjọ́ sì sọ pé kò bófin mu láti gbẹ́sẹ̀ lé ìwé àwọn onísìn nítorí pé èyí máa ta ko ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti “gba ohun tó wù wọ́n gbọ́.”

ÀBÁJÁDE Ìdájọ́ yìí mú kí àwọn ọlọ́pàá ṣíwọ́ bí wọ́n ṣe ń dí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ July 9, 1935

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Romania

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti sọ̀rọ̀.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Wọ́n mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà. Wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé tó ń “dá rògbòdìyàn sílẹ̀ tó sì ń dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́.” Wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15].

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ tó gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ìwàásù wọn dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìwé wọn kì í dá rúgúdù sílẹ̀, wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti máa sọ èrò wọn fún àwọn ẹlòmíì.

ÀBÁJÁDE Ìdájọ́ yìí àtàwọn míì lára ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé lọ́gbọ̀n [530] ẹjọ́ àwọn ará wa tí wọ́n dá láti ọdún 1933 sí ọdún 1939, fún àwọn ará wa ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti máa bá ìṣẹ́ ìwàásù wọn lọ láìsí ìdíwọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, à ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ láìsí ìdíwọ́.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ March 17, 1953

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Netherlands

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti sọ̀rọ̀ àti láti tẹ̀wé jáde.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Wọ́n mú Arákùnrin Pieter Havenaar, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó rú òfin tó sọ pé ọjọ́ Tuesday àti Wednesday nìkan ní aago mẹ́sàn-án sí mọ́kànlá àárọ̀ ni èèyàn lè pín ìwé.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé òfin yìí ti le jù.

ÀBÁJÁDE Ìdájọ́ yìí wọ́gi lé àṣẹ èyíkéyìí tí kò bá fún àwọn èèyàn láyè tó pọ̀ tó láti lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa pín ìwé.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ October 6, 1953

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Kánádà

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn àti láti sọ̀rọ̀.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Òfin kan kà á léèwọ̀ ní ìlú Quebec City pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ pín ìwé èyíkéyìí láìgba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá. Oṣù mẹ́ta ni Arákùnrin Laurier Saumur tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò lò lẹ́wọ̀n torí pé ó rú òfin yìí.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé kò tọ́ láti lo òfin yẹn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilé ẹjọ́ náà gbà pé ara ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni láti máa pín àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì. Ìjọsìn wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni sì jẹ́ ká ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí pé ẹnikẹ́ni ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò.

ÀBÁJÁDE Ìdájọ́ yìí mú kí wọ́n fagi lé ẹ̀sùn tó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] tí wọ́n fi kàn wá pé a rú àwọn òfin ìlú ní àgbègbè Quebec.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ July 13, 1983

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Serbia

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti sọ̀rọ̀ àti láti tẹ̀wé jáde.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Àwọn ọlọ́pàá mú àwọn arábìnrin méjì kan pé wọ́n ń pín ìwé tó dá lórí Bíbélì. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń da ìlú rú wọ́n sì ń dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́. Wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọjọ́ márùn-ún.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé wọn kò rú òfin kankan, kò sì sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé wọ́n ń da ìlú rú.

ÀBÁJÁDE Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dá wa láre, àwọn ọlọ́pàá kò fi bẹ́ẹ̀ mú wa mọ́, wọn kò sì gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé wa bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ May 26, 1986

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Tọ́kì

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti gba ohun tó wù wá gbọ́.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Lẹ́yìn tí ìdílé mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé pé àwọn fẹ́ fi orúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀. Wọ́n fi arákùnrin àti arábìnrin mẹ́tàlélógún [23] sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ da bí ìjọba ṣe ṣètò àwùjọ àti òṣèlú rú.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fagi lé ẹ̀sùn náà, ó sì dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a ní ẹ̀tọ́ láti gba ohun tó bá wù wá gbọ́.

ÀBÁJÁDE Ìdájọ́ yìí fòpin sí bí wọ́n ṣe ń mú àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni, ó sì jẹ́ kí àwọn ará ìlú túbọ̀ lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n lórílẹ̀-èdè Tọ́kì.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ May 25, 1993

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Gíríìsì

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti máa ṣe ẹ̀sìn wa.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Lọ́dún 1986, wọ́n dá Arákùnrin Minos Kokkinakis lẹ́bi fún ìgbà kejìdínlógún [18] lórí ẹ̀sìn pé ó ń yí àwọn èèyàn lọ́kàn pa dà láti wá ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Láti ọdún 1938 sí 1992, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún [19,000] ìgbà tí wọ́n mú lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé a rú òfin ilẹ̀ Gíríìsì tí kò gba àwọn èèyàn láyè láti yí ẹlòmíì lọkàn pa dà láti ṣe ẹ̀sìn wọn.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé ẹ̀sùn yìí ta ko ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti sọ èrò wọn, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà láyè àti láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n. Ó tún sọ pé bí wọ́n ṣe ń dí wa lọ́wọ́ láti ṣe ẹ̀sìn wa kò bófin mu. Ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé “ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa” ni ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀBÁJÁDE Ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì pàṣẹ pé gbogbo àwọn tó wà nípò àṣẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó bá yàtọ̀ sí ẹjọ́ tí wọ́n dá nínú ọ̀rọ̀ ti Kokkinakis yìí. Èyí fòpin sí bí wọ́n ṣe ń dá wa lẹ́bi lórí ẹ̀sùn pé à ń yí àwọn ẹlòmíì lọ́kàn pa dà láti ṣe ẹ̀sìn wa.

ỌJỌ́ TÍ WỌ́N DÁJỌ́ June 17, 2002

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Amẹ́ríkà

Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ YỌ Òmìnira láti sọ̀rọ̀.

BỌ́RỌ̀ ṢE WÁYÉ Wọ́n pa àṣẹ kan ní abúlé Stratton tó wà ní ìpínlẹ̀ Ohio pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa mú kó máa lọ láti ilé dé ilé gbọ́dọ̀ gba ìwé àṣẹ. Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sì gbà pé àṣẹ yìí bá òfin mu.

ÌDÁJỌ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ wọ́gi lé àṣẹ náà pé kò bófin mu, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn èèyàn ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn fàlàlà, wọ́n sì ní òmìnira láti sọ̀rọ̀. Ilé ẹjọ́ náà tún fara mọ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe sọ pé “Ìwé Mímọ́ ló pàṣẹ fún wọn láti máa wàásù.”

ÀBÁJÁDE Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbègbè tó ní ìjọba ìbílẹ̀ ló ti jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń fi irú àṣẹ yìí dí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́