Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ọlọ́run Yóò Ha Máa Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Mi Nìṣó Bí?
ỌBA DÁFÍDÌ jẹ́ ọkùnrin kan tí ó jàǹfààní jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ní àkókò kan, ó sọ pé: “Wàhálà ọkàn àyà mi ti di púpọ̀.” Kì í ṣe nítorí ìhùwàsí oníkà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn nìkan ni Dáfídì ṣe ń jìyà, bí kò ṣe nítorí àwọn ìṣìnà tirẹ̀ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé Ọlọ́run pàápàá ti kọ òun sílẹ̀, ó sì gbàdúrà pé: “Yí ojú rẹ sọ́dọ̀ mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi; nítorí tí mo dá nìkan wà, a sì ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.”—Orin Dáfídì 25:11, 16-19, NW.
Bóyá ìwọ náà ń nímọ̀lára wàhálà ọkàn àyà. Ó ṣeé ṣe kí o wà nínú ipò tí kò wulẹ̀ bára dé, tí ó sì ń pá ọ láyà nílé tàbí nílé ẹ̀kọ́. Ó tún ṣeé ṣe pẹ̀lú pé kí o ní àìsàn lílekoko, tàbí kí o máa rẹ̀wẹ̀sì nítorí àìlera kan tí ń bá ọ fínra. Ohun yòó wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, kò yẹ kí o máa dá kojú ìṣòro náà; tọ̀làwọ́tọ̀làwọ́ ni Ọlọ́run nawọ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀ sí ọ.a Bí o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ipò ìbátan kan dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, yóò jẹ́ ìtùnú fún ọ láti mọ̀ pé òun kì í fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ipò nǹkan bá le mọ́ wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí o bá ń kojú àwọn ìṣòro, o lè rò pé Ọlọ́run jìnnà sí ọ. Ó tilẹ̀ lè jọ lójú rẹ pé kò ṣèrànwọ́ kankan fún ọ. Ṣùgbọ́n, ṣé bí ọ̀ràn ti rí gan-an nìyẹn?
‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara’
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jọ̀wọ́ ka Kọ́ríńtì Kejì 12:7-10. Níbẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ nípa bí ó ṣe ń jìyà lọ́wọ́ ohun kan tí ó pè ní ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara.’ Ó ṣeé ṣe kí “ẹ̀gún” náà jẹ́ àìlera ti ara kan, tí ó ṣeé ṣe kí ó kan agbára ìríran rẹ̀. Ohun yòó wù kí ó jẹ́, ó ń ‘gbá a ní àbàrá’ ní ti ìmọ̀lára ṣáá. Láìka ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ onítara-ọkàn lẹ́ẹ̀mẹ́ta, pé kí Ọlọ́run mú un kúrò sí, “ẹ̀gún” náà wà níbẹ̀ ṣáá.
Ṣé Jèhófà ń kọtí ikún sí àwọn àdúrà Pọ́ọ̀lù ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Ọlọ́run sọ fún un pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà yàn láti má yọ “ẹ̀gún” yẹn kúrò, kò fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀. Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, Pọ́ọ̀lù gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ìyẹn ti “tó” láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti mú àìlera rẹ̀ mọ́ra. Bí Pọ́ọ̀lù ti ń tiraka láti ṣe bẹ́ẹ̀, yóò tún wá nírìírí agbára tí Ọlọ́run ní láti múni dúró ní ọ̀nà tuntun, tí ó sì jẹ́ ti ara ẹni kan.
Ìrànlọ́wọ́ Nínú Kíkojú Ipò Ìṣòro
Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìwọ pẹ̀lú lè ní “ẹ̀gún,” tàbí ìṣòro kan, tí ń gún ọ, tí ń mú ọ ronú pé nǹkan kò lè dára, tí ó sì ń mú ọ rẹ̀wẹ̀sì. Bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, Ọlọ́run lè yọ̀ǹda pé kí ìṣòro náà máa wà nìṣó. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kì í ṣe Ọ̀rẹ́ rẹ mọ́. Ọlọ́run sọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Bí o bá gbára lé agbára Ọlọ́run, láìṣe ti ara rẹ, o lè fara dà á. O tilẹ̀ lè rí i pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, o lè ṣàṣeparí àwọn ohun tí o kò rò pé ó ṣeé ṣe rí. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera . . . Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”
Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń jẹ́ Robinb rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́. Àrùn glaucoma fọ́ ọ lójú nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 14. Lọ́dún yẹn kan náà, ìyá rẹ̀ kú lójijì. Nípa bíbẹ̀rẹ̀ sí í kojú àwọn “ẹ̀gún” aronilára wọ̀nyí, Robin wí pé: “Jèhófà nìkan ni mo ní nísinsìnyí. Mo mọ̀ pé bí n óò bá ṣàṣeyọrí ní kíkojú ipò mi, mo gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ọn tímọ́tímọ́.” Ìyẹn ni ohun tí Robin ṣe gẹ́lẹ́, níkẹyìn, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́ nínú ohun gbogbo. Ó ṣe bẹ́ ní ti gidi.”
Ọ̀pọ̀ èwe ti rí i pé dídojúkọ ìdánwò ti ran àwọn lọ́wọ́ ní gidi láti túbọ̀ fà mọ́ Ọlọ́run. Gbé ọ̀ràn ti Jeff ọ̀dọ́ yẹ̀ wò. Bàbá rẹ̀ pa ìdílé rẹ̀ tì, ó fi ìyá Jeff sílẹ̀ láti máa bójú tó ọmọ méje. Jeff, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 12 péré nígbà náà, sọ pé: “Mo mọ ipò àìníbàbá lára gan-an. Mo yán hànhàn fún ẹnì kan tí yóò dí ìmọ̀lára òfò tí mo ń ní lójoojúmọ́.” Kí ni Jeff ṣe? “Mo gbàdúrà sí Jèhófà láti dí ipò àìní náà fún mi.” Jeff ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀, ó sì kó wọnú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Bí àkókò ti ń lọ, ó nímọ̀lára pé Jèhófà ń ti òun lẹ́yìn—nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tí ń fúnni lókun, àti nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. (Fi wé Orin Dáfídì 27:10.) Nísinsìnyí tí Jeff jẹ́ ẹni ọdún 27, ó ronú pa dà sẹ́yìn, ó sì sọ pé: “N kò ní ẹni tí mo lè yíjú sí fún ààbò nígbà yẹn, nítorí náà, mo fà mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́.” Ó pe ipò ìbátan tímọ́tímọ́ yẹn ní “ẹ̀bùn tí kò ṣeé díye lé, tí ó jẹ́ ìyọrísí ìdánwò yí.”
Bí O Ṣe Lè Rí Ìrànwọ́ Ọlọ́run Gbà
Ọ̀rẹ́ rẹ tí ń bẹ lọ́run yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ bákan náà la àwọn ìṣòro rẹ já. Àmọ́, kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe? Ó dára, kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ èyíkéyìí lè máa gbèrú, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ wà. Àdúrà ni ọ̀nà tí a fi ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ń jẹ́ kí ó mọ̀ pé a nílò ìrànwọ́ òun. Bí ó ti wù kí ó rí, àdúrà kò níye lórí bí kò bá fi ọ̀yàyà hàn, tàbí tí ó jẹ́ oréfèé. Bíi ti àwọn èwe tí a mẹ́nu bà lókè, o gbọ́dọ̀ “tú ọkàn àyà [rẹ] jáde” sí Ọlọ́run! (Orin Dáfídì 62:8, NW) O tilẹ̀ lè ní láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀. (Fílípì 4:6) Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ jẹ́ àdúrà jíjinlẹ̀, tí a fi ìtara ọkàn gbà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
Jẹ́ ká sọ pé o ní ìṣòro láti máa kápá ìrònú rẹ, tàbí ó ṣòro fún ọ láti ṣẹ́pá àṣà búburú kan. Rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà! Bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ rẹ̀ nígbà ìdẹwò. Èyí lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Gary gbà pé: “Nígbà tí mo bá ní ìsúnniṣe lílágbára láti ṣe ohun búburú kan, mo máa ń gbàdúrà. Nígbà míràn, mo máa ń ronú pé, ‘Ǹjẹ́ mo tóótun láti kàn sí Jèhófà?’ Síbẹ̀, mo máa ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Ó ń fún mi lókun tí mo nílò láti forí tì í.” Kódà, bí ó bá tilẹ̀ nira lákọ̀ọ́kọ́, máa ṣí ọkàn àyà rẹ payá fún Ọlọ́run.
Àmọ́ bí ó bá jọ pé a kì í dáhùn àdúrà rẹ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, Lora ń jìjàdù láti ṣẹ́pá àṣà búburú ti ìdáhùwà ìbálòpọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń fi òótọ́ inú bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, ṣùgbọ́n kò jọ pé mo lè ṣíwọ́.” Nígbà míràn, Ọlọ́run lè yọ̀ǹda fún wa pé kí a fi bí àwọn ẹ̀bẹ̀ wa ti mú wa lọ́kàn tó hàn. (Fi wé Orin Dáfídì 88:13, 14.) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ tẹra mọ́ gbígbàdúrà! (Mátíù 7:7; Róòmù 12:12) Lora ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Nígbà kan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìmọ̀ràn tí ń wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ń jíròrò kókó ọ̀ràn náà nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society.c Bí àkókò ti ń lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìyọrísí rẹ̀. Ó rántí pé: “Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ṣàṣeyọrí ní dídènà ìdẹwò náà, mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, nítorí tí mo mọ̀ pé, ó ń tì mí lẹ́yìn.” Òtítọ́ ni pé, o lè ní ìfàsẹ́yìn díẹ̀ bí o ti ń gbìyànjú láti borí ìṣòro rẹ. Ṣùgbọ́n, bí o bá ń jìjàdù nìṣó, tí o kò sì ń mọ̀ọ́mọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn àìlera rẹ, inú Ọlọ́run yóò dùn sí ‘ìsapá àfi-taratara-ṣe’ rẹ, yóò sì máa jẹ́ Ọ̀rẹ́ rẹ nìṣó.—Pétérù Kejì 1:5.
Bíbá Ọlọ́run Ṣiṣẹ́
Ọ̀nà míràn tí a fi lè rí ìrànwọ́ Ọlọ́run gbà ni nípa títẹ́wọ́gba ìkésíni rẹ̀ láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 3:9) Èyí kan nínípìn-ín nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Ọlọ́run. (Mátíù 28:19, 20) Nígbà tí o bá ní ìdààmú tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì, ìrònú lílọ́wọ́ nínú oríṣi iṣẹ́ kankan kì í jọ ohun tí ń fani mọ́ra. Bí ó ti wù kí ó rí, ‘níní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa’ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an. (Kọ́ríńtì Kíní 15:58) Ó kéré pin, yóò mú kí o gbọ́kàn kúrò lórí àwọn ìṣòro tìrẹ fúnra rẹ. (Fi wé Òwe 18:1.) Robin, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ṣáájú, sọ nípa àwọn àkókò ìṣòro rẹ̀ pé: “Ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ láti forí tì í ni iṣẹ́ tí mo ń ṣe fún Jèhófà!”
Bíbá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí ìmọ̀lára èyíkéyìí tí ń wà nìṣó pé Ọlọ́run ti pa ọ́ tì. Nígbà tí ẹni méjì bá ń ṣiṣẹ́ pọ̀ bí àwùjọ òṣìṣẹ́ tí ń lépa góńgó kan náà, wọn kò ha máa ń fìgbà gbogbo sún mọ́ra bí ọ̀rẹ́ bí? Bí o ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, nígbà gbogbo ni o ń kojú ìpèníjà. O rí i pé o máa ń yíjú sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Bí Ọlọ́run ti ń bù kún akitiyan rẹ, ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń di ojúlówó sí i. O bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ìgbẹ́kẹ̀lé tí Ọlọ́run ní nínú rẹ gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́. Èyí lè jẹ́ àlékún gidi kan fún bí o ṣe dá ara rẹ lójú tó.
Bí àpẹẹrẹ, Carol kò dá ara rẹ̀ lójú. Ìyá rẹ̀ ti pa ara rẹ̀, bàbá rẹ̀ aṣeniléṣe sì sábà máa ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọmọ ọdún 17, ó di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Nísinsìnyí, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ó ti jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, ó wí pé: “Iṣẹ́ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi nítorí pé, mo ti rí ìbùkún Jèhófà lórí mi. Mo ń sọ fún ara mi pé, ‘Bí Ọlọ́run bá fẹ́ràn mi, n kò ṣàìjámọ́ǹkan.’ Lílò tí Jèhófà ń lò mí láti polongo orúkọ rẹ̀ ti mú kí n túbọ̀ dá ara mi lójú sí i.”
“Ẹ Tọ́ Ọ Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Ẹni Rere”
Lẹ́yìn tí Ọba Dáfídì bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro kan tí ó wu ìwàláàyè rẹ̀ léwu, ó kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.” (Orin Dáfídì 34:4, 6, àkọlé, NW; Sámúẹ́lì Kíní 21:10-12) Nítorí náà, ìrírí tí Dáfídì ti ní mú kí ó lè sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.”—Orin Dáfídì 34:8, NW.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìwàláàyè rẹ lè má wà nínú ewu bíi ti Dáfídì, ó dájú pé ìwọ yóò máa nírìírí másùnmáwo àti ìtánnilókun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí ‘wàhálà bá di púpọ̀ nínú ọkàn àyà rẹ,’ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 25:17, NW) Má bẹ̀rù pé Ọlọ́run yóò fawọ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn. Bí o ti ń fi sùúrù fara dà á, tí o sì ń nírìírí ìtìlẹ́yìn àti àbójútó Jèhófà ní tààràtà, ìwọ yóò “tọ́ ọ wò,” ìwọ yóò “sì rí i” fúnra rẹ “pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” Òun yóò sì máa jẹ́ Ọ̀rẹ́ rẹ nìṣó títí láé.—Jákọ́bù 4:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Mo Ha Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọrun Níti Gidi Bí?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti July 22, 1995.
b A ti yí àwọn kan nínú orúkọ wọ̀nyí pa dà.
c Wo orí 25 àti 26 nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ọlọ́run ha máa ń pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tì nígbà ìṣòro bí?