O Ha Ní ‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara’ Bí?
1 A ní ìfẹ́-ọkàn gidigidi láti ṣe iṣẹ́ tí a pa láṣẹ fún wa, láti wàásù ìhìn rere náà, títí dé ibi tí agbára wa bá dé. Ṣùgbọ́n, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n láti nípìn-ín ní kíkún nítorí wọ́n ní òkùnrùn tàbí àbùkù ara tí ó mú kí ó ṣòro láti ṣe tó bí wọ́n ti ń fẹ́. Ó lè ṣòro fún wọn láti kojú àwọn ìmọ̀lára ìjákulẹ̀, pàápàá nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn ẹlòmíràn tí ó yí wọn ká jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.—1 Kọ́r. 9:16.
2 Àpẹẹrẹ Kan Láti Fara Wé: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ rẹ̀ jìjàkadì. Ó bẹ Jèhófà lẹ́ẹ̀mẹ́ta láti mú ohun ìdènà tí ń kó ìrora ọkàn báni náà kúrò, èyí tí òun ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “áńgẹ́lì Sátánì” tí ó ń gbá a ní àbàrá ṣáá. Síbẹ̀, láìka ìyẹn sí, Pọ́ọ̀lù fara dà á, ó sì ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ. Kò káàánú ara rẹ̀ tàbí kí ó máa ráhùn ṣáá. Ó ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe. Kọ́kọ́rọ́ sí àṣeyọrí rẹ̀ ní kíkojú ipò náà ni ìmúdánilójú yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Àìlera Pọ́ọ̀lù di okun nígbà tí ó kọ́ láti tẹ́wọ́ gba ipò tí ó wà kí ó sì gbára lé Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ láti lè fara dà.—2 Kọ́r. 12:7-10.
3 Bí O Ṣe Lè Fara Dà: Ipò ẹlẹgẹ́ ti ẹ̀dá ha ń dín iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Ọlọ́run kù bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ní ojú ìwòye tí Pọ́ọ̀lù ní. Àní bí àìlera tàbí àbùkù ara rẹ kò bá ní ojútùú pátápátá nínú ètò àwọn nǹkan yìí, o lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, ẹni tí ó mọ àwọn àìní rẹ tí yóò sì pèsè “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Lo àǹfààní ìrànwọ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ nínú ìjọ, má ṣe ya ara rẹ sọ́tọ̀. (Òwe 18:1) Bí ó bá ṣòro fún ọ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, wá àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà.
4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún kan nínú ara lè dín ohun tí o lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kù, kò yẹ kí o nímọ̀lára pé o kò nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí Pọ́ọ̀lù, ìwọ pẹ̀lú lè “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run,” ní ṣíṣe ohun tí okun àti àyíká ipò rẹ bá fàyè gbà. (Ìṣe 20:24) Bí o ti ń sapá láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeparí, mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn gidigidi.—Héb. 6:10.