ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/1 ojú ìwé 24-27
  • Àìlera Ẹ̀dá Ènìyàn Ń Fi Hàn Pé Agbára Jèhófà Pọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìlera Ẹ̀dá Ènìyàn Ń Fi Hàn Pé Agbára Jèhófà Pọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú Àdánwò
  • Kíkojú Àìpé
  • Agbára Àtiwàásù
  • Fífarada ‘Ẹ̀gún Nínú Ẹran Ara’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • O Ha Ní ‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara’ Bí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ẹ̀gún Nínú Ara Pọ́ọ̀lù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • 2 Kọ́ríńtì 12:9—“Oore-Ọ̀fẹ́ Mi Tó fún Ọ”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/1 ojú ìwé 24-27

Àìlera Ẹ̀dá Ènìyàn Ń Fi Hàn Pé Agbára Jèhófà Pọ̀

“Gbogbo ènìyàn rò pé òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí ó jẹ́ aláyọ̀, tí ó sì túra ká ni mí. Èmi ni mo sábà máa ń bá àwọn ẹlòmíràn yanjú ìṣòro wọn. Ṣùgbọ́n, lọ́wọ́ kan náà, nínú lọ́hùn-ún, mo ń nímọ̀lára bíi pé mo ń kú lọ. Àwọn ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè àti másùn máwo ń ṣàkóbá fún ìlera mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn fún àwọn ènìyàn. Mo ṣáà fẹ́ wà nínú ilé lórí ibùsùn. Fún ọ̀pọ̀ oṣù, mo bẹ Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí n kú.”—Vanessa.

GẸ́GẸ́ bí àpẹẹrẹ tí a mẹ́nu kàn lókè yí, kò ṣàjèjì pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò nímọ̀lára àbájáde gbígbé ní “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí. (Tímótì Kejì 3:1) Àwọn kan tilẹ̀ lè sorí kodò. (Fílípì 2:25-27) Nígbà tí ó bá ń bá a lọ fún ìgbà pípẹ́, ipò àìnírètí lè sọ wá di aláìlókun, nítorí Bíbélì sọ pé: “Bí ìwọ bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ ìpọ́njú, agbára rẹ kò tó nǹkan.” (Òwe 24:10) Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí a bá kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, a nílò agbára—ó tilẹ̀ lè jẹ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—Kọ́ríńtì Kejì 4:7.

Jèhófà Ọlọ́run ni orísun agbára tí kò láàlà. Èyí hàn kedere nígbà tí a bá ṣàyẹ̀wò ìṣẹ̀dá rẹ̀. (Róòmù 1:20) Fún àpẹẹrẹ, gbé oòrùn yẹ̀ wò. Ilẹ̀ ayé ń gba 240 tírílíọ̀nù ìwọ̀n agbára tí ń wá láti inú oòrùn láìdáwọ́ dúró. Síbẹ̀, iye yìí wulẹ̀ dúró fún nǹkan bí ìlàjì bílíọ̀nù kan nínú agbára tí ń ti inú oòrùn wá. Oòrùn sì kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ tí a mọ̀ sí ìràwọ̀ ràgàjì. Rigel jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí, ìràwọ̀ kan nínú ìṣùpọ̀ Óríónì tí ó tóbi ju oòrùn wa lọ ní ìlọ́po 50, tí ó sì ń mú agbára tí ó ju tirẹ̀ lọ jáde ní ìlọ́po ìgbà 150,000!

Ẹlẹ́dàá irú ilé agbára ọ̀run bẹ́ẹ̀ fúnra rẹ̀ gbọ́dọ̀ ‘tóbi ni ipá.’ (Aísáyà 40:26; Orin Dáfídì 8:3, 4) Ní tòótọ́, wòlíì Aísáyà sọ pé Jèhófà “kì í ṣàárẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àárẹ̀ kì í mú un.” Ọlọ́run múra tán láti ṣàjọpín agbára rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá nímọ̀lára pé òun ń ṣàárẹ̀, nítorí àìlera ẹ̀dá ènìyàn. (Aísáyà 40:28, 29) A ṣàkàwé bí ó ṣe ń ṣe èyí nínú ọ̀ràn Kristẹni náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

Kíkojú Àdánwò

Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì nípa ìṣòro kan tí òun ní láti fara dà. Ó pè é ní ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara.’ (Kọ́ríńtì Kejì 12:7) “Ẹ̀gún” yìí ti lè jẹ́ ìṣòro ìlera, bóyá ojú ṣíṣú. (Gálátíà 4:15; 6:11) Ó sì lè jẹ́ àwọn àpọ́sítélì èké àti àwọn ayọnilẹ́nu mìíràn tí wọ́n gbé ìpèníjà dìde sí jíjẹ́ tí ó jẹ́ àpọ́sítélì àti iṣẹ́ rẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. (Kọ́ríńtì Kejì 11:5, 6, 12-15; Gálátíà 1:6-9; 5:12) Ohun yòó wú tí ì báà jẹ́, ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ yìí kó ìdààmú bá Pọ́ọ̀lù, ó sì gbàdúrà léraléra pé kí a bá òun yọ ọ́ kúrò.—Kọ́ríńtì Kejì 12:8.

Ṣùgbọ́n, Jèhófà kò fọwọ́ sí ohun tí Pọ́ọ̀lù béèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:9) Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nípa èyí? Toò, nígbà tí a bá gbé ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni ní ìṣáájú yẹ̀ wò, kìkì nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nìkan ni ó fi lè ní ipò ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run rárá—áńbọ̀sìbọ́sí ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì!a (Fi wé Sekaráyà 2:8; Ìṣípayá 16:5, 6.) Ó lè jẹ́ ohun tí Jèhófà ń sọ fún Pọ́ọ̀lù ni pé àǹfààní jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn ‘ti tó fún un.’ Kò kan mímú ìṣòro ìgbésí ayé kúrò nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu. Ní tòótọ́, àwọn ìṣòro kan tilẹ̀ lè wá nítorí àfikún àǹfààní tí ó ní. (Kọ́ríńtì Kejì 11:24-27; Tímótì Kejì 3:12) Bí ó ti wù kí ó rí, Pọ́ọ̀lù ṣáà ní láti fara da ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ rẹ̀.

Ṣùgbọ́n, ó dájú pé kì í ṣe pé Jèhófà pa Pọ́ọ̀lù tì láìfi àánú hàn sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé: “Agbára mi ni a sọ di pípé nínú àìlera.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:9) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò fi ìfẹ́ fún Pọ́ọ̀lù ní okun láti kojú ipò rẹ̀. Nípa báyìí, ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ Pọ́ọ̀lù di ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n. Ó kọ́ ọ láti gbára lé okun Jèhófà dípò okun ti ara rẹ̀. Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù kọ́ ẹ̀kọ́ yìí dáradára, nítorí pé ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn àyíká ipò yòó wù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni náà tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:11, 13.

Ìwọ ńkọ́? Ìwọ ha ń fara da irú ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ kan bí, bóyá àìsàn tàbí ipò kan nínú ìgbésí ayé tí ń kó àníyàn púpọ̀ bá ọ? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ́kàn. Bí Jèhófà tilẹ̀ lè máà mú ìṣòro náà kúrò nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu, ó lè fún ọ ní ọgbọ́n àti okun inú láti kojú rẹ̀ bí o ṣe ń bá a nìṣó láti fi ire Ìjọba náà sí ipò kíní nínú ìgbésí ayé.—Mátíù 6:33.

Bí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó bá ń dí ọ lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ohun púpọ̀ tó bí o ṣe fẹ́ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni, má ṣe sọ̀rètí nù. Dípò tí ìwọ yóò fi máa wo àdánwò rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń pààlà sí iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Jèhófà, wò ó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan láti mú kí o túbọ̀ gbára lé e. Rántí, pẹ̀lú, pé kì í ṣe bí ìgbòkègbodò ṣe tó ni a fi ń díwọ̀n ìníyelórí Kristẹni kan, bí kò ṣe ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. (Fi wé Máàkù 12:41-44.) Nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ túmọ̀ sí pé ìwọ ń ṣiṣẹ́ sìn ín dé gbogbo ibi tí agbára rẹ mọ—kì í ṣe ibi tí agbára ẹlòmíràn mọ.—Mátíù 22:37; Gálátíà 6:4, 5.

Bí ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ rẹ bá ní ipò ìrora ọkàn nínú ìgbésí ayé nínú, irú bí ikú olólùfẹ́ kan, tẹ̀ lé ìṣílétí Bíbélì pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dáfídì 55:22) Kristẹni obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sylvia ṣe èyí. Láàárín ọdún díẹ̀, ó pàdánù ọkọ rẹ̀ àti mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ mẹ́sàn-án mìíràn nínú ikú, lẹ́yìn ìgbéyàwó 50 ọdún—títí kan àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kéékèèké méjì. Sylvia sọ pé: “Bí kì í bá ṣe agbára Jèhófà ni, ǹ bá ti banú jẹ́ ré kọjá ààlà. Ṣùgbọ́n mo rí ìtùnú ńláǹlà nínú àdúrà. Mo ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ láìdábọ̀. Mo mọ̀ pé ó ń fún mi ni okun láti fara dà á.”

Ẹ wo bí ó ti fini lọ́kàn balẹ̀ tó láti mọ̀ pé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” lè fún àwọn tí inú wọn bà jẹ́ ní agbára láti fara dà á! (Kọ́ríńtì Kejì 1:3; Tẹsalóníkà Kíní 4:13) Ní mímọrírì èyí, a lè lóye ìparí èrò tí Pọ́ọ̀lù dé lórí ọ̀ràn náà. Ó kọ̀wé pé: “Mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”—Kọ́ríńtì Kejì 12:10.

Kíkojú Àìpé

Gbogbo wa ti jogún àìpé láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. (Róòmù 5:12) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a ń bá ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ jìjàkadì. Ẹ wo bí yóò ti bani lọ́kàn jẹ́ tó láti wá mọ̀ pé àwọn àbùdá “ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà” ní agbára gírígírí lórí wa ju bí a ti rò lọ! (Éfésù 4:22-24) Nínú irú àkókò bẹ́ẹ̀, a lè nímọ̀lára bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó kọ̀wé pé: “Ní ti gidi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí nínú àwọn ẹ̀yà ara mi òfin mìíràn tí ń bá òfin èrò inú mi jagun tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:22, 23.

Níhìn-ín pẹ̀lú, a lè rí agbára Jèhófà gbà. Nígbà tí o bá ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àìlera ti ara ẹni, má ṣe dẹ́kun yíyíjú sí i nínú àdúrà, ní wíwá ìdáríjì rẹ̀ tọkàntọkàn láìka iye ìgbà tí o ní láti tọ̀ ọ́ lọ nípa ìṣòro kan náà sí. Nítorí inú rere rẹ̀ tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, Jèhófà, ẹni tí “ó ń díwọ̀n àwọn ọkàn àyà,” tí ó sì lè rí bí òótọ́ inú rẹ ti jinlẹ̀ tó, yóò fún ọ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́. (Òwe 21:2, NW) Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jèhófà lè fún ọ ní okun láti pa dà bẹ̀rẹ̀ bíbá àìlera ẹran ara jà.—Lúùkù 11:13.

A tún nílò okun láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nígbà tí a bá ń kojú àìpé àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan lè sọ̀rọ̀ sí wa “láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18, NW) Èyí lè dùn wá gan-an, ní pàtàkì nígbà tí ó bá wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí a rò pé ó yẹ kí ó mọ̀ ju ìyẹn lọ. Ó lè kó ìdààmú bá wa gidigidi. Àwọn kan tilẹ̀ ti lo irú ìwà láìfí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwíjàre fún fífi Jèhófà sílẹ̀—àṣìṣe búburú jù lọ tí ẹnì kan lè ṣe!

Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀mì ìrònú tí ó wà déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ojú tí ó tọ́ wo àìlera àwọn ẹlòmíràn. A kò lè retí ìjẹ́pípé láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà, Sólómọ́nì, rán wa létí pé: “Kò sí ènìyàn kan tí kì í ṣẹ̀.” (Àwọn Ọba Kìíní 8:46) Arthur, Kristẹni ẹni àmì òróró tí ó fi ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́ sin Jèhófà fún nǹkan bí àádọ́rin ọdún, sọ pé: “Àìlera àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa ń fún wa ní àǹfààní láti fi hàn pé a jẹ́ olùpa ìwà títọ́ mọ́, ní dídán bí a ṣe lè fàyà rán nǹkan tó gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni wò. Bí a bá fàyè gba ohun tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn sọ tàbí ṣe láti di iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà lọ́wọ́, ẹ̀dá ènìyàn ni a ń ṣiṣẹ́ sìn. Ó ṣe tán, àwọn ará wa pẹ̀lú ṣáà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí a bá fojú sílẹ̀ láti rí ìwà rere wọn, láìpẹ́ a óò rí i pé wọn kò burú tó bí a ti rò.”

Agbára Àtiwàásù

Ṣáájú kí ó tó gòkè re ọ̀run, Jésù wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin yóò gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá dé sórí yín, ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.

Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jésù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá iṣẹ́ yìí lọ ní 233 ilẹ̀ káàkiri àgbáyé. Lápapọ̀, wọ́n lo iye tí ó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí lọ́dọọdún ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ Jèhófà. Ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ yìí kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ní àwọn ilẹ̀ kan, a fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tàbí a kà á léèwọ̀. Bákan náà, gbé àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà yẹ̀ wò—àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, tí ara wọn kò le, àwọn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìṣòro àti àníyàn tirẹ̀. Síbẹ̀ iṣẹ́ náà ń lọ ní pẹrẹwu, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, ní ọdún mẹ́ta tí ó kọjá, iye tí ó lé ní mílíọ̀nù kan ènìyàn ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì fi ìyàsímímọ́ wọn hàn nípasẹ̀ ṣíṣe batisí nínú omi. (Mátíù 28:18-20) Lóòótọ́, okun Ọlọ́run nìkan ni a fi ń ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Sekaráyà sọ pé: “Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi.”—Sekaráyà 4:6.

Bí o bá jẹ́ akéde ìhìn rere náà, ìwọ ń nípìn-ín—bí ó ti wù kí ó dà bíi pé ó kéré tó—nínú àṣeparí kíkọyọyọ yẹn. Láìka “ẹ̀gún” tí o lè máa fara dà sí, ìwọ lè ní ìdánilójú pé, Jèhófà kì yóò gbàgbé ‘iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn sí orúkọ rẹ̀.’ (Hébérù 6:10) Nítorí náà, máa bá a nìṣó láti gbára lé Orísun gbogbo agbára gbígbéṣẹ́ fún ìrànlọ́wọ́. Rántí pé, okun Jèhófà nìkan ni ó lè fún wa ní ìfaradà; àìlera wa ń sọ agbára rẹ̀ di pípé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àmọ́ ṣáá o, níwọ̀n bí ‘gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ tí wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,’ ó jẹ́ ẹ̀rí àánú Ọlọ́run pé ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí lè wá sínú ipò ìbátan pẹ̀lú rẹ̀ rárá.—Róòmù 3:23.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Agbára Jèhófà nìkan ni a fi ń ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́