ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 14-19
  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń fi Ayọ̀ Ka Ìwé Ìṣípayá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń fi Ayọ̀ Ka Ìwé Ìṣípayá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjọ Tí Kristi Ń Darí
  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹrí Ba fún Ipò Ọba Aláṣẹ Jèhófà
  • ‘Aláyọ̀ Ni Ẹnikẹ́ni Tí Ń Pa Àwọn Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Mọ́’
  • Bí Ìṣípayá Ṣe Kàn Ọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ohun Tó Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • “Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀” Látinú Ìwé Ìṣípayá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 14-19

Jẹ́ Ẹni Tí Ń fi Ayọ̀ Ka Ìwé Ìṣípayá

“Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.”—ÌṢÍPAYÁ 1:3.

1. Ipò wo ni àpọ́sítélì Jòhánù wà nígbà tó kọ ìwé Ìṣípayá, ète wo la sì fi kọ àwọn ìran wọ̀nyí sílẹ̀?

“ÈMI JÒHÁNÙ, . . . wá wà ní erékùṣù tí a ń pè ní Pátímọ́sì nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Ipò tí àpọ́sítélì Jòhánù wà nìyẹn nígbà tó kọ ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn. Ó ní láti jẹ́ pé a kó o nígbèkùn lọ sí Pátímọ́sì nígbà ìṣàkóso Olú Ọba Domitian ti Róòmù (ní ọdún 81 sí 96 Sànmánì Tiwa), ẹni tó fi dandan lé e pé káwọn èèyàn máa jọ́sìn olú ọba, tó sì torí èyí ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni. Pátímọ́sì ni Jòhánù wà tó ti rí ọ̀pọ̀ ìran tó kọ sílẹ̀. Ó ṣàlàyé ohun tó rí fáwọn Kristẹni ìjímìjí, kì í ṣe kí ẹ̀rù lè máa bà wọ́n, ṣùgbọ́n kí ó lè fún wọn lókun, kí ó lè tù wọ́n nínú, kí ó sì lè fún wọn níṣìírí, nítorí àdánwò tó dé bá wọn àti èyí tó wà níwájú.—Ìṣe 28:22; Ìṣípayá 1:4; 2:3, 9, 10, 13.

2. Èé ṣe tí ipò tí Jòhánù àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá ara wọn fi jẹ́ ohun tí àwọn Kristẹni òde òní ń fún láfiyèsí?

2 Àwọn ipò táa ti kọ ìwé Bíbélì yìí ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn Kristẹni tó wà lóde ìwòyí. Jòhánù ń fara gbá inúnibíni nítorí pé ó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà àti Kristi Jésù, Ọmọ rẹ̀. Ẹ̀tanú pọ̀ lápọ̀jù lágbègbè tóun àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń gbé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń sapá láti jẹ́ aráàlú rere, kò gbà láti jọ́sìn olú ọba. (Lúùkù 4:8) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí bá ara wọn nírú ipò kan náà, níbi tí Ìjọba ti gbà pé àwọn ló lè pàṣẹ “ohun tó tọ́ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwé Ìṣípayá ti tuni nínú tó, ó wí pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Ìṣípayá 1:3) Òdodo ọ̀rọ̀ ni, àwọn tó bá ń fara balẹ̀ ka ìwé Ìṣípayá, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò rí ayọ̀ tòótọ́ àti ọ̀pọ̀ ìbùkún.

3. Ta ni Orísun Ìṣípayá táa fi han Jòhánù?

3 Ta ni Orísun ìwé Ìṣípayá náà gan-an, ọ̀nà wo ló sì gbà tàtaré rẹ̀ sí wa? Ẹsẹ àkọ́kọ́ fèsì pé: “Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Ó sì rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, ó sì gbé e kalẹ̀ nípa àwọn àmì nípasẹ̀ rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ Jòhánù.” (Ìṣípayá 1:1) Lọ́nà tó lè tètè yéni, Jèhófà Ọlọ́run ni Orísun ìwé Ìṣípayá, òun ló fún Jésù, Jésù sì tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan sọ ọ́ fún Jòhánù. Àyẹ̀wò fínnífínní síwájú sí i fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ni Jésù lò láti gbé ìhìn iṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ ìjọ, òun ló sì lò láti fi ìran náà han Jòhánù.—Ìṣípayá 2:7, 11, 17, 29; 3:6, 13, 22; 4:2; 17:3; 21:10; fi wé Ìṣe 2:33.

4. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ṣì ń lò lónìí láti darí àwọn ènìyàn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé?

4 Jèhófà ṣì ń lo Ọmọ rẹ̀, “orí ìjọ” láti kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. (Éfésù 5:23; Aísáyà 54:13; Jòhánù 6:45) Jèhófà tún ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (Jòhánù 15:26; 1 Kọ́ríńtì 2:10) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti lo “ẹrú rẹ̀ Jòhánù” láti mú oúnjẹ tẹ̀mí tí ń ṣara lóore lọ fún àwọn ìjọ tó wà ní ọ̀rúndún kìíní, bákan náà lónìí, ó ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn ni “àwọn arákùnrin” rẹ̀ ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé, láti pèsè “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” fún àwọn ará ilé rẹ̀ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Mátíù 24:45-47; 25:40) Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n mọ Orísun ‘ẹ̀bùn rere’ tí a ti ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà àti ọ̀nà tí Ó ń lò.—Jákọ́bù 1:17.

Ìjọ Tí Kristi Ń Darí

5. (a) Kí la fi àwọn ìjọ Kristẹni àti àwọn alábòójútó wọn wé? (b) Láìka àìpé ẹ̀dá ènìyàn sí, kí ni yóò máa fi kún ayọ̀ wa?

5 Nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìṣípayá, a fi àwọn ìjọ Kristẹni wé àwọn ọ̀pá fìtílà. A fi àwọn alábòójútó wọn wé áńgẹ́lì (àwọn ońṣẹ́), a sì tún fi wọ́n wé ìràwọ̀. (Ìṣípayá 1:20)a Nígbà tí Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀, ó ní kí Jòhánù kọ̀wé pé: “Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹni tí ó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà.” (Ìṣípayá 2:1) Iṣẹ́ méje tó rán sí àwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà fi hàn pé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn ìjọ àti àwọn alàgbà wọn ní àwọn ànímọ́ tó dáa, wọ́n sì tún ní ibi tó ti kù díẹ̀ káàtó fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí. Nítorí náà, a óò túbọ̀ jẹ́ aláyọ̀ bí a kò bá gbàgbé pé, Kristi, Orí wa, wà láàárín ìjọ. Ó kúkú mohun tó ń lọ. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó wà ní “ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,” ìyẹn ni pé, òun ló ń darí wọn, tó ń tọ́ wọn sọ́nà, òun sì ni wọn yóò jíhìn gbogbo ọ̀nà tí wọ́n bá gbà bójú tó ìjọ náà fún.—Ìṣe 20:28; Hébérù 13:17.

6. Kí ló fi hàn pé kì í ṣe àwọn alábòójútó nìkan ni yóò jíhìn fún Kristi?

6 Àmọ́ ṣá o, ara wa là ń tàn jẹ táa bá lọ rò pé àwọn alábòójútó nìkan ló máa jíhìn ohun tí wọ́n bá ṣe fún Kristi. Kristi sọ nínú ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ tó rán sí àwọn ìjọ pé: “Gbogbo àwọn ìjọ yóò mọ̀ pé èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.” (Ìṣípayá 2:23) Bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe jẹ́ ìkìlọ̀, bẹ́ẹ̀ ló tún jẹ́ ìṣírí—ìkìlọ̀ ni, ní ti pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé Kristi mọ ohun tó wà lọ́kàn wa lọ́hùn-ún, ìṣírí sì ni, nítorí pé ó mú un dá wa lójú pé Kristi rí gbogbo akitiyan wa, yóò sì bù kún wa, báa bá ṣe gbogbo èyí táa lè ṣe.—Máàkù 14:6-9; Lúùkù 21:3, 4.

7. Báwo ni àwọn Kristẹni ní Filadéfíà ‘ṣe pa ọ̀rọ̀ Jésù nípa ìfaradà mọ́’?

7 Nínú iṣẹ́ tí Kristi rán sí ìjọ tó wà ní ìlú Lìdíà tí à ń pè ní Filadéfíà, kò bá wọn wí rárá, ṣùgbọ́n ó ṣe ìlérí kan ti àwa pẹ̀lú yóò nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. “Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.” (Ìṣípayá 3:10) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà fún “pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́” lè túmọ̀ sí “pa ohun tí mo sọ nípa ìfaradà mọ́.” Ẹsẹ ìkẹjọ jẹ́ ká mọ̀ pé, kì í ṣe kìkì pé àwọn Kristẹni tó wà ní Filadéfíà ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi nìkan ni àmọ́ wọ́n tún tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ láti lo ìfaradà láìbojú wẹ̀yìn.—Mátíù 10:22; Lúùkù 21:19.

8. (a) Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún àwọn Kristẹni tó wà ní Filadéfíà? (b) Àwọn wo ni “wákàtí ìdánwò” kàn lónìí?

8 Jésù fi kún un pé òun yóò pa wọ́n mọ́ kúrò nínú “wákàtí ìdánwò.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí fáwọn Kristẹni nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a ò mọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́yìn tí Domitian kú lọ́dún 96 Sànmánì Tiwa, inúnibíni náà rọlẹ̀ fún sáà kan, ṣùgbọ́n nígbà tí Trajan gorí oyè (ọdún 98 sí 117 Sànmánì Tiwa), inúnibíni tún dé, kò sì sí àní-àní pé ó mú ọ̀pọ̀ àdánwò mìíràn wá. Ṣùgbọ́n “wákàtí ìdánwò” náà gan-an dé ní “ọjọ́ Olúwa” nígbà “àkókò òpin,” tí à ń gbé nínú rẹ̀ yìí. (Ìṣípayá 1:10; Dáníẹ́lì 12:4) Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń jà lọ́wọ́ àti nígbà tí ogun náà parí, àkókò àdánwò tí ó dé bá àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn kúrò ní kékeré. Síbẹ̀, “wákàtí ìdánwò” náà kò tíì parí. Kò sẹ́ni tí kò kàn ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé,” kódà ó kan àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tó para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n ní ìrètí láti la ìpọ́njú ńlá já. (Ìṣípayá 3:10; 7:9, 14) A óò jẹ́ aláyọ̀ báa bá ‘pa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ìfaradà mọ́,’ nígbà tó wí pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 24:13.

Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹrí Ba fún Ipò Ọba Aláṣẹ Jèhófà

9, 10. (a) Ọ̀nà wo ni ìran ìtẹ́ Jèhófà gbà kàn wá? (b) Báwo ni kíkà tí à ń ka ìwé Ìṣípayá ṣe lè fi kún ayọ̀ wa?

9 Ìran ìtẹ́ Jèhófà àti ààfin rẹ̀ ní ọ̀run táa fi hàn nínú orí kẹrin àti ìkarùn-ún ìwé Ìṣípayá yẹ kó mú wa wá rìrì. Ó yẹ kórí wa wú nígbà táa gbọ́ orin ìyìn àtọkànwá tí ń jáde lẹ́nu àwọn ẹ̀dá alágbára ńlá tí ń bẹ ní ọ̀run, tí wọ́n sí ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ òdodo ti Jèhófà. (Ìṣípayá 4:8-11) Ó yẹ ká lè gbóhùn wa láàárín àwọn tó ń sọ pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.”—Ìṣípayá 5:13.

10 Táa bá wò ó dáadáa, a óò rí i pé èyí túmọ̀ sí pé kí a máa fi tayọ̀tayọ̀ gbà láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà nínú ohun gbogbo. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní iṣẹ́, ẹ máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Jésù Olúwa, kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀.” (Kólósè 3:17) Táa bá ń ka ìwé Ìṣípayá, ayọ̀ wa yóò kún, ìyẹn tó bá jẹ́ pé lọ́kàn wa lọ́hùn-ún, a gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, táa sì ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa.

11, 12. (a) Báwo ni a óò ṣe mi ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé jìgìjìgì, tí a óò si pá a run? (b) Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá orí keje, ta ni yóò “lè dúró” nígbà yẹn?

11 Fífi tayọ̀tayọ̀ tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti gbogbo ayé lápapọ̀ bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀. Láìpẹ́, mìmì ńlá kan yóò mi ètò ayé Sátánì jìgìjìgì títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀, yóò sì pa á run. Gbogbo àwọn tí kò tẹrí ba fún Ìjọba Kristi ti ọ̀run, èyí tó ń ṣojú fún ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso aráyé, kò ní ríbi sá sí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ènìyàn onípò gíga jù lọ àti àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára àti olúkúlùkù ẹrú àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní òmìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò àti sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá. Wọ́n sì ń sọ fún àwọn òkè ńlá àti fún àwọn àpáta ràbàtà pé: ‘Ẹ wó bò wá, kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò ní ojú Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti kúrò nínú ìrunú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, nítorí ọjọ́ ńlá ìrunú wọn ti dé, ta ni ó sì lè dúró?’”—Ìṣípayá 6:12, 15-17.

12 Láti lè dáhùn ìbéèrè yìí, nínú orí tó tẹ̀ lé e, àpọ́sítélì Jòhánù ṣàpèjúwe àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá, ìyẹn ni àwọn tó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, pé “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 7:9, 14, 15) Dídúró tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run fi hàn pé wọ́n bọlá fún ìtẹ́ yẹn, wọ́n sì tẹrí ba pátápátá fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà. Abájọ táa fi tẹ́wọ́ gbà wọ́n.

13. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ayé ń jọ́sìn, kí sì ni àmì tó wà níwájú orí tàbí ọwọ́ wọn dúró fún? (b) Nítorí náá, èé ṣe tí ìfaradà fi ṣe pàtàkì?

13 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, orí kẹtàlá ṣàpèjúwe àwọn olùgbé ayé yòókù gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń jọ́sìn ètò ìṣèlú Sátánì, tí ẹranko ẹhànnà ń ṣàpẹẹrẹ. Wọ́n gba àmì kan sí “iwájú orí” wọn tàbí ní “ọwọ́” wọn, èyí to fi hàn pé bí wọ́n ti ń fi ọpọlọ wọn ṣètìlẹyìn fún ètò yẹn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń lo ara wọn fún un. (Ìṣípayá 13:1-8, 16, 17) Ẹ̀yìn èyí ni orí kẹrìnlá wá fi kún un pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, tí ó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀, òun yóò mu pẹ̀lú nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tí a tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìrunú rẹ̀ . . . Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.” (Ìṣípayá 14:9, 10, 12) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìbéèrè náà yóò túbọ̀ máa wá pé: Ti ta ni ìwọ í ṣe? Ṣé ti Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ni àbí ti ètò ìṣèlú tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí ẹranko ẹhànnà náà ń ṣàpẹẹrẹ? Gbogbo àwọn tó bá kọ̀ láti gba àmì ẹranko náà, tí wọ́n sì fara dà á délẹ̀délẹ̀ nípa títẹríba fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà yóò jẹ́ aláyọ̀.

14, 15. Ọ̀rọ̀ wo ló já lu àpèjúwe Amágẹ́dọ́nì nínú ìwé Ìṣípayá, kí lèyí sì túmọ̀ sí fún wa?

14 Àwọn alákòóso “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” ti ń forí jálé agbọ́n báyìí o, wọ́n fẹ́ gbéjà ko Jèhófà lórí ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé. Bíkún ló loko, bí tàkútè ni, ìpàdé di Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Gbólóhùn kan tó ṣeni ní kàyéfì jáde lẹ́yìn àpèjúwe nípa báa ṣe kó àwọn alákòóso ayé jọ láti bá Jèhófà jà. Jésù fúnra rẹ̀ ló já lu ìràn tó ń lọ lọ́wọ́ náà, ó sì wí pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò, tí ó sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.” (Ìṣípayá 16:15) Èyí lè máa tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, àwọn tó jẹ́ pé bíbọ́ là ń bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto, tí a sì máa ń dójú tì wọ́n ní gbangba, báa bá ká wọn mọ́ pé wọ́n ń sùn lẹ́nu iṣẹ́.

15 Ìkìlọ̀ náà ṣe kedere: Báa bá fẹ́ la Amágẹ́dọ́nì já, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí a sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè wa mọ́, ìyẹn ẹ̀wù ìṣàpẹẹrẹ tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí tòótọ́ la jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. A óò jẹ́ aláyọ̀ báa bá yẹra fún títòògbé nípa tẹ̀mí, táa sì ń bá a lọ láìṣàárẹ̀, tí a ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú pípòkìkí “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” ti Ìjọba Ọlọ́run táa ti gbé kalẹ̀.—Ìṣípayá 14:6.

‘Aláyọ̀ Ni Ẹnikẹ́ni Tí Ń Pa Àwọn Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Mọ́’

16. Èé ṣe tí àwọn orí tó kẹ́yìn nínú ìwé Ìṣípayá fi jẹ́ ìdí pàtàkì fún ayọ̀?

16 Kò sí nǹkan míì táwọn tó ń fayọ̀ ka ìwé Ìṣípayá lè ṣe ju pé kí wọ́n túbọ̀ máa yọ̀ bí wọ́n ti ń ka àwọn orí tó kẹ́yìn tó ṣàpèjúwe ìrètí ológo tó ń dúró dè wá—ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun, ìyẹn ni, Ìjọba òdodo ti òkè ọ̀run tí yóò ṣàkóso lórí àwùjọ ènìyàn tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fọ̀ mọ́, tí gbogbo rẹ̀ yóò sì mú ìyìn wá fún “Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 21:22) Bí àwọn ìran àgbàyanu náà ti ń parí lọ, áńgẹ́lì tó ń jíṣẹ́ náà sọ fún Jòhánù pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run àwọn àgbéjáde onímìísí tí ó jẹ́ ti àwọn wòlíì rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde láti fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀. Sì wò ó! mo ń bọ̀ kíákíá. Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́.”—Ìṣípayá 22:6, 7.

17. (a) Ìdánilójú wo la fúnni nínú Ìṣípayá 22:6?(b) Kí ló yẹ ká wà lójúfò láti yẹra fún?

17 Àwọn tí ń fayọ̀ ka ìwé Ìṣípayá yóò rántí pé ọ̀rọ̀ bí èyí wà ní ìbẹ̀rẹ̀ “àkájọ ìwé” yìí. (Ìṣípayá 1:1, 3) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú kó dá wa lójú pé gbogbo “àwọn ohun” táa sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì yìí yóò “ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” A ti wọnú àkókó òpin tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì táa sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá gbọ́dọ̀ tètè ṣẹlẹ̀ ní tẹ̀-lé-ǹ-tẹ̀-lé. Nítorí náà, tó bá dà bí pé ètò Sátánì ń fẹsẹ̀ múlẹ̀, èyí ò gbọ́dọ̀ mú wa sùn lọ. Àwọn òǹkàwé tó wà lójúfò yóò máa rántí àwọn ìkìlọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ táa rán sí àwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà, wọ́n á sì yẹra fún kíkó sínú ọ̀fìn ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, ẹ̀mí ìlọ́wọ́ọ́wọ́, àti ìpẹ̀yìndà.

18, 19. (a) Èé ṣe tí Jésù fi gbọ́dọ̀ wá, ìrétí wo ni Jòhánù sọ tí àwa náà nígbàgbọ́ nínú rẹ̀? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi ní láti “máa bọ̀”?

18 Nínú ìwé Ìṣípayá, Jésù kéde lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Mo ń bọ̀ kíákíá.” (Ìṣípayá 2:16; 3:11; 22:7, 20a) Àfi kó yáa wá o, kó wá ṣèdájọ́ Bábílónì Ńlá, ètò ìṣèlú Sátánì, àti gbogbo àwọn tó kọ̀ láti tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà, èyí tí Ìjọba Mèsáyà ń ṣojú fún báyìí. A pa ohùn wa pọ̀ mọ́ tí àpọ́sítélì Jòhánù, ẹni tó polongo pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”—Ìṣípayá 22:20b.

19 Jèhófà fúnra rẹ̀ wí pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ kíákíá, èrè tí mo sì ń fi fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ ti rí.” (Ìṣípayá 22:12) Báa ti ń dúró de èrè ológo ti ìyè tí kò lópin gẹ́gẹ́ bí apá kan “ọ̀run tuntun” tàbí “ilẹ̀ ayé tuntun” táa ṣèlérí, ẹ jẹ́ ká máa fi ìtara dara pọ̀ nínú nínawọ́ ìkésíni náà sí àwọn olóòótọ́ ọkàn, ká máa wí pé: “Máa bọ̀!” Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ǹjẹ́ kí àwọn pẹ̀lú wá di ẹni tó ń fi ayọ̀ kàwé Ìṣípayá, ìwé tó ní ìmísí, tó sì ń múni lórí yá!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, ojú ìwé 28 sí 29, 136 (àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé).

Àwọn Kókó Àtúnyẹ̀wò

◻ Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà tàtaré ìwé Ìṣípayá, kí la sì lè rí kọ́ nínú èyí?

◻ Èé ṣe táa fi ní láti láyọ̀ pé a láǹfààní láti ka iṣẹ́ táa rán sí àwọn ìjọ méje ní Éṣíà?

◻ Báwo la ṣe lè pa wá mọ́ nígbà “wákàtí ìdánwò”?

◻ Ayọ̀ wo ni a óò ní báa bá tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé tó wà nínú ìwé Ìṣípayá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Aláyọ̀ ni àwọn tó bọlá fún Orísun àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Aláyọ̀ ni ẹni tó bá wà lójúfò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́