Ìgbọ́kànlé Mi Nínú Jèhófà Mú Mi Dúró
GẸ́GẸ́ BÍ AGENOR DA PAIXÃO ṢE SỌ
Àrùn gbọ̀fungbọ̀fun pa Paul, ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ oṣù 11 péré. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní August 15, 1945, àrùn òtútù àyà pa aya mi ọ̀wọ́n. Mo jẹ́ ẹni ọdún 28, àwọn ìyọnu wọ̀nyí bà mí nínú jẹ́, wọ́n sì kó ìdààmú bá mi. Síbẹ̀ ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀ mú mi dúró. Jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe wá ní ìgbọ́kànlé yìí.
LÁTI ìgbà tí a ti bí mi ní Salvador, Ìpínlẹ̀ Bahia, Brazil, ní January 5, 1917, ni Màmá ti ń kọ́ mi láti jọ́sìn “àwọn ẹni mímọ́” Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Ó tilẹ̀ máa ń jí èmi àti àwọn arákùnrin mi ní òwúrọ̀ kùtù, kí a baà lè gbàdúrà pa pọ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn òbí mi tún máa ń lọ sí ìpàdé ẹgbẹ́ awo candomblé, ẹgbẹ́ awo ẹ̀sìn fúdù ti àwọn ará Áfíríkà òun Brazil. Mo ka ẹ̀sìn wọ̀nyí sí gidigidi, ṣùgbọ́n n kò ní ìgbọ́kànlé kankan nínú ohun tí wọ́n ń pè ní àwọn ẹni mímọ́ Kátólíìkì tàbí nínú ẹgbẹ́ awo candomblé. Ohun tí ó já mi kulẹ̀ jù lọ ni ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran tí a ń fi hàn nínú àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí.
Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì fi ilé sílẹ̀ láti wá iṣẹ́. Lẹ́yìn náà, bàbá mi pa ìdílé wa tì. Nítorí náà, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, mo ní láti wá iṣẹ́ láti ran màmá àti àbúrò mi obìnrin lọ́wọ́. Ní nǹkan bí ọdún 16 lẹ́yìn náà, ìjíròrò pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan ní ilé iṣẹ́ yọrí sí ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi.
Jíjèrè Ìgbọ́kànlé Nínú Jèhófà
Mo pàdé Fernando Teles ní 1942. Ó sábà máa ń sọ pé ó lòdì láti jọ́sìn “àwọn ẹni mímọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 10:14; Jòhánù Kíní 5:21) Lákọ̀ọ́kọ́, n kò tẹ́tí sí i rárá. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọkàn àti ọkàn ìfẹ́ tí ó ní nínú àwọn ènìyàn, láìka àwọ̀ wọn sí, fà mí mọ́ra, mo sì wá kan sáárá sí ìmọ̀ Bíbélì tí ó ní, ní pàtàkì ohun tí ó sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti nípa párádísè ilẹ̀ ayé kan. (Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:3, 4) Ní ṣíṣàkíyèsí ọkàn ìfẹ́ mi, ó fún mi ní Bíbélì kan àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀.
Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo tẹ́wọ́ gba ìkésíni kan sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìjọ. Àwùjọ náà ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, Religion, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society. Mo gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí ó wú mi lórí ní pàtàkì ní àìsí ẹ̀tanú àti bí a ṣe tẹ́wọ́ gbà mí lójú ẹsẹ̀. Ní àkókò yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ Lindaura sọ́nà. Nígbà tí mo bá a sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo ń kọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi lọ sí àwọn ìpàdé.
Ohun mìíràn tí ó wú mi lórí ní àwọn ìpàdé ni bí a ṣe tẹnu mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. (Mátíù 24:14; Ìṣe 20:20) Bí àwọn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ti fún mi níṣìírí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láìjẹ́ bí àṣà nínú ọkọ̀ ojú irin bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́. Nígbà tí mo bá rí ẹnì kan tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn, n óò gba àdírẹ́sì rẹ̀, n óò sì bẹ̀ ẹ́ wò láti mú ọkàn ìfẹ́ yẹn dàgbà.
Láàárín àkókò náà, ìgbọ́kànlé mi nínú Jèhófà àti nínú ètò àjọ tí ó ń lò ń dàgbà sókè. Nípa báyìí, lẹ́yìn títẹ́tí sí àwíyé Bíbélì lórí ìyàsímímọ́ Kristẹni, mo ṣe ìrìbọmi nínú Òkun Atlantic, ní April 19, 1943. Ní ọjọ́ kan náà yẹn, mo ṣàjọpín fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé tí a máa ń ṣe déédéé.
Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ní May 5, èmi àti Lindaura ṣègbéyàwó. Lẹ́yìn náà, ní August 1943, ó ṣe ìrìbọmi nígbà àpéjọ àkọ́kọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní ìlú Salvador. Ìwé 1973 Yearbook of Jehovah’s Witnesses sọ nípa àpéjọ yẹn pé: “Ìgbésẹ̀ ẹgbẹ́ àlùfáà rọ́nà láti dá àsọyé ìtagbangba dúró ní Salvador, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe títí di ẹ̀yìn ìgbà tí ìkéde àtàtà . . . ti wáyé.” Ẹ̀rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà lójú inúnibíni gbígbóná janjan fún ìgbọ́kànlé mi nínú rẹ̀ lókun.
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, ọdún méjì péré lẹ́yìn tí Lindaura ṣe ìrìbọmi—àti oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ikú ọmọkùnrin wa—aya mi ọ̀wọ́n kú. Ẹni ọdún 22 péré ni. Ṣùgbọ́n ìgbọ́kànlé tí mo ní nínú Jèhófà mú mi dúró ní àwọn oṣù lílekoko wọ̀nyẹn.
Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí fún Mi Lókun
Ní 1946, ọdún kan lẹ́yìn tí mo pàdánù aya àti ọmọkùnrin mi, a yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìjọ kan ṣoṣo tí ó wà ní Salvador nígbà yẹn. Ní ọdún kan náà yẹn, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ìjọ tí ń bẹ ní Brazil, mo sì di olùdarí àkọ́kọ́ fún ilé ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Bahia. Lẹ́yìn náà ní October 1946, a ṣe Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti “Àwọn Orílẹ̀-Èdè Aláyọ̀” ní ìlú São Paulo. Ẹni tí ó gbà mí síṣẹ́ fún ọdún mẹ́wàá sọ pé òun nílò mi, ó sì rọ̀ mí pé kí n má lọ. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí mo ṣàlàyé fún un bí ó ti ṣe pàtàkì fún mi tó láti lọ sí àpéjọ náà, ó fún mi ní ẹ̀bùn púpọ̀, ó sì sọ pé n óò lọ re, n óò bọ̀ re.
Èdè Potogí ni a fi darí àwọn apá àpéjọ náà ní Gbọ̀ngàn Ìlú São Paulo—èdè ìlú Brazil—títí kan èdè Gẹ̀ẹ́sì, German, Hungarian, Polish, àti èdè Russian. Ní àpéjọ yẹn, a mú ìwé ìròyìn Jí! jáde ní èdè Potogí. Àpéjọ náà ru mí sókè gidigidi—nǹkan bí 1,700 ènìyàn pésẹ̀ síbi àsọyé ìtagbangba—tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi kọ̀wé ìbéèrè láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ní November 1, 1946.
Ní àkókò yẹn, a lo ohun èèlò agbóhùnjáde gidigidi nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa. Àsọyé náà, “Ààbò” ni a sábà máa ń gbé sí i fún àwọn onílé. Lẹ́yìn náà, a óò sọ pé: “Láti dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá tí a kò lè fojú rí, a gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ọ̀rẹ́ kan tí a kò lè fojú rí pẹ̀lú. Jèhófà ni ọ̀rẹ́ wa gíga jù lọ, ó sì ní agbára fíìfíì ju ọ̀tá wa, Sátánì lọ. Nítorí náà, a ní láti rọ̀ mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ láti dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, a óò fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Protection, tí ó pèsè ìsọfúnni síwájú sí i lọ̀ ọ́.
N kò tí ì ṣe aṣáájú ọ̀nà pé ọdún kan nígbà tí mo gba ìkésíni láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe nínú Ìjọ Carioca ní Rio de Janeiro. Níbẹ̀, nígbà míràn, a máa ń dojú kọ àtakò lílekoko. Nígbà kan, onílé kan gbéjà ko alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi, Ivan Brenner. Àwọn aládùúgbò pé ọlọ́pàá, a sì kó gbogbo wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.
Nígbà tí a ń fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, onílé náà tí inú ti bí fẹ̀sùn kàn wá pé a ń dí àlàáfíà lọ́wọ́. Ọ̀gá ọlọ́pàá pàṣẹ fún un láti panu mọ́. Lẹ́yìn náà, ọ̀gá ọlọ́pàá náà kọjú sí wa, ó sì rọra sọ fún wa pé a lè máa lọ. Ó dá olùfisùn wa dúró, ó sì fi ẹ̀sùn jàgídíjàgan kàn án. Irú ipò yẹn mú ìgbọ́kànlé mi nínú Jèhófà dúró.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Tí A Mú Gbòòrò Sí I
Ní July 1, 1949, mo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé a ké sí mi láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn ilé lílò pàtàkì ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè kan. Bẹ́tẹ́lì tí ó wà ní Brazil wà ní ojúlé 330 Òpópónà Licínio Cardoso nígbà yẹn, ní Rio de Janeiro. Ní àkókò náà, ènìyàn 17 péré ni ó wà nínú odindi ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Fún ìgbà díẹ̀, mo ń lọ sí Ìjọ Engenho de Dentro tí ó wà ládùúgbò, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, a yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága ní ìjọ kan ṣoṣo tí ó wà ní Belford Roxo, ìlú kan tí ó wà ní kìlómítà mélòó kan sí Rio de Janeiro.
Ọwọ́ mi máa ń dí púpọ̀ ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ Saturday, n óò rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin lọ sí Belford Roxo, n óò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní ọ̀sán, lẹ́yìn náà, n óò sì lọ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ìrọ̀lẹ́. Mo máa ń sùn sọ́dọ̀ àwọn ará di ọjọ́ kejì, mo sì máa ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ní ọ̀sán yẹn, n óò lọ fún àsọyé Bíbélì fún gbogbo ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, n óò sì pa dà sí Bẹ́tẹ́lì ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́. Lónìí, ìjọ 18 ní ń bẹ ní Belford Roxo.
Ní 1954, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àbọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn, a yàn mí pa dà sí Rio de Janeiro gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága ní Ìjọ São Cristóvão. Fún ọdún mẹ́wàá tí ó tẹ̀ lé e, mo ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ yẹn.
Àwọn Iṣẹ́ Àyànfúnni Mi Ní Bẹ́tẹ́lì
Iṣẹ́ àyànfúnni mi àkọ́kọ́ ní Bẹ́tẹ́lì jẹ́ láti kọ́ ibi ìgbọ́kọ̀sí fún ọkọ̀ kan ṣoṣo tí Society ní, ọkọ̀ 1949 Dodge, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣokoléètì nítorí àwọ̀ ilẹ̀ tí ó ní. Nígbà tí ibi ìgbọ́kọ̀sí náà parí, a yàn mí láti ṣiṣẹ́ ní ilé ìdáná, níbi tí mo wà fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, a gbé mi lọ sí Ẹ̀ka Ìtẹ̀wé, ibi tí mo ti wà báyìí fún ohun tí ó ju 40 ọdún.
Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé tí a ní ni ó jẹ́ àlòkù. Fún àpẹẹrẹ, fún ọ̀pọ̀ ọdún, a ní ògbólógbòó ẹ̀rọ ìtẹ̀wé olójú pẹlẹbẹ kan tí a máa ń fi ìfẹ́ pè ní Sárà, orúkọ ìyàwó Ábúráhámù. A ti lò ó fún ọ̀pọ̀ ọdún ní ilé ìtẹ̀wé ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, New York. Lẹ́yìn náà ní àwọn ọdún 1950, a gbé e wá sí Brazil. Níhìn-ín, gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Ábúráhámù, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ó méso jáde—irú bí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
Ìlọsókè nínú iye àwọn ìtẹ̀jáde tí ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Brazil ń tẹ̀ kì í yé yà mí lẹ́nu. Ní gbogbo ọdún 1953, a tẹ ìwé ìròyìn 324,400 jáde, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta tí a ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù!
Àwọn Ilé Bẹ́tẹ́lì Wa
Fún àwọn ọdún tí ó ti kọjá, ó ń múni yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti rí bí a ṣe ń mú àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì wa ní Brazil gbòòrò sí i. Ní 1952, a kọ́ ilé iṣẹ́ alájà méjì sẹ́yìn ilé wa ní Rio de Janeiro. Lẹ́yìn náà ní 1968, a kó Bẹ́tẹ́lì lọ sí ilé tuntun kan ní ìlú São Paulo. Nígbà tí a kó dé ibẹ̀, ó dà bíi pé gbogbo nǹkan tóbi, ó sì ní àyè fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa tí ó ní mẹ́ńbà 42 nínú. Ní ti gidi, a ronú pé ilé yìí yóò tó fún gbogbo ìdàgbàsókè wa ní ọjọ́ ọ̀la. Ṣùgbọ́n, ní 1971, a kọ́ ilé alájà márùn-ún méjì míràn sí i, a sì ra ilé iṣẹ́ kan tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a tún un ṣe, a sì so ó pọ̀ mọ́ ilé yìí. Ṣùgbọ́n, láàárín ọdún díẹ̀, iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí ń pọ̀ sí i—a kọjá góńgó 100,000 ní 1975—béèrè fún ọ̀pọ̀ yàrá sí i.
Nítorí náà, a kọ́ àwọn ilé alásokọ́ra mìíràn sí nǹkan bíi 140 kìlómítà sí São Paulo nítòsí ìlú kékeré Cesário Lange. Ní 1980, a kó ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa tí ó ní 170 mẹ́ńbà nínú lọ sí àwọn ilé tuntun wọ̀nyí. Láti ìgbà náà wá, iṣẹ́ Ìjọba ti dàgbà sókè lọ́nà tí ń jọni lójú. Nísinsìnyí, a ní iye tí ó ju 410,000 tí ń nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù ní Brazil! Láti bójú tó àìní tẹ̀mí gbogbo àwọn olùpòkìkí Ìjọba wọ̀nyí, a ní láti máa bá a nìṣó ní kíkọ́ àwọn ilé iṣẹ́ tuntun láti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti láti kọ́ àwọn ilé gbígbé tuntun tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ní Bẹ́tẹ́lì yóò máa gbé. Lọ́wọ́lọ́wọ́, a ní nǹkan bíi 1,100 mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì!
Àwọn Àǹfààní Tí Mo Ṣìkẹ́
Mo ka iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì sí àǹfààní ṣíṣeyebíye. Nípa báyìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀, mo ronú nípa títún ìgbéyàwó ṣe, mo yàn láti fún àwọn àǹfààní mi ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú iṣẹ́ ìwàásù ní àfiyèsí kíkún. Níhìn-ín, mo ti ní ìdùnnú ti ṣíṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ní ibi ìtẹ̀wé, àti ní dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn. Mo ti gbìyànjú láti bá wọn lò bí ẹni pé èmi gan-an ni mo bí wọn. Ìtara àti àìmọtara-ẹni-nìkan wọn ti jẹ́ orísun ìṣírí ńlá fún mi.
Àǹfààní mìíràn jẹ́ gbígbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ènìyàn àtàtà tí a jọ gbé yàrá láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Ní tòótọ́, àkópọ̀ ìwà tí ó yàtọ̀ nígbà míràn ti fa ìṣòro. Síbẹ̀, mo kọ́ láti má ṣe retí ìjẹ́pípé láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Mo ti sakun láti yẹra fún sísọ ọ̀ràn tí kò tó nǹkan di ran-n-to tàbí ríro ara mi ju bí ó ti yẹ lọ. Ṣíṣàìka ara mi sí bàbàrà ti ràn mí lọ́wọ́ láti rára gba àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn.
Àǹfààní ṣíṣeyebíye mìíràn tí mo gbádùn jẹ ti lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní United States. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ní Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun,” tí a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee, New York, ní 1963, òmíràn sì ni Àpéjọ Àgbáyé ti “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” tí a ṣe ní ibi kan náà ní 1969. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo ní ìdùnnú ṣíṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà nítòsí ní Brooklyn, New York!
Ó tún jẹ́ àǹfààní mi fún ọdún mẹ́wàá láti nípìn-ín—pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí a jọ ń gbà á fúnra wa—nínú ṣíṣalága níbi ìjọsìn ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní òròòwúrọ̀. Síbẹ̀, àǹfààní gíga jù lọ, ọ̀kan tí ó ti mú ìdùnnú àti ìṣírí ńlá wá bá mi ni mímú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tọ àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ, àní gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá wa, Jésù Kristi, ti ṣe.
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, mo ti dojú kọ ìṣòro gbígbé pẹ̀lú àrùn Parkinson. Ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní ibi ìtọ́jú àìlera ní Bẹ́tẹ́lì fi hàn ti jẹ́ orísun ìrànwọ́ àti ìtùnú tí ń bá a nìṣó fún mi. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi ní okun láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe nínú ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀ka ti Brazil tí mo ń gbé nísinsìnyí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú aya mi, ẹni tí ó kú ní 1945