MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe
Bíi tàwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ní àǹfààní láti fi hàn pé a fẹ́ràn àwọn ará wa tí àjálù dé bá. (Jo 13:34, 35) Láti rí bí àwọn ará ṣe ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ní Caribbean nígbà tí àjálù dé bá wọn, wo fídíò náà Ìfẹ́ Sún Wọn Ṣiṣẹ́—Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Tó Wáyé Láwọn Erékùṣù Caribbean, lẹ́yìn náà dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa ní Caribbean nígbà tí ìjì líle Hurricane Irma àti Hurricane Maria ṣọṣẹ́?
Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn ará láti ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ní Caribbean?
Báwo ló ṣe rí lára àwọn ará tí àjálù dé bá nígbà tí àwọn ará fi ìfẹ́ hàn sí wọn?
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòó ló ti lọ́wọ́ nínú ètò ìrànwọ́ yìí ní Caribbean?
Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará tí àjálù dé bá?
Nígbà tó o wo fídíò yìí, báwo ló ṣe rí lára rẹ pé o wà nínú ètò tó ń fi ìfẹ́ hàn?