Ẹ̀KỌ́ 42
Jónátánì Nígboyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini
Jónátánì lorúkọ ọmọkùnrin tí Ọba Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bí. Jagunjagun tó lákíkanjú ni, kì í bẹ̀rù. Dáfídì tiẹ̀ sọ pé Jónátánì yára ju ẹyẹ idì lọ, ó sì lágbára ju kìnnìún lọ. Lọ́jọ́ kan, Jónátánì ráwọn ọmọ ogun Filísínì tí wọ́n tó ogún (20) lórí òkè kan. Ó wá sọ fún ẹni tó máa ń ràn án lọ́wọ́ pé: ‘Tí Jèhófà bá fún wa ní àmì nìkan la máa lọ bá wọn jà. Táwọn ọmọ ogun yẹn bá sọ pé ká máa bọ̀, a máa lọ bá wọn jà.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Àwọn ọmọ ogun Filísínì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa gòkè bọ̀, ká jọ jà!’ Bí Jónátánì àti ìkejì ẹ̀ ṣe lọ bá wọn nìyẹn, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun náà.
Torí pé Jónátánì ni àkọ́bí lára àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, òun ló yẹ kó jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n Jónátánì mọ̀ pé Jèhófà ti yan Dáfídì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, kò sì bínú sí i. Ńṣe lòun àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àwọn méjèèjì ṣèlérí pé àwọn á máa ti ara wọn lẹ́yìn, àwọn ò sì ní fi ara wọn sílẹ̀. Jónátánì wá bọ́ ẹ̀wù ẹ̀ ó sì fún Dáfídì, ó tún fún un ní idà, ọrun àti bẹ́líìtì ẹ̀ kí Dáfídì lè mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.
Nígbà tí Dáfídì sá lọ torí Sọ́ọ̀lù, Jónátánì lọ bá Dáfídì níbi tó wà, ó sì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù, ṣó o gbọ́? Ìwọ ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba. Bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.’ Ṣé ìwọ náà fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tó dà bíi Jónátánì?
Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jónátánì fi ẹ̀mí ara ẹ̀ wewu torí Dáfídì. Ó mọ̀ pé bàbá òun fẹ́ pa Dáfídì, ó wá sọ fún bàbá ẹ̀ pé: ‘Inú Ọlọ́run ò ní dùn tẹ́ ẹ bá pa Dáfídì; kò hùwà burúkú kankan.’ Ṣé Sọ́ọ̀lù wá gbọ́rọ̀ sí ọmọ ẹ̀ lẹ́nu? Rárá o, ṣe ló bínú gan-an sí Jónátánì. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì kú sójú ogun lọ́jọ́ kan náà.
Lẹ́yìn tí Jónátánì kú, Dáfídì lọ wá ọmọ Jónátánì tó ń jẹ́ Méfíbóṣétì. Nígbà tí Dáfídì rí Méfíbóṣétì, ó sọ fún un pé: ‘Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni èmi àti bàbá rẹ, torí náà màá tọ́jú ẹ. Wàá máa gbé nínú ààfin mi, wàá sì máa jẹun lọ́dọ̀ mi.’ Ó dájú pé Dáfídì ò gbàgbé Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀.
“Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:12, 13