Ṣíṣiṣẹ́ Sin Jèhófà Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé Tí Ó Wà Níṣọ̀kan
GẸ́GẸ́ BÍ ANTONIO SANTOLERI TI SỌ
Ọmọ ọdún 17 ni bàbá mi, nígbà tí ó fi Ítálì sílẹ̀ ní ọdún 1919. Ó ṣí lọ sí Brazil, ní wíwá ìgbésí ayé tí ó sàn jù kiri. Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣí ṣọ́ọ̀bù onígbàjámọ̀ sí ìlú kékeré kan nínú ìpínlẹ̀ São Paulo.
NÍ ỌJỌ́ kan ní ọdún 1938, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún méje, Bàbá gba ìtẹ̀jáde Bíbélì ti èdè Brasileira lọ́wọ́ ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ níwájú ṣọ́ọ̀bù rẹ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, àìsàn dá Màmá wólẹ̀, ó sì di aláàbọ̀ ara títí tí ó fi kú. Bàbá náà dùbúlẹ̀ àìsàn, nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wa pátá—Màmá, Bàbá, arábìnrin mi Ana, àti èmi—lọ gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ní ìlú São Paulo.
Nígbà tí mò ń lọ sílé ẹ̀kọ́ ní São Paulo, mo di òǹkàwé tí ń kí yànyán, ní pàtàkì fún àwọn ìwé ìtàn. Ó wú mi lórí pé a máa ń mẹ́nu kan Bíbélì nínú wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé ìtàn àròsọ kan, tí mo yá ní ilé àkójọ ìwé kíkà ti gbogbogbòò ní São Paulo, mẹ́nu kan Ìwàásù Lórí Òkè lọ́pọ̀ ìgbà. Ìgbà yẹn ni mo pinnu láti ní Bíbélì kan, kí n baà lè ka ìwàásù yẹn fúnra mi. Mo wá Bíbélì ti Bàbá ti rà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo rí i ní ìsàlẹ̀ àpótí, níbi tí ó ti wà fún ọdún méje.
Onísìn Kátólíìkì ní ìdílé wa, nítorí náà, a kò tí ì fìgbà kankan fún mi níṣìírí láti ka Bíbélì. Wàyí o, fúnra mi, mo kọ́ láti wá orí àti ẹsẹ kàn. Mo kà á lọ́nà tí ó gbádùn mọ́ mi gidigidi, kì í ṣe kìkì Ìwàásù Lórí Òkè nìkan ṣùgbọ́n gbogbo ìwé Mátíù àti àwọn ìwé Bíbélì míràn. Ohun tí ó wú mi lórí jù lọ ni ọ̀nà òtítọ́ tí Jésù gbà kọ́ni, tí ó sì fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.
Ní rírí bí ìsìn Kátólíìkì ṣe yàtọ̀ sí ohun tí mo kà nínú Bíbélì tó, mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian, Ana sì dara pọ̀ mọ́ mi. Síbẹ̀, ọkàn-àyà mi ṣì ṣófo. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, mo ti ń wá Ọlọ́run kiri pẹ̀lú ìháragàgà. (Ìṣe 17:27) Ní alẹ́ ọjọ́ kan tí ìràwọ̀ gba ojú ọ̀run, nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́, mo ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí mo fi wà níhìn-ín? Kí ni ète ìgbésí ayé?’ Mo wà ibi àdádó kan ní ẹ̀yìnkùlé, mo kúnlẹ̀, mo sì gbàdúrà pé, ‘Olúwa Ọlọ́run! Ta ni ọ́? Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ ọ́?’ Kété lẹ́yìn náà ni ìdáhùn dé.
Kíkọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Ní ọjọ́ kan ní ọdún 1949, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tọ Bàbá wa, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ nínú takisí. Ó fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ ọ́. Ó san àsansílẹ̀ fún Ilé Ìṣọ́, ó sì ní kí ó ṣe ìbẹ̀wò sí ilé wa, ní ṣíṣàlàyé pé, òun ní ọmọ méjì tí ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian. Nígbà ìbẹ̀wò obìnrin náà, ó fi ìwé náà, Children, sílẹ̀ fún Ana, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, mo dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
Ní November ọdún 1950, a lọ sí àpéjọpọ̀ wa àkọ́kọ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níbẹ̀ ni a ti mú ìwé náà, “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” jáde, a sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nìṣó ní lílo ìwé yẹn gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà wa. Kò pẹ́ kò jìnnà, a fòye mọ̀ pé, a ti rí òtítọ́, nígbà tí ó sì di April ọdún 1951, a ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí àmì ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà. Bàbá ṣe ìyàsímímọ́ rẹ̀ ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sì kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run ní ọdún 1982.
Jíjẹ́ Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
Ní January ọdún 1954, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ẹni ọdún 22, a gbà mí fún iṣẹ́ ìsìn ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí a ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí mo débẹ̀, ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé ọkùnrin kan tí ó fi ọdún méjì péré jù mí lọ, Richard Mucha, ni alábòójútó ẹ̀ka. Ní ọdún 1955, nígbà tí àìní kan dìde fún àwọn ìránṣẹ́ àyíká, bí a ṣe ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn àjò nígbà náà, mo wà lára àwọn ọkùnrin márùn-ún tí a ké sí láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn yìí.
Ìpínlẹ̀ Rio Grande do Sul ní ibi iṣẹ́ àyànfúnni mi. Ìjọ 8 péré ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó wà níbẹ̀ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n láàárín oṣù 18, a ti dá ìjọ tuntun 2 àti 20 àwùjọ àdádó sílẹ̀. Ní agbègbè yìí lónìí, a ní àyíká 15 ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní nǹkan bí ìjọ 20! Ní ìparí ọdún 1956, a sọ fún mi pé a ti pín àyíká mi sí àyíká mẹ́rin kéékèèké, tí àwọn ìránṣẹ́ àyíká mẹ́rin yóò máa bẹ̀ wò. Ní àkókò yẹn, a ní kí n padà wá sí Bẹ́tẹ́lì fún iṣẹ́ àyànfúnni tuntun.
Sí ìyàlẹ́nu àti ìdùnnú mi, a yàn mí sí àríwá Brazil gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àgbègbè, òjíṣẹ́ arìnrìn àjò tí ń bẹ àwọn àyíká mélòó kan wò. Nígbà yẹn, Brazil ní 12,000 òjíṣẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, orílẹ̀-èdè náà sì ní àgbègbè méjì. Richard Wuttke ń bẹ gúúsù wò, èmi sì ń bẹ àgbègbè àríwá wò. A dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ní Bẹ́tẹ́lì láti lo ẹ̀rọ agbáwòrányọ fún fífi fíìmù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe hàn, The New World Society in Action àti The Happiness of the New World Society.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìrìn àjò yàtọ̀ púpọ̀. Kò sí Ẹlẹ́rìí kan tí ó ní ọkọ̀ ìrìnnà, nítorí ìdí èyí mo máa ń wọ ọkọ̀ ìgbájá, ọkọ̀ òbèlè, ẹṣin, kẹ́kẹ́ àfẹranfà, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ọkọ̀ ẹrù, mo sì wọ ọkọ̀ òfuurufú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ó ń runi nímọ̀lára sókè láti fò kọjà aginjù Amazon láti balẹ̀ ní Santarém, ìlú kan ní àárín Belém lẹ́nu Amazon àti Manaus, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Amazonas. Àwọn ìránṣẹ́ àgbègbè nígbà yẹn ní ìwọ̀nba àpèjọ àyíká díẹ̀ láti bẹ̀ wò, nítorí náà, mo máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókó mi láti fi fíìmù Society hàn. Ní àwọn ilú títóbi, ọgọ́rọ̀ọ̀rún máa ń wá.
Ohun tí ó wú mi lórí jù lọ ní àríwá Brazil ni ẹkùn Amazon. Nígbà tí mo ń bẹ ibẹ̀ wò ní April 1957, Odò Amazon àti àwọn itọ́ rẹ̀ kún bo bèbè wọn. Mo ní àǹfààní fífi ọ̀kan nínú àwọn fíìmù náà hàn ní aginjù náà, ní títa aṣọ sí àárín igi méjì. Agbára iná mànàmáná tí ẹ̀rọ agbáwòrányọ náà lò wá láti inú ọkọ̀ ojú omi ẹlẹ́ńjìnì kan tí a so mọ́ etí odò itòsí. Ó jẹ́ fíìmù àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn àwùjọ náà yóò wò.
Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, mo padà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ní ọdún tí ó sì tẹ̀ lé e, ní ọdún 1958, mo ní àǹfààní lílọ sí Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Àtọ̀runwá,” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní New York City, tí ó jẹ́ àpéjọ mánigbàgbé. Àwọn àyànṣaṣojú láti 123 ilẹ̀ wà lára 253,922 tí ó kún Pápá Ìṣeré Yankee àti Ibi Ìṣeré Polo tí ó wà nítòsí fọ́fọ́, ní ọjọ́ tí ó kẹ́yìn àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́jọ náà.
Gbígbádùn Ìyípadà Nínú Ìgbésí Ayé Mi
Kété lẹ́yìn tí mo padà sí Bẹ́tẹ́lì, mo di ojúlùmọ̀ Clara Berndt, nígbà tí ó sì di March ọdún 1959, a ṣègbéyàwó. A yàn wá sí iṣẹ́ àyíká ní ìpínlẹ̀ Bahia, níbi tí a ti ṣiṣẹ́ sìn fún nǹkan bí ọdún kan. Èmi àti Clara ṣì lè fi ìdùnnú rántí ìrẹ̀lẹ̀, aájò àlejò, ìtara, àti ìfẹ́ ti àwọn ará tí ó wà níbẹ̀ ní; wọ́n tòṣì nípa ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n lọ́rọ̀ nínú èso Ìjọba. Lẹ́yìn náà, a gbé wa lọ sí Ìpínlẹ̀ São Paulo. Ibẹ̀ ni a wà ní ọdún 1960, nígbà tí aya mi fẹ́ra kù, tí a sì ní láti fi ìṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀.
A pinnu láti ṣí lọ sí ibì kan ní ìpínlẹ̀ Santa Catarina, níbi tí a bí aya mi sí. Ọmọkùnrin wa, Gerson, jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn ọmọ wa márùn-ún. Gilson ni ó tẹ̀ lé e ní ọdún 1962, Talita ní ọdún 1965, Tárcio ní ọdún 1969, àti Janice ní ọdún 1974. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà àti ìmọ̀ràn àtàtà tí ó ń pèsè, ó ṣeé ṣe fún wa láti dojú kọ ìpènijà títọ́ wọn dàgbà nínú “ìbáwí ati ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
A ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wa sí iyebíye. Onísáàmù náà sọ ìmọ̀lára wa jáde dáradára pé: “Kíyè sí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa.” (Orin Dáfídì 127:3) Láìka àwọn ìṣòro sí, a ti tọ́jú àwọn ọmọ wa, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe tọ́jú ohunkóhun tí ó bá jẹ́ “ìní Olúwa,” ní fífi àwọn ìtọ́ni tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́kàn. Èrè rẹ̀ ti pọ̀ jaburata. Ó fún wa ní ìdùnnú tí kò ṣeé fẹnu sọ, nígbà tí àwọn márààrún ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, lọ́kọ̀ọ̀kan, àti láti inú ọkàn olúkúlùkù wọn sọ ìfẹ́ ọkàn wọn jáde láti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà.—Oníwàásù 12:1.
Yíyàn Tí Àwọn Ọmọ Wa Ṣe
Inú wa dùn jọjọ nígbà tí Gerson sọ pé òun fẹ́ ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, kété lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ rẹ̀ lórí sísọ àkójọ ìsọfúnni di ọ̀rọ̀ kọ̀m̀pútà, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yan iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìgbésí ayé dípò iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kan. Síbẹ̀, ìgbésí ayé ní Bẹ́tẹ́lì kò kọ́kọ́ rọrùn fún Gerson. Lẹ́yìn bíbẹ̀ ẹ́ wò nígbà tí ó ti wà ní Bẹ́tẹ́lì fún oṣù mẹ́rin péré, ìbànújẹ́ tí ó hàn lójú rẹ̀ nígbà tí a ń lọ nípa lórí mi lọ́nà jíjinlẹ̀. Nínú dígí àfiwẹ̀yìn ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, mo rí i tí ó ń wò wá títí a fi yí kọ́nà àkọ́kọ́ ní ojú ọ̀nà náà. Ojú mi kún fún omijé tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi ní láti dúró lẹ́bàá ọ̀nà, kí n tó máa bá ìrìn àjò oní 700 kìlómítà náà padà sílé lọ.
Ní tòótọ́, Gerson wá gbádùn Bẹ́tẹ́lì púpọ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wà níbẹ̀ fún ọdún mẹ́fà, ó gbé Heidi Besser níyàwó, wọ́n sì jọ ṣiṣẹ́ sìn papọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún méjì mìíràn. Lẹ́yìn náà Heidi fẹ́ra kù, wọ́n sì ní láti fibẹ̀ sílẹ̀. Ọmọbìnrin wọn, Cintia, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà báyìí, ń bá wọn lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò Ìjọba wọn.
Kó pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí a kọ́kọ́ bẹ Gerson wò ní Bẹ́tẹ́lì, Gilson, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìṣàbójútó okòwò, wí pé, òun pẹ̀lú fẹ́ ṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀. Ìwéwèé rẹ̀ ni pé, kí ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ okòwò rẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọdún kan ní Bẹ́tẹ́lì. Ṣùgbọ́n ìwéwèé rẹ̀ yí padà, ó sì ń bá iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì lọ. Ní ọdún 1988, ó gbé Vivian Gonçalves níyàwó, aṣáájú ọ̀nà kan, gẹ́gẹ́ bí a ti máa ń pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Láti ìgbà yẹn wá, wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ sìn pọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.
Ìdùnnú wa ń bá a lọ nígbà tí ọmọ wa kẹta, Talita, yàn láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ní ọdún 1986, lẹ́yìn gbígba ẹ̀kọ́ lórí ìyàwòrán ilé. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, a pe òun pẹ̀lú láti wá ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ní ọdún 1991, José Cozzi gbé e níyàwó, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá. Wọ́n ń bá a nìṣó níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya.
Inú èmi àti aya mi tún dùn nígbà tí Tárcio, tí a bí tẹ̀ lé e, tún gbólóhùn kan náà tí a ti gbọ́ nígbà mẹ́ta sọ pé, “Bàbá, mo fẹ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì.” A tẹ́wọ́ gba ìwé tí ó kọ béèrè fún un, ní ọdún 1991, òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, ibi tí ó wà títí di ọdún 1995. A láyọ̀ pé ó lo okun ọ̀dọ́ rẹ̀ láti gbé ire Ìjọba Jèhófà lárugẹ lọ́nà yìí fún ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́ta.
Àbíkẹ́yìn wa, Janice, ṣe ìpinnu láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, ó sì ṣe batisí ní ọmọ ọdún 13. Nígbà tí ó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, ó ṣiṣẹ́ sìn fún ọdún kan gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ní September 1, 1993, ó bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà déédéé nínú ìjọ wa níhìn-ín ní ìlú Gaspar.
Ọ̀nà Àṣeyọrí
Kí ni àṣírí mímú kí ìdílé kan máa wá ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà? N kò gbà gbọ́ pé àwọn ìlànà ajẹ́bíidán kan wà. Jèhófà ti pèsè ìmọ̀ràn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn Kristẹni òbí láti tẹ̀ lé, nítorí náà gbogbo ògo ní láti lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún àbájáde rere tí a ti gbádùn. A wulẹ̀ ti gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ni. (Òwe 22:6) Gbogbo àwọn ọmọ wa jogún èrò orí àwọn Latin America lára mi, wọ́n sì jogún ìwà àwọn ará Germany lára màmá wọn. Ṣùgbọ́n ohun pàtàkì jù lọ tí wọ́n jogún lára wa ni ogún tẹ̀mí.
Ire Ìjọba ni ó jẹ wá lógún jù lọ nínú ìgbèsí ayé ìdílé wa. Fífi ire yìí sí ipò kíní kò rọrùn. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣòro fún wa láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìdílé déédéé, síbẹ̀ a kò jẹ́ kí ó rẹ̀ wá. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ ìgbésí ayé wọn, a ń gbé ọmọ kọ̀ọ̀kan wá sí ìpàdé Kristẹni àti àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀. Àìsàn àti àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì míràn nìkan ni ó lè dí wa lọ́wọ́ lílọ sí ìpàdé. Ní àfikún sí i, láti kékeré, àwọn ọmọ máa ń bá wa lọ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.
Nígbà tí wọ́n bá fi máa tó ọmọ ọdún mẹ́wàá, àwọn ọmọ ti máa ń sọ̀ àsọyé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. A máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra àsọyé wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀, ní fífún wọn níṣìírí láti lo ìlapa èrò dípò kíká gbogbo ọ̀rọ̀ pátá. Lẹ́yìn náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò máa múra àsọyé tirẹ̀. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá ti tó ọmọ ọdún 10 sí 12, olúkúlùkù wọn máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé. Kìkì ọ̀nà ìgbésí ayé kan ṣoṣo tí wọ́n mọ̀ nìyí.
Aya mi, Clara, kó ipa pàtàkì nínú títọ́ àwọn ọmọ. Ní alaalẹ́, nígbà tí wọ́n bá ṣì wà ní ọmọdé—àkókò tí ọmọ máa ń gba gbogbo ohun tí a bá kọ́ ọ sínú bí kàn-ìnkàn-ìn òyìnbó ṣe ń gba omi sínú—Clara máa ń ka ìtàn Bíbélì fún wọn, ó sì máa ń gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Ó lo àwọn ìwé wọ̀nyí dáradára, Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, àti Iwe Itan Bibeli Mi.a A tún lo àwọn àrànṣe àtẹ́tísí àti fídíò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè, nígbà tí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
Ìrírí wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni òbí jẹ́rìí sí i pé, àwọn ọmọ nílò àfiyèsí ojoojúmọ́. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀, ọkàn ìfẹ́ ara ẹni, àti àkókò púpọ̀ wà lára àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí tí àwọn ọ̀dọ́ nílò. A kò kà á sí ẹrù iṣẹ́ òbí níkan láti tẹ́ àwọn àìní wọ̀nyí lọ́rùn dé ibi tí agbára wa bá dé, ṣùgbọ́n a rí adùn púpọ̀ nínú ṣíṣe é.
Ní tòótọ́, ó ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún òbí láti rì ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní Orin Dáfídì 127:3-5 pè: “Kíyè sí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa; ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀. Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn.” Ní ti gàsíkíá, ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí ó wà níṣọ̀kan ti mú kí a hó ìhó ayọ̀!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ gbogbo wọn jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Antonio Santoleri pẹ̀lú ìdílé rẹ̀