Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 4
Orin 10
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
15 min: “Ẹ̀mí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tí o bá ń kárí ìpínrọ̀ 3, fi àyọkà tí ó bá a mu láti inú ìwé 1998 Yearbook kún un.
22 min: “Ṣàṣàyàn Àwọn Àpilẹ̀kọ Láti Fi Fa Àwọn Ènìyàn Mọ́ra Lórí Ohun Tí Wọ́n Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Pàtó.” Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì láti inú àpilẹ̀kọ náà. Ṣàlàyé pé àwọn ìtẹ̀jáde tí ó ti pẹ́ pàápàá tí ó ṣì dára ni a lè fi lọni lọ́nà yìí. Ké sí àwọn akéde láti ṣàlàyé àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí láti gbé jáde lákànṣe. Ṣàṣefihàn ìfilọni tí ó wà ní ìpínrọ̀ 7.
Orin 212 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 11
Orin 197
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
12 min: “Kíkọ́ Àwọn Àgbà Bí A Ṣe Ń Kàwé.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ láti ẹnu alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́.
25 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1998.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 8) Kí alàgbà kan kárí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5 àti 8. Tẹnu mọ́ bí mímúrasílẹ̀ ṣáájú ṣe ní ìjẹ́pàtàkì nínú Ìwé Mímọ́.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 18
Orin 141
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣe ìfilọ̀ àkànṣe ìṣètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “O Ha Ní ‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara’ Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ̀rọ̀ lórí “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe” nínú Ilé-ìṣọ́nà, November 15, 1987, ojú ìwé 29.
22 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1998.” (Ìpínrọ̀ 9 sí 16) Kí akọ̀wé kárí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 13 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Tẹnu mọ́ bí ìtìlẹyìn onígbọràn sí ìṣètò ilé gbígbé ṣe ní ìjẹ́pàtàkì nínú Ìwé Mímọ́.
Orin 139 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 25
Orin 137
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Àìní àdúgbò.
20 min: Ìdí Tí Mo Fi Ka Àwọn Ìpàdé Ìjọ Sí Gidigidi. Alàgbà darí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àwọn tí ó máa ń wá sí ìpàdé déédéé tí wọ́n ṣojú fún onírúurú àwọn tí ọ̀ràn wọn rí bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ, bóyá kí ó ní tọkọtaya kan, àgbàlagbà kan, àti ọ̀dọ́langba kan nínú. Wọ́n sọ èrò ọkàn wọn nípa ìdí tí wọ́n fi máa ń wá sí ìpàdé ní gbogbo ìgbà: ìbákẹ́gbẹ́ rere, ìtọ́ni àtọ̀runwá, àti ìmọ̀ràn tí ó yè kooro, tí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ kí wọ́n sì máa jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí nìṣó. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ tẹnu mọ́ bí a ṣe ń bù kún gbogbo wa nígbà tí a bá ń wá sí àwọn ìpàdé déédéé.
Orin 222 àti àdúrà ìparí.