Ẹ̀KỌ́ 43
Ọba Dáfídì Dẹ́ṣẹ̀
Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kú, Dáfídì di ọba. Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni nígbà yẹn. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan tó di ọba, ohun kan ṣẹlẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ó wà lórí òkè ààfin ẹ̀, ó sì rí obìnrin kan tó rẹwà. Dáfídì wádìí nípa obìnrin yẹn, wọ́n sì sọ fún un pé Bátí-ṣébà lorúkọ ẹ̀ àti pé ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Ùráyà lọkọ ẹ̀. Dáfídì ní kí wọ́n bá òun pe Bátí-ṣébà wá. Dáfídì bá obìnrin náà sùn, obìnrin náà sì lóyún. Torí pé Dáfídì ò fẹ́ kí àṣírí òun tú, ó sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n fi Ùráyà síwájú ogun, kí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn ẹ̀. Bó ṣe di pé Ùráyà kú sójú ogun nìyẹn, Dáfídì sì fi Bátí-ṣébà ṣe aya.
Àmọ́ Jèhófà rí gbogbo ìwà búburú tí Dáfídì hù. Kí wá ni Jèhófà ṣe? Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Dáfídì. Nátánì sọ fún Dáfídì pé: ‘Ọkùnrin olówó kan ní àgùntàn tó pọ̀ gan-an, tálákà kan sì ní ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo, ó sì máa ń tọ́jú ẹ̀ gan-an. Àmọ́, ṣe ni olówó yẹn gba ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo tí tálákà náà ní.’ Nígbà tí Dáfídì gbọ́, inú bí i, ó sì sọ pé: ‘Ṣe ló yẹ ká pa ọkùnrin olówó yẹn!’ Nátánì wá sọ fún Dáfídì pé: ‘Ìwọ gan-an ni ọkùnrin yẹn!’ Inú Dáfídì bà jẹ́, ó sì jẹ́wọ́ fún Nátánì pé: ‘Mo ti ṣẹ Jèhófà.’ Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá yẹn mú wàhálà bá òun àtàwọn ará ilé ẹ̀. Jèhófà fìyà jẹ Dáfídì, àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kó kú torí pé Dáfídì jẹ́ olóòótọ́, ó sì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀.
Ó wu Dáfídì láti kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà, àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ni Jèhófà yàn pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì fóun. Síbẹ̀, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn nǹkan jọ fún Sólómọ́nì. Dáfídì wá sọ pé: ‘Tẹ́ńpìlì Jèhófà máa tóbi, ó sì máa lẹ́wà gan-an. Àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ mi ṣì kéré, torí náà mo ti kó àwọn nǹkan tó máa lò sílẹ̀ fún un.’ Dáfídì kó owó rẹpẹtẹ sílẹ̀ kí wọ́n lè fi kọ́ ilé náà. Ó wá àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ dáadáa. Ó kó àwọn nǹkan míì jọ, bíi wúrà àti fàdákà, ó sì kó àwọn igi kédárì wá láti ìlú Tírè àti Sídónì. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáfídì kú, ó fún Sólómọ́nì ní ìwé tí wọ́n ya àwòrán tẹ́ńpìlì náà sí. Ó wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ló ní kí n ya àwòrán yìí sílẹ̀ fún ẹ. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má bẹ̀rù, ṣe bí ọkùnrin, kó o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà.’
“Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.”—Òwe 28:13