ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 11-13
Ẹ̀gún Nínú Ara Pọ́ọ̀lù
Bíbélì sábà máa ń lo ẹ̀gún lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bíbélì lè lò ó láti tọ́ka sí èèyàn tó máa ń fa ìjàǹbá, tó sì máa ń kó ìdààmú báni tàbí nǹkan míì tó lè fa ìṣòro. (Nọ 33:55; Owe 22:5; Isk 28:24) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “ẹ̀gún” tó wà nínú ara rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí àwọn àpọ́sítélì èké àtàwọn míì tó ń ta kò ó pé ayédèrú àpọ́sítélì ni. Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣe jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó ṣeé ṣe kó tún jẹ́ “ẹ̀gún” nínú ẹran ara Pọ́ọ̀lù?
Kí ni “ẹ̀gún” tó wà nínú ara rẹ?
Báwo lo ṣe lè gbára lé Jèhófà kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara dà á?