ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/8 ojú ìwé 19-21
  • Àwùjọ Àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ha Wà Lójúfò Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwùjọ Àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ha Wà Lójúfò Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ha Jẹ́ Apá Kan Ayé Yìí Bí?
  • Wọn Kò Sí Ní Ìṣọ̀kan
  • “‘Ìṣípayá’ Afẹ́”
  • Gbígbé Ìrònú Karí Ìrètí Èké
  • Wọn Kò Sí Lójúfò
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì—Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
    Jí!—1996
  • Pátímọ́sì—Erékùṣù Àpókálíìsì
    Jí!—2000
  • Akitiyan Láti Tẹ Bíbélì Jáde Lédè Gíríìkì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń fi Ayọ̀ Ka Ìwé Ìṣípayá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/8 ojú ìwé 19-21

Àwùjọ Àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ha Wà Lójúfò Bí?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GÍRÍÌSÌ

“NÍGBÀ tí Jésù wọ inú tẹ́ḿpìlì . . . tí ó sì rí ‘àwọn tí ń tajà,’ inú bí i, ó sì kébòòsí pé: ‘Ẹ yéé fi ilé Baba mi ṣe ilé ìtajà!’ Bí ó bá ní láti wọ ọkọ̀ lọ sí erékùṣu Pátímọ́sì lónìí, . . . yóò sọ̀rọ̀ lọ́nà líle ju ìyẹn lọ. Àmọ́, kò dá mi lójú pé ẹnikẹ́ni yóò tẹ́tí sí i.” Báyìí ni akọ̀ròyìn kan tí ń gbé ìròyìn nípa ohun tí a pè ní “ìkórajọ ṣíṣe pàtàkì gan-an fún Ìṣọ̀kan Kristẹni” àti “ọ̀kan lára àwọn àkókò líle koko jù lọ nínú ìsìn Kristẹni òde òní,” ṣe kédàárò.

Baba ìsàlẹ̀ àpapọ̀ ṣọ́ọ̀ṣi Constantinople, Bartholomew Kìíní, tí a kà sí olórí ìṣàpẹẹrẹ Ṣọ́ọ̀ṣi Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì jákèjádò ayé, kéde ọdún 1995 ní “Ọdún Àpókálíìsì.”a Láti September 23 sí 27, 1995, àjọ̀dún náà dé òtéńté bí àwọn àlùfáà onípò gíga láti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ibùjókòó àwọn baba ìsàlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣi Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti kóra jọ lórí òke Pátímọ́sì. Àwọn aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà, àti onírúurú ẹ̀yà Pùròtẹ́sítáǹtì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn aláṣẹ òṣèlú àti ológun gíga jù lọ ní ilẹ̀ Gíríìsì wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, pà pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́, òṣèlú, gbajúgbajà oníṣòwò láti ilẹ̀ òkèèrè, àti àwọn àlejò tí a ké sí láti ibi gbogbo yíká ayé.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣípayá yóò rántí àwọn ìránnilétí pàjáwìrì tí Jésù Kristi gbé jáde nínú rẹ̀ pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó wà lójúfò.” (Ìṣípayá 16:15) Lójú èyí àti ayẹyẹ ìsìn tí a ti polongo púpọ̀ tí ó dá lórí Ìṣípayá náà, a nímọ̀lára láti béèrè pé: Kirisẹ́ńdọ̀mù ha ń wà lójúfò bí? Wọ́n ha ń ṣọ́nà, ní fífi ìháragàgà dúró de bíbọ̀ Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a ti gbé gorí ìtẹ́ bí? Àjọ̀dún wọ̀nyí ha dá lórí àkọlé Bíbélì, tí ó dé òtéńté rẹ̀ nínú Ìṣípayá—ìyàsímímọ́ orúkọ Jèhófà àti ìgbéga ipò ọba aláṣẹ àgbáye rẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọba náà lábẹ́ Kristi bí? Ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn òkodoro òtítọ́ díẹ̀ wò.

Ó Ha Jẹ́ Apá Kan Ayé Yìí Bí?

Sí ọ̀pọ̀ àwọn òǹwòran, àjọṣepọ̀ tí kò rọrùn láàárín àwọn aṣáájú ìsìn, àwọn òṣèlú, àti àwọn oníṣòwò nígbà àjọ̀dún náà kò fani mọ́ra. Àwọn kan lérò pé gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn ń gbìyànjú láti lo ipò ọ̀ràn náà fún àǹfààní ara wọn ní pàtàkì. Àwọn àlùfáà ti ipa ìdarí wọn lẹ́yìn nípa fífi ara hàn tẹ̀ lé àwọn òṣèlú jàǹkàn jàǹkàn, nígbà tí àwọn òṣèlú náà sì ń gbìyànjú láti mú orúkọ wọn sunwọ̀n nípa lílo èrò àwọn aráàlú nípa ìsìn fún àǹfààní ara wọn. Agbẹnusọ fún Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣi ilẹ̀ Gíríìsì tilẹ̀ sọ pé: “Ìṣípayá pẹ̀lú ní ìtumọ̀ ti ìṣèlú . . . Ó jẹ́ ìràn kan lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Ẹ wo bí èyí ti bá àpèjúwe tí a rí nínú Ìṣípayá 17:1, 2 mu tó, níbi tí a ti ṣàpèjúwe “aṣẹ́wó ńlá” ìṣàpẹẹrẹ náà, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé tí Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá lílókìkí nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń ṣe “àgbèrè” nípa tẹ̀mí pẹ̀lú “awọn ọba ilẹ̀ ayé”! Dípo wíwà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì wà lójúfò, ńṣe ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, bíi ti àwọn yòó kù nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, ń tan àwọn alákòóso òṣèlú sínu ìbádọ́rẹ̀ẹ́ aláìmọ́ pẹ̀lu rẹ̀, tí wọ́n ń ru inúbibíni sí ìsìn sókè, ní pàtàkì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Wọn Kò Sí Ní Ìṣọ̀kan

Ó hàn gbangba pé àwọn baba ìsàlẹ̀ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì méjèèjì kò sí níbi àṣeyẹ náà. Èé ṣe? Nínú ìgbésẹ̀ ìṣàtakò kan, baba ìsàlẹ̀ Alexios Kejì ti Moscow kọ̀ jálẹ̀ láti lọ síbẹ̀ nítorí pé ibùjókòó Constantinople ti fara mọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ibùjókòó bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti Estonia àti Ukraine láti fi ara wọn sábẹ́ agbègbè tí Constantinople ń ṣàkóso dípò ti Moscow. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, “èyí ni yánpọnyánrin gbígbópọn jù lọ tí ó tí ì ṣẹlẹ̀ rí nínú àjọṣepọ̀ láàárín [ibùjókòó Constantinople] àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Rọ́ṣíà tí ó túbọ̀ lágbára,” tí ń ṣèkìlọ̀ “àbájáde tí kò ṣeé sọ tẹ́lẹ̀ fún ìṣọ̀kan àti àṣẹ ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì.”

Ní àfikún sí i, àwọn baba ìsàlẹ̀ ti Jerúsálẹ́mù ṣá ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn náà tì. Èé ṣe? Ìròyín sọ pé nítorí pé inú bí i, nítorí ààtò ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ibùjókòó Constantinople ní kí ó ṣe ní ọdún mẹ́ta ṣáájú, nítorí gbígbìyànjú láti máa ṣàkóso Ṣọ́ọ̀ṣi Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Australia.

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n fẹ́ pe Póòpù John Paul Kejì síbẹ̀, àmọ́ èyí yí padà nígbẹ̀yìngbẹ́yín nítorí ìlòdì sí gbígbóná janjan tí àwọn arọ̀mọ́pìlẹ̀ kan nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì gbé dìde. Ní May 1995, òléwájú àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan ní Áténì pe póòpù ní “ọ̀daràn nígbà ogun.” Nígbà náà ni wọ́n kéde pé lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, “póòpù . . . kò lè ṣàjọpín nínú ayẹyẹ náà ní Pátímọ́sì.”

Ohun tí ó tún pa kún ipò amúni banújẹ́ yìí ni àìbáramu náà pé lákòókò ayẹyẹ yìí, ní nǹkan bí 1,500 kìlómítà péré sí ìwọ̀ oòrùn àríwá Pátímọ́sì, àwọn “Kristẹni” Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti Roman Kátólíìkì ń pa ara wọn ní Bosnia òun Herzegovina!

Ní kedere, àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni tí ń tòògbé nípa tẹ̀mí ń fàyè gba ẹ̀ya ìsìn láti pín wọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ! Nígbà tí Iakovos, àlùfáà àgbà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Àríwá àti Gúúsù America ń bẹnu àtẹ́ lu àìṣọ̀kan yìí, ó sọ nínú ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò kan pé: “A ti fìdí rẹmi nínú ìsapá wa láti mú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣọ̀kan kí a lè ṣiṣẹ́ ìsìn fún ẹ̀dá ènìyàn, dípò àwọn alágbára ayé. . . . Ìsúre láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ìsàlẹ̀ . . . ti sú àwọn ènìyàn.”

“‘Ìṣípayá’ Afẹ́”

Ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n pè ní “ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí ti nínáwó ré kọjá àlà” náà di ohun tí a ṣàríwí sí lọ́nà lílágbára. Ìwé agbéròyìnjáde kan sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àjọ̀dún náà ní Pátímọ́sì fẹ̀rí hàn pé ó jẹ́ ‘ìṣípayá’ afẹ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. . . . Yòyòyìnyìn ìlẹ̀ ọba Byzantium àtijọ́ náà tayọ ààlà ayẹyẹ ṣọ́ọ̀ṣì, tí ń fi àmi yíyí ìṣẹ̀lẹ̀ àkójọpọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì padà sí àjọ̀dún olówó ńlá hàn.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣàníyàn nípa iye owó tí wọ́n ná lórí àwọn ayẹyẹ náà, ní pàtàkì ní àkókò tí àwọn ènìyàn tí wọ́n sún mọ́ wọn ní Balkan àti Ìhà Ìlà Oòrùn Europe wà nínú ewu lílà á já. Àwọn ìdíyelé kan ṣírò pé “ayẹyẹ tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí” yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà tó mílíọ̀nù 17 dọ́là (ti United States). Àwọn ọkọ̀ ìgbafẹ́ lójú òkun ń dé sí etíkun Pátímọ́sì láti pèsè ibùgbé fún díẹ̀ lára àwọn àlejò ọlọ́lá tí wọ́n pè sí ibi àpéjọpọ̀ náà. Sí ìríra ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi ibẹ̀ ṣe ilé, wọ́n yára tún erékùṣù náà ṣe láti bá ìgbà mu, kí ó lè fi èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn dídára jù kan sínú àwọn àlejò onípò gíga náà—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ tí ó bójú mu níbẹ̀.

Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Ìṣípayá 18:2, 3, 7 ṣe bá ipò ọ̀ràn yìí mu tó pé: “Àwọn olówò arìnrìn àjò ilẹ̀ ayé sì di ọlọ́rọ̀ nítorí agbára fàájì aláìnítìjú [Bábílónì Ńlá]. Dé àyè tí òun ṣe ara rẹ̀ lógo tí ó sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú, dé àyè yẹn ni kí ẹ fún un ní ìjoró àti ọ̀fọ̀”! Ní àkókò tí àwọn ènìyàn gbáàtúù ń jìyà, ńṣe ni ọwọ́ Ṣọ́ọ̀ṣi Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì dí nínú àwọn àjọ̀dún aláìjámọ́ nǹkan kan nípa tẹ̀mí, tí ó mú nínáwó ré kọjá ààlà lọ́wọ́, dípò kí wọ́n máa wà lójúfò láti pèsè ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.

Gbígbé Ìrònú Karí Ìrètí Èké

Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ayẹyẹ yìí, àwọn àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé àti àpérò bíi mélòó kan wáyé. Wọ́n wéwèé àwọn ojútùú láti kojú àwọn ìṣòro líle koko tí ìran aráyé ń dojú kọ. Wọ́n gbé ìpinnu kan kalẹ̀ tí ń béèrè pé kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tètè gbégbèésẹ̀ láti yanjú àwọn ìṣòro aráyé. Wọn kò mẹ́nu kan Ìjọba Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn apá Bíbélì yòó kù, ìwé Ìṣípayá tẹnu mọ́ ọn pé Ìjọba Ọlọ́run ní ọwọ́ Jésù Kristi ni ojútùú kan ṣoṣo fún gbogbo ìṣòro aráyé.—Ìṣípayá 11:15-18; 12:10; 21:1-5.

Abájọ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi ọwọ́ gidi mú ìrètí tí a gbé karí Bíbélì nípa Ìjọba náà. Nígbà tí ó ń sọ nípa ìṣarasíhùwà tí ó gbalẹ̀ náà, ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkangbé ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkangbé ti Pátímọ́sì sójú abẹ níkòó pé: “A kò fọwọ́ mú ìwé Ìṣípayá gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò ṣeé jà níyàn. Ó jẹ́ irú ìwé mímọ́ tí a kì í kà ní ṣọ́ọ̀ṣì.” Bákan náà, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan sọ pé: “Ó léwu láti so Ìṣípayá pọ̀ mọ́ ìtàn ayé yìí bíi pé ó jẹ́ ìwé tí ń ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní kúlẹ̀kúlẹ̀. . . . Ṣíṣe èyí jẹ́ ìwà ọ̀gbẹ̀rì, ó sì jẹ́ ìtumọ̀ tí ó léwu.” Ẹ wo irú ìtòògbé nípa tẹ̀mí tí èyí jẹ́!

Wọn Kò Sí Lójúfò

Ó ṣe kedere, nígbà náà, pé Kirisẹ́ńdọ̀mù kò sí lójúfò. Dípò kí ayẹyẹ yìí darí àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìléri rẹ̀, ó jẹ́ ètò ìsìn “ìpàtẹ eléré ìnàjú” lásánlàsàn tí kò wúlò. Ipò tí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn aláfẹnújẹ́ Kristẹni wà rí gẹ́lẹ́ bíi ti ìjọ tí ó wà ní Laodéṣíà, tí Jésù wí fún pé: “Nítorí ìwọ́ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.”—Ìṣípayá 3:17.

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ẹnì kan tí ń fi torí tọrùn ṣàtìlẹ́yìn Ṣọ́ọ̀ṣi Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kọ̀wé sí ilé iṣẹ́ ìwé agbéròyìnjáde kan ní ṣíṣàròyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “nìkan ṣoṣo ni wọ́n jàǹfààní láti inú” ayẹyẹ yìí. Kí ló dé tí ó fi rò bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé pé ìṣípayá tí a fi han Jòhánù “ní ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ kan náà nípa òpin ayé pẹ̀lú ti ipò ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi taápọntaápọn sakun láti “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” nípa wíwà lójúfò sí ìmúṣẹ ète Ọlọ́run. Wọ́n tún ń fẹ́ láti ran gbogbo àwọn olótìítọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti ‘wà lójúfò, kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn,’ Jésù Kristi.—Mátíù 24:42; Lúùkù 21:36.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe lọ, ọdún yẹn ní àyájọ́ àjọ̀dún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún tí a kọ ìwé Ìṣípayá (Gíríìkì, a·po·kaʹly·psis) lókè Pátímọ́sì. Ẹ̀rí tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé fi hàn pé ọdún 96 Sànmánì Tiwa ni a kọ Ìṣípayá.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

“Ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí ti nínáwó ré kọjá àlà” àti “ayẹyẹ tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

“Ìsúre láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ìsàlẹ̀ . . . ti sú àwọn ènìyàn”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Fọ́tò: Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́