ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/22 ojú ìwé 26-27
  • Ewéko Yucca Aláradídán—Ewéko Tó Ṣeé Yí Pa Dà Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ewéko Yucca Aláradídán—Ewéko Tó Ṣeé Yí Pa Dà Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mẹ́ńbà Ìsọ̀rí Ewéko Bíbáratan
  • Ohun Jíjẹ Aládùn!
  • Lọ́fínńdà Ylang-Ylang—Nǹkan Olóòórùn-Dídùn Láti Erékùṣù Olóòórùn-Dídùn
    Jí!—1998
Jí!—1998
g98 1/22 ojú ìwé 26-27

Ewéko Yucca Aláradídán—Ewéko Tó Ṣeé Yí Pa Dà Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ COSTA RICA

EWÉKO àfiṣegbòogi, tó rí bí ọṣẹ, tó ládùn, tó sì ń ṣara lóore. Ewéko àrà ọ̀tọ̀ yí ní gbogbo ànímọ́ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn! Àwọn ará Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà mọ̀ ọ́n dunjú, ṣùgbọ́n wọn kì í pè é ní yucca aláradídán. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ pè é ní Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn wò ọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti bí ẹni tí ẹnu yà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ yóò rí kí wọ́n bú sẹ́rìn-ín tí ó fi hàn pé wọ́n mọ ohun tí o ń wí ní gbàrà tí o bá dárúkọ itabo, izote, tàbí daguillo, bí wọ́n ti mọ ewéko náà sí dáradára ní Costa Rica, Guatemala, Honduras, àti Nicaragua. Àwọn ará Costa Rica àti àwọn ará Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà míràn máa ń fi òdòdó rẹ̀ sínú oríṣiríṣi oúnjẹ.

Mẹ́ńbà Ìsọ̀rí Ewéko Bíbáratan

Nínú ohun tó jọ fàmí-n-fà-ọ́ kan, àwọn apín-ǹkan-sísọ̀rí ti pín ewéko yucca sí ìsọ̀rí àwọn ewéko Liliaceae, láìpẹ́ yìí ni wọ́n sì tún pín in sí ìsọ̀rí Agavaceae. Àwùjọ ti ìkẹyìn yí, tí ó wà fún àwọn ewéko tí ara wọn kò dán, ní nǹkan bí 550 irú ọ̀wọ́ láti inú ìsọ̀rí Liliales (lílì) nínú. Àwọn onímọ̀ nípa ewéko ti pe orúkọ rẹ̀ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Yucca elephantipes.

A fojú bù ú pé 40 irú ọ̀wọ́ ìsọ̀rí Yucca ló wà, tí a lè rí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ní Àríwá Amẹ́ríkà, Mexico, Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà, àti Gúúsù Amẹ́ríkà. Lára àwọn ìbátan wọn tí a mọ̀ dáradára ní igi Joshua ńlá (Yucca brevifolia) àti igi bayonet ti Sípéènì (Yucca aloifolia). Wọ́n mà pọ̀ nísọ̀rí náà ní tòótọ́ o!

Kí ni díẹ̀ lára àwọn àbùdá ewéko tó wúlò lọ́nà púpọ̀ yí? Ìrísí tí kò ní láárí, síbẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àwọn ewé rẹ̀ tó dúró gbagidi, tó sì gùn fi nǹkan bíi mítà kan yọ síta láti ara igi náà. Ara igi tó ki, tó ṣù mọ́ra náà, pẹ̀lú àbùdá onífọ́nrán àti àwọ̀ ilẹ̀ òun eérú rẹ̀, fara jọ ẹsẹ̀ iwájú erin—ìdí nìyẹn tí ó fi ní orúkọ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì náà, elephantipes.

Bí a bá kọ́kọ́ rí ewéko yucca aláradídán, tí gíga rẹ̀ wà láàárín mítà 4.6 sí 7.6 náà, ó rọrùn kí a fàṣìṣe pè é ní igi. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ní Costa Rica, ní pàtàkì láàárín oṣù February àti March, ọgọ́rọ̀ọ̀rún òdòdó tó rí bí agogo, tó ní àwọ̀ funfun òun ìyeyè, máa ń bo orí ewéko itabo. Bí wọ́n ti ń tà wọ́n ní ọjà, tí àwọn tí ń kiri ọjà ní pópó sì ń tà wọ́n, ó jọ pé ibi gbogbo la ti ń rí wọn nígbà kan náà! Láìdàbí àwọn ewé rẹ̀ tó gan, tó dà bí ẹnu ìbọn, àwọn òdòdó ẹlẹgẹ́ wọ̀nyí ń rú ní ìdìpọ̀ aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀, tí ń wà ní àárín ewéko náà gan-an, lóòró gangan, àti láìtẹ̀.

Ewéko itabo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn irú ọ̀wọ́ ewéko yucca tí àwọn olùtọ́jú ọgbà àti àwọn tí ń tún ìrísí ojú ilẹ̀ ṣe ń yàn láàyò, nítorí pé ó máa ń mú ara rẹ̀ bá oríṣiríṣi ipò ojú ọjọ́ àti ilẹ̀ mu, ó sì ń mú ìrísí àrà ọ̀tọ̀, ti ilẹ̀ olóoru, jáde. Nígbà kan rí, a ti fi ṣe ọgbà àdánidá láti pààlà ilẹ̀ ní Costa Rica, abájọ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹkùn ilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà ni ewéko itabo náà ti pọ̀ rẹpẹtẹ.

Ó dájú pé àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ ti kófà bí ewéko yìí ṣe wúlò lọ́nà púpọ̀ yí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn fọ́nrán tí wọ́n ń yọ lára ewé rẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe ẹní, bẹ́líìtì, àti àpò ìkẹ́rùsí. Bákan náà, bí wọ́n bá se ewé yìí dé àyè kan, àwọn olùtọ́jú ọgbà lè lò ó bí okùn tí wọ́n fi ń di irè oko wọn. Ó jọ pé ìwúlò ewéko yìí kò lópin!

Ohun Jíjẹ Aládùn!

Frances Perry, tó kọ ìwé Flowers of the World, sọ pé: “Àwọn Àmẹ́ríńdíà ń jẹ àwọn ìrudi òdòdó àwọn irú ọ̀wọ́ Yucca, àwọn èso àti gbòǹgbò rẹ̀ sì ṣeé fọ nǹkan [tó rí bí ọṣẹ] tó bẹ́ẹ̀ tí a lè fi wọn fọ aṣọ.” Àwọn ará Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà ti lo àwọn ànímọ́ ìpèsè oúnjẹ àti ti ìṣeéfọǹkan tí ewéko yucca ní gidigidi. Wọ́n ń gbádùn ìtọ́wò rẹ̀ tó kan lọ́nà kan, síbẹ̀ tó mú lẹ́nu, tó sì ń pẹ́. Wọ́n ń fi òdòdó náà sínú àwọn sàláàdì tí wọ́n ń jẹ ní tútù, wọ́n sì ń sè é pọ̀ mọ́ ẹyin àti ọ̀dùnkún, irú oúnjẹ kan tí àwọn ará Costa Rica àti àwọn ará Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà míràn kúndùn. Ewéko yucca ń ṣara lóore nítorí pé ó ní ọ̀pọ̀ èròjà fítámì àti mínírà bíi calcium, iron, thiamine, phosphorous, àti riboflavin lọ́pọ̀ yanturu nínú.

Ti pé ewéko yucca ṣeé fi ṣe egbòogi tún gbàfiyèsí; tọ́níìkì kan tí a ń ṣe nípa síse òdòdó rẹ̀, àti títẹ́ ẹ sómi ń mú inú tuni. A lè fi ewé rẹ̀ ṣèwòsàn àrùn albuminuria àti ìfun ńlá tí ń wú, a sì lè lò ó láti mú kí ènìyàn máa tọ̀ dáadáa. Ewéko àfiṣegbòogi, tó rí bí ọṣẹ, tó ládùn, tó sì ń ṣara lóore yìí sì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú àwọn ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé tí a lè jàǹfààní adùn wọn ni!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àsèpọ̀ òdòdó “yucca,” ẹyin òun ọ̀dùnkún, oúnjẹ kan tí a kúndùn ní Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn “yucca” tí ń hù ní àrọko ń dà bí igi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́