May 20-26
2 KỌ́RÍŃTÌ 11-13
Orin 3 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ̀gún Nínú Ara Pọ́ọ̀lù”: (10 min.)
2Kọ 12:7—Ìṣòro kan tó dà bí ẹ̀gún ń bá Pọ́ọ̀lù fínra nígbà gbogbo (w08 6/15 3-4)
2Kọ 12:8, 9—Pọ́ọ̀lù bẹ Jèhófà pé kó mú ẹ̀gún náà kúrò, àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀ (w06 12/15 24 ¶17-18)
2Kọ 12:10—Pọ́ọ̀lù ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ torí pé ó gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run (w18.01 9 ¶8-9)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
2Kọ 12:2-4—Kí ló ṣeé ṣe kí “ọ̀run kẹta” àti “párádísè” máa tọ́ka sí? (w18.12 8 ¶10-12)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 2Kọ 11:1-15 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni han onílé. (th ẹ̀kọ́ 4)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“O Lè Ṣàṣeyọrí Láìka Ti ‘Ẹ̀gún’ Tó Wà Nínú Ara Rẹ Sí!”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà “Ojú Àwọn Afọ́jú Yóò Là”. Jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé a ní àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè mẹ́tàdínláàádọ́ta (47) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn afọ́jú àtàwọn tó ní ìṣòro ojú. Sọ fún àwọn ará pé tí wọ́n bá fẹ́ gba irú ìwé bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sọ fún ẹni tó ń bójú tó ìwé. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa ṣàkíyèsí àwọn tó bá ní ìṣòro ojú ní ìjọ tàbí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 6 àfikún Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 78 àti Àdúrà