Ìyàlẹ́nu Amúniláyọ̀ Kan
Dana Folz jẹ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó mọ̀ pé a gba òun ṣọmọ ni. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni ìyá mi? Báwo ló ṣe rí? Èé ṣe tí ó fi jẹ́ kí a gbà mí ṣọmọ? Mo ha ní àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin bí?’ Ka ìròyìn tí Dana ṣe nípa bí ó ṣe wá ìyá tó bí i gan-an rí níkẹyìn àti ìyàlẹ́nu oníran àpéwò tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà.
AUGUST 1, 1966, ni wọ́n bí mi ní Ketchikan, Alaska, U.S.A. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, Pam, gba ọdún méjì lọ́wọ́ mi. Bàbá wa jẹ́ òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re ní Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Àlámọ̀rí Àwọn Àmẹ́ríńdíà, iṣẹ́ sì máa ń gbé e kiri léraléra. A máa ń ṣí kiri ní Alaska. Lẹ́yìn náà, a gbé ní Iowa, Oklahoma, Arizona, àti Oregon.
Nígbà tí a ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ìbátan ní Wisconsin nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1975, àwọn mọ̀lẹ́bí bàbá mi kan sọ̀rọ̀ àìdára nípa mọ̀lẹ́bí bàbá mi mìíràn. Wọ́n sọ pé: “Wọ́n gbà á ṣọmọ ni, nítorí náà, kì í ṣe ojúlówó ọmọ Folz.” Lẹ́yìn tí a pa dà délé, mo bi Màmá léèrè ọ̀rọ̀ yí, ìrísí ìwárìrì tí mo rí lójú rẹ̀ sì yà mí lẹ́nu. Ó ṣàlàyé ohun tí ìgbàṣọmọ túmọ̀ sí. Ní alẹ́ yẹn, bí ó ti ń da omi lójú, ó sọ fún mi pé àwọn gba èmi àti arábìnrin mi pẹ̀lú ṣọmọ ni.
Ìgbàṣọmọ kò nítumọ̀ dan-indan-in sí mi nígbà náà, n kò sì ronú lé e lórí jù bẹ́ẹ̀ lọ fún ọdún mélòó kan. Mo ní mọ́mì kan àti dádì kan, ó sì jọ pé ìgbésí ayé ń rí bó ṣe yẹ kí ó rí. Àwọn òbí mi pinnu láti ṣíwọ́ àńkókiri, kí ìdílé náà sì fìdí kalẹ̀ síbì kan. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí nígbà tí a fìdí kalẹ̀ sí Vancouver, Washington. Èmi àti Dádì sún mọ́ra tímọ́tímọ́ ju bí èmi àti Mọ́mì ṣe sún mọ́ra tó lọ. Mo wà lómìnira, mo sì ń ṣọ̀tẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìjákulẹ̀ tí èyí sì ń fà fún Mọ́mì lè jẹ́ ìdí tí a kò fi sún mọ́ra tó bẹ́ẹ̀.
Òòfà Ìfẹ́ àti Kọ́lẹ́ẹ̀jì
Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo pàdé Trina, a sì di ọ̀rẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lẹ́yìn tí mo jáde, mo gba àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ sí Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Oregon, ní Corvallis, Oregon. Mo ń lo àkókò ọwọ́dilẹ̀ mi láti rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Trina, tí ó ku ọdún kan kí ó lò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ní Vancouver, mo ń lọ, mo sì ń bọ̀. N kò fi bẹ́ẹ̀ kọjú sí ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n mo gbà pé n óò ṣe dáadáa ní kọ́lẹ́ẹ̀jì lọ́nàkọnà. Èsì ìdánwò tí mo kọ́kọ́ gbà múni gbọ̀n rìrì—òun ni èsì ìdánwò tí ó burú jù lọ tí mo tí ì gbà rí! Ó tì mí lójú. Ṣùgbọ́n n kò yéé ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Trina; mo wulẹ̀ máa ń kó ìwé mi dání kí n lè kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí mo bá ń ṣèbẹ̀wò ni.
Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe ń gun alùpùpù mi pa dà sílé ẹ̀kọ́ láti Vancouver, ìjàǹbá bíbanilẹ́rù kan ṣe mi. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo fara pa jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan gbá mi, nígbà tí mo ń ré títì kọjá níbi ìfẹsẹ̀sọdá kan. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́, mo sì pàdánù ìfẹ́ ọkàn láti pa dà sí kọ́lẹ́ẹ̀jì.
Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìsìn
Láìpẹ́, èmi àti Trina bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pọ̀. A gba Ọlọ́run gbọ́, a sì fẹ́ mọ̀ ọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, a ní ìmọ̀lára pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kún fún àgàbàgebè. Nítorí náà, a gbìyànjú láti ka Bíbélì fúnra wa, ṣùgbọ́n a kò lóye rẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ ní Portland, Oregon, àwọn alábàáṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọkùnrin kan tí mo kà sí ọ̀kan lára àwọn ènìyàn rere tí mo tí ì bá pàdé rí ṣẹ̀sín. Randy fi sùúrù fara da ìfòòró náà. Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ yẹn, mo bi í pé: “Kí ni ìtúmọ̀ ohun tí mo gbọ́ yìí pé o jẹ́ òjíṣẹ́ kan?”
Ó dáhùn pé: “Òtítọ́ ni, mo jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Mo bi í pé: “Ti ìsìn wo?”
“Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
“Àwọn wo ní ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”
Ó béèrè tìyanutìyanu pé: “Ṣé lóòótọ́ ni o kò mọ̀ wọ́n?”
Mo wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣé ó yẹ kí n mọ̀ wọ́n ni?”
Ó dáhùn tẹ̀ríntẹ̀rín pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí o mọ̀ wọ́n. Kí ni ó fẹ́ ṣe nígbà ìsinmi oúnjẹ?”
Ìyẹn ni àkọ́kọ́ lára àwọn ìjíròrò Bíbélì mélòó kan nígbà ìsinmi oúnjẹ. Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ fún Trina nípa wọn. Ó jágbe mọ́ mi pé: “Má ṣe bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ o. Wọn ò bẹ́gbẹ́ mu! Wọn kì í tilẹ̀ í ṣe Kristẹni pàápàá. Wọn kì í ṣayẹyẹ Kérésìmesì.” Ó sì ń bá a lọ láti sọ àwọn nǹkan mìíràn tí ó ti gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún mi.
Mo ní: “Ẹnì kan ti sọ ohun púpọ̀ tí kì í wulẹ̀ í ṣe òtítọ́ fún ọ.” Lẹ́yìn ìjíròrò gígùn kan, ó ṣeé ṣe fún mi láti mú un dá a lójú pé kò tí ì gbọ́ gbogbo ohun tí ó jẹ́ òtítọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí n máa béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ Randy, mo sì máa ń pa dà wá fún un ní àwọn ìdáhùn kedere tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu léraléra. Níkẹyìn, Trina wí pé: “N kò fìgbà kankan mọ̀ pé gbogbo ìwọ̀nyí wà nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n síbẹ̀, mo ṣì rò pé wọn kò bẹ́gbẹ́ mu. Bí o bá fẹ́ máa bá a jíròrò nípa Bíbélì nìṣó, kò kàn mí; ṣùgbọ́n sá ti máà wá sílé, kí o sì gbìyànjú láti mú kí n tẹ́wọ́ gba àwọn ìgbàgbọ́ wọn.”
Sáà Oníwàhálà Kan
Mo gba ohun tí mo ń kọ́ láti inú Bíbélì gbọ́, ṣùgbọ́n mo nímọ̀lára pé n kò wulẹ̀ lè mú ìgbésí ayé mi bá a mu ni. Ó jọ pé èmi àti Trina túbọ̀ ń ní èdèkòyédè léraléra. Nítorí náà, èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan pinnu láti já àwọn ọ̀rẹ́bìnrin wa sílẹ̀, kí a sì lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun ní Oklahoma. Mo ṣètò ìsinmi ọlọ́jọ́ pípẹ́ níbi iṣẹ́. Láìpẹ́, èmi àti ọ̀rẹ́ mi ti fìdí kalẹ̀ sílé ibùgbé kan ní ìlú kékeré kan nítòsí ibodè Texas. Kò pẹ́ kí n tó mọ àìsíníbẹ̀ Trina lára gan-an, ṣùgbọ́n mo pinnu pé mo fẹ́ gbádùn ara mi lọ́nàkọ́nà ṣáá.
Mo gbọ́ pé ọjọ́ orí tí òfin fàyè gbà láti bẹ̀rẹ̀ sí í mutí líle ní Texas ni ọdún 19, nítorí náà, nígbà tí ọ̀rẹ́ mi lọ ìrìn àjò kan, mo ré ẹnubodè kọjá lóru ọjọ́ kan láti lọ gbádùn ara mi ní ilé ọtí oníjó rọ́ọ̀kì lílókìkí kan. Mo mutí yó bìnàkù, mo rún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi wómúwómú, wọ́n sì mú mi lọ sí àtìmọ́lé. Láìpẹ́, mo lè kàn sí dádì mi, ó sì sanwó ìdúró mi kúrò látìmọ́lé. Bákan náà, Trina gbà mí pa dà, mo ṣọpẹ́ fún ìyẹn! Mo pa dà síbi iṣẹ́ mi àtijọ́, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò Bíbélì pẹ̀lú Randy.
Dídarí Ìgbésí Ayé Mi
Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì tí mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì pinnu láti tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi. Mo ti di ọmọ 20 ọdún báyìí, àwọn ìbéèrè tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ nípa bí mo ṣe di àgbàṣọmọ sì bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi taratara wá ìyá tó bí mi gan-an kiri.
Mo kàn sí ilé ìwòsàn tí a ti bí mi ní Alaska, mo sì wádìí ohun tí mo gbọ́dọ̀ ṣe. Lẹ́yìn tí mo mọ ohun tí ó yẹ kí n ṣe, mo gba ẹ̀dà kan ojúlówó ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí mi, mo sì ṣàwárí pé Sandra Lee Hirsch ni orúkọ ìyá mi; ṣùgbọ́n kò sí àkọsílẹ̀ kankan nípa bàbá mi. Ọmọ ọdún 19 péré ni Sandra nígbà tí ó bí mi, nítorí náà, mo gbà pé ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin anìkànwà kan tí jìnnìjìnnì bá, tí ó lóyún láìṣègbéyàwó, tí ó sì ṣe ìpinnu ṣíṣòro gidigidi kan. Ìwọ̀n ìsọfúnni tí ó wà lórí ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí mi kò tó fún mi láti fi wá ìyá mi rí.
Láàárín àkókò kan náà, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi pẹ̀lú Randy, ó dá mi lójú pé mo ti rí ìsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n léraléra ni mo ń kùnà láti ṣíwọ́ àṣà lílo tábà tí ń sọni dẹlẹ́gbin. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Mo lérò pé Jèhófà kò ní ìgbọ́kànlé kankan nínú mi. Nígbà náà ni Ẹlẹ́rìí kan sọ ohun kan tí ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó sọ pé Sátánì ni ẹni tí ń fẹ́ kí a kùnà, ó sì máa ń bani nínú jẹ́ láti rí àwọn kan tí ń pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun nípa jíjuwọ́sílẹ̀. Ó sọ pé: “Ó yẹ kí a kó gbogbo ẹrù ìnira wa lé Jèhófà, kí a sì gbára lé e pátápátá láti ràn wá lọ́wọ́ la gbogbo àkókò wàhálà wa já.”—Orin Dáfídì 55:22.
Ìyẹn gẹ́lẹ́ ni ohun tí ó yẹ kí n gbọ́! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí ó wí, ní gbígbàdúrà fún ìrànwọ́ Jèhófà nígbà gbogbo. Láìpẹ́, mo ṣíwọ́ tábà, lílo èmi àti Trina ṣègbéyàwó, mo sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi déédéé. Láìpẹ́, Trina pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́. Mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní June 9, 1991. Kò pé ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni a bí àkọ́bí ọmọbìnrin wa, Breanna Jean.
Ipò Ìbátan Mi Pẹ̀lú Dádì
Èmi àti dádì sún mọ́ra tímọ́tímọ́. Ó jẹ́ onínúure tí ó sábà máa ń fún mi níṣìírí nígbà tí mo bá ní ìjákulẹ̀. Síbẹ̀, ó ń dúró gbọn-in nígbà tí mo bá nílò ìbáwí. Nítorí náà, nǹkan kò rọrùn níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1991 tí mo gbọ́ pé Dádì ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró aṣekúpani. Nígbà yẹn, Mọ́mì àti Dádì ti kó lọ sí Hamilton, Montana. A sábà máa ń rìnrìn àjò lọ wò ó níbẹ̀, kí a sì fún Mọ́mì níṣìírí.
Ó ṣeé ṣe fún wa láti fún Dádì ní ìwé náà, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi? Ó ṣèlérí láti kà á, ó sì sọ pé ire ìdílé òun ń jẹ òun lọ́kàn. Nígbà ìbẹ̀wò tí mo ṣe kẹ́yìn, ó sọ fún mi nípa bí òun ṣe lè fi yangàn tó pé òun ní mi bí ọmọkùnrin òun àti bí òun ṣe fẹ́ràn mi tó. Lẹ́yìn náà, bí omijé ṣe ń dà pòròpòrò lójú rẹ̀, ó yí orí síbi fèrèsé. A rọ̀ mọ́ ara wa níye ìgbà kí n tó kúrò níbẹ̀. Dádì ka ìwé náà dé nǹkan bí ìdámẹ́ta kí ó tó kú, ní November 21, 1991.
Lẹ́yìn tí Dádì kú tí èmi àti ìdílé mi sì kó lọ sí ìlú ńlá Moses Lake, Washington, ìfẹ́ ọkàn mi túbọ̀ jinlẹ̀ sí i láti mọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá. Ṣùgbọ́n, láìka gbogbo àkókò tí mo fi jin ìwákiri náà sí, a kò pa àwọn ohun tẹ̀mí tì. Trina ṣe batisí ní June 5, 1993, ó sì bí ọmọbìnrin wa kejì, Sierra Lynn, ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà.
Bí Mo Ṣe Rí Màmá Tó Bí Mi Gan-an
Mo ń tẹ̀ síwájú láti máa gba ìsọfúnni lọ́dọ̀ ẹ̀ka òfin Alaska, láti máa kọ lẹ́tà léraléra sí onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́, àti láti máa fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣèwádìí fúnra mi. Gbogbo rẹ̀ já sí pàbó. Lẹ́yìn náà ni mo ṣe àyẹ̀wò ìlera kan ní apá ìparí ọdún 1995, tí ó fi hàn pé ọkàn àyà mi kò ṣiṣẹ́ déédéé bó ti yẹ. Ọmọ ọdún 29 péré ni mí, dókítà mi sì fẹ́ mọ gbogbo ìtàn ìlera ìdílé mi.
Dókítà náà kọ ìwé ìbéèrè kan tí ó kún rẹ́rẹ́, tí ó sì ṣe ṣàkó, ní títẹnu mọ́ ọn pé àwọn ìsọfúnni tí ó wà nínú fáìlì ìgbàṣọmọ mi lè ṣe pàtàkì fún ìlera mi. Láìpẹ́, a rí ìdáhùn kan gbà. Ó jẹ́ ìpinnu ìdájọ́ adájọ́ kan pé òun kò rò pé ọ̀ràn ìlera mi le tó pé kí a ṣí àwọn fáìlì náà. Mo rẹ̀wẹ̀sì. Ṣùgbọ́n ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, lẹ́tà kan dé láti ọ̀dọ̀ adájọ́ kejì. Ilé ẹjọ́ ti fún mi láṣẹ láti wo àwọn fáìlì ìgbàṣọmọ mi!
Àwọn fáìlì ìgbàṣọmọ mi gan-an dé ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1996. A rí orúkọ ìlú ìbílẹ̀ màmá tó bí mi àti ìtàn ìdílé rẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo ṣe ìwádìí orí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà lórí orúkọ Sandra àti orúkọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, mo sì rí nọ́ńbà tẹlifóònù mẹ́fà. Èmi àti Trina pinnu pé ì bá dára jù kí ó jẹ́ pé Trina ni yóò ṣe ìtẹ̀láago náà. Nígbà ìtẹ̀láago kẹta, obìnrin kan sọ pé ọmọ arákùnrin òun ni Sandra, ó sì sọ nọ́ńbà fóònù rẹ̀.
Ìtẹ̀láago àti Ìyàlẹ́nu Náà
Nígbà tí Trina tẹ nọ́ńbà náà, obìnrin tí ó dáhùn kọ̀ láti dárúkọ ara rẹ̀. Níkẹyìn, Trina sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Wọ́n bí ọkọ mi ní Ketchikan, Alaska, ní August 1, 1966, mo sì fẹ́ mọ̀ bóyá ìwọ ni ẹni tí mo ń wá.” Gbogbo rẹ̀ pa rọ́rọ́ fúngbà pípẹ́ díẹ̀, lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ohùn tí ń gbọ̀n, obìnrin náà béèrè orúkọ Trina àti nọ́ńbà fóònù rẹ̀, ó sì sọ pé òun yóò tẹ̀ ẹ́ láago pa dà. N kò rò pé yóò tẹ̀ wá láago pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nítorí náà, mo pinnu láti lọ ra àwọn ohun díẹ̀ tí a nílò nílé ìtajà.
Nígbà tí mo pa dà dé, mo bá Trina nídìí fóònù pẹ̀lú omi lójú rẹ̀. Ó gbé fóònù fún mi. Bí èmi àti Màmá ṣe ń kí ara wa, tí a sì ń sọ àhesọ ọ̀rọ̀, Trina sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí mi létí pé, “Kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti gbé ọ sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ.” Àánú màmá mi ṣe mí bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nípa ara rẹ̀. Mo wí pé: “Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún bíbí tí o bí mi. Ìgbésí ayé mi dára, mo sì ní gbogbo ohun tí mo nílò. Mo ti ní àwọn òbí rere, mo sì jàǹfààní ìfẹ́ wọn, nísinsìnyí, mo ní ìyàwó rere kan àti àwọn arẹwà ọmọbìnrin méjì. Mo láyọ̀ gan-an.”
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ lọ, ó sọ bí wọ́n ṣe fipá bá òun lò pọ̀, tí òun lóyún, tí wọ́n sì rọ òun láti gbé mi kalẹ̀ fún ìgbàṣọmọ; ó sọ fún mi pé òún ṣègbéyàwó lẹ́yìn náà, láìpẹ́, nígbà tí òun ń kọ́fẹ pa dà nílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kan, ọmọbìnrin òun àti ìyá òun kú nínú iná kan. Ó ní nígbà yẹn, òun rò pé Ọlọ́run gba àwọn olólùfẹ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìjìyà òun nítorí ọmọkùnrin tí òun gbé sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ ni. Mo dáhùn lọ́gán pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ọlọ́run kì í ṣe nǹkan lọ́nà yẹn!” Ó ní òun mọ ìyẹn nísinsìnyí, nítorí pé lẹ́yìn ọ̀ràn ìbànújẹ́ yẹn, òun bẹ̀rẹ̀ sí í “wá òtítọ́ Bíbélì kiri,” òun sì jẹ́ “akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” kan báyìí.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀,’ bí mo ṣe béèrè pé: “Ta ni o bá kẹ́kọ̀ọ́?” Nǹkan tún pa rọ́rọ́ fúngbà pípẹ́ díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ìmọ̀lára mi bò mí tó bẹ́ẹ̀ tí n kò lè sọ̀rọ̀. Níkẹyìn, pẹ̀lú omijé lójú, mo tiraka sọ pé, “Èmi náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí kan pẹ̀lú.” Nígbà tí mo tún un sọ ní kedere, inú rẹ̀ dùn dẹ́yìn. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ àgbàyanu gan-an!
Màmá di Ẹlẹ́rìí ní 1975, àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ikú ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, màmá mi sọ fún un nípa mi. Ó tu màmá mi nínú, ó sì sọ pé àwọn yóò wá mi kàn. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, tí ó sì fi àwọn ọmọ kéékèèké mẹ́ta sílẹ̀ fún màmá mi tọ́. Lẹ́yìn náà, a sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí ní ọ̀pọ̀ ìrọ̀lẹ́. Níkẹyìn, a ṣètò láti pàdé ni Phoenix, Arizona, ní ọ̀sẹ̀ kejì nínú oṣù February 1996. Màmá ti ṣètò tẹ́lẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ pẹ̀lú Kristẹni arábìnrin mìíràn kan.
Ìtúnrarí Mánìígbàgbé Kan
Èmi àti Trina kò mú àwọn ọmọ wa lọ ìrìn àjò yí. Bí mo ti ń sọ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú, mo rí màmá mi, ó sì ṣeé ṣe fún mi níkẹyìn láti gbá a mọ́ra. Nígbà tí a rọ̀ mọ́ ara wa, ó sọ pé, òun ti ń retí láti ọdún 29 láti gbá mi mọ́ra, ó sì gbá mi mọ́ra fún ìgbà pípẹ́. Ìbẹ̀wò náà jẹ́ àgbàyanu, a sì jùmọ̀ wo àwọn àwòrán, a sì sọ ìtàn pa pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó gbani lọ́kàn jù lọ ni jíjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Màmá ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Phoenix! A jùmọ̀ tẹ́tí sí ìpàdé náà, a sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wa bí a ti ń kọ àwọn orin Ìjọba. Ìmọ̀lára kíkọyọyọ tí n óò máa rántí láéláé ni.
Ní April 1996, arábìnrin mi, Laura, wá bẹ̀ wá wò láti ilé rẹ̀ ní Iowa. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà ti Kristẹni pẹ̀lú rẹ̀! Mo tún ti bá àwọn arákùnrin mi méjèèjì tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù. Ohun àgbàyanu ni láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìdílé mi, ṣùgbọ́n, wíwà níṣọ̀kan nínú ìfẹ́ láàárín ètò àjọ Jèhófà jẹ́ ẹ̀bùn kan tí Ọlọ́run wa aláìlẹ́gbẹ́, Jèhófà, nìkan lè fúnni.—Gẹ́gẹ́ bí Dana Folz ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú màmá tó bí mi gan-an