ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w22 March ojú ìwé 13
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Àjèjì Ni Ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jónátánì Nígboyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Wọ́n Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • ‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
w22 March ojú ìwé 13

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí 2 Sámúẹ́lì 21:7-9 fi sọ pé Dáfídì “ṣàánú Méfíbóṣétì” síbẹ̀ tí Dáfídì tún ní kí wọ́n pa Méfíbóṣétì?

Àwọn kan tó ka ìtàn Bíbélì yẹn máa ń béèrè ìbéèrè yìí. Àmọ́ nínú ìtàn yẹn, ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ Méfíbóṣétì, a sì máa jàǹfààní gan-an tá a bá fara balẹ̀ ronú nípa ìtàn yẹn.

Ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin méjì ni Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì bí. Jónátánì ni ọmọkùnrin tí Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bí. Àmọ́ nígbà tó yá, àlè Ọba Sọ́ọ̀lù kan tó ń jẹ́ Rísípà bí ọmọkùnrin kan fún un, Méfíbóṣétì sì lorúkọ ẹ̀. Bíbélì tún sọ pé Jónátánì náà bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Méfíbóṣétì. Torí náà, Ọba Sọ́ọ̀lù ní ọmọkùnrin kan àti ọmọ ọmọ kan tórúkọ àwọn méjèèjì ń jẹ́ Méfíbóṣétì.

Ìgbà kan wà tí Ọba Sọ́ọ̀lù kórìíra àwọn ará Gíbíónì tó ń gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì gbìyànjú láti pa gbogbo wọn run. Ẹ̀rí fi hàn pé ó pa ọ̀pọ̀ lára wọn. Ohun tó ṣe yẹn burú gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà ayé Jóṣúà, àwọn ìjòyè láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá àwọn ará Gíbíónì dá májẹ̀mú àlàáfíà.—Jóṣ. 9:3-27.

Májẹ̀mú yẹn ò tíì kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba Ísírẹ́lì. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ṣe ohun tó lòdì sí májẹ̀mú yẹn nígbà tó fẹ́ pa àwọn ará Gíbíónì run pátápátá. Ohun tó ṣe yìí mú kí “ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà lórí Sọ́ọ̀lù àti lórí ilé rẹ̀.” (2 Sám. 21:1) Nígbà tó yá, Dáfídì di ọba. Àwọn tí Sọ́ọ̀lù ò rí pa lára àwọn ará Gíbíónì wá ròyìn fún Dáfídì nípa ìwà burúkú tí Sọ́ọ̀lù hù sí wọn. Dáfídì wá bi wọ́n pé kí ni wọ́n fẹ́ kóun ṣe fún wọn kí Jèhófà lè bù kún ilẹ̀ náà. Kí ọ̀rọ̀ náà lè tán nínú wọn, wọn ò béèrè owó. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kí Dáfídì fún àwọn ní méje lára àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù káwọn lè pa wọ́n, torí pé Sọ́ọ̀lù ló “gbìmọ̀ láti pa [àwọn] rẹ́.” (Nọ́ń. 35:30, 31) Dáfídì náà sì ṣe ohun tí wọ́n béèrè.—2 Sám. 21:2-6.

Lásìkò yẹn, Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú sójú ogun, àmọ́ Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì ṣì wà láyé. Nǹkan kan ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé tó jẹ́ kí ẹsẹ̀ ẹ̀ rọ, ó sì dájú pé kò lọ́wọ́ sí bí bàba bàbá ẹ̀ ṣe gbógun ti àwọn ará Gíbíónì. Dáfídì ti bá Jónátánì ọ̀rẹ́ ẹ̀ dá májẹ̀mú, àwọn ọmọ Jónátánì títí kan Méfíbóṣétì sì máa jàǹfààní nínú májẹ̀mú yẹn. (1 Sám. 18:1; 20:42) Ìtàn yẹn sọ pé: “Ọba [Dáfídì] ṣàánú Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nítorí ìbúra tó wáyé níwájú Jèhófà.”—2 Sám. 21:7.

Síbẹ̀, Dáfídì ṣe ohun táwọn ará Gíbíónì fẹ́. Ó fún wọn ní méjì lára àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù tí ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Méfíbóṣétì àti àwọn ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù márùn-ún. (2 Sám. 21:8, 9) Ohun tí Dáfídì ṣe yìí ló mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ náà.

Lónìí, àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Òfin Ọlọ́run ṣe kedere, ó ní: “Ẹ má . . .  pa àwọn ọmọ torí ohun tí àwọn bàbá wọn ṣe.” (Diu. 24:16) Ó dájú pé Jèhófà ò bá má fọwọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù méjì àtàwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ márùn-ún ká sọ pé wọn ò mọwọ́ mẹsẹ̀ sóhun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Òfin yẹn tún sọ pé: “Kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ó jọ pé àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù méje tó kú yìí náà lọ́wọ́ sí bí Sọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ pa àwọn ará Gíbíónì run. Torí náà, ikú yẹn tọ́ sí wọn.

Ìtàn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan ò lè máa hùwà burúkú, kó wá sọ pé òun ò mọwọ́ mẹsẹ̀ torí pé ohun tí wọ́n ní kóun ṣe lòun ń ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi òwe Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Mú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ ń gbà jọ̀lọ̀, gbogbo ọ̀nà rẹ á sì lójú.”—Òwe 4:24-27; Éfé. 5:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́