Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Yí Padà
“Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà.”—2 TÍMOTÌ 2:15.
1. Àwọn ìyípadà wo ló ń fa ìdánwò bá ìlera wa nípa tẹ̀mí?
ŃṢE ni ayé tó yí wa ká ń yí padà ṣáá. Bá a ti ń rí àwọn ìtẹ̀síwájú kíkàmàmà nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ là ń rí i tí ìwà ọmọlúwàbí ń pòórá láwùjọ. Gẹ́gẹ́ bí a ti gbé e yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ kọ ẹ̀mí ìṣòdìsí Ọlọ́run ti ayé yìí. Àmọ́, bí ayé ti ń yí padà, bẹ́ẹ̀ náà làwa pẹ̀lú ṣe ń yí padà lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. À ń kúrò lọ́mọdé à ń di àgbàlagbà. A lè di ọlọ́rọ̀ tàbí ká pàdánù ọrọ̀, ìlera wa tàbí àwọn èèyàn wa. Púpọ̀ nínú àwọn ìyípadà wọ̀nyí la ò lè ṣe ohunkóhun sí, wọ́n sì lè fa àwọn ìdánwò tuntun tó ga bá ìlera wa nípa tẹ̀mí.
2. Àwọn ìyípadà lóríṣiríṣi wo ló ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Dáfídì?
2 Àwọn èèyàn tó rí irú ìyípadà ńláǹlà tí Dáfídì ọmọ Jésè rí nígbèésí ayé kò tó nǹkan. Kíá, Dáfídì ti kúrò lẹ́ni tẹ́nì kankan ò mọ̀, ìyẹn ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn, ó dẹni tó lókìkí jákèjádò orílẹ̀-èdè. Ẹ̀yìn ìyẹn ló di ìsáǹsá tí òjòwú ọba kan ń dọdẹ rẹ̀ kiri bí ẹran. Lẹ́yìn náà, Dáfídì di ọba àti ajagunṣẹ́gun. Ó fara da àwọn àbájáde kíkorò tí ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì máa ń fà. Nǹkan ìbànújẹ́ ṣẹlẹ̀ sí i, bákan náà ni ìpínyà bá ìdílé rẹ̀. Ó di ọlọ́rọ̀, ó darúgbó, ó sì ní àwọn àìlera tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Àmọ́ láìka ọ̀pọ̀ ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Dáfídì sí, ó gbọ́kàn lé Jèhófà àti ẹ̀mí Rẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì fọkàn tán an. Ó ṣe gbogbo ohun tó wà lágbára rẹ̀ láti fi ara rẹ̀ hàn “fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà,” Ọlọ́run sì bù kún un. (2 Tímótì 2:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò wa yàtọ̀ sí ti Dáfídì, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tó gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè máa bá a lọ láti rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run gbà bá a ti ń dojú kọ ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa.
Àpẹẹrẹ Rere Ni Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Dáfídì Jẹ́
3, 4. Báwo ni Dáfídì ṣe kúrò lẹ́ni tẹ́nì kankan ò mọ̀, ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn, tó di gbajúmọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ̀?
3 Nígbà tí Dáfídì wà lọ́mọdé, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kà á sí rárá, kódà nínú ìdílé tirẹ̀ pàápàá. Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, bàbá Dáfídì fi méje lára ọmọkùnrin mẹ́jọ tó ní hàn án. Wọ́n fi Dáfídì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn sílẹ̀ láti máa ṣọ́ àwọn àgùntàn. Síbẹ̀, Dáfídì ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la ní Ísírẹ́lì. Wọ́n pe Dáfídì wá látinú pápá. Lẹ́yìn èyí, àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì fòróró yàn án láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.” (1 Sámúẹ́lì 16:12, 13) Ẹ̀mí yìí ni Dáfídì gbára lé jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.
4 Láìpẹ́, ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn yìí máa wá di ẹni tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó dẹni tá a ké sí láti wá máa ṣèránṣẹ́ fún ọba kó sì máa fi orin dá ọba lára yá. Ó pa Gòláyátì tó jẹ́ òmíràn àti jagunjagun tó rorò débi pé, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tó mọṣẹ́ dunjú gan-an ń bẹ̀rù láti kò ó lójú. Wọ́n sọ Dáfídì di olórí ogun, ó sì rẹ́yìn àwọn Filísínì pátápátá. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Wọ́n ṣe orin fún un tí wọ́n fi ń gbé e lárugẹ. Ṣáájú àkókò yìí, bọ́bajíròrò kan ti sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé kì í ṣe pé ọ̀dọ́kùnrin náà Dáfídì jẹ́ “ọ̀jáfáfá nínú títa háàpù” nìkan ni, àmọ́ ó tún “jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin àti ọkùnrin ogun àti olùbánisọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ onílàákàyè àti ọkùnrin tí ó dára délẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 16:18; 17:23, 24, 45-51; 18:5-7.
5. Kí làwọn ohun tó ti lè mú kí Dáfídì di onígbèéraga èèyàn, báwo la sì ṣe mọ̀ pé kò di irú èèyàn bẹ́ẹ̀?
5 Ò dà bíi pé kò sóhun tí ẹ̀dá ń wá tí Dáfídì ò ní, ì báà jẹ́ òkìkí, ẹwà, jíjẹ́ ọ̀dọ́, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá, mímọ orin kọ, jíjẹ́ akọni ológun tàbí rírí ojú rere Ọlọ́run. Èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí sì ti lè sọ ọ́ di onígbèéraga èèyàn, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbọ́ ohun tí Dáfídì fi dá Sọ́ọ̀lù Ọba lóhùn nígbà tó ní kó wá fi ọmọbìnrin òun ṣaya. Pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ńláǹlà, Dáfídì sọ pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn ẹbí mi, ìdílé baba mi, ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò fi di ọkọ ọmọ ọba?” (1 Sámúẹ́lì 18:18) Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ń ṣe àlàyé lórí ẹsẹ yìí, ó kọ̀wé pé: “Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé, yálà àwọn àṣeyọrí tóun ti ṣe ni o tàbí irú ẹni tóun jẹ́ láwùjọ ni o, tàbí ìran òun ni o, kò sí èyí tó tó láti mú òun tọ́ sí iyì jíjẹ́ àna ọba.”
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
6 Ohun tó mú Dáfídì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni mímọ̀ tó mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣẹgbẹ́ ẹ̀dá èèyàn aláìpé lọ́nàkọnà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún Dáfídì pé Ọlọ́run tiẹ̀ ka èèyàn sí. (Sáàmù 144:3) Dáfídì tún mọ̀ pé èèyàn ńlá yòówù tí òun ì báà dà, ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà fi hàn ni, ní ti pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti mẹ́sẹ̀ òun dúró, láti dáàbò bo òun àti láti ṣètọ́jú òun. (Sáàmù 18:35) Ẹ̀kọ́ gidi lèyí mà jẹ́ fún wa o! A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ẹ̀bùn àbínibí wa, àwọn àṣeyọrí wa àtàwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní sọ wá di onígbèéraga èèyàn láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ni ìwọ ní tí kì í ṣe pé ìwọ gbà? Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé gbígbà ni ìwọ gbà á ní tòótọ́, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣògo bí ẹni pé ìwọ kò gbà á?” (1 Kọ́ríńtì 4:7) Tá a bá fẹ́ láti ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ká sì rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ká má sì yí ìwà náà padà.—Jákọ́bù 4:6.
“Ẹ Má Ṣe Gbẹ̀san Ara Yín”
7. Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fún Dáfídì láti pa Sọ́ọ̀lù Ọba?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òkìkí tí Dáfídì ní kò mú un gbéra ga, Sọ́ọ̀lù Ọba tí ẹ̀mí Ọlọ́run ti fi sílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀ débi pé ó fẹ́ pa á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì kò ṣe àìdáa kankan, ó ní láti sá lọ nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ó sì dẹni tó ń gbénú aginjù. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé, níbi tí Sọ́ọ̀lù Ọba ti ń wá Dáfídì kiri lójú méjèèjì, ó wọnú hòrò kan, láìmọ̀ pé Dáfídì àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sá pa mọ́ síbẹ̀. Àwọn èèyàn Dáfídì sọ fún un pé kó lo àǹfààní tó dá bíi pé Ọlọ́run fún un yìí láti pa Sọ́ọ̀lù. A lè fọkàn yàwòrán wọn nínú òkùnkùn, tí wọ́n ń fohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sọ fún Dáfídì pé: “Ọjọ́ náà nìyí tí Jèhófà sọ fún ọ ní tòótọ́ pé, ‘Wò ó! Èmi yóò fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o sì ṣe sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti dára ní ojú rẹ.’”—1 Sámúẹ́lì 24:2-6.
8. Kí ló mú kí Dáfídì kó ara rẹ̀ níjàánu tí kò sì gbẹ̀san fúnra rẹ̀?
8 Dáfídì kọ̀ láti ṣe Sọ́ọ̀lù níbi. Ìgbàgbọ́ àti sùúrù tó ní jẹ́ kó fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ fún Jèhófà. Lẹ́yìn tí ọba náà jáde kúrò nínú hòrò náà, Dáfídì pè é látòkèèrè, ó sì sọ fún un pé: “Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ; kí Jèhófà sì gbẹ̀san fún mi lára rẹ, ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò wá sára rẹ.” (1 Sámúẹ́lì 24:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù ń ṣe àìdáa sóun, kò fúnra rẹ̀ gbẹ̀san; bẹ́ẹ̀ ni kò sọ̀rọ̀ burúkú sí Sọ́ọ̀lù tàbí nípa Sọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ ìgbà mìíràn ni Dáfídì kó ara rẹ̀ níjàánu, kò fúnra rẹ̀ gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀ Jèhófà ló gbára lé láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà.—1 Sámúẹ́lì 25:32-34; 26:10, 11.
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbẹ̀san bí wọ́n bá ń ṣàtakò tàbí inúnibíni sí wa?
9 Bíi ti Dáfídì, o lè bá ara rẹ nínú àwọn ipò tí kò bára dé. Àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ tàbí àwọn mìíràn tẹ́ ò jọ ṣẹ̀sìn kan náà lè máa ṣàtakò sí ọ tàbí kí wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ọ. Má ṣe gbẹ̀san lára wọn. Dúró de Jèhófà, kó o máa bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí ìwà rere rẹ wú àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyí lórí kí wọ́n sì di onígbàgbọ́. (1 Pétérù 3:1) Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà ń rí ipò rẹ yóò sì ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ nígbà tí àsìkò bá tó lójú rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:19.
“Fetí sí Ìbáwí”
10. Báwo ni Dáfídì ṣe ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, báwo ló sì ṣe gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀?
10 Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá. Dáfídì di ọba táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ gidigidi ó sì gbajúmọ̀ nílé lóko. Ìgbésí ayé rẹ̀ tó fi ìdúróṣinṣin àrà ọ̀tọ̀ hàn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn sáàmù alárinrin tó kọ láti fi yin Jèhófà, ti lè mú kéèyàn ronú láìṣiyèméjì pé ẹni tí kò lè ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ láéláé ni. Àmọ́ ó ṣubú o. Lọ́jọ́ kan, láti orí òrùlé rẹ̀, ọba rí obìnrin arẹwà kan tó ń wẹ̀. Ló bá wádìí ẹni tó jẹ́. Nígbà tí Dáfídì mọ̀ pé Bátí-ṣébà lobìnrin náà àti pé ọkọ̀ rẹ̀ Ùráyà kò sí nílé, pé ó ti lọ sógun, ó ránṣẹ́ sí i ó sì bá a lò pọ̀. Lẹ́yìn náà, ó rí i pé obìnrin náà lóyún. Ẹ̀sín ńlá mà rèé bí ọ̀rọ̀ náà bá lọ tú síta! Lábẹ́ Òfin Mósè, ẹ̀ṣẹ̀ tó la ikú lọ ni ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà. Ó dájú pé ohun tí ọba rò ni pé òun lè bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀ ó ránṣẹ́ sáwọn ọmọ ogun, ó sì pàṣẹ pé kí Ùráyà padà wá sí Jerúsálẹ́mù. Ìrètí Dáfídì ni pé Ùráyà yóò lọ sùn ti Bátí-ṣébà lálẹ́ ọjọ́ náà, àmọ́ irọ́, ìyẹn ò ṣẹlẹ̀. Jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé Dáfídì lọ́wọ́ wàyí, ló bá dá Ùráyà padà sójú ogun ó sì fún un ní lẹ́tà kan láti fún Jóábù tó jẹ́ olórí ogun. Lẹ́tà náà sọ pé kí wọ́n fi Ùráyà sápá ibi tí yóò ti bógun lọ. Jóábù ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì pa Ùráyà. Lẹ́yìn tí Bátí-ṣébà parí sáà ìṣọ̀fọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà, Dáfídì mú un ó sì fi ṣaya.—2 Sámúẹ́lì 11:1-27.
11. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Nátánì sọ fún Dáfídì, kí sì ní Dáfídì ṣe?
11 Lójú Dáfídì, ọgbọ́n tó ta ṣiṣẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kó mọ̀ pé kedere báyìí ni gbogbo ọ̀ràn náà hàn sí Jèhófà. (Hébérù 4:13) Oṣù gorí oṣù, wọ́n sì bí ọmọ náà. Ìgbà yìí ni Ọlọ́run rán Nátánì wòlíì sí Dáfídì. Wòlíì yìí sọ fún ọba nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àmọ́ tó lọ mú àgùntàn kan ṣoṣo tó jẹ́ ti ọkùnrin aláìní kan èyí tí ọkùnrin náà fẹ́ràn gidigidi ó sì pa á. Bí Dáfídì ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fẹ́ láti rí i pé wọ́n ṣe ìdájọ́ tó yẹ, kò fura rárá pé ó nítumọ̀ kan tó fara sin. Kíá, Dáfídì ti ṣèdájọ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà. Ó fìbínú sọ fún Nátánì pé: “Ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!”—2 Sámúẹ́lì 12:1-6.
12. Ìdájọ́ wo ni Jèhófà ṣe fún Dáfídì?
12 Wòlíì náà wá dáhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!” Dáfídì ti ṣèdájọ́ ara rẹ̀. Kò sí àní-àní pé kíá ni inú Dáfídì tó ń ru náà yí padà di ìtìjú ńlá àti ìbànújẹ́ kíkorò. Ìdààmú bá Dáfídì bó ṣe ń gbọ́ bí Nátánì ṣe ń sọ ìdájọ́ Jèhófà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Kò sí ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan nínú rẹ̀. Dáfídì ti ṣàìka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, ó ṣe ohun tó burú. Ǹjẹ́ kò ti fi idà ọ̀tá pa Ùráyà? Ìdá ò ní kúrò nínú ilé Dáfídì náà. Ǹjẹ́ kò ti gba ìyàwó Ùráyà ní kọ̀rọ̀? Irú aburú bẹ́ẹ̀ yóò bá òun náà, àmọ́ tiẹ̀ kò wá ní jẹ́ ní kọ̀rọ̀ o, gbangba ni.—2 Sámúẹ́lì 12:7-12.
13. Kí ni ìṣesí Dáfídì nígbà tí Jèhófà bá a wí?
13 Dáfídì ṣe ohun kan tó dára, kò sẹ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ náà. Kò fìbínú jágbe mọ́ Nátánì. Kò di ẹ̀bi ru ẹlòmíràn tàbí kó máa wá àwáwí fún ohun tó ṣe. Nígbà tí wọ́n sọ ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fún un, ó gbà ó sì sọ pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 12:13) Sáàmù kọkànléláàádọ́ta fi hàn bí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá náà ṣe kó ìdààmú bá a tó àti bí ìrònúpìwàdà rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ó bẹ Jèhófà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ; ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.” Ó gbà gbọ́ pé Jèhófà, nínú àánú rẹ̀, kò ní fojú tẹ́ńbẹ́lú “ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀.” (Sáàmù 51:11, 17) Dáfídì ń bá a nìṣó ní gbígbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò gba Dáfídì kúrò lọ́wọ́ àwọn àbájáde kíkorò tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fà, ó darí jì í.
14. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣé nígbà tí Jèhófà bá bá wa wí?
14 Aláìpé ni gbogbo wa, gbogbo wa la sì ń ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Nígbà míì, a lè ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì bíi ti Dáfídì. Gẹ́gẹ́ bí bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń tọ́ àwọn tó fẹ́ láti sìn ín sọ́nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí máa ń ṣàǹfààní, síbẹ̀ kò rọrùn láti gbà. Àní, nígbà míì ó máa ń kó “ẹ̀dùn-ọkàn-báni.” (Hébérù 12:6, 11) Àmọ́ bá a bá “fetí sí ìbáwí,” àwa àti Jèhófà lè rẹ́ padà. (Òwe 8:33) Láti lè máa bá a lọ láti gbádùn ìbùkún ẹ̀mí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ gba ìbáwí ká sì ṣiṣẹ́ láti dẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà.
Má Ṣe Gbé Ìrètí Rẹ Lé Ọrọ̀ Àìdánilójú
15. (a) Àwọn ọ̀nà wo làwọn èèyàn kan máa ń gbà lo ọrọ̀ wọn? (b) Báwo ni Dáfídì ṣe fẹ́ láti lo ọrọ̀ tirẹ̀?
15 Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé èèyàn ńlá kan ni Dáfídì tẹ́lẹ̀ tàbí pé ìdílé rẹ̀ lọ́rọ̀. Àmọ́ nígbà tí Dáfídì ń ṣàkóso, ó dẹni tó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ọ̀pọ̀ ló máa ń fi ọrọ̀ wọn pa mọ́, tí wọ́n á máa fi ojúkòkòrò wá sí i, tàbí kó jẹ́ pé ara wọn nìkan ní wọ́n máa fi mọ̀. Àwọn mìíràn máa ń lo owó wọn láti fi gbayì lójú aráyé. (Mátíù 6:2) Ọ̀nà tí Dáfídì gbà lo ọrọ̀ tirẹ̀ yàtọ̀ pátápátá. Bí yóò ṣe bọlá fún Jèhófà lóhun tó jẹ ẹ́ lógún. Dáfídì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Nátánì, pé òun fẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà, kí àpótí májẹ̀mú lè wà níbẹ̀, èyí tó “ń gbé ní àárín àwọn aṣọ àgọ́” ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn. Inú Jèhófà dùn sí èrò ọkàn Dáfídì yìí àmọ́ ó gbẹnu Nátánì sọ fún un pé ọmọ rẹ̀, Sólómọ́nì, ni yóò kọ́ ọ.—2 Sámúẹ́lì 7:1, 2, 12, 13.
16. Àwọn nǹkan wo ni Dáfídì pèsè sílẹ̀ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà?
16 Dáfídì kó ohun èlò tí wọ́n máa lò fún kíkọ́ ilé tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ yìí jọ. Dáfídì wá sọ fún ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì pé: “Mo ti pèsè ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ńtì wúrà sílẹ̀ fún ilé Jèhófà àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ tálẹ́ńtì fàdákà, àti bàbà àti irin láìsí ọ̀nà tí a fi lè wọ̀n wọ́n nítorí tí wọ́n wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀n; mo sì ti pèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣe àwọn àfikún sí wọn.” Látinú ọrọ̀ rẹ̀, ó pèsè ẹgbẹ̀rún tálẹ́ńtì wúrà àti ẹgbẹ̀rún méje tálẹ́ńtì fàdákà.a (1 Kíróníkà 22:14; 29:3, 4) Ẹ̀bùn tí Dáfídì fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ pèsè yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣekárími o, ó jẹ́ ọ̀nà kan tó gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ àti ìfọkànsìn rẹ̀ hàn sí Jèhófà Ọlọ́run. Láti fi hàn pé òun mọ Ẹni tó jẹ́ orísun ọrọ̀ òun, ó sọ fún Jèhófà pé: “Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, láti ọwọ́ rẹ wá sì ni a ti fi fún ọ.” (1 Kíróníkà 29:14) Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ Dáfídì sún un láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gbé ìjọsìn mímọ́ ga.
17. Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà ní 1 Tímótì 6:17-19 ṣe kan àtolówó àti tálákà?
17 Bíi ti Dáfídì, ẹ jẹ́ kí àwa náà lo àwọn ohun ìní wa fún ṣíṣe rere. Dípò tá ó fi máa lépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kiri, ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run lohun tó dára jù tó yẹ ká máa wá, ìyẹn la fi lè ní ọgbọ́n tòótọ́ àti ojúlówó ayọ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa; láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:17-19) Yálà á jẹ́ olówó tàbí a ò jẹ́ olówó, ẹ jẹ́ ká gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run ká sì máa lépa ìgbésí ayé tó máa jẹ́ ká ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Kò sóhun tó ṣeyebíye tó kéèyàn wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́.
Fi Ara Rẹ Hàn fún Ọlọ́run Ní Ẹni Tí A Tẹ́wọ́ Gbà
18. Ọ̀nà wo ni Dáfídì gbà fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún àwa Kristẹni?
18 Jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé Dáfídì, ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ló ń wá. Nínú orin, ó sọ pé: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, fi ojú rere hàn sí mi, nítorí pé ìwọ ni ọkàn mi sá di.” (Sáàmù 57:1) Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Jèhófà kò já sófo. Dáfídì dàgbà ó darúgbó, “ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́.” (1 Kíróníkà 23:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe ńlá, à ń rántí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run tí wọ́n fi ìdúróṣinṣin àrà ọ̀tọ̀ hàn.—Hébérù 11:32.
19. Báwo la ṣe lè fi ara wa hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà?
19 Bó o ti ń dojú kọ àwọn ipò tó ń yí padà nínú ìgbésí ayé, máa rántí pé bí Jèhófà ṣe di Dáfídì mú, tó fún un lókun, tó sì bá a wí, ó lè ṣe ohun kan náà fún ọ. Bíi ti Dáfídì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà rí onírúurú ìyípadà nínú ìgbésí ayé. Síbẹ̀, òun náà dúró ṣinṣin nípa gbígbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:12, 13) Bá a bá gbára lé Jèhófà, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. Ó fẹ́ ká ṣàṣeyọrí. Bá a bá tẹ́tí sí i tá a sì ń sún mọ́ ọ, yóò fún wa ní okun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bá a bá sì ń bá a nìṣó láti gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run, yóò ṣeé ṣe fún wa láti ‘fi ara wa hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà’ nísinsìnyí àti títí láé.—2 Tímótì 2:15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tá a bá ní ká sọ bí ohun tí Dáfídì pèsè ṣe pọ̀ tó ní iye tọjọ́ òní, ó lé ní bílíọ̀nù kan àti igba mílíọ̀nù [1,200,000,000] dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè ṣọ́ra ká má bàa di onígbèéraga?
• Ìdí wo la ò fi gbọ́dọ̀ gbẹ̀san ara wa?
• Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìbáwí?
• Kí nídìí tá a fi ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ká máà gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Dáfídì gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run ó sì wá ojú rere Rẹ̀. Ṣé ìwọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, láti ọwọ́ rẹ wá sì ni a ti fi fún ọ”