ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 May ojú ìwé 6
  • May 27–June 2

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May 27–June 2
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 May ojú ìwé 6

May 27–June 2

GÁLÁTÍÀ 1-3

  • Orin 106 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Mo Ta Kò Ó Lójúkojú”: (10 min.)

    • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà.]

    • Ga 2:11-13​—Nígbà tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù dé ọ̀dọ̀ Pétérù, ìbẹ̀rù èèyàn mú kí Pétérù máa yẹra fún àwọn ará tó jẹ́ Kèfèrí (w17.04 27 ¶16)

    • Ga 2:14​—Pọ́ọ̀lù bá Pétérù wí (w13 3/15 5 ¶12)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Ga 2:20​—Irú ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo ìràpadà, kí sì nìdí? (w14 9/15 16 ¶20-21)

    • Ga 3:1​—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pe àwọn ará Gálátíà ní “aláìnírònú”? (it-1 880)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ga 2:11-21 (th ẹ̀kọ́ 10)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 2)

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 191-192 ¶18-19 (th ẹ̀kọ́ 6)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 92

  • “Bí Gbogbo Wa Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn táwọn ará bá ti wo fídíò Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa, tẹ́ ẹ sì ti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀, ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń ṣojú ìjọ yín nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Tí ìjọ yín ò bá ní ẹni tó ń ṣojú fún yín, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé ìjọ yín nìkan ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń bójú tó àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba.) Ṣé à ń ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa nígbà tó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé à ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí kò fi ní sí ìpalára èyíkéyìí? Àwọn àtúnṣe wo lẹ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láìpẹ́ yìí, kí lẹ sì tún ń gbèrò láti ṣe? Tí ẹnì kan bá mọ iṣẹ́ kan tàbí tó bá fẹ́ máa ran àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe, kí ni ẹni náà máa ṣe? Báwo ni tọmọdé tàgbà wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, láìka ipò yòówù ká wà sí?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 6 ¶7-13

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 72 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́