A Ṣe Àwọn Àpéjọpọ̀ Romania Láìka Àtakò Sí
A ṢÈTÒ fún Àpéjọpọ̀ Àgbáyé “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bucharest, Romania, láti July 19 sí 21, 1996. Àwọn 40,000 àyànṣaṣojú, tí ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn láti àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè nínú, wéwèé láti bẹ olú ìlú ẹlẹ́wà yí, tí ó ní ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ ènìyàn nínú ní ilẹ̀ Europe, wò. Wọ́n ti gba Pápá Ìṣeré ti Orílẹ̀-Èdè, tí ó ní àyè ìjókòó 60,000, fún ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àmọ́ ṣáá, ní June 24, àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Romania tí a ti fún ní ìsọfúnni òdì kọ̀ láti fún wọn láṣẹ láti ṣe àpéjọpọ̀ náà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbìyànjú gan-an láti gba àṣẹ tí yóò bẹ́gi dí fífagi lé àpéjọpọ̀ wọn, àmọ́ pàbó ló já sí. Nítorí náà, wọ́n ní láti yí ètò tí wọ́n ti ṣe pa dà, kí àwọn ẹgbẹ̀rún bíi mélòó kan àwọn àyànṣaṣojú tí a ti pè láti àwọn orílẹ̀-èdè Europe, Àríwá America, àti Japan, lè lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní Budapest, Hungary, láti July 12 sí 14. Àwọn ìyípadà pàjáwìrì náà yọrí sí ìnáwó ńlá, àìrọgbọ, àti ìjákulẹ̀ fún àwọn púpọ̀.
Àmọ́, kí ni a lè ṣètò fún àwọn àyànṣaṣojú tí àwọn fúnra wọn jẹ́ ará Romania? Wọ́n kàn sí àwọn òṣìṣẹ́ ní ìlú ńlá Cluj-Napoca àti Brasov, ní paríparí rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ níbẹ̀, láti July 19 sí 21. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará Romania kò lè dé Cluj-Napoca tàbí Brasov. Nítorí náà, wọ́n ṣe àwọn àpéjọpọ̀ méjì sí i ní September 13 sí 15, ọ̀kan ní Baia-Mare àti èkejì ní Bucharest.
Kí ló dé tí wọ́n fi fagi lé àpéjọpọ̀ tí a ṣètò fún tẹ́lẹ̀ ní Bucharest? Kí ló sì mú kí àwọn òṣìṣẹ́ kan wá yí ojú ìwòye wọn pa dà níkẹyìn, tí wọ́n fi lè ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ní Romania, tí ó ní ọ̀kan ní Bucharest nínú?
Ta Ló Wà Nídìí Àtakò Náà?
Nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Budapest, ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Hungary náà, Színes Vasárnap, sọ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Bucharest ni ibi tí wọ́n ti wéwèé tẹ́lẹ̀ láti ṣe ìpàdé ọlọ́dọọdún wọn, àmọ́ nítorí àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Romania kò fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Ó wá di ohun tí gbogbo ayé mọ̀ pé ṣọ́ọ̀ṣì ló wà nídìí àtakò náà. Fún àpẹẹrẹ, Times Union, ìwé agbéròyìnjáde kan ní ìlú ńlá Albany, New York, U.S.A., ròyìn pé: “Teoctist, Baba Ńlá Ìgbàgbọ́ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kìlọ̀ fún àwọn ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì láti wà lójúfò nípa ohun tí ó pè ní àwọn èrò ìgbàgbọ́ ‘aládàámọ̀’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Àwọn ìròyìn nípa àtakò àwùjọ àlùfáà sí àpéjọpọ̀ náà ha jẹ́ òtítọ́ bí? Ó dára, ní June, àwọn olùgbé Bucharest bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni tí ń ba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́ káàkiri ìlú ńlá náà—tí wọ́n lẹ̀ sára ṣọ́ọ̀ṣì, sára ògiri àti ẹ̀gbẹ́ àwọn ilé, àti sí àwọn ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀. Ọ̀kan tí ó ní àkọlé náà “SÍ GBOGBO ARÁ ROMANIA!” béèrè pé: “Ǹjẹ́ Romania nílò àpéjọpọ̀ àgbáyé àwọn oní-Jèhófà nísinsìnyí . . . July 19 sí 21 bí? Ẹ̀yin Kristẹni—ẹ jẹ́ kí a gbéjà ko àpéjọpọ̀ ẹlẹ́mìí Èṣù yí!”
Òmíràn tí ó ní àkọlé náà, “Ẹ Wà Lójúfò sí EWU ÀWỌN ONÍ-JÈHÓFÀ!” fi ìtẹnumọ́ kéde pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbógun ti ìsìn Kristẹni . . . Wọ́n ń wá ọ̀nà láti pín àwọn ènìyàn wa níyà, kí wọ́n sì dá ìjà ẹ̀sìn sílẹ̀. . . . GBOGBO Ẹ̀YIN ARÁ ROMANIA, ẹ gbógun ti àpéjọpọ̀ yí!”
“ÌPÈ LÁTI GBÉGBÈÉSẸ̀” ni àkọlé ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni mìíràn. “Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Romania . . . ń pe gbogbo onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sí ìpàdé ìṣàtakò kan, tí a óò ṣe ní Sunday, June 30.” Ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni náà parí ọ̀rọ̀ sí pé: “A óò ní kí àwọn aláṣẹ fagi lé àpéjọpọ̀ yí. Ẹ WÁ KÍ A LÈ GBÈJÀ ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN BABA ŃLÁ WA. Kí Ọlọ́run kí ó ràn wá lọ́wọ́!”
Àwùjọ àlùfáà tilẹ̀ tẹ ìwé ìléwọ́ kan tí ń sọ pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ “ètò àjọ ìṣèlú ti ẹ̀yà ẹgbẹ́ kọ́múníìsì” jáde, wọ́n sì pín in kiri. Ṣùgbọ́n, èyí pẹ̀lú jẹ́ irọ́ ńlá, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Romania mọ̀ pé irọ́ ni. Wọ́n mọ̀ pé àwọn Kọ́múníìsì ń ṣenúnibíni sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì sábà máa ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá.
Bí Wọ́n Ṣe Nípa Lórí Ẹ̀mí Ìrònú
Wéré ni àwọn ènìyàn ké gbàjarè ní inú àti lóde ilẹ̀ Romania láti ṣẹ́pá ìkọlù tí ṣọ́ọ̀ṣì ru sókè náà, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sì lè rí i pé fífún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní àǹfààní tí a fi fún àwọn ẹlòmíràn bẹ́tọ̀ọ́ mu. Flagrant, ìwé agbéròyìnjáde kan ní Bucharest, sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìjì túláàsì, ìkóguntini, àti ìfìbínúhàn lòdì sí àpéjọpọ̀ àgbáyé àkọ́kọ́ yìí yóò ní ìyọrísí yíyàtọ̀ pátápátá. Dípò mímú kí àwọn ènìyàn kẹ̀yìn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí, ìgbésẹ̀ náà yóò ru ọkàn ìfẹ́, ìfẹ́ ìtọpinpin, ìráragbaǹkan, àti ìbánikẹ́dùn wọn sókè ni.”
Ẹ wo bí àsọtẹ́lẹ̀ yí ṣe wáá ṣẹ! Ọ̀pọ̀ lára àwọn mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kọ̀wé, àwọn kan sì tẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bucharest láago, wọ́n sì sọ bí inú ṣe bí wọn tó sí ìgbésẹ̀ tí àwùjọ àlùfáà wọn gbé. Àwọn olóye ènìyàn mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe irú ènìyàn tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Romania sọ pé wọ́n jẹ́ rárá.
Nígbà tí Marius Milla ń kọ̀ròyìn nínú ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Romania náà, Timishoara, ti July 6, 1996, ó wí pé: “Ó dá mi lójú pé ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n ń fi ìgbéjàkoni fẹ̀sùn kan àwọn oní-Jèhófà ni kò ní ìfẹ́ ìtọpinpin tí ó pọ̀ tó láti bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí láti lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wọn.” Ó fi kún un pé: “Yóò túbọ̀ gbéni ró bí àwa, ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, yóò bá túbọ̀ ṣàníyàn nípa igi ìrólé tí ó wà lójú wa, kí a sì fi ègé koríko tí ó wà ní ojú aládùúgbò wa sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣèdájọ́ tí ó sàn jù.”—Mátíù 7:3-5.
Lẹ́yìn náà, Ọ̀gbẹ́ni Milla ṣe àyọlò ọ̀rọ̀ tí olókìkí amòfin ní ọ̀rúndún kìíní náà, Gàmálíẹ́lì, sọ sí àwọn aṣáájú ìsìn tí ń ta ko àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé: “Ẹ má ṣe tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ fi wọ́n sílẹ̀; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìrònúpète tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a óò bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;) bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gàsíkíá.” (Ìṣe 5:38, 39) Ní paríparí rẹ̀, Milla kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí ìrònú wa lòdì sí ètò ìjọba tiwa-n-tiwa, kò bá Bíbélì mu, ó sì jẹ́ jàgídíjàgan sí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.”
Láìpẹ́, àríwísí lòdì sí ìfagilé àpéjọpọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá láti àwọn apá ibòmíràn ní Europe àti láti United States. Ìgbìmọ̀ Romania ní Helsinki pèsè àkọsílẹ̀ kan tí ó dẹ́bi fún “irú ìgbésẹ̀ tí Bàbá Ìgbàgbọ́ Teoctist, aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Romania, gbé ní gbangba lòdì sí ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà’” fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti gbé jáde.
Hillary Clinton, aya ààrẹ United States, ṣèbẹ̀wò sí Romania ní àkókò náà. Ikọ̀ United States ní Romania, Alfred Moses, ṣàlàyé ìdí tí obìnrin náà kò fi wọ inú Ṣọ́ọ̀ṣì Kretzulescu ti ọ̀rúndún kejìdínlógún gẹ́gẹ́ bí ó ti wéwèé láti ṣe pé: “Òmìnira ìsìn jẹ́ ìlànà tí Òfin United States of America fọwọ́ sí, tí Òfin ilẹ̀ Romania pẹ̀lú sì fọwọ́ sí. Wíwà tí àwọn ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni tí ó fi ìwà àìsí ìráragbaǹkan ní ti ìsìn hàn wà ní àyíká ṣọ́ọ̀ṣì náà kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀mí àjọṣepọ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa àti pẹ̀lú àwọn ìdí tí Ìyáàfin Clinton ṣe bẹ Romania wò.”
Ẹ̀rí Ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ní ìlú ńlá Cluj-Napoca tẹ́lẹ̀ rí, àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sì tún gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ nígbà tí a kò gbà wọ́n láyè láti lo Pápá Ìṣeré Orílẹ̀-Èdè ní Bucharest. Àmọ́, ọ̀sẹ̀ kan péré ló kù kí àpéjọpọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ kí a tóó lọ kọwọ́ bọ ìwé àdéhùn fún lílo pápá ìṣeré ní Cluj-Napoca. Oníròyìn kan béèrè pé: “Báwo ló ṣe ṣeé ṣe láti ṣètò fún irú àpéjọpọ̀ gígọntiọ bẹ́ẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀?”
A wí fún un pé: “Ètò àjọ tí ó ṣọ̀kan ni wá. Ṣíṣe àwọn àpéjọpọ̀ ti mọ́ wa lára. Àmọ́, lékè gbogbo rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run wa ń tì wá lẹ́yìn.”
Lótìítọ́, ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn Jèhófà ló jẹ́ kí a ṣàṣeparí ohun púpọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú. Finú wòye àwọn ènìyàn tí ó lé ní 20,000, tí ń pàdé pọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta láàárín àkókò kúkúrú tí wọ́n fi gbọ́! Iye tí ó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ jẹ́ 22,004, àwọn 799 sì ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, ìwé agbéròyìnjáde Adevărul de Cluj ròyìn pé: “Èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí àwọn ènìyàn yí fúnni ni pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tọkàntọkàn ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Ìsowọ́pọ̀ṣọ̀kan wọn wúni lórí . . . Wọ́n fi ìwà ìkóra-ẹni-níjàánu tí ó ṣeé wò fi ṣàpẹẹrẹ hàn lọ́nà tí wọ́n gbà hùwà, wọ́n sì mọ́ tónítóní lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.”
Ní pàtàkì, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Brasov wúni lórí, nítorí pé ọjọ́ bíi mélòó kan péré ló kù kí àpéjọpọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí i pé kí a ṣe é! Síbẹ̀, a rí 7,500 ilé ìfiniwọ̀sí gbà ní àwọn ibùgbé àdáni. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan bá àwọn aládùúgbò rẹ̀ sọ̀rọ̀, wọ́n fún àwọn 30 ẹni àyànṣaṣojú ní ilé ìfiniwọ̀sí. Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ní Brasov sì wá ilé fún àwọn 500 ẹni àyànṣaṣojú lọ́dọ̀ àwọn akéde. Wọ́n pèsè àgọ́ fún àwọn àyànṣaṣojú kan láti wọ̀ sí nítòsí ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà; nígbà tí òjò sì rọ̀, àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò, tí ń gbé àwọn ilé tí ó wà nítòsí, wáá ké sí wọn láti máa bọ̀ ní ilé wọn.—Fi wé Ìṣe 28:2.
A pààlà sí ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bulgaria tí àwọn ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì pọ̀ sí, tí ó pààlà pẹ̀lú Romania lápá ìsàlẹ̀. Nígbà tí bọ́ọ̀sì tí ó kún fún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Bulgaria dorí kọ Bucharest, dájúdájú, àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè kan ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ibi ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà ti yí pa dà. Ní Brasov, àpapọ̀ 1,056 àwọn ará Bulgaria ni wọ́n gbádùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní èdè wọn. Lápapọ̀, 12,862 ènìyàn ló lọ sí àpéjọpọ̀ ti Brasov náà, àwọn 832—tí 66 lára wọ́n jẹ́ ará Bulgaria—ni ó ṣèrìbọmi.
Ní September, ó ṣeé ṣe láti ṣètò fún àpéjọpọ̀ tí ó túbọ̀ kéré ní Baia-Mare àti Bucharest fún àwọn tí kò lè dé Cluj-Napoca àti Brasov. Àpapọ̀ iye 5,340 ènìyàn ló lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ méjì tí a fi kún un yìí, àwọn 48 sì ṣèrìbọmi. Nípa bẹ́ẹ̀, àròpọ̀ 40,206 ènìyàn ló lọ sí àpéjọpọ̀ “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ní Romania nígbà òtútù tó kọjá, àwọn 1,679 sì ṣèrìbọmi. Dájúdájú, ìbùkún Jèhófà wà lórí àwọn tí ń gbìyànjú láti sìn ín ní Romania!
Aṣojú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Bucharest sọ pé: “Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, a rí ìpolongo ní gbangba tí ó dọ́gba pẹ̀lú èyí tí a ti ní láti àìmọye ọdún tí a ti ń wàásù jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Ohun tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Romania rò pé yóò ṣèdíwọ́ fún wa wáá di èyí tí ó mú ìlọsíwájú bá ìhìn rere náà.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìlú ńlá òde oní, tí ó lẹ́wà, ni Bucharest
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni tí ń ba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣèrìbọmi ní Bucharest
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ní Brasov, níbi tí a ti gba ìfọwọ́sí láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ní ọjọ́ bíi mélòó kan péré ṣáájú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Iye tí ó pọ̀ jù lọ ní àpéjọpọ̀ Cluj-Napoca jẹ́ 22,004