Wọ́n Fara Da Ẹ̀gún Nínú Ẹran Ara Wọn
“A fi ẹ̀gún kan sínú ẹran ara mi, áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá ṣáá.” —2 KỌ́RÍŃTÌ 12:7.
1. Kí ni díẹ̀ lára ìṣòro táwọn èèyàn ń bá yí lóde òní?
ÌDÁNWÒ ha wà tí ò ń bá yí bí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, àwọn Kristẹni olóòótọ́ ń fojú winá àtakò rírorò, ìṣòro ìdílé, àìsàn, àìrówóná, pákáǹleke, ikú olólùfẹ́ ẹni, àtàwọn ìṣòro mìíràn. (2 Tímótì 3:1-5) Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àìtó oúnjẹ àti ogun ń wu ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn léwu.
2, 3. Èrò òdì wo ló lè jẹ yọ látinú àwọn ìṣòro tí ń gún wa lára bí ẹ̀gún, èé sì ti ṣe tó fi léwu?
2 Irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ káyé súni pátápátá, àgàgà bó bá jẹ́ pé ìgbà kan náà ni gbogbo rẹ̀ rọ́ dé wìì. Kíyè sí ohun tí ìwé Òwe 24:10 sọ, pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Òdodo ọ̀rọ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí àwọn àdánwò tí à ń rí lè tán wa lókun pátápátá. Ó tilẹ̀ lè jẹ́ kí ọwọ́ wa rọ, tí a kò fi ní lè forí tì í dópin. Lọ́nà wo?
3 Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ìrẹ̀wẹ̀sì lè jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà òdì nípa ìṣòro wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè wá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ ìṣòro náà lójú ju bó ṣe yẹ lọ, ká wá bẹ̀rẹ̀ sí káàánú ara wa. Àwọn kan tiẹ̀ lè ké gbàjarè sí Ọlọ́run pé, “Kí ló dé tó o fi jẹ́ kí irú ìyà yìí máa jẹ mí?” Béèyàn bá jẹ́ kí irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ gba òun lọ́kàn, onítọ̀hún lè pàdánù ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrẹ̀wẹ̀sì lè wá bo ìránṣẹ́ Ọlọ́run débi pé kí ó ṣíwọ́ jíja “ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 6:12.
4, 5. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ipa wo ni Sátánì ń kó nínú àwọn ìṣòro wa, síbẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wo la ní?
4 Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run kọ́ ló ń fà wá sínú àdánwò. (Jákọ́bù 1:13) Ìdí táwọn àdánwò kan fi ń dé bá wa kò ju pé à ń gbìyànjú láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà ni Sátánì Èṣù, olórí ọ̀tá Ọlọ́run, ń dojú ìjà kọ. Ní ìwọ̀nba àkókò kúkúrú tó ṣẹ́ kù fún un, ẹni ibi yẹn, tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” fẹ́ rí i dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Onírúurú ìyà tí ọwọ́ Sátánì ká ló fi ń jẹ ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé. (1 Pétérù 5:9) Òótọ́ ni pé Sátánì kọ́ ló dìídì ń fa gbogbo ìṣòro wa, àmọ́ ó lè lo ìṣòro wọ̀nyẹn láti túbọ̀ fi kó àárẹ̀ bá wa.
5 Àmọ́ bó ti wù kí Sátánì tàbí àwọn ohun ìjà rẹ̀ lágbára tó, a lè ṣẹ́gun rẹ̀! Kí ló fún wa ní ìdánilójú yẹn? Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ń jà fún wa ni. Ó ti jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ gbogbo àrékérekè Sátánì. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Àní, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ púpọ̀ fún wa nípa àwọn àdánwò tó ń dé bá àwọn Kristẹni tòótọ́. Bíbélì pe àdánwò ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara.’ Èé ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàlàyé gbólóhùn yẹn. A óò wá rí i pé àwa nìkan kọ́ la nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti lè borí àdánwò.
Ìdí Tí Àdánwò Fi Ń Dà Bí Ẹ̀gún
6. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara,’ kí ló sì ṣeé ṣe kí ẹ̀gún náà jẹ́?
6 Pọ́ọ̀lù, tí ojú rẹ̀ rí màbo, kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “A fi ẹ̀gún kan sínú ẹran ara mi, áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá ṣáá, kí a má bàa gbé mi ga púpọ̀ jù.” (2 Kọ́ríńtì 12:7) Kí ni ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara Pọ́ọ̀lù yìí? Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, ẹ̀gún tó wọnú ara lọ á máa roni lára gógó. Nítorí náà àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ tí Pọ́ọ̀lù lò yìí ń sọ̀rọ̀ nípa nǹkan kan tó ń ro ó lára—ì báà jẹ́ ìrora nípa ti ara tàbí nípa ti ìmí ẹ̀dùn tàbí kó jẹ́ àpapọ̀ méjèèjì yìí. Ó lè jẹ́ ojú ló ń dun Pọ́ọ̀lù tàbí kó jẹ́ àìsàn kan nínú àgọ́ ara rẹ̀. Tàbí kẹ̀, ẹ̀gún náà lè jẹ mọ́ àwọn tí ń sọ pé ayédèrú àpọ́sítélì ni Pọ́ọ̀lù jẹ́, tí wọ́n sì ń sọ pé ìranù ni iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́ni tó ń ṣe. (2 Kọ́ríńtì 10:10-12; 11:5, 6, 13) Ohun yòówù kí ẹ̀gún náà jẹ́, ó ti wọlé sí Pọ́ọ̀lù lára, kò sì ṣeé yọ.
7, 8. (a) Kí ni gbólóhùn náà “láti máa gbá mi ní àbàrá ṣáá” tọ́ka sí? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fara da ẹ̀gún èyíkéyìí tó bá ń gún wa lára nísinsìnyí?
7 Ṣàkíyèsí pé ẹ̀gún náà ń gbá Pọ́ọ̀lù lábàrá ṣáá. Ó yẹ fún àfiyèsí pé, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín wá látinú ọ̀rọ̀ tá à ń lò fún “ìkúùkù.” A lo ọ̀rọ̀ yẹn ní ṣáńgílítí nínú Mátíù 26:67, a sì lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú 1 Kọ́ríńtì 4:11. Ohun tó túmọ̀ sí nínú ẹsẹ wọ̀nyẹn ni gbígbáni ní ìkúùkù. Nítorí inú burúkú tí Sátánì ní sí Jèhófà àtàwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, a mọ̀ pé inú Èṣù dùn pé ẹ̀gún kan ń gún Pọ́ọ̀lù ṣáá. Bẹ́ẹ̀ náà ni inú Sátánì máa ń dùn lónìí nígbà tí ẹ̀gún kan nínú ẹran ara bá ń dá wa lóró.
8 Fún ìdí yìí, gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká mọ bá a ṣe lè fara da irú àwọn ẹ̀gún bẹ́ẹ̀. Ẹ̀mí wa lè lọ sí i bí a kò bá mọ bó ṣe yẹ ká fara dà á! Rántí pé Jèhófà fẹ́ fún wa ní ìyè ayérayé nínú ètò tuntun rẹ̀, níbi tí àwọn ìṣòro tí ń gúnni bí ẹ̀gún kò ti ní sí mọ́ láé. Kí ọwọ́ wa lè tẹ ẹ̀bùn àgbàyanu yìí, Ọlọ́run ti fún wa ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mímọ́, láti fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ti fara da àwọn ẹ̀gún nínú ẹran ara láìjuwọ́sílẹ̀. Èèyàn aláìpé, ẹlẹ́ran ara bíi tiwa náà ni wọ́n. Gbígbé àpẹẹrẹ díẹ̀ lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” púpọ̀ rẹpẹtẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò lè ràn wá lọ́wọ́ láti “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Hébérù 12:1) Ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n fara dà lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwa náà lè fara da ẹ̀gún èyíkéyìí tí Sátánì bá fẹ́ fi ṣe wá lọ́ṣẹ́.
Àwọn Ẹ̀gún Tó Gún Mẹfibóṣẹ́tì Lára
9, 10. (a) Báwo ni Mẹfibóṣẹ́tì ṣe wá di ẹni tó ní ẹ̀gún nínú ara? (b) Ojú àánú wo ni Ọba Dáfídì fi hàn sí Mẹfibóṣẹ́tì, báwo sì ni a ṣe lè fara wé Dáfídì?
9 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Mẹfibóṣẹ́tì, ọmọ Jónátánì, ọ̀rẹ́ Dáfídì yẹ̀ wò. Ìgbà tí Mẹfibóṣẹ́tì jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún ni ìròyìn dé, pé Jónátánì bàbá rẹ̀ àti Sọ́ọ̀lù Ọba, bàbá rẹ̀ àgbà, ti kú. Ni jìnnìjìnnì bá bo ẹni tó ń tọ́jú ọmọ yìí. Ló bá “gbé e . . . , ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé bí obìnrin náà ti ń sá nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì láti sá lọ, nígbà náà ni ọmọkùnrin náà ṣubú, ó sì yarọ.” (2 Sámúẹ́lì 4:4) Yíyarọ tí Mẹfibóṣẹ́tì yarọ yìí kò ní ṣàìjẹ́ ẹ̀gún ńlá tí á máa dá a lóró bó ṣe ń dàgbà.
10 Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Dáfídì Ọba ṣe inú rere onífẹ̀ẹ́ sí Mẹfibóṣẹ́tì nítorí ìfẹ́ ńlá tí Dáfídì ní fún Jónátánì. Dáfídì ní kí wọ́n fún un ní gbogbo dúkìá Sọ́ọ̀lù, kí Síbà tó jẹ́ ẹmẹ̀wà rẹ̀ sì máa bójú tó ilẹ̀ yìí. Dáfídì tún sọ fún Mẹfibóṣẹ́tì pé: ‘Ìwọ yóò máa jẹ oúnjẹ ní tábìlì mi nígbà gbogbo.’ (2 Sámúẹ́lì 9:6-10) Ó dájú pé inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Dáfídì ṣe sí Mẹfibóṣẹ́tì á tù ú nínú, á sì pẹ̀rọ̀ sí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ abirùn. Ẹ̀kọ́ gidi mà lèyí o! Ó yẹ kí àwa náà máa ṣojú àánú sáwọn tí ẹ̀gún bá ń gún lára.
11. Kí ni Síbà sọ nípa Mẹfibóṣẹ́tì, ṣùgbọ́n báwo la ṣe mọ̀ pé irọ́ ló pa mọ́ ọn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Nígbà tó tún yá, ẹ̀gún mìíràn tún bẹ̀rẹ̀ sí gún Mẹfibóṣẹ́tì lára. Síbà ìránṣẹ́ rẹ̀ purọ́ mọ́ ọn níwájú Dáfídì Ọba, tó ń sá fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ nígbà yẹn, nítorí ọ̀tẹ̀ Ábúsálómù ọmọ rẹ̀. Síbà sọ pé Mẹfibóṣẹ́tì ti kẹ̀yìn sí Dáfídì. Ó ní ìyẹn ló jẹ́ kó jókòó pa sí Jerúsálẹ́mù, kí ó bàa lè gbàjọba.a Dáfídì gba irọ́ tí Síbà pa gbọ́. Ìyẹn ló jẹ́ kó pàṣẹ pé kí gbogbo dúkìá Mẹfibóṣẹ́tì di ti òpùrọ́ yẹn!—2 Sámúẹ́lì 16:1-4.
12. Ojú wo ni Mẹfibóṣẹ́tì fi wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, báwo ló sì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa?
12 Àmọ́ ṣá o, ìgbà tí Mẹfibóṣẹ́tì rí Dáfídì sójú níkẹyìn ló wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an fún ọba. Mẹfibóṣẹ́tì ń múra lọ́wọ́ láti wá bá Dáfídì ni Síbà tàn án, tó sọ fún un pé kó má ṣèyọnu, kó jẹ́ kóun kúkú lọ ṣojú fún un. Ǹjẹ́ Dáfídì yí ìpinnu tó ṣe tẹ́lẹ̀ padà? Kò yí i padà délẹ̀délẹ̀. Ńṣe ló wá ní kí àwọn méjèèjì jọ pín dúkìá náà. Ẹ̀gún mìíràn ló tún fẹ́ gún Mẹfibóṣẹ́tì lára yìí o. Ṣé ọ̀rọ̀ náà wá dùn ún ju bó ṣe yẹ lọ? Ṣé ó yarí pé òun ò gba ìpinnu tí Dáfídì ṣe, kó wá máa pariwo pé wọ́n yan òun jẹ? Rárá o. Ńṣe ló gba ohun tí ọba sọ láìjanpata. Ìròyìn ayọ̀ ló pe àfiyèsí sí ní tirẹ̀. Ó ní ayọ̀ tòun ni pé ẹni tí ipò ọba Ísírẹ́lì tọ́ sí padà dé láyọ̀. Ní ti tòótọ́, Mẹfibóṣẹ́tì fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú ọ̀ràn fífarada àìlera, ìfọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́ àti ìjákulẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 19:24-30.
Nehemáyà Fara Da Àwọn Àdánwò Tirẹ̀
13, 14. Àwọn ẹ̀gún wo ló di dandan kí Nehemáyà fara dà nígbà tó padà wálé láti wá tún odi Jerúsálẹ́mù mọ?
13 Ronú nípa àwọn ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ tí Nehemáyà fara dà nígbà tó padà sí ìlú Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ aláìlódi ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó rí i pé ìlú náà kò ní ohun ààbò kankan. Inú ìdàrúdàpọ̀ làwọn Júù tó padà dé láti oko ẹrú wà. Ìrẹ̀wẹ̀sì tún bá wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n jẹ́ aláìmọ́ lójú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Atasásítà Ọba fún Nehemáyà láṣẹ láti tún odi Jerúsálẹ́mù mọ, láìpẹ́ láìjìnnà ni Nehemáyà rí i pé inú àwọn gómìnà tó wà ládùúgbò náà ò dùn rárá sí iṣẹ́ tóun wá ṣe. “Ó dà bí ohun tí ó burú lójú wọn pé ọkùnrin kan wá láti wá ohun rere fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Nehemáyà 2:10.
14 Àwọn alátakò wọ̀nyẹn tó wà ládùúgbò wọn pa gbogbo itú ọwọ́ wọn láti rí i dájú pé àwọn dá iṣẹ́ Nehemáyà dúró. Gbogbo bí wọ́n ṣe ń dún mọ̀huru-mọ̀huru, tí wọ́n ń purọ́, tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ èké bà á jẹ́, àní tí wọ́n fẹ́ kó jìnnìjìnnì bá a—títí kan àwọn amí tí wọ́n rán wá láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a—ti ní láti dà bíi fífi ẹ̀gún gún un lára ṣáá. Ṣé ó wá jọ̀gọ̀ nù nítorí ètekéte àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn? Ká má rí i! Ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, láìjuwọ́sílẹ̀. Nítorí èyí, píparí tí wọ́n parí títún odi Jerúsálẹ́mù mọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jèhófà ti Nehemáyà lẹ́yìn gbágbáágbá.—Nehemáyà 4:1-12; 6:1-19.
15. Àwọn ìṣòro wo ló dìde láàárín àwọn Júù tó dun Nehemáyà gan-an?
15 Gẹ́gẹ́ bíi gómìnà, Nehemáyà tún fojú winá ọ̀pọ̀ ìṣòro láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìṣòro wọ̀nyí dà bí ẹ̀gún tí ń gún un lára burúkú-burúkú, torí pé ìṣòro wọ̀nyí kan àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn náà àti Jèhófà. Àwọn ọlọ́rọ̀ ń gba owó èlé gegere. Àwọn tálákà arákùnrin wọn sì ń fi ilẹ̀ wọn dúró, àní wọ́n ń ta àwọn ọmọ wọn pàápàá sóko ẹrú láti rówó san gbèsè àti láti san owó orí tí Páṣíà bù lé wọn. (Nehemáyà 5:1-10) Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń rú òfin Sábáàtì, wọn ò sì ṣètìlẹyìn fáwọn ọmọ Léfì àti tẹ́ńpìlì mọ́. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn kan ń fẹ́ “àwọn aya tí wọ́n jẹ́ ará Áṣídódì, ọmọ Ámónì àti ọmọ Móábù.” Ọ̀ràn náà mà dun Nehemáyà o! Ṣùgbọ́n kò tìtorí èyíkéyìí lára ẹ̀gún wọ̀nyí jáwọ́. Léraléra ló ṣara gírí, tó ń fi tìtara-tìtara gbé àwọn òfin òdodo Ọlọ́run lárugẹ. Gẹ́gẹ́ bíi Nehemáyà, ǹjẹ́ ká má ṣe jẹ́ kí ìwà àìṣòótọ́ àwọn ẹlòmíràn mú wa yẹsẹ̀ kúrò nínú fífi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà.—Nehemáyà 13:10-13, 23-27.
Ọ̀pọ̀ Àwọn Olóòótọ́ Mìíràn Fara Dà Á
16-18. Báwo ni wàhálà ìdílé ṣe kó hílàhílo bá Ísákì àti Rèbékà, Hánà, Dáfídì àti Hóséà?
16 Nínú Bíbélì, a tún rí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tó fara da àwọn ìṣòro tó dà bí ẹ̀gún. Ohun tó sábà máa ń fa irú ẹ̀gún bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro ìdílé. Àwọn ìyàwó Ísọ̀ méjèèjì “jẹ́ orísun ìkorò ẹ̀mí fún Ísákì àti Rèbékà,” ìyẹn àwọn òbí Ísọ̀. Rèbékà tiẹ̀ sọ pé ayé sú òun nítorí àwọn aya wọ̀nyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 26:34, 35; 27:46) Tún ronú nípa Hánà. Rántí bí Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ ṣe ń “mú un bínú gidigidi,” torí pé Hánà yàgàn. Ó kúkú lè jẹ́ ìgbà gbogbo ni obìnrin yìí ń fi ọ̀rọ̀ gún Hánà lára nínú ilé. Pẹ̀nínà tún máa ń fòòró rẹ̀ níṣojú àwọn èèyàn—pàápàá níṣojú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́—nígbà tí ìdílé wọ́n bá lọ ṣe àjọ̀dún ní Ṣílò. Èyí dà bí títúbọ̀ ti ẹ̀gún náà wọnú ara Hánà.—1 Sámúẹ́lì 1:4-7.
17 Ronú nípa ohun tí Dáfídì fara da nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba, tó jẹ́ àna Dáfídì ń jowú rẹ̀ burúkú-burúkú. Kí ẹ̀mí Dáfídì má bàa lọ sí i, ńṣe ló lọ ń gbénú ihò àpáta ní aginjù Ẹ́ń-gédì, níbi tó ti ní láti gòkè lọ sí àwọn ibi eléwu ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àárín àwọn òkè ńlá. Ìwà ìrẹ́nijẹ náà ní láti bà á nínú jẹ́ gan-an ni, nítorí kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ Sọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún ni Dáfídì fi ń sá kìjokìjo kiri—torí pé Sọ́ọ̀lù ń jowú rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 24:14, 15; Òwe 27:4.
18 Fojú inú wo wàhálà ìdílé, èyí tó kó hílàhílo bá wòlíì Hóséà. Ìyàwó rẹ̀ di panṣágà. Ìṣekúṣe tó ń ṣe kiri kò ní ṣàì dà bí ẹ̀gún tó gún Hóséà wọnú ọkàn. Ẹ sì wo bí ọkàn rẹ̀ ṣe tún máa gbọgbẹ́ tó nígbà tóbìnrin yìí bí ọmọ àlè méjì nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀!—Hóséà 1:2-9.
19. Inúnibíni wo ni wọ́n ṣe sí Mikáyà wòlíì?
19 Ẹ̀gún mìíràn tí ń gúnni nínú ẹran ara ni inúnibíni. Gbé ìrírí Mikáyà wòlíì yẹ̀ wò. Rírí tí Mikáyà rí àwọn wòlíì èké tí Áhábù Ọba burúkú yẹn kó sòdí, tí Áhábù tún gba irọ́ gbuu tí wọ́n ń pa gbọ́, kò ní ṣàì dá ọkàn òdodo rẹ̀ lóró. Nígbà tí Mikáyà tún sọ fún Áhábù pé “ẹ̀mí ìtannijẹ” ló wà lẹ́nu gbogbo wòlíì wọ̀nyẹn, kí ni aṣáájú àwọn ẹlẹ́tàn yẹn ṣe? Họ́wù, ńṣe ló “gbá Mikáyà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́”! Kékeré tiẹ̀ tún nìyẹn jẹ́, lójú ohun tí Áhábù ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà ti kìlọ̀ pé òtúbáńtẹ́ ni gbogbo akitiyan wọn láti gba Ramoti-gílíádì. Áhábù pàṣẹ pé kí wọ́n sọ Mikáyà sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì febi pa á dáadáa. (1 Àwọn Ọba 22:6, 9, 15-17, 23-28) Tún rántí Jeremáyà àti ohun tí àwọn ìkà tó ṣe inúnibíni sí i fojú rẹ̀ rí.—Jeremáyà 20:1-9.
20. Àwọn ẹ̀gún wo ni Náómì fara dà, báwo la sì ṣe san án lẹ́san?
20 Ikú olólùfẹ́ ẹni tún jẹ́ nǹkan míì tó ń fa àròdùn, tó lè dà bí ẹ̀gún nínú ẹran ara. Náómì fara da àròdùn tó dé bá a nítorí ikú ọkọ rẹ̀ àti ikú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Inú ọ̀fọ̀ yẹn ló ṣì wà nígbà tó padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ó ní kí àwọn ọ̀rẹ́ òun má pe òun ní Náómì mọ́, bí kò ṣe Márà, ìyẹn orúkọ tó sọ ara rẹ̀ nítorí bí ọkàn rẹ̀ ṣe gbọgbẹ́ tó. Àmọ́ níkẹyìn, Jèhófà san án lẹ́san ìfaradà rẹ̀ nígbà tá a bí ọmọ-ọmọ kan fún un, tó mú kí Mèsáyà náà wá láti ìlà ìdílé rẹ̀.—Rúùtù 1:3-5, 19-21; 4:13-17; Mátíù 1:1, 5.
21, 22. Kí ni onírúurú àdánù tó dé bá Jóòbù, ojú wo ló sì fi wò ó?
21 Tún ronú nípa bí ọkàn Jóòbù á ti gbọgbẹ́ tó nígbà tó gbọ́ pé àwọn ọmọ òun ọ̀wọ́n mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti kú ikú gbígbóná, ikú oró. Ká má tiẹ̀ sọ ti gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó pàdánù. Áà, rẹ́rẹ́ rún! Ẹnu yánpọnyánrin yìí ni Jóòbù ṣì wà, nígbà tí Sátánì tún bẹ̀rẹ̀ sí fi àrùn bá a jà. Ó ṣeé ṣe kí Jóòbù ti máa ronú pé kò sí bí òun ṣe máa bọ́ nínú àrùn burúkú yìí. Ìrora ọ̀hún pọ̀ débi pé ó wá gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín.—Jóòbù 1:13-20; 2:7, 8.
22 Bí ìgbà tí ìyà ńlá bá gbéni ṣánlẹ̀ tí kéékèèké tún wá gorí ẹ̀ lọ̀ràn ọ̀hún rí nígbà tí aya rẹ̀ tí ẹ̀dùn ọkàn àti làásìgbò bá, wá bá a, tó sì kígbe pé: “Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” Ẹ ò rí i pé ẹ̀gún ríroni lára gógó lèyí jẹ́ nínú ẹran ara tó ti kún fún ìrora tẹ́lẹ̀! Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kóra wọn dé. Kàkà kí wọ́n tù ú nínú, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wé ẹ̀sùn èké mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, tí wọ́n ń sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó ń yọ́ dá ló fa gbogbo àjálù tó dé bá a. Ńṣe ni èrò òdì wọ̀nyí jẹ́ kí àwọn ẹ̀gún náà túbọ̀ wọlé sí Jóòbù lára. Tún rántí pé Jóòbù kò mọ ìdí tí gbogbo nǹkan burúkú wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sóun; bẹ́ẹ̀ náà ni kò mọ̀ pé a máa dá ẹ̀mí òun sí. Síbẹ̀síbẹ̀, “nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.” (Jóòbù 1:22; 2:9, 10; 3:3; 14:13; 30:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀gún ń gún un lára láàárín àkókò kan náà, kò yéé tọ ipa ọ̀nà ìwà títọ́. Èyí mà múni lọ́kàn le o!
23. Èé ṣe tí àwọn olóòótọ́ tá a jíròrò nípa wọn fi lè fara da onírúurú ẹ̀gún tó wà nínú ara wọn?
23 Díẹ̀ kín-ún làpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tá a lè tọ́ka sí. Àwọn àpẹẹrẹ ṣì pọ̀ lọ jàra nínú Bíbélì. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyí fàyà rán àwọn ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ tó ń gún wọn lára. Mélòó la sì fẹ́ kà lára ọkàn-kò-jọ̀kan ìṣòro tí wọ́n dojú kọ! Síbẹ̀, ìpinnu wọ́n bára mu. Kò sí ìkankan lára wọn tó ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Láìfi gbogbo àdánwò lílekoko tó dé bá wọn pè, wọ́n borí Sátánì nípasẹ̀ okun tí Jèhófà fún wọn. Lọ́nà wo? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn ìbéèrè yìí, yóò sì jẹ́ ká mọ bí àwa náà ṣe lè fara da ohunkóhun tó bá dà bí ẹ̀gún nínú ẹran ara wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn, tó moore ni Mẹfibóṣẹ́tì jẹ́. Kì í ṣe ẹ̀dá tó lè hu irú ìwà màkàrúrù bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé ó mọ ìwà ìṣòtítọ́ tí Jónátánì, bàbá rẹ̀ hù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba ni Jónátánì jẹ́, síbẹ̀ ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé Dáfídì ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 20:12-17) Gẹ́gẹ́ bí bàbá tó bẹ̀rù Ọlọ́run, Jónátánì bàbá Mẹfibóṣẹ́tì, tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dúró ti Dáfídì gbágbáágbá, kò ní kọ́ ọmọ rẹ̀ pé kí ó dìtẹ̀ gbàjọba.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tá a fi lè fi àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ wé ẹ̀gún nínú ẹran ara?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀gún tí Mẹfibóṣẹ́tì àti Nehemáyà fara dà?
• Lára àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí Ìwé Mímọ́ fi hàn pé wọ́n fara da onírúurú ẹ̀gún nínú ẹran ara, èwo lára wọn ló wú ọ lórí jù lọ, èé sì ti ṣe?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Mẹfibóṣẹ́tì fara da àìlera, ìfọ̀rọ̀-èké-báni-jẹ́ àti ìjákulẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nehemáyà forí ti àtakò