ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 9/8 ojú ìwé 22
  • Ògbógi Nínú Pípalẹ̀ Pàǹtírí Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ògbógi Nínú Pípalẹ̀ Pàǹtírí Mọ́
  • Jí!—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Àwọn Èèrà Ṣe Ń Rìn Láìsí Sún Kẹẹrẹ Fà Kẹẹrẹ?
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!
    Jí!—2003
  • Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Wa Lójú Pé Ọlọ́gbọ́n Ni
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli—Nínú Ọgbà Ẹranko!
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2002
g02 9/8 ojú ìwé 22

Ògbógi Nínú Pípalẹ̀ Pàǹtírí Mọ́

KÒ TÍÌ ju àádọ́jọ ọdún lọ nísinsìnyí táwọn èèyàn jágbọ́n ọ̀nà ìgbàpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́. Àmọ́ ṣá o, ògbógi kan ti wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí látọjọ́ pípẹ́—òun ni èèrà kan tí wọ́n máa ń rí láwọn àgbègbè ilẹ̀ olóoru ní Amẹ́ríkà.

Nǹkan bíi mílíọ̀nù kan èèrà tó ń gé ewé sí wẹ́wẹ́ ló máa ń gbé inú ihò ńlá kan lábẹ́ ilẹ̀. Gbogbo àwọn èèrà wọ̀nyí ló ní iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ tàwọn kan ni pé kí wọ́n máa kó àwọn pàǹtírí ewé jọ, èyí tí àwọn mìíràn yóò jẹ lẹ́nu títí yóò fi rọ̀. Àwọn èèrà tó jẹ́ olùtọ́jú ọgbà á wá lo ewé tí wọ́n ti jẹ kúnná yìí láti fi gbin àwọn olú tó ṣeé jẹ nínú àwọn ihò wọn kéékèèké náà. Wọ́n tún máa ń palẹ̀ ohunkóhun tó bá lè tan àrùn kálẹ̀ mọ́, irú bí àwọn olú tó léwu, àwọn èèrà tó ti kú tàbí àwọn tó ti fẹ́ gbẹ́mìí mì, àtàwọn nǹkan mìíràn tó ti jẹrà. Àmọ́ ibo làwọn èèrà máa ń kó àwọn pàǹtírí wọ̀nyí dà sí?

Ìwé ìròyìn The Independent sọ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wà ní Yunifásítì Sheffield ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí o. Inú àwọn ihò ńláńlá kan tó wà nítòsí àwọn ihò táwọn èèrà tó jẹ́ olùtọ́jú ọgbà ti ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n ń kó àwọn ìdọ̀tí náà sí. Àwọn èèrà tó ń bójú tó àwọn pàǹtírí yìí kò ní iṣẹ́ méjì tí wọ́n ń ṣe jùyẹn lọ, tí wọ́n á máa yí àwọn pàǹtírí náà padà kó lè tètè jẹrà, èyí sì máa ń pa àwọn nǹkan tó ń fa àìsàn. Àwọn èèrà tó jẹ́ olùtọ́jú ọgbà kì í dé inú àwọn ihò tí pàǹtírí máa ń wà. Ńṣe ni wọ́n máa ń kó àwọn pàǹtírí náà wá sí ẹnu ihò kan, ibẹ̀ làwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí pàǹtírí á ti gbà á. Pípalẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ yìí ń dènà ẹ̀gbin èyíkéyìí, ó sì tún ń dáàbò bo ìlera àwọn èèrà tí wọ́n jọ ń gbé inú ihò náà.

Kì í ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run dá ọgbọ́n mọ́ àwọn kòkòrò nìkan ni, àmọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn, bákan náà ló ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn ìtọ́ni tó ní í ṣe pẹ̀lú ìlera, èyí tó gbéṣẹ́ gan-an. Fífi àwọn òfin yìí sílò á jẹ́ kí oúnjẹ àti omi wọn bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbin, á dáwọ́ àwọn àrùn tó lè tàn kálẹ̀ dúró, á sì jẹ́ kí wọ́n lè palẹ̀ ẹ̀gbin mọ́ lọ́nà tí kò mú ewu lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ ìyọnu àti ikú lá máa lè yẹra fún tá a bá tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀!—Léfítíkù 11:32-38; Númérì 19:11, 12; Diutarónómì 23:9-14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́