ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 15
  • Ẹyẹ Robin Ayáramọ́ni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹyẹ Robin Ayáramọ́ni
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Ọlọ́run Yóò Ha Máa Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Mi Nìṣó Bí?
    Jí!—1997
  • Ìdí Tá ò Fi Ṣẹ́yún
    Jí!—2009
  • 8 Àpẹẹrẹ Rere
    Jí!—2018
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 15

Ẹyẹ Robin Ayáramọ́ni

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN

TIPẸ́TIPẸ́ ṣaájú kí àwọn ẹgàn Northumberland wa tó yí padà sí àwọ̀ osùn tí ń fi ìgbà ìwọ́wé tí ń tuni lára hàn, ẹyẹ robin yóò kanlẹ̀kùn koko. Gẹngẹ àyà rẹ̀ tí ó pọ́n yòò àti ìlọsókè-lọsílẹ̀ ohùn rẹ̀ tí ń já gaara máa ń mú kí ọgbà ní àwọ̀ mèremère, ó sì máa ń fi ayọ̀ kún un. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ẹ̀dá tí ó fani lọ́kàn mọ́ra tó!

Ohun tí a lè fi tètè dá robin mọ̀ ni èjìká àti orí rẹ̀ tí ó ní àwọ̀ ilẹ̀ rẹ́súrẹ́sú; gẹngẹ àyà, ọrùn àti iwájú rẹ̀ tí ó jẹ́ olómi ọsàn; àti ikùn rẹ̀ tí ó funfun. Ẹyẹ tí ó rí rùmúrùmú yìí, tí ó máa ń wà lójúfò nígbà gbogbo, máa ń nàró wámúwámú, ó sì gùn tó sẹ̀ǹtímítà 14 láti ṣóńṣó ẹnu rẹ̀ dé ìrù. Ní 1961, kò yani lẹ́nu pé wọ́n yàn pé kí ẹyẹ robin jẹ́ ẹyẹ orílẹ̀-èdè Britain.

Ẹyẹ robin ilẹ̀ Britain kéré ju èkejì rẹ̀ ti ilẹ̀ America, tí àwọn agbókèèrè ṣàkóso ìgbàanì tí wọ́n wá láti England, fún ní orúkọ náà, robin, orúkọ tí wọ́n mọ̀ dunjú dunjú. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹyẹ robin ilẹ̀ Britain ní àwọn ànímọ́ tí kò pa pọ̀ mọ́ ti àwọn mìíràn.

Nígbà tí ìgbà ìwọ́wé bá ń sún mọ́lé, ènìyàn yóò máa rí àríṣá ẹyẹ robin nínú ọgbà ilẹ̀ Britain. Ó máa ń sún mọ́ ẹni tí ó bá ń gbẹ́lẹ̀, tí yóò sì máa ṣọ́ kí ekòló jáde síta. Nígbà míràn, nígbà tí àwọn ọlọ́gbà bá ń sinmi, ẹyẹ robin yóò bà lé orí ṣọ́bìrì ìgbẹ́lẹ̀ láti wo gbogbo àyíká dáradára. Àwọn ènìyàn tilẹ̀ sọ pé ẹyẹ awútutu yìí máa ń tọpasẹ̀ ẹranko mole kí ó lè ṣàyẹ̀wò àwọn òkìtì rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wà jáde fínnífínní. Bí ó ti wù kí ó rí, oúnjẹ ẹyẹ robin pé onírúurú—kòkòrò, kóró èso, àti èso berry, àti ekòló.

Ẹ wo bí ó ti máa ń dùn mọ́ni tó láti rí ìtẹ́ ẹyẹ robin! Gbogbo ilẹ̀kùn tàbí fèrèsé búkà tí ó bá ṣí sílẹ̀ ló máa ń fa àwọn takọtabo tí wọ́n bá ń gùn lọ́wọ́ mọ́ra. Wọ́n lè yára kọ́ ìtẹ́ wọn kíákíá sínú ògbólógbòó ìkòkò tí a fi ń gbin òdòdó kan tàbí sínú odù tí a kò lò mọ́, tàbí sórí wáyà tí ó ká, tàbí sínú àpò ẹ̀wù tí a fi ń ṣiṣẹ́ lóko pàápàá! Ọgbọ́n inú tí ẹyẹ robin ni láti ṣàwárí àwọn ibi tí ó ṣàjèjì tí ó lè kọ́ ìtẹ́ sí kò lópin.

Ẹyẹ robin jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ tí ó rọrùn láti kọ́ kí ó lè máa jẹun ní ọwọ́ rẹ. Bí ìgbà òtútù tí ń sún mọ́lé, tí àwọn oúnjẹ àdánidá rẹ̀ sì ń dín kù, fi oúnjẹ díẹ̀ sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ—bóyá ègé wàrà tàbí ìdin kòkòrò—kí ó sì fi díẹ̀ sórí àwọn nǹkan tí wọ́n wá lójú kan nítòsí. Lẹ́yìn ìgbà méjì tàbí mẹ́ta tí ẹyẹ robin bá ti jẹ àwọn oúnjẹ tí ó wà lórí àwọn nǹkan tí wọ́n wà lójú kan tán, ọkàn rẹ̀ yóò balẹ̀, yóò sì mú díẹ̀ jẹ́ láti inú ọwọ́ tí o nà síta. Ó lè jẹ́ pé kò ní bà sórí ọwọ́ rẹ, àmọ́ ẹyẹ robin náà yóò máa wò ọ́ bí ọ̀rẹ́ láti ìgbà náà lọ. Kò tí ì ní gbàgbé rẹ nígbà tí ó bá tún padà wá ní ìgbà tí ń bọ̀—gan-an bí ìwọ náà kò ti ní tí ì gbàgbé ọ̀rẹ́ rẹ, ẹyẹ robin!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́