ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 9-14
  • “Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀” Látinú Ìwé Ìṣípayá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀” Látinú Ìwé Ìṣípayá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Onílàbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀
  • Ohun Tí Ìwé Ìṣípayá Ní fún Wa
  • Ọ̀dọ́ Àgùntàn Tó Tóó Bọlá Fún
  • “Òótọ́ àti Òdodo ni Àwọn Ìdájọ́ Rẹ̀”
  • Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Ológo
  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń fi Ayọ̀ Ka Ìwé Ìṣípayá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Aláyọ̀!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Bí Ìṣípayá Ṣe Kàn Ọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 9-14

“Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀” Látinú Ìwé Ìṣípayá

“Mo . . . rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé.”—ÌṢÍPAYÁ 14:6.

1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé a mí sí ìwé Ìṣípayá, èé ṣe tí a kò fi lè pè wọ́n ní “ẹ̀sìn aríran ìyọnu”?

NÍ ÒDÌKEJÌ pátápátá sí ẹ̀sùn táwọn kan fi kàn wọ́n, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe “aríran ìyọnu” tàbí “ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ akéde àjálù.” Àmọ́ ṣá o, wọ́n gbà pé apá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí ni ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn jẹ́. Òótọ́ ni pé, ìdájọ́ àwọn ẹni ibi wà nínú ìwé Ìṣípayá. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ń jẹ́rìí fáwọn èèyàn, ohun tí wọ́n ń tẹnu mọ́ ni ìrètí àgbàyanu tí Bíbélì gbé kalẹ̀, títí kan èyí tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn. Wọn ò jẹ́ fi kún àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, tàbí kí wọ́n yọ kúrò níbẹ̀.

Àwọn Onílàbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀

2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn?

2 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń fi gbe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba tí wọ́n ń ṣe lẹ́sẹ̀ ni gbólóhùn Jésù náà pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW) Kí ni “ìhìn rere ìjọba yìí”? Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ni yóò dáhùn nípa fífa àwọn ẹsẹ yọ látinú ìwé Ìṣípayá orí ogún àti orí kọkànlélógún, tó sọ nípa Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi àti Ìjọba rẹ̀ àti àwùjọ ènìyàn, níbi tí ikú, ọ̀fọ̀, àti ìrora ‘kò ní sí mọ́.’—Ìṣípayá 20:6; 21:1, 4.

3. Iṣẹ́ wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe bá mu?

3 Gẹ́gẹ́ bí onílàbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ agbẹnusọ fún ońṣẹ́ ìṣàpẹẹrẹ kan ní ọ̀run, ẹni táa ṣàpèjúwe iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá. “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6) Lára ohun tó para pọ̀ jẹ́ “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” ni ìkéde náà pé “ìjọba [tàbí, ìṣàkóso] ayé” ti “di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀” àti pé “àkókò [tí Jèhófà] yàn kalẹ̀” ti dé “láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:15, 17, 18) Àbí èyí kì í ṣe ìhìn rere ni?

Ohun Tí Ìwé Ìṣípayá Ní fún Wa

4. (a) Àwọn òtítọ́ pàtàkì wo la là sílẹ̀ nínú Ìṣípayá orí kìíní? (b) Kí là ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní nínú làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ náà?

4 Òrí àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣípayá fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí “Ááfà àti Ómégà, . . . “Ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀, Olódùmarè.” Ó sì fi Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, hàn gẹ́gẹ́ bí “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé,” “Àkọ́bí nínú àwọn òkú,” àti “Olùṣàkóso àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Ó tún sọ nípa Jésù gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì tú wa kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:5, 8) Nípa báyìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ìwé Ìṣípayá ti ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ pàtàkì tó ń gbẹ̀mí là. “Àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé” kò ní lè jàǹfààní nínú làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ táa mú wá fún wọn àyàfi tí wọ́n bá gba Jèhófà lọ́ba aláṣẹ, tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù táa ta sílẹ̀, tí wọ́n sì gbà pé Jèhófà jí Kristi dìde àti pé òun ni Alákòóso tí Ọlọ́run yàn láti darí ayé.—Sáàmù 2:6-8.

5. Iṣẹ́ wo la sọ pé Kristi ń ṣe nínú orí kejì àti ìkẹta inú ìwé Ìṣípayá?

5 Orí méjì tó tẹ̀ lé e sọ̀rọ̀ Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bí Alábòójútó onífẹ̀ẹ́, tó ń ti òkè ọ̀run bójú tó ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ìmọ̀ràn tó gbámúṣé tó ṣeé múlò lóde ìwòyí ló wà nínú àkájọ ìwé táa kọ sí àwọn ìjọ Kristẹni méje táa ṣàyàn, tó wà ní Éṣíà Kékeré, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀rọ̀ bí “mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ” tàbí “mo mọ ìpọ́njú . . . rẹ” la fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ táa rán sáwọn ìjọ ọ̀hún. (Ìṣípayá 2:2, 9) Bẹ́ẹ̀ ni, Kristi mọ gbogbo ohun tó ń lọ nínú ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó gbóríyìn fún wọn fún ìfẹ́ tí wọ́n ní, ìgbàgbọ́ wọn, òpò wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ìfaradà wọn, àti ìṣòtítọ́ wọn sí orúkọ àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó bá àwọn mìíràn wí nítorí pé wọ́n ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ tutù, tàbí nítorí pé wọ́n ti sọra wọn di oníṣekúṣe, abọ̀rìṣà, tàbí torí pé wọ́n ti di apẹ̀yìndà tó ti yapa.

6. Kí ni ìran táa kọ sínú orí kẹrin ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀?

6 Orí kẹrin gbé ìran kan tó bani lẹ́rù gidigidi kalẹ̀ nípa ìtẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ní ọ̀run. Ó jẹ́ ká rí díẹ̀ lára ògo Jèhófà tó yí ibi tó wà ká, ó sì jẹ́ ká rí ètò ìṣàkóso ti ọ̀run tó fẹ́ẹ́ lò. Bẹ́ẹ̀ ló tún jẹ́ ká rí àwọn alákòóso táa dé ládé, tí ìtẹ́ wọn wà yíká ìtẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ ní gbogbo àgbáyé, tí gbogbo wọ́n sì ń júbà Jèhófà, tí wọ́n sì ń pòkìkí pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”—Ìṣípayá 4:11.

7. (a) Kí ni áńgẹ́lì náà pe gbogbo olùgbé ayé láti ṣe? (b) Kí ni apá pàtàkì tó wà nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa?

7 Ǹjẹ́ èyí ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí wọ́n bá fẹ́ gbé lábẹ́ Ìjọba Ẹgbẹ̀rúndún náà, wọ́n gbọ́dọ̀ kọbi ara sí ohun tí “áńgẹ́lì . . . tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run” ń polongo pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.” (Ìṣípayá 14:6, 7) Ọ̀kan lára olórí ète iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ni láti ran “àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé” lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, kí wọ́n máa sìn ín, kí wọ́n gbà pé òun ni Ẹlẹ́dàá, kí wọ́n sì máa fínnúfíndọ̀ tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ òdodo rẹ̀.

Ọ̀dọ́ Àgùntàn Tó Tóó Bọlá Fún

8. (a) Báwo la ṣe sọ̀rọ̀ Kristi nínú orí karùn-ún àti ìkẹfà? (b) Kí ni gbogbo àwọn tí wọ́n bá tẹ́tí sí làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ nínú ìran yìí?

8 Àwọn orí méjì tó tẹ̀ lé e, orí karùn-ún àti ìkẹfà, fi Jésù Kristi hàn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn tó tóó ṣí àkájọ ìwé táa fi èdìdì méje dì, tó sì tipa báyìí ṣí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa payá ní èdè ìṣàpẹẹrẹ. (Fi wé Jòhánù 1:29.) Àwọn ohùn kan lókè ọ̀run sọ nípa Ọ̀dọ́ Àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ yìí pé: “Ìwọ ni ó yẹ láti gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, nítorí pé a fikú pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Ìran yìí fi kọ́ni pé lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi táa ta sílẹ̀, a pe àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ibi gbogbo, pé kí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ọ̀run, kí wọ́n sì “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Fi wé Ìṣípayá 1:5, 6.) Lẹ́yìn èyí ni ìwé Ìṣípayá wá sọ ìwọ̀nba iye tí wọ́n mọ.

9. Báwo la ṣe sọ̀rọ̀ Kristi nínú orí kẹfà?

9 Nínú ìran kan náà, a tún fi Kristi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gun ẹsin funfun pẹ̀lú adé lórí, tó ń lọ “ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Ayọ̀ wa ló jẹ́ láti mọ̀ pé, yóò sọ gbogbo òkè àjálù burúkú tí àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́ta yòókù nínú ìwé Ìṣípayá ń ṣàpẹẹrẹ dilẹ̀, àwọn tí ìbínú tí wọ́n fi ń gẹṣin wọn ti yọrí sí ogun, ìyàn, àti ikú fún aráyé láti ọdún mánigbàgbé yẹn, 1914. (Ìṣípayá 6:1-8) Ipa tí kò láfiwé tí Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ń kó nínú ìgbàlà aráyé àti nínú ìmúṣẹ àwọn àgbàyanu ìlérí Jèhófà ni ẹṣin ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.

10. (a) Ìsọfúnni pàtàkì wo la rí nínú orí keje? (b) Báwo ni Kristi ṣe sọ̀rọ̀ àwọn tó gba Ìjọba náà?

10 Tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ló kún inú orí keje ìwé yìí. Inú ìwé Ìṣípayá nìkan la ti rí iye àwọn tí Jésù pè ní “agbo kékeré,” àwọn tí Baba Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà fún ní Ìjọba náà. (Lúùkù 12:32; 22:28-30) Jèhófà Ọlọ́run sì fi èdìdì di àwọn wọ̀nyí nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22) Àpọ́sítélì Jòhánù, ẹni tó gba Ìṣípayá náà, jẹ́rìí sí i pé: “Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì dì, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.” (Ìṣípayá 7:4) Orí mìíràn nínú ìwé yìí tún jẹ́rìí sí iye pàtó táa sọ yìí pé, iye náà ni àpapọ̀ àwọn tí “a rà lára aráyé” láti ṣàkóso pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lórí Òkè Síónì ti ọ̀run. (Ìṣípayá 14:1-4) Níbi tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń fi àtamọ́-mátamọ̀, tálàyé wọn ò lórí tí kò sì nídìí nípa iye yìí, ó dùn mọ́ni pé, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ náà, E. W. Bullinger sọ nípa rẹ̀ pé: “Òtítọ́ tó lè tètè yéni lèyí jẹ́: fífi iye kan pàtó wéra pẹ̀lú iye kan tí kò ṣe pàtó ninú orí kan náà yìí.”

11. (a) Àwọn làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ wo la lè rí nínú orí keje? (b) Kí làwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lè máa fojú sọ́nà fún?

11 Iye tí kò ṣe pàtó wo ni Bullinger ń tọ́ka sí? Ní ẹsẹ ìkẹsàn-án, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Àwọn wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí, kí ni dídúró tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run báyìí túmọ̀ sí, kí sì ni ọjọ́ ọ̀la ní nípamọ́ fún wọn? Ìhìn rere ni ìdáhùn tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ fún àwọn olùgbé ayé. A kà pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi táa ta sílẹ̀, a óò dáàbò bò wọ́n nígbà “ìpọ́njú ńlá náà.” Kristi “yóò . . . máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:14-17) Bẹ́ẹ̀ ni, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tó wà láàyè lónìí lè di apá kan ogunlọ́gọ̀ tí a kò lè kà náà tí yóò la òpin ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí já. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ Ọba náà, Jésù Kristi, nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún rẹ̀, a óò ṣamọ̀nà wọn lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Àbí ìyẹn kì í ṣe ìhìn rere?

“Òótọ́ àti Òdodo ni Àwọn Ìdájọ́ Rẹ̀”

12, 13. (a) Kí ló wà nínú orí kẹjọ sí ìkọkàndínlógún? (b) Èé ṣe tí àwọn olóòótọ́ ènìyàn kò fi gbọ́dọ̀ dààmú nípa irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀?

12 Orí kẹjọ sí ìkọkàndínlógún gan-an ló fà á táwọn kan fi ka ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn sí ìwé alásọtẹ́lẹ̀ àjálù burúkú. Àwọn gbankọgbì iṣẹ́ ìdájọ́ táa darí sí gbogbo apá tó wà nínú ètò àwọn nǹkan ti Sátánì ló wà níbẹ̀ (èyí tí àwọn kàkàkí tó ń dún, ìyọnu, àti àwo ìbínú àtọ̀runwá ń ṣàpẹẹrẹ). Ìsìn èké (ìyẹn ni, Bábílónì Ńlá) ni yóò kọ́kọ́ gba ìdájọ́ yìí, lẹ́yìn náà ni ètò òṣèlú tí kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ yóò rí tiẹ̀ gbà, ètò òṣèlú yìí ni ẹranko ẹhànnà ń ṣàpẹẹrẹ.—Ìṣípayá 13:1, 2; 17:5-7, 15, 16.a

13 Àwọn òrí wọ̀nyí fi bí a óò ṣe fọ ọ̀run mọ́ hàn, nígbà táa bá fi Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Èyí ló fún wa ní àlàyé kan ṣoṣo tó ṣe gúnmọ́ nípa ohun tó fa sábàbí másùnmáwo tírú ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, èyí tó ti dé bá ayé láti ọdún 1914. (Ìṣípayá 12:7-12) Nípa lílo èdè ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n tún ṣàlàyé ìparun tí yóò dé bá ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì, tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 19:19-21) Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kó jìnnìjìnnì bá àwọn olóòótọ́ èèyàn? Rárá o, nítorí pé nígbà tí Ọlọ́run mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, àwọn ogun ọ̀run ké ní ohùn rara pé: “Ẹ yin Jáà! Ìgbàlà àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ọlọ́run wa, nítorí òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀.”—Ìṣípayá 19:1, 2.

14, 15. (a) Báwo la ó ṣe mú òpin ètò nǹkan búburú yìí wá lọ́nà òdodo? (b) Èé ṣe tí apá yìí nínú ìwé Ìṣípayá fi gbọ́dọ̀ mú ayọ̀ wá fún àwọn olóòótọ́ ènìyàn?

14 Jèhófà kò ní mú ètò tuntun òdodo wá láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ mú àwọn tó ń pa ayé run kúrò. (Ìṣípayá 11:17, 18; 19:11-16; 20:1, 2) Àmọ́ ṣá o, kò sí ènìyàn tàbí ètò òṣèlú èyíkéyìí tó ní ọlá àṣẹ tàbí tó lágbára láti ṣe é. Jèhófà nìkan àti Ọba tó ti yàn, tí yóò sì tún jẹ́ Onídàájọ́, ìyẹn ni Kristi Jésù, ló lè fi òdodo ṣe èyí.—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.

15 Gégẹ́ bí ìwé Ìṣípayá ti fi hàn kedere, Jèhófà ní in lọ́kàn láti mú òpin dé bá ètò búburú ti ìsinsìnyí. Èyí tó ayọ̀ fún tọkùnrin tobìnrin “tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí [àwọn ènìyàn] ń ṣe.” (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ó yẹ kí èyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé, ó ṣe pàtàkì láti tètè kọbi ara sí ìpè tí ń dún látẹnu áńgẹ́lì tó ń kéde làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tó kéde pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, . . . nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 14:7) Ǹjẹ́ kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ máa jọ́sìn Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, “tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.”—Ìṣípayá 12:17.

Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Ológo

16. (a) Èé ṣe tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù fi kọ ìrètí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀? (b) Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé a óò gbọ́ àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà?

16 Orí ogún àti ìkejìlélógún ìwé Ìṣípayá ní ìdí tí Ìwé Mímọ́ fún wa táa fi lè ní ìrètí nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún náà. Nínú Bíbélì, apá yìí nìkan ló mẹ́nu kan àkókò ẹgbẹ̀rún ọdún tí yóò ṣáájú ayọ̀ ayérayé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ti kọ ìrètí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀. Níwọ̀n bí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ti fi kọ́ni pé àwọn olódodo yóò lọ sí ọ̀run, tí àwọn ẹni búburú yóò lọ sí ọ̀run àpáàdì, ẹ̀kọ́ náà kò ṣàlàyé nípa párádísè ilẹ̀ ayé rárá. Àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó sọ pé kí “ìfẹ́ [Ọlọ́run] di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run,” kò yé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù rárá. (Mátíù 6:10, New International Version) Ṣùgbọ́n tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run kò dá ayé “lásán,” ṣùgbọ́n ó dá a “kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:12, 18) Nípa báyìí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì, àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ, àti ìrètí tó wà nínú ìwé Ìṣípayá nípa Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún bára mu. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba rẹ̀, Kristi yóò rí i pé ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, àní bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.

17. Kí ló fi hàn pé “ẹgbẹ̀rún ọdún náà” yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún gidi?

17 Gbólóhùn náà “ẹgbẹ̀rún ọdún” fara hàn nígbà mẹ́fà nínú ẹsẹ méje àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣípayá orí ogún. Èyí tó tún gba àfiyèsí ni kókó náà pé a lò ó nígbà mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀rọ̀ atọ́ka tó ṣe pàtó, “náà,” èyí tó fi hàn pé ẹgbẹ̀rún ọdún gidi ló ń tọ́ka sí, kì í ṣe àkókò gígùn kan tí kò ní iye kan pàtó, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé Kirisẹ́ńdọ̀mù fẹ́ kí a gbà gbọ́. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú Ẹgbẹ̀rúndún náà? Lákọ̀ọ́kọ́, ní gbogbo àkókò yẹn, gbogbo gìràgìrà Sátánì á dópin, kò ní lè ta pútú mọ́. (Ìṣípayá 20:1-3; fi wé Hébérù 2:14.) Ìhìn rere mà lèyí jẹ́ o!

18. (a) Èé ṣe táa fi lè pe Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ni “ọjọ́” ìdájọ́? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà?

18 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ń “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún,” la ó fún ní “agbára ṣíṣèdájọ́,” kò sí àní-àní pé àkókò ẹgbẹ̀rún ọdún “ọjọ́” ìdájọ́ gidi ni àkókò yìí yóò jẹ́. (Ìṣípayá 20:4, 6; fi wé Ìṣe 17:31; 2 Pétérù 3:8.) A óò jí àwọn òkú dìde, a óò sì ṣèdájọ́ wọn pẹ̀lú àwọn tó bá la “ìpọ́njú ńlá” já gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, tàbí ìwà wọn ní àkókò yẹn. (Ìṣípayá 20:12, 13) Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà, a óò wá tú Sátánì sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí ó lè dán aráyé wò fún ìgbà ìkẹyìn lẹ́yìn náà, a óò wá pa òun àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ èyíkéyìí tó jẹ́ agbódegbà rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé run títí láé. (Ìṣípayá 20:7-10) A óò kọ orúkọ àwọn ènìyàn tó bá yege ìdánwò náà sínú “ìwé ìyè” lọ́nà tí kò ní ṣeé parẹ́, a óò sì mú wọn wọnú ìgbésí ayé aláyọ̀ àìnípẹ̀kun, wọ́n yóò sì máa sin Jèhófà nínú párádísè ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 20:14, 15; Sáàmù 37:9, 29; Aísáyà 66:22, 23.

19. (a) Èé ṣe táa fi lè ní ìdánilójú pé a óò mú ìlérí àgbàyanu táa là sílẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá ṣẹ láìkùnà? (b) Kí la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀ lé e?

19 Irú làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá nìyẹn. Ìwọ̀nyí kì í ṣe ìlérí asán látẹnu èèyàn o. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’” (Ìṣípayá 21:5) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àwọn làbárè àmúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí? Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ló wà nínú ìwé Ìṣípayá fún àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ti fi hàn, báa bá tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ yóò mú ayọ̀ tí kò lópin wá fún wa nísinsìnyí àti títí láé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìwé Ìṣípayá, wo ìwé náà, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde lọ́dún 1988.

Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Àwọn òtítọ́ pàtàkì wo la rí nínú Ìṣípayá orí kẹrin sí ìkẹfà tó jẹ́ apá pàtàkì nínú làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀?

◻ Àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ wo la rí nínú Ìṣípayá orí keje?

◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn olóòótọ́ ènìyàn dààmú nípa ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá?

◻ Lọ́nà wo ni Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún yóò fi jẹ́ “ọjọ́” ìdájọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọba náà, Jésù Kristi, yóò mú ogun, ìyàn, àti ikú kúrò lórí ilẹ̀ ayé pátápátá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́