MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
O Lè Ṣàṣeyọrí Láìka Ti “Ẹ̀gún” Tó Wà Nínú Ara Rẹ Sí!
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan le gan-an yìí, àwọn ìṣòro tó dà bí ẹ̀gún ń bá gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run fínra. (2Ti 3:1) Báwo la ṣe lè gbára lé Jèhófà, kí la sì lè ṣe láti fara dà àwọn ìṣòro yìí? Wo fídíò náà “Ojú Àwọn Afọ́jú Yóò Là” kó o lè rí ohun tí Talita Alnashi àti àwọn òbí rẹ̀ ṣe, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni “ẹ̀gún” tó wà nínú ara Talita?
Àwọn ìlérí inú Bíbélì wo ló ti ran Talita àtàwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́ láti má sọ̀rètí nù?
Báwo ni àwọn òbí Talita ṣe fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún Talita?
Báwo ni àwọn òbí Talita ṣe lo àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run pèsè láti ran Talita lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
Báwo ni Talita ṣe fi hàn pé òun ń dàgbà nípa tẹ̀mí láìka “ẹ̀gún” tó wà nínú ara rẹ̀ sí?
Ìṣírí wo lo ti rí látinú ìrírí Talita?