Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Kan Ṣàtúnṣe Àìtọ́ Kan
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GÍRíÌSÌ
IṢẸ́ ológun jẹ ọ̀ranyàn ní ilẹ̀ Gíríìsì. Kò sí àkókò tí kì í tó 300 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń wà lẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ ológun. Àjọ Adáríjini Lágbàáyé wò wọ́n bí ẹni tí ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀rí ọkàn, léraléra ni ó sì máa ń rọ àwọn ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì kan tí ń jẹ tẹ̀ léra láti dá wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ṣe òfin tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun tí kò sì jọ ti ìfìyàjẹni.
Ní 1988, wọ́n ṣe òfin tuntun tí ó kan ọ̀ràn iṣẹ́ ológun. Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ó sọ pé, “àwọn tí a yọ̀ǹda fún láti má ṣe iṣẹ́ ológun nìwọ̀nyí: . . . Àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ ìsìn, àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́-ànìkàngbé tàbí àwọn tí ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ìṣètò ìjẹ́jẹ̀ẹ́-ìnìkàngbé ti ìsìn kan tí a mọ̀ dáradára, bí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Àwọn òjíṣẹ́ ìsìn ti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ni a sábà máa ń yọ sílẹ̀ láìsí wàhálà àti lọ́nà rírọrùn, láìsí pé wọ́n ń kojú ìṣòro kankan tàbí irú ìfìyàjẹni ní ti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn pàtàkì kan tí wọ́n ní. Irú ohun kan náà yóò ha ṣẹlẹ̀ sí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn kan tí kò gbajúmọ̀ bí? Àyẹ̀wò kan pèsè ìdáhùn kan láìpẹ́.
Ìfinisẹ́wọ̀n Láìbófinmu
Ní ìbámu pẹ̀lú òfin yìí, ní apá ìparí 1989 àti ìbẹ̀rẹ̀ 1990, Dimitrios Tsirlis àti Timotheos Kouloumpas, àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tí Ìjọ Central ti Àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gíríìsì yàn sípò, kọ̀wé béèrè pé kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ́fíìsì ìfinisíṣẹ́-ológun wọn má ṣe jẹ́ kí àwọn ṣiṣẹ́ ológun. Wọ́n kó ìwé tí wọ́n kọ àti àwọn ìwé tí ń fẹ̀rí hàn pé wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ ìsìn lójú méjèèjì ránṣẹ́. Bí a ti lérò pé yóò ṣẹlẹ̀, wọ́n kò gba ìwé tí wọ́n kọ náà wọlé látàrí ọ̀rọ̀ èké tí ó fojú jọ òtítọ́ náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ara “ìsìn tí a mọ̀.”
Arákùnrin Tsirlis àti Kouloumpas lọ sí àwọn ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun tí wọ́n pín ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú wọn, wọ́n fẹ̀sùn àìgbọràn sí àṣẹ kàn wọ́n, wọ́n sì fi wọ́n sí àhámọ́. Láàárín àkókò kan náà, Orílé-Iṣẹ́ Àpapọ̀ fún Ààbò Orílẹ̀-Èdè kò gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí wọ́n pè lórí ìdájọ́ tí àwọn ọ́fíìsì tí ń fini síṣẹ́ ológun ṣe. Àwọn aláṣẹ ológun ṣàlàyé pé Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ ti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì sọ fún àwọn pé ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbajúmọ̀! Èyí ta ko ẹjọ́ tí àwọn ilé ẹjọ́ gbogbogbòò mélòó kan dá pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìsìn tí a mọ̀ ní ti gidi.
Àwọn ilé ẹjọ́ ológun wá dájọ́ pé Tsirlis àti Kouloumpas jẹ̀bi ṣíṣàìgbọràn sí àṣẹ, wọ́n sì fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin. Àwọn arákùnrin méjèèjì náà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí sí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ológun, tí ó sún ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà síwájú lẹ́ẹ̀mẹta nítorí onírúurú ìdí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó kọ̀ ní ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti pàṣẹ pé kí wọ́n dá àwọn olùpẹjọ́-kòtẹ́milọ́rùn náà sílẹ̀ lẹ́wọ̀n fún ìgbà díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ilẹ̀ Gíríìsì fàyè gba ìyẹn.
Láàárín àkókò kan náà, nínú ọ̀wọ́ àwọn ìgbẹ́jọ́ mìíràn, Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ fagi lé ìdájọ́ Orílé-Iṣẹ́ Àpapọ̀ fún Ààbò Orílẹ̀-Èdè, látàrí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìsìn kan tí a mọ̀ ní ti gidi.
Ọ̀nà tí wọ́n gbà bá Tsirlis àti Kouloumpas àti Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lò láàárín oṣù 15 tí wọ́n fi ní láti wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ológun ní Avlona kò dára rárá, ó sì ń tẹ́ni lógo. Ìròyìn kan tí ó jáde lákòókò yẹn sọ nípa “àwọn ipò burúkú tí [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ń gbé inú rẹ̀, ó sì mẹ́nu kan ẹran bíbàjẹ́ àti ìrù èkúté ilé, tí wọ́n sábà máa ń fi sínú oúnjẹ fún wọn, dídín àkókò ìbẹ̀wò kù sí ìgbà tí Alákòóso bá fẹ́, àìsáyè nítorí àwọn túbú tí ó kún àkúnya nítorí àpọ̀jù àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ọ̀nà rírorò gan-an tí wọ́n gbà bá irú àwọn ẹlẹ́wọ̀n bẹ́ẹ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn lò.”
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ológun dá Arákùnrin Tsirlis àti Kouloumpas sílẹ̀ pé wọn kò jẹ̀bi rárá, àmọ́ ó tún pàṣẹ lákòókò kan náà pé, Ìjọba kò sí lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti sanwó gbà-máà-bínú fún fífi wọ́n sí àhámọ́ nítorí “a fi wọ́n sí àhámọ́ nítorí ìwà àìkaǹkansí tí gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n hù.” Èyí gbé àwọn ìbéèrè gbígbéṣẹ́ dìde ní àwùjọ àwọn amòfin pé: Ta ni ó hu ìwà àìkaǹkansí tí gbogbo ẹ̀rí fi hàn náà? Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ni tàbí àwọn ilé ẹjọ́ ológun?
Wọ́n dá àwọn arákùnrin náà sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́gán, wọ́n sì yọ wọ́n kúrò nínú agbo òṣìṣẹ́ adìhámọ́ra látàrí pé wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ ìsìn. Nígbà tí a dá wọn sílẹ̀, Àjọ Adáríjini Lágbàáyé kéde pé òun fara mọ́ dídá tí wọ́n dá Dimitrios Tsirlis àti Timotheos Kouloumpas sílẹ̀, ó sì sọ pé òun retí pé, lọ́jọ́ iwájú, a óò yọ̀ǹda àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nínú iṣẹ́ ológun ní ìbámu pẹ̀lú àǹfààní tí òfin ilẹ̀ Gíríìsì fi fúnni. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láìpẹ́, a óò ba ìrètí yìí jẹ́.
Ìfinisẹ́wọ̀n Léraléra
Àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà míràn tí a yàn sípò ní láti la ìrírí agbonijìgì kan tí ó yàtọ̀ díẹ̀ kọjá nítorí ìdí kan náà. Ní September 11, 1991, Anastasios Georgiadis béèrè pé kí wọ́n yọ̀ǹda òun kúrò nínú iṣẹ́ ológun lọ́nà kan náà. Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, ọ́fíìsì ìfinisíṣẹ́-ológun sọ fún un pé àwọn kò fọwọ́ sí ohun tí ó béèrè fún, àti pé nítorí pé Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ ti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kò gbà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìsìn kan tí a mọ̀. Èyí sì ṣẹlẹ̀ lójú ẹjọ́ ṣíṣekedere tí Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ dá lórí ọ̀ràn Tsirlis àti Kouloumpas!
Ìdáhùn tí Orílé-Iṣẹ́ Àpapọ̀ fún Ààbò Orílẹ̀-Èdè kọ náà kà pé: “Ìpinnu ẹgbẹ́ Alákòóso náà, tí wọ́n gbé karí èrò jíjáfáfá ti Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ ti Ìjọ Gíríìsì, tí kò ka ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí èyí tí a mọ̀, kò fara mọ́ ìwé ìbéèrè ìyọ̀ǹda tí [Georgiadis] kọ.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Georgiadis lọ sí Àgọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Nafplion ní January 20, wọ́n sì fi í sí túbú ìfìyàjẹni tó wà ní àgọ́ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ológun ní Avlona.
Ní March 16, 1992, Ilé Ẹjọ́ Ológun ní Áténì dá Georgiadis sílẹ̀ pé kò jẹ̀bi rárá. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ilé ẹjọ́ ológun kan ní ilẹ̀ Gíríìsì gbà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìsìn tí a mọ̀ ní gidi. Olùdarí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ológun ní Avlona dá a sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ ó pàṣẹ fún un láti tún pa dà ṣẹ́nu iṣẹ́ ní April 4, ní ibùdó ìfinisíṣẹ́-ológun ní Nafplion. Ní ọjọ́ yẹn, Georgiadis tún kọ̀ láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun, wọ́n sì tún fẹ̀sùn àìgbọràn sí àṣẹ kàn án, wọ́n fi sí àhámọ́ ní ẹ̀ẹ̀kejì, wọ́n sì tún ṣe ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Ní May 8, 1992, Ilé Ẹjọ́ Ológun ní Áténì dá a sílẹ̀ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tuntun tí wọ́n fi kàn án rárá, àmọ́ ó dájọ́ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fún un ní owó gbà-máà-bínú kankan fún fífi í sí àhámọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n dá Georgiadis sílẹ̀ kúrò ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ológun ní Avlona àmọ́ wọ́n pàṣẹ fún un ní ẹ̀ẹ̀kẹta láti wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ibùdó ìfinisíṣẹ́-ológun ní Nafplion, ní May 22, 1992! Ó tún kọ̀ láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun, wọ́n sì tún fẹ̀sùn àìgbọràn sí àṣẹ kàn án ní ẹ̀ẹ̀kẹta, wọ́n sì fi sí àhámọ́.
Ní July 7, 1992, Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ fagi lé ìdájọ́ ti September 1991, látàrí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìsìn tí a mọ̀ ní gidi. Ní July 27, 1992, wọ́n dá Georgiadis sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ológun ní Tẹsalóníkà. Ní September 10, 1992, Ilé Ẹjọ́ Ológun ní Tẹsalóníkà dá a sílẹ̀ pé kò jẹ̀bi rárá, àmọ́ ó sọ pé Georgiadis kò lẹ́tọ̀ọ́ sí owó gbà-máà-bínú nítorí pé wọ́n tún sọ pé àhámọ́ tí a fi í sí jẹ́ nítorí ‘ìwà àìkaǹkansí tí gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé ó hù.’
Ìhùwàpadà Tí Ó Gbalẹ̀ Kan
Nígbà tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Yúróòpù ń sọ nípa ọ̀ràn Georgiadis, ó sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yí jẹ́ ọ̀ràn kèéta lòdì sí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ti ìlànà èròǹgbà àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa òfin àti gbígbádùn ẹ̀tọ́ ìbálò ọgbọọgba.”
Ní February 1992, Àjọ Adáríjini Lágbàáyé sọ pé, òun “gbà gbọ́ pé wọ́n fi [Anastasios Georgiadis] sẹ́wọ̀n kìkì nítorí ìbálò oníkèéta níhà àwọn aláṣẹ ológun lòdì sí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì béèrè pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, láìsí ipò àfilélẹ̀ kankan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀rí ọkàn.”
Kódà, ó mú kí olùpẹjọ́ ológun ní ọ̀kan lára ìgbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Georgiadis sọ pé: “Ọ̀nà tí ẹgbẹ́ àwùjọ kan ń gbà kojú àwọn ìṣòro kan tí ó kan àwọn ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ ń fi bí ó ṣe dàgbà sókè tó ní ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ hàn kedere. Bí àwa tí a wà ní ilẹ̀ Gíríìsì níhìn-ín bá fẹ́ kí ìdàgbàsókè àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù, bí a bá fẹ́ láti tẹ̀ síwájú, a jẹ́ pé a ní láti gbà pẹ̀lú àwọn ìlànà káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, kí a sì jáwọ́ ṣíṣe ẹ̀tanú. Èyí hàn kedere ní ẹ̀ka ti bíbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ olúkúlùkù ọmọ ìbílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní gidi àti àwọn ọgbọ́n tí àwọn alákòóso ń lò fi ẹ̀tanú àti àìráragba-nǹkan-sí ní ti ìsìn tí ń ṣẹlẹ̀ sí lòdì sí àwọn onísìn tí kò gbajúmọ̀ hàn. Ẹjọ́ tí a ń gbọ́ lọ́wọ́ yìí kò bójú mu.”
Ian White, tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ilẹ̀ Yúróòpù, tí ó wá láti Bristol, England, kọ̀wé pé: “Èrò ti pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ‘ìsìn tí a mọ̀’ yóò pa ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́rìn-ín ní Orílẹ̀-èdè yí. Dájúdájú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré níye dé ìwọ̀n kan, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí dáradára ní Orílẹ̀-èdè yí, wọ́n sì sábà máa ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.” Pẹ̀lú pé Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń wàásù ní ilẹ̀ Gíríìsì lé ní 26,000, ó ṣòro kí wọ́n jẹ́ ‘ìsìn tí a kò mọ̀’!
Àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́wàá kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Yúróòpù kọ̀wé láti sọ bí ọ̀ràn Georgiadis ṣe bí wọn nínú, wọ́n sọ pé, “ó ya àwọn lẹ́nu, ó sì dun àwọn gan-an” bí wọ́n ṣe tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú lọ́nà yẹn ní ilẹ̀ Gíríìsì.
Ìpẹ̀jọ́ Kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù
Lẹ́yìn dídá àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n jìyà ìṣekèéta ìsìn sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n pé wọn kò jẹ̀bi rárá, wọ́n ronú pé ẹ̀tọ́ àwọn ni láti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tí wọ́n ṣe pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yí ni fífi tí wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ láìbófinmu, tí ó fi àìṣòdodo hàn, àti dídá tí wọ́n dá wọn lóró ní ti èrò orí àti ara, àti ìpalára púpọ̀ tí fífi òmìnira wọn dù wọ́n léraléra fún ìgbà tí ó pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ ṣe fún wọ́n ní ti ìwà rere àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Nítorí ìdí yìí, wọ́n béèrè fún owó gbà-máà-bínú tí ó yẹ, lọ́nà tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù panu pọ̀ sọ pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ òmìnira àti ààbò ẹni lójú nínú ọ̀ràn Tsirlis àti Kouloumpas, fífi tí wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ kò bófin mu, wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti gba owó gbà-máà-bínú, àti pé ilé ẹjọ́ ṣègbè nínú ìgbẹ́jọ́ wọn. Ohun kan náà ni Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe tí ń rí sí ọ̀ràn ẹjọ́ ti Georgiadis pẹ̀lú sọ.
A Ṣàtúnṣe Ìṣègbè Náà
Wọ́n fi ìgbẹ́jọ́ náà sí January 21, 1997. Kóòtù kún fọ́fọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti yunifásítì àdúgbò, àwọn oníròyìn, àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi mélòó kan láti ilẹ̀ Gíríìsì, Germany, Belgium, àti ilẹ̀ Faransé wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Ọ̀gbẹ́ni Panos Bitsaxis, agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí náà, sọ̀rọ̀ nípa “ìwà oríkunkun tí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gíríìsì ń hù léraléra, láìdábọ̀, láti má ṣe mọ̀ pé ìsìn kan tí kò ní ènìyàn púpọ̀ nínú wà,” ìyẹn ni ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àṣà gbígbé tí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gíríìsì ń gbé ìpinnu àfàṣẹṣe wọn nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí karí èrò àwọn ẹni tí ń kọjú ìjà sí wọn jù lọ—Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì! Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Báwo ni a óò ti jẹ́ kí wọ́n ṣe èyí pẹ́ tó? . . . Ìgbà wo ni yóò sì dópin?” Ó sọ̀rọ̀ nípa “kíkùnà láti mọ irú ẹgbẹ́ àwọn onísìn kan lábẹ́ òfin, ìkùnà tí ó jọ pé kò nítumọ̀ bí o bá rí i pé ó wá tààràtà, lọ́nà tí kò ṣeé fi bò, lọ́nà tí kò bá ìrònú kankan mu, tí ó lòdì sí òfin, tí ó lòdì sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ.”
Aṣojú ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì jẹ́rìí sí ìwà kèéta tí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gíríìsì hù nípa sísọ pé: “A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Gíríìsì ní wọn ti wà nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àbáyọrí kan tí a retí nípa èyí ni pé ètò Ìjọ yẹn àti ipò àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ipa tí wọ́n ń kó nínú Ìjọ náà ṣe kedere. . . . Ipò àwọn òjíṣẹ́ láti Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò yéni tó bẹ́ẹ̀.” Ẹ wo bí ó ṣe gba lọ́nà tí kò ṣeé fi bò tó pé wọ́n ń hùwà ẹ̀tanú sí àwọn onísìn tí kò ní ènìyàn púpọ̀ nínú ní ilẹ̀ Gíríìsì!
A Gbé Òmìnira Ìsìn Lárugẹ
Wọ́n ṣe ìdájọ́ ní May 29. Alága Ìgbìmọ̀ Ìdájọ́, Ọ̀gbẹ́ni Rolv Ryssdal, ka ìdájọ́. Ilé Ẹjọ́ náà, tí ó ní adájọ́ mẹ́sàn-án nínú, panu pọ̀ sọ pé ilẹ̀ Gíríìsì rú Apá 5 àti 6 lára òfin Ìparapọ̀ Yúróòpù. Ó tún pàṣẹ pé kí wọ́n san nǹkan bí 72,000 dọ́là fún àwọn olùpẹ̀jọ́ náà gẹ́gẹ́ bí owó gbà-máà-bínú àti owó tí wọ́n ti ná. Ní pàtàkì jù lọ, ìdájọ́ náà ní ọ̀pọ̀ àlàyé gbígbàfiyèsí tí ó pọ̀n síhà òmìnira ìsìn.
Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé, “ó hàn kedere pé àwọn aláṣẹ ológun kọtí ikún” sí òkodoro òtítọ́ náà pé a ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí “ìsìn tí a mọ̀” ní ilẹ̀ Gíríìsì, gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ ṣe. Ó sọ síwájú sí i pé: “Jíjáwọ́ tí àwọn aláṣẹ ológun kò jáwọ́ nínú ṣíṣàìfẹ́ láti gbà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ‘ìsìn tí a mọ̀’ àti ṣíṣàìka ẹ̀tọ́ òmìnira àwọn olùpẹ̀jọ́ náà sí tí ó jẹ́ àbáyọrí rẹ̀ jẹ́ ìṣekèéta tí a bá fi wé ọ̀nà tí a fi ń yọ àwọn òjíṣẹ́ Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì sílẹ̀.”
Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ní ilẹ̀ Gíríìsì polongo ọ̀ràn ẹjọ́ náà káàkiri. Ìwé agbéròyìnjáde Athens News polongo pé: ‘Ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Yúróòpù ṣàríwísí ilẹ̀ Gíríìsì lórí ohun tí Jèhófà sọ.’ Ìdájọ́ lórí ẹjọ́ Tsirlis & Kouloumpas pẹ̀lú Georgiadis ní ìdojúkọ ilẹ̀ Gíríìsì yọrí sí ìrètí náà pé Ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì yóò mú òfin rẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù, kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Gíríìsì lè máa gbádùn òmìnira ìsìn láìsí pé àwọn alákòóso, àwọn ológun, tàbí ṣọ́ọ̀ṣì dá sí i. Síwájú sí i, ìdájọ́ mìíràn tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù dá lòdì sí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Gíríìsì lórí àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òmìnira ìsìn nìyí.a
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì òmìnira wọn, wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi sin Ọlọ́run àti láti fi ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. Kì í ṣe nítorí àtijèrè ohun tí ara ni Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ ìsìn náà ṣe gbé ẹjọ́ wọn lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí ìwà rere àti ìlànà ṣíṣètẹ́wọ́gbà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti pinnu pé àwọn óò ná owó gbà-máà-bínú tí wọ́n fún àwọn sórí ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìdájọ́ àkọ́kọ́, tí wọ́n ṣe ní 1993, ni ọ̀ràn ti Kokkinakis ní ìdojúkọ ilẹ̀ Gíríìsì; èkejì, tí wọ́n ṣe ní 1996, ni ọ̀ràn ti Manoussakis àti àwọn Ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìdojúkọ ilẹ̀ Gíríìsì.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31; Jí!, March 22, 1997, ojú ìwé 14 sí 16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Esther àti Dimitrios Tsirlis
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Timotheos àti Nafsika Kouloumpas
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Anastasios àti Koula Georgiadis