Lọ́fínńdà Ylang-Ylang—Nǹkan Olóòórùn-Dídùn Láti Erékùṣù Olóòórùn-Dídùn
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MAYOTTE
ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí o ti lò ó rí. Ó kéré tán, o ti gbóòórùn rẹ̀ rí! Kí ni? Kò burú, igi kan ni, ó tún jẹ́ lọ́fínńdà.
Igi ylang-ylang (ēläng-ēʹläng) máa ń pèsè èròjà kan tí a fi ń ṣe àwọn lọ́fínńdà olówó ńlá. Àwọn kan sọ pé erékùṣù Madagascar ló ti wá; àwọn mìíràn sọ pé Malaysia tí a tún ti ń ṣọ̀gbìn rẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n níbí, ní àwọn Erékùṣù Comoro tó wà láàárín Áfíríkà àti Madagascar, ní pàtàkì, ní Erékùṣù Mayotte, ojú ọjọ́ wulẹ̀ bá ṣíṣe èròjà lọ́fínńdà tó dára ta yọ mu ni—àwọn kan sọ pé, òun ló dára jù lágbàáyé.
Mayotte, tí a ń pè ní erékùṣù olóòórùn-dídùn nígbà mìíràn, ni a ti ń mú ìpín tó pọ̀ jù lágbàáyé nínú èròjà oníyebíye yìí wá. Àwọn igi ylang-ylang kún àwọn oko àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn òkè erékùṣù rírẹwà yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun àkọ́kọ́ tí ènìyàn ń kíyè sí ni ìrísí igi náà tí kò wuni. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ dà bí ìgbà tí òmìrán kan ti tẹ̀ wọ́n lọ sílẹ̀, tí ó wá lọ́ wọn yíká igi aláwọ̀ eérú ràkọ̀ràkọ̀, tí kò ga náà. Àmọ́ èyí kì í ṣe ìrísí àdánidá rẹ̀. Díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n yí i padà, tó fi dà bẹ́ẹ̀.
Ní gbàrà tí igi ylang-ylang bá ti ga dé ìwọ̀n èjìká ènìyàn, tí ọwọ́ fi lè tó àwọn òdòdó rẹ̀ dáradára, wọ́n ń fipá tẹ àwọn ẹ̀ka náà wálẹ̀. Bí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, igi náà yóò tọ́, yóò sì ga, ọwọ́ kò sì ní lè tètè tó àwọn òdòdó oníyebíye rẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, gẹdú nìkan ni igi náà yóò wúlò fún.
Kódà, kí o tó dá igi ylang-ylang mọ̀ láàárín àwọn igi ilẹ̀ olóoru náà, òórùn dídùn rẹ̀ ni yóò kọ́ gba àfiyèsí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òdòdó rẹ̀ kò lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀, òórùn dídùn tí wọ́n ní kò ṣeé gbàgbé. Dájúdájú, àjèjì kò lè tètè rí àwọn òdòdó náà, nítorí wọ́n ṣòro mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn ewé. Ìgbà tí àwọn òdòdó náà bá gbó ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń ní àwọ̀ ìyeyè rẹ́súrẹ́sú. Bí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n tó já nìyẹn.
Ní erékùṣù ilẹ̀ olóoru wa, igi ylang-ylang máa ń bẹ̀rẹ̀ sí yọ òdòdó tó bá pé ọdún méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ti gbìn ín. Bí àwọn òdòdó rẹ̀ ti ń pọ̀ tó jẹ́ àgbàyanu àpẹẹrẹ bí Ẹlẹ́dàá ti lawọ́ tó! Láàárín oṣù May sí December, wọ́n máa ń já òdòdó tí ó tó kìlógíráàmù kan sí méjì lórí igi kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún-kẹẹ̀ẹ́dógún. Ó tún máa ń yọ òdòdó láti January sí April, ṣùgbọ́n òjò ilẹ̀ olóoru ní ń ba ìwọ̀nyí jẹ́.
Ìdílé lápapọ̀, pàápàá àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, ló ń ṣiṣẹ́ jíjá àwọn òdòdó náà. Ó rọrùn láti já wọn nítorí pé àwọn ẹ̀ka náà kò ga. A ń kó àwọn òdòdó náà sínú kangas—orúkọ tí àwọn ará àdúgbò ń pe apẹ̀rẹ̀ ńlá kan tí a ń fi ewé àgbọn hun. Ǹjẹ́ o lè finú wòye ọmọ kan tí ó ru kangas tí ara rẹ̀ rọ̀, tí òdòdó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ní àkúnwọ́sílẹ̀? Ó dà bí pé ẹrù òdòdó 20 sí 30 kìlógíráàmù náà ti mú orí rẹ̀ mù bí ó ṣe ń bá àwọn mìíràn rìn lọ lórí ìlà kan ṣoṣo lójú ọ̀nà ibi tí wọn yóò ti yọ èròjà náà.
Ìgbà yí ni iṣẹ́ àṣekára oníwákàtí 24 wá bẹ̀rẹ̀ láti yọ èròjà náà. Iná á máa jó nídìí apẹ alambic gìrìwò kan, tàbí èlò ìpọntí kan. Nínú apẹ alambic náà, 200 kìlógíráàmù òdòdó tó ti gbó á máa hó nínú omi 70 lítà. Ọ̀pá ìpọntí náà gbọ́dọ̀ tutù dé ìwọ̀n tó yẹ kí èròjà náà lè rí bó ṣe yẹ gẹ́lẹ́. A lè yọ tó lítà kan ògidì èròjà yìí láti inú ìwọ̀n òdòdó yìí, àgbègbè tí a ti mú un wá ló ń pinnu bí yóò ṣe pọ̀ tó gan-an. A tún lè yọ èròjà díẹ̀ tí kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ láfikún sí i láti inú apẹ kan náà. Níkẹyìn, a ń fi èròjà náà ránṣẹ́ sí Yúróòpù, níbi tí wọ́n ti ń pò ó mọ́ àwọn lọ́fínńdà olówó ńlá.
Bóyá o ti wá lè mọ ìdí tí a fi ń pe erékùṣù Mayotte ní erékùṣù olóòórùn-dídùn. Ní tòótọ́, òórùn dídùn igi ylang-ylang tó wá nínú afẹ́fẹ́ erékùṣù wa túbọ̀ ń mú kí a mọyì iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÁFÍRÍKÀ
MADAGASCAR
Comoro Ńlá
ÀWỌN ERÉKÙṢÙ COMORO
Anjouan
Mohéli
Mayotte
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn òdòdó igi “ylang-ylang”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Oko ọ̀gbìn igi “ylang-ylang”