Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì ní Romania
GẸ́GẸ́ BÍ GOLDIE ROMOCEAN TI SỌ Ọ́
Ní 1970, mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ìbátan mi ní Romania, fún ìgbà àkọ́kọ́ ní nǹkan bí 50 ọdún. Àwọn ènìyàn ń gbé lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì agbonimọ́lẹ̀, a sì kìlọ̀ fún mi lemọ́lemọ́ láti ṣọ́ ohun tí mo bá sọ. Nígbà yẹn, bí mo ti dúró nínú ọ́fíìsì ìjọba ní abúlé wa, òṣìṣẹ́ ọba náà rọ̀ mí láti fi ìlú sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kí n tó sọ ìdí tí ó fi sọ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì ní Romania ná.
A BÍ mi ní March 3, 1903, ní abúlé Ortelec, ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Romania, nítòsí ìlú Zalău. Àyíká ẹlẹ́wà ni a ń gbé. Kò sí èérí nínú omi àti afẹ́fẹ́. Fúnra wa ni a gbin oúnjẹ tí a ń jẹ, kò sì sí ohun tí ó wọ́n wa nípa ti ara. Nígbà tí mo wà ní kékeré, orílẹ̀-èdè náà tòrò.
Àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn gan-an. Ní tòótọ́, oríṣi ìsìn mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìdílé wa dara pọ̀ mọ́. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni ìyá bàbá mi, ìjọ Adventist ni ìyá ìyá mi ń lọ, ìjọ Onítẹ̀bọmi sì ni àwọn òbí mi ń dara pọ̀ mọ́. Nítorí pé n kò fara mọ́ èyíkéyìí nínú ẹ̀sìn wọn, àwọn ìdílé mi sọ pé èmi yóò di aláìgbọlọ́run-gbọ́. Mo ronú pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni ó wà, ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni ó yẹ kí ó wà pẹ̀lú—kì í ṣe mẹ́ta nínú ìdílé kan ṣoṣo.’
Àwọn ohun tí mo rí nínú ìsìn dààmú mi. Fún àpẹẹrẹ, àlùfáà máa ń bẹ àwọn ènìyàn wò nílé láti gba ẹ̀tọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Bí àwọn ènìyàn kò bá ní owó lọ́wọ́ láti san, yóò gbé kúbùsù olówùú wọn tí ó dára jù lọ láti fi rọ́pò owó wọn. Nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, mo máa ń wo ìyá bàbá mi bí ó ti ń kúnlẹ̀ síwájú àwòrán Màríà. Mo máa ń ronú pé, ‘Èé ṣe tí a fi ní láti gbàdúrà sí àwòrán?’
Àwọn Àkókò Oníyọnu
Bàbá mi lọ sí United States ní 1912 láti lọ ṣiṣẹ́ owó tí yóò fi san gbèsè. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ogun bẹ́ sílẹ̀, àwọn ọkùnrin abúlé wa sì lọ jagun—kìkì àwọn obìnrin, ọmọdé, àti àwọn arúgbó ọkùnrin ni ó kù nílùú. Abúlé wa wà lábẹ́ àkóso àwọn ará Hungary fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn sójà Romania darí dé, wọ́n sì gba abúlé náà pa dà. Wọ́n pàṣẹ fún wa láti fi abúlé sílẹ̀ kíákíá. Ṣùgbọ́n, nínú ìkánjú àti ìdàrúdàpọ̀ kíkó àwọn ohun ìní àti àwọn ọmọ kékeré sínú ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin, wọ́n fi mí sílẹ̀ sẹ́yìn. Ṣé ẹ rí i, èmi ni mo dàgbà jù lọ nínú àwa ọmọ márùn-ún.
Mo sá lọ sọ́dọ̀ aládùúgbò wa, bàbá arúgbó kan tí kò lọ, ó sì sọ fún mi pé: “Lọ sílé. Ti àwọn ilẹ̀kùn yín, má sì ṣílẹ̀kùn fún ẹnikẹ́ni.” Mo tètè ṣègbọràn. Lẹ́yìn tí mo ti jẹ ọbẹ̀ adìyẹ tí a yí mọ́ ewé kábéèjì, tí wọ́n gbà gbé bí wọ́n ti ń kánjú fi abúlé sílẹ̀, mo kúnlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn mi, mo sì gbàdúrà. Kò pẹ́ tí mo fi sùn lọ fọnfọn.
Nígbà tí mo la ojú mi, ilẹ̀ ti mọ́, mo sì sọ pé: “Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ o! Mo jí sílẹ̀ alààyè!” Àwọn ihò ọta kún ara ògiri, níwọ̀n bí wọ́n ti fi gbogbo òru yìnbọn. Nígbà tí Màmá rí i pé n kò sí pẹ̀lú wọn ní abúlé kejì, ó rán ọmọdékùnrin kan tí ń jẹ́ George Romocean, ẹni tí ó rí mi, tí ó sì mú mi lọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó ṣeé ṣe fún wa láti pa dà sí abúlé wa, kí a sì máa gbé ibẹ̀.
Ìfẹ́ Ọkàn Mi fún Òtítọ́ Bíbélì
Ìyá mi fẹ́ kí n ṣe ìrìbọmi sínú ìjọ Onítẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n, n kò fẹ́ ṣe ìyẹn, nítorí pé n kò lè gbà gbọ́ pé, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yóò jó àwọn ènìyàn nínú hẹ́ẹ̀lì títí láé. Ní gbígbìyànjú láti ṣàlàyé, Màmá wí pé: “Hẹn, tí wọ́n bá burú.” Ṣùgbọ́n, mo fèsì pé: “Bí wọ́n bá burú, pa wọ́n run pátápátá, ṣùgbọ́n, máà dá wọn lóró. N kò tilẹ̀ lè dá ajá tàbí ológbò pàápàá lóró.”
Mo rántí pé, ní ọjọ́ dáradára kan ní ìgbà ìrúwé, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 14, Màmá ní kí n kó àwọn màlúù lọ jẹ̀. Bí mo ti dùbúlẹ̀ sórí kóríko lẹ́bàá odò, tí ẹgàn sì wà lẹ́yìn, mo wo ojú ọ̀run, mo sì sọ pé: “Ọlọ́run, mo mọ̀ pé o ń bẹ lókè; ṣùgbọ́n, n kò nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí. O gbọ́dọ̀ ní ọ̀kan tí ó dára.”
Mo gbà gbọ́ ní tòótọ́ pé Ọlọ́run gbọ́ àdúrà mi, nítorí pé, nígbà ẹ̀rùn ti 1917 yẹn gan-an, Àwọn Àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (orúkọ tí a ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà lọ́hùn-ún) méjì wá sí abúlé wa. Apínwèé-ìsìn-kiri, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ni wọ́n, wọ́n sì wọ inú ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi lọ, nígbà tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́.
Òtítọ́ Bíbélì Tàn Kálẹ̀ ní Romania
Ní àwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú, ní 1911, Carol Szabo àti Josif Kiss, tí wọ́n ti di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní United States, pa dà wá sí Romania láti fi òtítọ́ Bíbélì lọ àwọn ènìyàn ibẹ̀. Wọ́n fìdí kalẹ̀ sí Tîrgu-Mureş, tí kò tó 160 kìlómítà ní gúúsù ìlà oòrùn sí abúlé wa. Láàárín ọdún díẹ̀, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn ní ti gidi dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.—Mátíù 24:14.
Tóò, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì náà wọ inú ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi, ní abúlé wa ní Ortelec, George Romocean, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún 18 péré, ni ó ń darí ìsìn náà, ó sì ń gbìdánwò láti ṣàlàyé ìtumọ̀ Róòmù 12:1. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ apínwèé-ìsìn-kiri náà dìde, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ará, ọ̀rẹ́, kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń gbìyànjú láti sọ fún wa níhìn-ín?”
Nígbà tí mo gbọ́ ìyẹn, inú mi dùn! Mo ronú pé, ‘Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní láti mọ bí a ti ń ṣàlàyé Bíbélì.’ Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó wà níjokòó pariwo pé: “Ẹ̀yin èké wòlíì! A mọ ẹni tí ẹ jẹ́!” Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, bàbá George dìde, ó sì sọ pé: “Gbogbo yín, ẹ dákẹ́ ẹnu yín! Irú ẹ̀mí wo nìyí—irú èyí tí ìmutípara ń fà? Bí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bá ní ohun kan láti sọ fún wa, tí ẹ kò sì fẹ́ tẹ́tí sílẹ̀, èmi ń ké sí wọn wá sí ilé mi. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ láti wá lè wá.”
Tìdùnnútìdùnnú, mo sáré lọ sílé, mo sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Màmá. Mo wà lára àwọn tí ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti wá sílé Romocean. Ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì pé, kò sí hẹ́ẹ̀lì oníná, àti láti rí orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, nínú Bíbélì mi lédè Romania! Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri náà ṣètò fún Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan láti máa ṣèbẹ̀wò sí ilé Romocean ní gbogbo ọjọ́ Sunday, láti máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 15, mo ṣe ìrìbọmi ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà.
Bí àkókò ti ń lọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìdílé Prodan àti ti Romocean ni ó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ sí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ míràn ní abúlé wa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, títí kan tọkọtaya tí a lo ilé wọn fún ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n yí i dà di ibi tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ti máa padé fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ tàn kálẹ̀ kíákíá ní àwọn abúlé tí ó wà nítòsí, nígbà tí ó sì máa fi di 1920, àwọn akéde Ìjọba ti tó 1,800 ní Romania!
Mo Lọ sí United States
A ń hára gàgà láti ṣàjọpín ohun tí a ti kọ́ pẹ̀lú bàbá mi, Peter Prodan. Ṣùgbọ́n, lọ́nà yíyanilẹ́nu, kí a tó kọ̀wé, a gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí ń fi tó wa létí pé, òun ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó ti ṣèrìbọmi. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Akron, Ohio, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa dara pọ̀ mọ́ òun ní United States. Ṣùgbọ́n, Màmá kọ̀ láti fi Romania sílẹ̀. Nítorí náà, ní 1921, ní lílo owó tí Bàbá fi ránṣẹ́ sí mi, mo dara pọ̀ mọ́ ọn ní Akron. George Romocean àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ti ṣí lọ sí United States ní ọdún kan ṣáájú.
Nígbà tí mo bá ọkọ̀ ojú omi dé sí Erékùṣù Ellis, New York, òṣìṣẹ́ ọba tí ń wo ìwé àwọn tí ń wọ̀lú, kò mọ ohun tí yóò tú orúkọ mi, Aurelia, sí ní Gẹ̀ẹ́sì, nítorí náà, ó sọ pé: “Goldie ni orúkọ rẹ.” Orúkọ mi nìyẹn láti ìgbà náà wá. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ní May 1, 1921, èmi àti George Romocean ṣèyàwó. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Bàbá pa dà lọ sí Romania, ó sì mú Mary, àbúrò mi, pa dà wá sí Akron, ní 1925. Lẹ́yìn náà, Bàbá pa dà sí Romania láti wà pẹ̀lú Màmá àti ìyókù ìdílé wa.
Ìbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa ní United States
George jẹ́ adúróṣinṣin, ìránṣẹ́ tí ó fara jin Jèhófà pátápátá. Láàárín 1922 sí 1932, a fi àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin àtàtà jíǹkí wa—Esther, Anne, Goldie Elizabeth, àti Irene. A bẹ̀rẹ̀ ìjọ tí ń sọ èdè Romania ní Akron, ilé wa ni a sì ti ń ṣe àwọn ìpàdé ní ìbẹ̀rẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní oṣù mẹ́fà mẹ́fà, aṣojú láti orílé-iṣẹ́ àgbáyé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Brooklyn, New York, máa ń ṣèbẹ̀wò sí ìjọ wa, ó sì máa ń dé sílé wa.
Ní ọ̀pọ̀ Sunday, a máa ń ya gbogbo ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù. A óò di àwọn àpò tí a ń kó ìwé sí, a óò sì di oúnjẹ ọ̀sán, a óò kó àwọn ọmọdébìnrin wa sínú ọkọ̀ Model T Ford wa, a óò sì lo ọjọ́ náà nínú iṣẹ́ ìwàásù ní ìgbèríko. Lẹ́yìn náà, ní ìrọ̀lẹ́, a máa ń péjọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àwọn ọmọdébìnrin wa wá nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù. Ní 1931, mo wà níbẹ̀, ní Columbus, Ohio, nígbà tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́wọ́ gba orúkọ tí ó fi wọ́n hàn yàtọ̀ gédégbé náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àtúnṣe Tí Mo Nílò
Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo bínú sí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà lọ́hùn-ún. Ẹlẹ́rìí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi kan rò pé Arákùnrin Rutherford kò bá òun lò lọ́nà tí ó tọ́, ní ṣíṣàì tẹ́tí sí ìṣòro òun dáradára. Mo rò pé, ohun tí Arákùnrin Rutherford ṣe kò tọ̀nà. Tóò, ní ọjọ́ Sunday kan, àbúrò mi, Mary, àti ọkọ rẹ̀, Dan Pestrui, bẹ̀ wá wò. Lẹ́yìn oúnjẹ, Dan sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a múra láti lọ sí ìpàdé.”
Mo sọ pé: “A kì í lọ sí ìpàdé mọ́. A ń bínú sí Arákùnrin Rutherford.”
Dan ká ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn rẹ̀, ó rìn lọ rìn bọ̀, ó wá sọ pé: “Ìwọ ha mọ Arákùnrin Rutherford nígbà tí o ṣèrìbọmi bí?”
Mo fèsì pé: “N kò mọ̀ ọ́n rárá. O ṣáà mọ̀ pé Romania ni mo ti ṣèrìbọmi.”
Ó béèrè pé: “Èé ṣe tí o fi ṣèrìbọmi?”
Mo fèsì pé: “Nítorí tí mo kọ́ pé, Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ náà, mo sì fẹ́ ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ín.”
Ó fèsì pé: “Má ṣe gbàgbé ìyẹn láé! Bí Arákùnrin Rutherford bá fi òtítọ́ sílẹ̀, ìwọ yóò ha fi í sílẹ̀ bí?”
Mo sọ pé: “Láéláé!” Ìyẹn pe orí mi wálé, mo sì sọ pé: “Gbogbo yín, ẹ múra ìpàdé.” A kò sì tí ì ṣíwọ́ láti ìgbà yẹn. Ẹ wo bí mo ti kún fún ìmoore tó sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ tí àna mi fún mi!
Mímú Awọ Kájú Ìlù Nígbà Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé
Nígbà Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé ní àwọn ọdún 1930, nǹkan le gan-an. Ní ọjọ́ kan, George darí sílé láti ibi iṣẹ́ tìbànújẹ́-tìbànújẹ́, ó fi tó mi létí pé wọ́n ti lé òun kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tí òun ń ṣe ní ilé iṣẹ́ rọ́bà. Mo sọ fún un pé: “Má dààmú, a ní Bàbá ọlọ́rọ̀ ní ọ̀run, òun kò sì ní fi wá sílẹ̀.”
Ní ọjọ́ yẹn gan-an, George ṣalábàápàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó ní agbọ̀n ńlá tí olú kún inú rẹ̀. Nígbà tí George gbọ́ ibi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ṣà wọ́n, ó wá sílé pẹ̀lú ẹ̀kún agbọ̀n olú. Lẹ́yìn náà, ó lo dọ́là mẹ́ta tí ó kù sọ́wọ́ wa lórí ríra àwọn apẹ̀rẹ̀ kéékèèké. Mo bi í pé: “Èé ṣe tí o fi ṣe ìyẹn, nígbà tí o mọ̀ pé a ní àwọn ọmọdébìnrin kéékèèké, tí wọ́n nílò wàrà?”
Ó fèsì pé: “Fọkàn balẹ̀, ṣáà ṣe bí mo ti wí.” Fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, a ní ilé iṣẹ́ kékeré kan ní ilé wa, tí ń fọ olú tí ó sì ń kó wọn jọ. A máa ń tà wọ́n fún àwọn ilé àrójẹ tí ń pa àdéhùn mọ́, a sì máa ń pa 30 sí 40 dọ́là lóòjọ́, owó ńlá ni ó jẹ́ fún wa nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Àgbẹ̀ tí ó fún wa láṣẹ láti tu olú nínú ọgbà rẹ̀, sọ pé, ó ti tó ọdún 25 tí òun ti ń gbé níbẹ̀, òun kò sì tí ì rí olú tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ilé iṣẹ́ rọ́bà náà pe George pa dà sẹ́nu iṣẹ́.
Dídi Ìgbàgbọ́ Wa Mú
Ní 1943, a ṣí lọ sí Los Angeles, California, a sì fi Elsinore ṣe ibùjókòó, ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà. A ṣí ìsọ̀ ọjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ níbẹ̀, gbogbo mẹ́ńbà ìdílé wa sì máa ń gba dídúró síbẹ̀ fún ara wa. Ní ìgbà náà lọ́hùn-ún, Elsinore wulẹ̀ jẹ́ ìlú kékeré kan, tí ó ní nǹkan bí 2,000 ènìyàn, a sì ní láti rìnrìn àjò 30 kìlómítà lọ sí ìlú mìíràn fún àwọn ìpàdé Kristẹni wa. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti rí ìjọ kékeré kan tí a dá sílẹ̀ ní Elsinore ní 1950! Lónìí, ìjọ 13 ni ó wà ní àgbègbè kan náà.
Ní 1950, ọmọbìnrin wa, Goldie Elizabeth (tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nísinsìnyí sí Beth), kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní South Lansing, New York, a sì yàn án sí Venezuela gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ní 1955, inú Irene, ọmọbìnrin wa tí ó kéré jù lọ, dùn pé a ké sí ọkọ òun láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò nínú iṣẹ́ àyíká. Lẹ́yìn náà, ní 1961, lẹ́yìn lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba ní South Lansing, New York, a rán wọn lọ sí Thailand. Nígbà míràn, àárò àwọn ọmọbìnrin mi máa ń sọ mí gan-an débi pé omi máa ń bọ́ lójú mi, ṣùgbọ́n, mo máa ń ronú lẹ́yìn náà pé, ‘Ohun tí mo fẹ́ kí wọ́n ṣe nìyẹn.’ Nítorí náà, màá gbé àpò ìwé mi, màá sì lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń pa dà sílé tayọ̀tayọ̀.
Ni 1966, ọkọ mi ọ̀wọ́n, George, ní àrùn ẹ̀gbà. Beth, tí ó ti darí wálé láti Venezuela, nítorí ìṣòro ìlera, ṣèrànwọ́ láti tọ́jú rẹ̀. George kú ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, òtítọ́ náà pé, ó pa ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́, pé ó sì ti gba èrè rẹ̀ ti lílọ sí ọ̀run, tù mí nínú. Lẹ́yìn náà, Beth lọ sí Sípéènì láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní fún àwọn oníwàásù Ìjọba ti pọ̀. Esther, ọmọbìnrin mi tí ó dàgbà jù lọ, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn jẹjẹrẹ, ó sì kú ní 1977, ní 1984, àrùn leukemia pa Anne. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti jẹ́ ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
Nígbà tí Anne fi máa kú, Beth àti Irene ti darí wálé láti ibi iṣẹ́ àyànfúnni ìwàásù wọn ní ilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ti ṣèrànwọ́ ní títọ́jú àwọn ẹ̀gbọ́n wọn, gbogbo wá sì kẹ́dùn gidigidi. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo sọ fún àwọn ọmọbìnrin mi pé: “Tóò, ìyẹn ti tó gẹ́ẹ́! A ti fi àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye inú Bíbélì tu àwọn ẹlòmíràn nínú. Nísinsìnyí, a gbọ́dọ̀ gbà kí a tu àwa pẹ̀lú nínú. Sátánì fẹ́ fi ayọ̀ tí a ń rí nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jèhófà dù wá, ṣùgbọ́n, a kò lè gbà á láàyè.”
Ìdílé Wa Olùṣòtítọ́ ní Romania
Èmi àti àbúrò mi, Mary, ni ó rin ìrìn àjò mánigbàgbé yẹn láti bẹ ìdílé wa wò ní Romania ní 1970. Ọ̀kan lára àwọn àbúrò wa obìnrin ti kú, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ John, àbúrò wa ọkùnrin, àti Lodovica, àbúrò wa obìnrin, tí wọ́n ṣì ń gbé ní abúlé Ortelec. Nígbà tí a óò fi ṣèbẹ̀wò, Bàbá àti Màmá ti kú, ní dídúró ní olùṣòtítọ́ sí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ fún wa pé, Bàbá ti jẹ́ òpómúléró nínú ìjọ. Kódà, lára àwọn ọmọ ọmọ ọmọ rẹ̀ ní Romania jẹ́ Ẹlẹ́rìí nísinsìnyí. A tún bẹ ọ̀pọ̀ ìbátan ọkọ mi wò, tí wọ́n ti dúró gbọn-in nínú òtítọ́ Bíbélì.
Ní 1970, Romania wà lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì òǹrorò ti Nicolae Ceauşescu, a sì ṣe inúnibíni rírorò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Flore, ọmọ John, àbúrò mi, àti àwọn mọ̀lẹ́bí mi mìíràn, lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, nítorí ìgbàgbọ́ Kristẹni wọn, bákan náà sì ni ọmọ àbúrò bàbá ọkọ mi, Gábor Romocean. Abájọ tí àwọn arákùnrin wa ni Romania fi sọ pé ọkàn àwọn kò ní balẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n bá gbọ́ pé a ti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ láìséwu, nígbà tí wọ́n fi àwọn lẹ́tà tí ń lọ sí orílé-iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York, sí ìkáwọ́ wa!
Nígbà tí a fura pé ìwé àṣẹ ìrìnnà tí a fún wa ti léjọ́, a lọ sí ọ́fíìsì ìjọba ní Ortelec. Ọ̀sán Friday ni, òṣìṣẹ́ ọba kan ṣoṣo ni ó sì wà lẹ́nú iṣẹ́. Ní mímọ àwọn ẹni tí a ti ń bẹ̀ wò, àti pé ọmọ àbúrò wa tí lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ rí, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìyá yìí, ẹ fi ibí sílẹ̀!”
Àbúrò mi fèsì pé: “Ṣùgbọ́n, kò sí ọkọ ojú irin tí ń lọ lónìí.”
Kíá ni ó sọ pé: “Ìyẹn kò ṣe nǹkankan. Ẹ wọkọ̀. Ẹ wọ ọkọ̀ ojú irin. Ẹ wọ takisí. Ẹ rìn. Kí ẹ ṣáà ti fibí sílẹ̀ ní kía mọ́sá!”
Bí a ti fẹ́ máa lọ, ó pè wá pa dà, ó sì sọ fún wa pé, ọkọ ojú irin àwọn ológun, tí a kò ṣètò fún tẹ́lẹ̀, ń bọ̀ ní aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́. Ẹ wo bí èyí ti fẹ̀rí hàn pé ó ní ọwọ́ Ọlọ́run nínú tó! Nínú ọkọ̀ ojú irin tí ó wọ́pọ̀, wọn yóò wo àwọn ìwé wa ní àwòtúnwò, ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn sójà ni ọkọ̀ yí gbé, àwa méjèèjì nìkan sì ni ará ìlú tí ó wà nínú ọkọ̀, kò sí ẹni tí ó béèrè ìwé àṣẹ ìrìn àjò wa. Wọ́n lè ti gbà pé, a jẹ́ ìyá ìyá àwọn sójà kan.
A gúnlẹ̀ sí Timisoara ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, pẹ̀lú ìrànwọ́ ọ̀rẹ́ ìbátan wa kan, ó ṣeé ṣe fún wa láti gba ìwé àṣẹ ìrìnnà. Ní ọjọ́ kejì, a fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. A wá sílé pẹ̀lú àwọn ìrántí amọ́kànyọ̀ àti mánigbàgbé, ti àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa àdúróṣinṣin, ní Romania.
Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé ìbẹ̀wò wa sí Romania, a gbọ́ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ìwàásù láti ẹ̀yìn Ìbòjú Irin. Síbẹ̀, a ní ìgbọ́kànlé pé àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa yóò máa bá a lọ ní jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run wa—láìka ipò èyíkéyìí sí. Dájúdájú, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìdùnnú wa tó láti mọ̀ pé, a tẹ́wọ́ gba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ ìsìn kan ní Romania, ní April 1990! Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó tẹ̀ lé e, ìròyìn nípa àwọn àpéjọpọ̀ tí a ṣe ní Romania mú inú wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Họ́wù, iye tí ó lé ní 34,000 ní ó pésẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá mẹ́jọ, tí àwọn 2,260 sì ṣèrìbọmi! Nísinsìnyí, iye tí ó lé ní 35,000 ni ó ń ṣàjọpìn nínú iṣẹ́ ìwàásù ní Romania, àwọn 86,034 ni ó sì pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní ọdún tí ó kọjá.
Òtítọ́ Ṣì Ṣeyebíye sí Mi
Fún ọdún díẹ̀, mo ṣíwọ́ jíjẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ní ibi Ìṣe Ìrántí. Mo kíyè sí àwọn arákùnrin tí ó tóótun dáradára, tí wọn kì í jẹ ẹ́, mo sì ronú pé: ‘Èé ṣe tí Jèhófà yóò fi fún mi ní àǹfààní jíjẹ́ àjògún pẹ̀lú Ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọ̀run, nígbà tí àwọn mìíràn jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ já geerege mọ́ lẹ́nu?’ Ṣùgbọ́n, nígbà tí n kò jẹ ẹ́, ìdààmú bá mi gidigidi. Ńṣe ni ó dà bíi pé mo ń kọ nǹkan kan sílẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tàdúràtàdúrà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Àlàáfíà ọkàn àti ayọ̀ mi pa dà wá, wọn kò sì fi mí sílẹ̀ láti ìgbà yẹn.
Bí n kò tilẹ̀ lè ríran dáradára mọ́ láti kàwé, mo máa ń fetí sílẹ̀ lójoojúmọ́ sí kásẹ́ẹ̀tì Bíbélì àti ti àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Mo ṣì ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù. Mo sábà máa ń fi ìwé ìròyìn 60 sí 100 síta lóṣooṣù, ṣùgbọ́n, nígbà tí a ṣe ìgbétásì àkànṣe pẹ̀lú ìwé ìròyìn Jí!, ní April tí ó kọjá, mo fi 323 síta. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin mi, ó tún ṣeé ṣe fún mi láti kópa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Mo láyọ̀ pé mo lè máa bá a lọ láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ará ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ń pè mí ní Ìyá àgbà.
Ní bíbojú wẹ̀yìn wo nǹkan bí ọdún 79, ti iṣẹ́ ìsìn tí a yà sí mímọ́ fún Jèhófà, mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ pé, ó ti yọ̀ǹda fún mi láti mọ òtítọ́ rẹ̀ ṣíṣeyebíye, kí n sì lo ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Mo dúpẹ́ gidigidi pé, ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yíyanilẹ́nu ti inú Bíbélì, tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìkójọpọ̀ àwọn ẹni-bí-àgùntàn Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ṣe ojú mi.—Aísáyà 60:22; Sekaráyà 8:23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àbúrò mi Mary àti Bàbá mi nídùúró, àti èmi, George, àti àwọn ọmọbìnrin wa, Esther àti Anne
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi Beth àti Irene àti ọkọ Irene àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì, tí gbogbo wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà