ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Ẹyẹ Robin Ayáramọ́ni
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ọlọ́rọ̀ Ń Kó Àwọn Tí Kò Lọ́rọ̀ Nífà Ọmọ ọdún 14 ni mí, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gan-an fún àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ọlọ́rọ̀ Yóò Ti Kó Àwọn Tí Kò Lọ́rọ̀ Nífà Pẹ́ Tó?” (November 22, 1995) Olùkọ́ tí ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀ fún wa ní ìṣẹ́ láti kọ̀wé lórí kókó ẹ̀kọ́ “Ipò Òṣì.” Mo wá inú àwọn ìwé agbéròyìnjáde àti ìwé ìròyìn ṣùgbọ́n n kò rí ohunkóhun tí yóò dára láti lò. Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo nílò ìsọfúnni náà gan-an ni ìwé ìròyìn yìí dé, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún àlàyé mi. Mo gba máàkì tí ó ga jù lọ ní kíláàsì, mo sì dúpẹ́ gan-an fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.

A. O., Brazil

Ìwà Àìlèkóra-Ẹni-Níjàánu Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ń gbéni ró náà, “Ìwà Àìlèkóra-Ẹni-Níjàánu—Ó Ha Ń Ṣàkóso Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?” (February 8, 1996) Ìwà àìlèkóra-ẹni-níjàánu ń yọ mí lẹ́nu, ó sì jẹ́ ohun ìṣírí gidigidi láti mọ̀ pé èmi nìkan kọ́ ló ń ṣe. Ó ti ń dà mí láàmú gan-an láti ìgbà tí mo wà lọ́mọdé. Láti ìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ti ní ìrònú àròkúdórógbó pé mo ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́. Mo ti ń yanjú ìṣòro mi díẹ̀díẹ̀. Ẹ wo bí ó ti dára tó láti mọ̀ pé Jèhófà lóye àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ aláìpé!

A. B., Germany

Mo mọrírì gan-an pé Ẹlẹ́dàá wa lóye àrùn yìí àti pé òún “tóbi ju ọkàn àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (Jòhánù Kìíní 3:20) Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa tẹ irú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yẹn jáde; wọ́n máa ń fún wa ní ìṣírí gan-an.

W. E., Switzerland

Ẹ kò lè mòye bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ṣe tù mí nínú tó. Mo ti máa ń ní àwọn èrò òdì, tí ó burú jáì, tí ó ti yọrí sí ìsoríkọ́ àti nígbà míràn, sí èrò ṣíṣekú pa ara mi. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ńṣe ló jọ pé a ti gbé ẹrù ńlá kàbìtì kan kúrò ní èjìká mi, nígbà tí mo wáá mọ̀ pé Jèhófà kò tí ì kọ̀ mí sílẹ̀, ṣùgbọ́n pé ó fẹ́ràn mi dénúdénú.

I. B., ilẹ̀ Faransé

Láti ìgbà tí mo ṣì kéré ni mo ti máa ń fọ ọwọ́ mi léraléra. Mo máa ń yẹ ìdáná wò lẹ́ẹ̀mẹta, kódà bí mo bá ní láti padà wá láti ìta láti ṣe é. Mo máa ń yẹ àwọn abọ́ mi wò bóyá wọ́n ní ìdérí, bóyá mo ti pa gbogbo ilẹ̀kùn dé dáadáa. Tí mo bá fi máa lọ sùn, yóò ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu nítorí ìjàkadì pẹ̀lú ìwà àìlèkóra-ẹni-níjàánu. Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín.

M. P., Venezuela

Ẹyẹ Robin Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ẹyẹ Robin Ayáramọ́ni” (February 8, 1996) fà ọkàn mi mọ́ra gan-an. Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tí mo ń gbẹ́ ihò kan nínú ọgbà wa, mo gbọ́ orin aládùn ẹyẹ robin kan tí ń wò mí níbi tí ó dúró sí ní ojú ọ̀nà kan nítòsí. Gbàrà tí mo gbìyànjú láti máa bá a kọ orin rẹ̀ ló ti bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nínú ihò náà. Ẹyẹ robin náà gbádùn ṣíṣa kòkòrò tó bá wà nínú iyẹ̀pẹ̀ tí ẹ̀kún ṣọ́bìrì ń kó jáde. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa bá a lọ ní títẹ àwọn àlàyé nípa àwọn ẹranko jáde!

F. S., Germany

Àwọn Òkìtì Yìnyín Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àwọn Ààfin Dídán Yanranyanran Inú Òkun.” (December 8, 1995) Kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yẹn lásán àti fífinú wòye pé mo wà níwájú ọ̀kan lára àwọn òkìtì yìnyín ràgàjìràgàjì wọ̀nyẹn, mú kí àwọn ohun àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ti pèsè fún ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn wa wú mi lórí. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ṣe sọ nípa Jèhófà nínú Orin Dáfídì 104:24 pé, “ayé kún fún ẹ̀dá [rẹ̀].”

A. I. B., Brazil

Àròkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ tí Eric kọ nínú àròkọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, “Ká Ní Mo Lè Yí Ìgbà Padà Ni” (February 22, 1996), wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. O ru ìmọ̀lára ìkansáárá àti fífi ìmoore hàn sí àwọn òbí rẹ̀ sókè nínú mi. Ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ pé wọ́n ti ya ọ̀pọ̀ àkókò àti agbára sọ́tọ̀ fún títọ́ ọmọkùnrin kan tí ó ní irú ìgboyà àti ìfẹ́ fún Jèhófà lọ́nà gbígbàfiyèsí bẹ́ẹ̀ dàgbà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni.

C. N., Ítálì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́