Àwọn Òdòdó Ń fi Hàn Pé Ẹnì Kan Bìkítà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ COLOMBIA
Ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ kan tí inú rẹ̀ dùn ṣa ìdì òdòdó “buttercup” sọ́wọ́ rẹ̀ tí ó dì bọ̀ǹbọ̀, ó sì sáré kó ohun iyebíye tí ó rí náà lọ bá Mọ́mì. Ní ibi ìtajà kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ọkọ onífẹ̀ẹ́ kan ṣa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òdòdó “rose” tí ó fẹ́ lọ fún aya rẹ̀, láti fi bí ó ṣe bìkítà tó hàn án. Ọmọkùnrin kan tí ó lẹ́mìí ìmọrírì tẹ ẹnì kan tí ń ta òdòdó ládùúgbò láago láti ra òdòdó “pompon” tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ já láti mú kí inú ìyá rẹ̀ dùn. Ìyàwó ilé kan tí ń ṣiṣẹ́ tọkàntara gbé ìdì irúgbìn òdòdó “carnation” aláwọ̀ oríṣiríṣi sórí kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rùsí nílé ìtajà ńlá. Wọn óò fi kún ẹwà ilé rẹ̀ tí ó ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ dáradára.
ÒDÒDÓ máa ń mú ọ̀kan tọmọdétàgbà yọ̀. Wọ́n jẹ́ ọ̀nà gíga kan láti gbé èrò náà pé “Ẹnì kan bìkítà” yọ. Òwe ilẹ̀ Sípéènì kan ti sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí a bá fún ní òdòdó rose tí kò dúpẹ́, bí a bá fún un ní ohunkóhun mìíràn, kò ní dúpẹ́.” (Quien no agradece una rosa, no agradecerá ninguna cosa.)
Òdòdó ń tà gan-an ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Ní sànmánì ìrìnnà lójú òfuurufú yíyára kánkán yìí, a lè gbin òdòdó ní àwọn ibi tí ó jìnnà sí ilé ìtajà, ilé ìtajà ńláńlá, àti ibi ìtajà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, níbi tí wọ́n ti ń gba àfiyèsí àwọn tí ń kọjá. Ìwé ìròyìn Time sọ pé, àwọn tí ń ta òdòdó “ń yára pọ̀ sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń yí pa dà sí i: púpọ̀púpọ̀ sí i ìṣèmújáde náà ń wá láti apá ìsàlẹ̀ ìlàjì ayé—èyí tí ó pọ̀ jù lọ jẹ́ láti Colombia, tí ó ti mú ipò kejì tẹ̀ lé Holland lára àwọn tí ń kó o lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.”
Àwọn Ibi Ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ Irúgbìn Tí A Fi Ike Bò àti Àwọn Adágún Àtọwọ́dá
Nítorí tí Colombia ti lo ohun tí ó lé ní ọdún 25 nínú òwò náà, ó ń mú ipò iwájú lágbàáyé nínú kíkó àwọn irúgbìn òdòdó carnation lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, nígbà tí ó jẹ́ pé ipò kejì ló wà nínú títa òdòdó lágbàáyé. Ní 1964, akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì kan ní California, U.S.A., fi kọ̀ǹpútà ṣe ìwádìí kan láti mọ àwọn àyíká ibi tí ó dára jù lọ fún ọ̀gbìn òdòdó yíká ọdún. Ó ṣàwárí pé ipò ojú ọjọ́ àti gíga òkè tí Bogotá wà, ní àríwá agbedeméjì ayé, tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó 2,600 mítà ní Òkè Ńlá Andes, ní ipò tí ó bára dé.
Ọ̀dàn títutù yọ̀yọ̀ lọ́nà yíyani lẹ́nu ní Santa Fe de Bogotá, níbi tí ìpín 92 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọ̀gbìn òdòdó Colombia tí a ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè wà, ní àwọn adágún àtọwọ́dá àti àwọn ibi ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ irúgbìn tí a fi ike bò. Nínú ohun onípákó tàbí onírin wọ̀nyí, àyíká ìgbà ìrúwé tí a fìṣọ́ra darí kan ń mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀gbìn òdòdó carnation, pompon, rose, chrysanthemum, alstroemeria, àti ọ̀pọ̀ onírúurú mìíràn, tí a óò gé láìpẹ́, tí a óò sì dì wọ́n lọ sí Àríwá America, Europe, àti Asia, dàgbà.
Ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù tí ó dára jù lọ fún ìṣọ̀gbìn òdòdó jẹ́ láàárín ìwọ̀n 18 sí 20 lórí òṣùwọ̀n Celsius, ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù tí ó sábà máa ń wà lójúmọmọ jálẹ̀ ọdún nínú ọ̀dàn náà. Níhìn-ín, omi òjò pọ̀ gidigidi, ilẹ̀ náà lọ́ràá, owó tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà kò sì wọ́n. Lọ́wọ́ alẹ́, ìwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù lè lọ sílẹ̀ sún mọ́ ìpele títutù nini, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó sì lè lọ sísàlẹ̀ oódo sí ìwọ̀n -2 títutù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n Celsius. Àwọn ìkòkò ìfidínà-atẹ́gùn, àwọn iná alágbára gíga, tàbí àwọn ohun afọ́nmi ni a fi ń dènà òtútù. Àwọn iná náà pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ láti mú kí wákàtí tí ìmọ́lẹ̀ fi wà pọ̀ sí i, tí èyí ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn irúgbìn kan wà láìsùn kí ìdàgbàsókè wọn sì yára.
A Ti Ṣètò Ìṣèmújáde Tipẹ́tipẹ́
Ó lé ní 120,000 òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú àwọn apá kan ilé iṣẹ́ òdòdó náà ní Colombia. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń gbé ní àwọn àdúgbò tí ó wà káàkiri ọ̀dàn náà pọ̀ lára wọn. Benito Quintana, Kristẹni alàgbà kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní Facatativá, ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìṣèmújáde ní ibi ọ̀gbìn kan. Ó ṣàlàyé pé: “Ní àwọn oṣù díẹ̀ ṣáájú ni a óò ti ṣètò ìṣèmújáde láti kájú ohun tí àwọn òǹrajà ń fẹ́ lákòókò náà. Àwọn igi ńlá fún irúgbìn òdòdó carnation ni a ń kó wọlé láti Holland tàbí Ítálì, òdòdó pompon láti Florida. Àwọn obìnrin ń gé àwọn ọ̀mùnú kéékèèké tìṣọ́ratìṣọ́ra, wọ́n sì ń gbìn wọ́n ní ìlà ebè nínú ibi ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ irúgbìn tí a fi ike bò, tí ó lọ́ wọ́ọ́wọ́, níbi tí ìrì tí ó dà bí ìkùukùu ti ń fomi rin wọ́n títí wọn óò fi ta gbòǹgbò. Àwọn òdòdó pompon ń gba ọjọ́ 12 ní ìpele ìgbóná-òun-ìtutù 20 sí 35 lórí òṣùwọ̀n Celsius (68 sí 95 lórí òṣùwọ̀n Fahrenheit), pẹ̀lú àfikún ìmọ́lẹ̀ wákàtí méjì ní alẹ́. Àwọn irúgbìn òdòdó carnation ń gba ọjọ́ 23 ní ìwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù tí ó wà láàárín ìwọ̀n 15 sí 25 lórí òṣùwọ̀n Celsius (59 sí 77 lórí òṣùwọ̀n Fahrenheit), láìsí ìmọ́lẹ̀ ní alẹ́. Lẹ́yìn náà, a óò gbé àwọn irúgbìn kéékèèké lọ sí ibi tí a óò gbìn wọ́n sí ní àwọn ibi ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ míràn níbi tí wọn óò ti gba àwọn èròjà aṣaralóore, tí a óò ti da oògùn apakòkòrò sí wọn lára, tí a óò sì bomi rin wọ́n títí wọn óò fi yọ òdòdó, èyí yóò gba àwọn irúgbìn òdòdó carnation ní oṣù mẹ́fà, yóò sì gba àwọn òdòdó pompon ní oṣù mẹ́ta.”
Iṣẹ́ Àṣekára ní Sáà Tí Ọwọ́ Dí Gan-an
Tí ó bá di ìgbà gígé òdòdó, àwọn obìnrin ní ń ṣiṣẹ́ náà dáradára jù lọ, wọ́n sì máa ń yàn láti má lo ìbọ̀wọ́, ní lílo ọwọ́ tí wọ́n ti fọ̀ mọ́ tónítóní. Àwọn ẹ̀rọ kò lè pinnu bí àwọn ìrudi náà ṣe là tó tàbí bí àwọn ìtì náà ṣe tọ́ tó, àwọn ohun tí ń pinnu ìjójúlówó òdòdó náà.
Judith Corredor, láti Facatativá, ṣàlàyé pé: “Àwọn obìnrin ní sùúrù àti ọ̀nà ìfọwọ́kan nǹkan lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, wọ́n sì ní ìwọ̀n ìyára àti òye iṣẹ́ tí a nílò.” Judith ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí a wọ ibi ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ irúgbìn náà ní ìrọ̀lẹ́, ọ̀wọwọ omi ló sábà máa ń bo ọ̀dàn náà; ó lè tutù gan-an, kódà dé ìwọ̀n títutù nini. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọdébìnrin náà ló máa ń ta aṣọ mọ́rí. Ní ojúmọmọ, ó máa ń lọ́ wọ́ọ́wọ́, nígbà míràn, ó máa ń sún mọ́ ìpele tí ó lé ní ìwọ̀n 90 lórí òṣùwọ̀n Fahrenheit [ìwọ̀n 32 lórí òṣùwọ̀n Celsius]. Iṣẹ́ àṣekára ni, ní pàtàkì ní àkókò tí ọwọ́ dí gan-an nígbà tí a ń kánjú tí a sì ní láti ṣe àṣekún iṣẹ́.”
Ìhìn Iṣẹ́ Olóòórùn Dídùn Tí Ó Sì Jojú Ní Gbèsè
Lẹ́yìn tí a bá ti gé òdòdó náà, a óò kó o lọ sí àkànṣe iyàrá kan níbi tí afẹ́fẹ́ àti ìmọ́lẹ̀ gbé pọ̀. Níhìn-ín ni àwọn obìnrin tí máa ń ṣà wọ́n, wọ́n sì ń fi wọ́n sí ìsọ̀rí tí ó yẹ ní ìbámu pẹ̀lú bí ìtànná òdòdó náà ṣe jẹ́ ojúlówó sí àti bí ó ṣe tọ́, tí ó nípọn, àti bí àwọn ìtì náà ṣe gùn tó. Lẹ́yìn náà ni a óò fi rọ́bà mímọ́lẹ̀ kadara wé àwọn òdòdó náà, 25 nínú ìdì kan, ó ti yá láti dì í. Àwọn tí ó dára jù lọ nìkan ni a óò yàn láti kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.
Àwọn ọkùnrin ń di àwọn òdòdó náà sínú àkànṣe àpótí onípáálí tí wọ́n dáhò sí lára, tí orúkọ ibi ìṣọ̀gbìn náà wà lára rẹ̀—ìdì irúgbìn òdòdó carnation 24 nínú àpótí. Ẹ̀gbọ́n Benito ọkùnrin, Alejandro Quintana, tí ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń dì í, sọ pé: “A ní láti yára ṣiṣẹ́, níwọ̀n bí òdòdó ti wà lára àwọn irúgbìn tí ó tètè máa ń bà jẹ́ jù lọ. Ilé iṣẹ́ wa ní ẹ̀rọ méjì tí ó máa ń fa afẹ́fẹ́ lílọ́wọ́ọ́wọ́ kúrò nínú àwọn àpótí náà, ó máa ń fa ti àpótí 112 lẹ́ẹ̀kan náà, bí wọ́n ti ń ti afẹ́fẹ́ tútù wọlé fún wákàtí méjì, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dín ìwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù àwọn òdòdó kù sí ìwọ̀n díẹ̀ ré kọjá ìpele títutù nini. Lẹ́yìn náà, wọn óò dí àwọn ihò tí ó wà lára àwọn àpótí náà, wọ́n óò sì kó àwọn òdòdó náà sí ibi títutù títí wọn óò fi kó wọn sínú ọkọ̀ akẹ́rù láti kó wọn lọ sí ibùdókọ̀ òfuurufú.”
Ní Ibùdókọ̀ Òfuurufú Ńlá El Dorado ní Bogotá, wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn òdòdó náà bí ẹrù tí a ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá kó wọn sí ibi ìtọ́júpamọ́ títutù fún wákàtí bíi mélòó kan, títí wọn óò fi kó àwọn ẹrù náà sínú àwọn ọkọ̀ òfuurufú ńláńlá tí yóò gbé wọn lọ sí àwọn ibi tí a óò ti pín wọn ní ilẹ̀ òkèèrè. Láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan péré, àwọn òdòdó yìí yóò máa rúwé nínú àwọn ilé, ọ́fíìsì, iyàrá aláìsàn, àti níbòmíràn, tí wọn yóò sì máa gbé ìhìn iṣẹ́ olóòórùn dídùn, tí ó sì jojú ní gbèsè, jáde pé ẹnì kan bìkítà.
Ẹni Tí Ó Bìkítà Ní Tòótọ́
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ibi tí a bá lọ lórí ilẹ̀ ayé ni a ti ń rí òdòdó fún ìgbádùn ara wa. A ń rí wọn lórí àwọn òkè ńlá ní èteetí àwọn ibi tí òjò dídì àti ìṣàn òkìtì yìnyín gbé wà, nínú àwọn igbó àti ilẹ̀ eléwéko tútù, lẹ́bàá àwọn omi tí ń ṣàn àti odò, ní etíkun, kódà ní àwọn aṣálẹ̀ gbígbẹ, tí ó gbóná pàápàá. Àwọn òdòdó ti wà níhìn-ín fún ìgbà pípẹ́ kí a tó dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Àwọn onímọ̀ nípa ewéko fi ìtẹnumọ́ kéde pé, ‘àwọn irúgbìn tí ń yọ òdòdó ni ìpìlẹ̀ fún ìwàláàyè gbogbo ẹranko àti ẹ̀dá ènìyàn. Láìsí wọn, àwọn ẹranko àti ènìyàn kò lè wà láàyè.’
Ọba Sólómọ́nì fi ìfòyemọ̀ polongo pé: ‘Ọlọ́run ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní ìgbà tirẹ̀.’ (Oníwàásù 3:11) Èyí ní nínú, onírúurú òdòdó, tí í ṣe ẹ̀bùn Ọlọ́run, nínú ìtànná ọlọ́láńlá wọn. Látayébáyé ni wọ́n ti ń mú ọkàn tọmọdétàgbà yọ̀. Ní tòótọ́, Ọlọ́run bìkítà gidigidi!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Láti Mú Kí Àwọn Òdòdó Wà Pẹ́ Títí
• Gé àwọn ìtì rẹ̀ ní ìdẹ̀gbẹ́ lábẹ́ omi kí o tó fi òdòdó sínú àgé òdòdó. Bí ẹ̀kán omi bá wà nídìí ìtì náà kò ní jẹ́ kí afẹ́fẹ́ wọlé, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ dínà fún omi àti àwọn èròjà aṣaralóore tí ó ṣì ń bọ̀ wá wọlé.
• Ìwé ìròyìn GeoMundo fa ọ̀rọ̀ tí àwọn onímọ̀ nípa òdòdó ará Colombia wí yọ pé, tí a bá fi tábúlẹ́ẹ̀tì aspirin kan, ẹ̀kún ṣíbí ṣúgà kan, tàbí ìwọ̀nba cola díẹ̀ sínú omi yóò mú kí òdòdó wà lọ́tun fún ìgbà pípẹ́. Máa pààrọ̀ omi ní ọjọ́ kejì-kejì tàbí ọjọ́ kẹta-kẹ́ta, ní lílo omi tí ìwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù rẹ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lo omi lílọ́ wọ́ọ́wọ́ láti mú kí ó yára rudi.
• A lè mú àwọn ìtànná òdòdó tí wọ́n rọ díẹ̀ sọ jí nípa kíki ìtì náà bọ inú omi gbígbóná fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá nígbà tí a ń wọ́n omi tútù sára àwọn ewé rẹ̀. Gbé àwọn òdòdó kúrò níbi tí ooru ti ń wá, kúrò lójú afẹ́fẹ́, àti kúrò lábẹ́ ìtànṣán oòrùn tààràtà.