Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Nigba ti ẹnikan ba kú, o ha tọna fun awọn Kristẹni lati fun idile naa ni òdòdó tabi lati fi òdòdó ranṣẹ si ile isinku naa?
Ni awọn ilẹ kan o jẹ aṣa lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn lilo òdòdó ni ibi isinku nigba miiran ti ni itumọ onisin. Nitori naa ẹ jẹ ki a ṣayẹwo ọran naa ni kulẹkulẹ diẹ sii, paapaa julọ niwọn igba ti awọn aṣa miiran ti wà ti o le dabi eyi ti o ni isopọ fifarajọra si isin eke. Ṣakiyesi awọn àlàyé diẹ lati inu iwe naa The Encyclopedia of Religion (1987):
“Awọn òdòdó ni isopọ pẹlu ilẹ ọba mimọ nipasẹ idapọ wọn pẹlu awọn ọlọrun ati awọn abo ọlọrun. Flora, abo ọlọrun Roomu ti akoko ìrúwé ati awọn òdòdó, nmu ẹwa ati itasansan gbèrú . . . Awọn ọlọrun àkúnlẹ̀bọ ni a le tù loju ki a si bọ . . . nipasẹ pipese ounjẹ ati awọn òdòdó.
“Isopọ òdòdó pẹlu awọn ààtò isin oku nṣẹlẹ ni gbogbo aye. Awọn Giriiki ati awọn ara Roomu nfi òdòdó bo oku ati iboji wọn. Awọn ọkan ti nku lọ ti awọn onisin Buddha ni Japan ni a gbe lọ soke lori lotus [igi olódòdó] kan, awọn okuta iboji ni ibi isinku si lè farati awọn igi lotus ti a gbẹ́ . . . Awọn ara Tahiti a maa fi ìṣùpọ̀ òdòdó ti a wé sinu yẹtuyẹtu ewéko silẹ lẹgbẹ ara oku lẹhin iku ti wọn a si da lọfinda olooorun òdòdó sara oku lẹhin naa lati mu ki ikọja rẹ̀ lọ sinu iwalaaye lẹhin iku ti o jẹ mimọ rọrun . . . Awọn òdòdó tun le wà ni awọn akoko mímọ́ gẹgẹ bii turari tabi lọfinda.”
Ni mimọ pe awọn òdòdó ni a ti lò ni isopọ pẹlu ijọsin eke, awọn Kristẹni kan le nimọlara pe awọn kò nilati fifunni tabi fi òdòdó ranṣẹ si ibi isinku kan. Imọlara wọn tun le fi ifẹ ọkan lati yẹra fun awọn aṣa aye han, niwọn igba ti awọn ọmọlẹhin Jesu ‘kii tii ṣe apakan aye.’ (Johanu 15:19, NW) Bi o ti wu ki o ri, awọn akọsilẹ ẹsẹ iwe Bibeli ti o tan mọ ọn ati awọn ero adugbo nipa lori ọran naa.
Awọn òdòdó jẹ apakan ẹbun rere ti Ọlọrun fun awọn alaaye lati gbadun. (Iṣe 14:15-17; Jakọbu 1:17) Ẹwà ti òdòdó rẹ̀ ti o dá ni a ti lò ninu ijọsin tootọ. Ọpa fitila ninu agọ isin ni a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu “itanna alimọndi . . . ati iruwe.” (Ẹkisodu 25:31-34, NW) Awọn ohun ti a figi gbẹ ninu tẹmpili naa ní itanna ati igi ọpẹ nínú. (1 Ọba 6:18, 29, 32) Ni kedere, lilo awọn òdòdó ati itanna birikiti lọna oloriṣa kò tumọsi pe awọn olujọsin tootọ nilati maa yẹra fun lilo wọn nigba gbogbo.—Iṣe 14:13.
Bi o ti wu ki o ri, ki ni nipa ọran gbigbooro jù ti titẹle awọn aṣa, iru bii awọn aṣa isinku? Bibeli tọka si ọpọlọpọ awọn aṣa, awọn kan kò bojumu fun awọn olujọsin tootọ, ti awọn eniyan Ọlọrun si ntẹle awọn miiran. Ọba Kìn-ín-ní 18:28 tọka si “aṣa” awọn olujọsin Baali ti ‘kikigbe lohun rara ti wọn si nfi ọbẹ ati ọ̀kọ̀ ya araawọn’—aṣa ti awọn olujọsin tootọ ki yoo tẹle. Ni ọwọ keji ẹwẹ, Ruutu 4:7 (NW) ko damọran ṣiṣaifọwọsi “aṣa igba atijọ ni Isirẹli nipa [ọna lilo] ẹtọ itunrapada.”
Awọn aṣa ti Ọlọrun fọwọ si tilẹ le gbèrú ninu awọn ọran isin patapata gbáà. Nigba ti Ọlọrun la ayẹyẹ Irekọja lẹsẹẹsẹ, oun ko mẹnukan ilo waini, ṣugbọn ni ọgọrun un ọdun kìn-ín-ní, o jẹ aṣa lati lo awọn ago ọti waini. Jesu ati awọn apọsiteli rẹ kò ṣá aṣa onisin yii tì. Wọn ko ri i pe o lodi. Wọn sì tẹ̀lé e.—Ẹkisodu 12:6-18; Luuku 22:15-18; 1 Kọrinti 11:25.
O baramu pẹlu awọn aṣa isinku diẹ. O jẹ aṣa awọn ara Ijibiti lati fi ọṣẹ kun oku wọn. Josẹfu babanla oluṣotitọ naa ko huwapada lọna ainironu pe, ‘aṣa abọriṣa niyii, nitori naa awa Heberu gbọdọ yẹra fun un.’ Kaka bẹẹ, o “paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki wọn ki o kun baba rẹ̀ ni ọṣẹ.” Ni kedere ki a baa lè sin Jakọbu si Ilẹ Ileri. (Jẹnẹsisi 49:29-50:3) Awọn Juu lẹhin naa mu oriṣiriṣi aṣa isinku dàgbà, iru bii wiwẹ ara oku ati sisin in ni ọjọ ti o ku. Awọn Kristẹni ijimiji tẹwọgba iru awọn aṣa Juu bẹẹ.—Iṣe 9:37.
Bi o ti wu ki o ri, ki ni bi a ba ri aṣa isinku kan gẹgẹ bi eyi ti o ni itumọ ti a gbekari aṣiṣe isin, iru bii igbagbọ ninu aileeku ọkàn? Pè é sọkan pada lati inu iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa pe awọn kan “fi iṣupọ òdòdó ti a wé sinu yẹtuyẹtu eweko silẹ lẹgbẹ ara oku lẹhin iku ti wọn a si da lọfinda olooorun òdòdó sara oku lẹhin naa lati mu ki ikọja rẹ̀ lọ sinu iwalaaye lẹhin iku ti o jẹ́ mimọ rọrun.” Pe iru aṣa kan bẹẹ le wà ko tumọ si pe awọn iranṣẹ Ọlọrun gbọdọ ṣá ohunkohun ti o farajọ ọ tì. Nigba ti awọn Juu ko gbagbọ ninu “ikọja lọ sinu iwalaaye lẹhin iku ti o jẹ mimọ,” Bibeli wi pe: “Wọn gbe oku Jesu, wọn si fi aṣọ ọgbọ dii pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Juu ti ri ni isinku wọn.”—Johanu 12:2-8; 19:40.
Awọn Kristẹni nilati yẹra fun awọn àṣà ti o forigbari pẹlu otitọ Bibeli. (2 Kọrinti 6:14-18) Sibẹ, gbogbo iru aworan, ọnà, ati awọn àṣà ni a ti fun ni itumọ eke, ni awọn igba kan tabi ni awọn ibikan tabi ki a ti so ó pọ̀ pẹlu awọn ẹkọ ti ko ba iwe mimọ mu. Awọn igi ni a ti bọ, irisi ọkan-aya ni a ti wò bi ohun mimọ, turari ni a si ti lò ninu awọn ayẹyẹ oloriṣa. Eyi ha tumọ si pe Kristẹni kan kò gbọdọ lo turari, ní awọn igi ninu ọṣọ eyikeyii, tabi wọ ohun ọṣọ ti a ṣe ni irisi ọkan-aya bi?a Iyẹn kii ṣe ipari ero ti o fidimulẹ.
Kristẹni ojulowo kan nilati ṣagbeyẹwo pe: Njẹ titẹle aṣa kan ha lè fihan awọn ẹlomiran pe mo ti tẹwọgba awọn igbagbọ ati àṣà ti kò bá iwe mimọ mu bi? Saa akoko ati ibi ti a wà le nipa lori idahun naa. Aṣa kan (tabi iṣẹ́ ọnà) ti le ni itumọ isin eke ninu ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹhin tabi ti le ni iru rẹ̀ lonii ni ilẹ jijinna réré kan. Ṣugbọn lai lọ sinu iṣayẹwo ti o gba akoko, beere lọwọ araarẹ pe: ‘Ki ni oju iwoye ti o wọpọ nibi ti mo ngbe?’—Fiwe 1 Kọrinti 10:25-29.
Bi a ba mọ ọn daradara pe aṣa kan (tabi iṣẹ ọnà kan, iru bii agbelebuu) ni itumọ isin eke, yẹra fun un. Awọn Kristẹni ki yoo maa tipa bayii fi òdòdó ranṣẹ gẹgẹ bi agbelebuu kan, tabi ọkan-aya pupa bi a ba foju wo iyẹn bi eyi ti o ni ijẹpataki ti isin. Tabi ọna kan ti o fidimulẹ le wà ninu eyi ti a ti nlo òdòdó ni ibi isinku tabi lẹ́bàá iboji ti o ni itumọ isin ni adugbo. Awọn Kristẹni gbọdọ yẹra fun iyẹn pẹlu. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn ko tumọ si pe wiwulẹ pese iṣupọ òdòdó ni ibi isinku tabi fifun ọrẹ kan ni òdòdó ni ile iwosan ni a gbọdọ wò bi iṣe onisin ti a sì gbọdọ yẹra fun.b
Ni odikeji ẹwẹ, ni ọpọlọpọ ilẹ aṣa pipese òdòdó gbalẹ kaakiri a sì nwo o bii inurere kan ti o bojumu. Awọn òdòdó lè fikun ẹwà o si le mu iṣẹlẹ bibanininujẹ kan di eyi ti o tubọ gbadunmọni sii. Wọn tun le jẹ ifihan ibanikẹdun ati ibikita. Nibomiran aṣa naa le jẹ lati fi iru ero bẹẹ han nipa iṣe ọlọlawọ, iru bii pipese ounjẹ fun alaisan tabi ẹni ti nbanujẹ. (Ranti ifẹni ti a nimọlara rẹ̀ fun Dọkaasi nitori pe o fi ifẹ rẹ̀ ati idaniyan rẹ̀ ninu awọn ẹlomiran han. [Iṣe 9:36-39]) Nigba ti ṣiṣe bẹẹ ni kedere ko sopọ mọ awọn igbagbọ eke, diẹ lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni pipese awọn òdòdó títutù yọ̀yọ̀ fun ọrẹ kan ti o wa ni ile iwosan tabi ninu ọran iku kan ti mọ́ lara. Ati lẹnikọọkan wọn le fi ifẹ ati imọlara wọn han sode nipa awọn iṣe ti o bọgbọnmu.—Jakọbu 1:27; 2:14-17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Awọn abọriṣa ti nlo turari olódòdó tipẹtipẹ ninu awọn ayẹyẹ wọn, ṣugbọn ko lodi fun awọn eniyan Ọlọrun lati lo turari ninu ijọsin tootọ. (Ẹkisodu 30:1, 7, 8; 37:29; Iṣipaya 5:8) Tun wo “Nwọn Ha Jẹ Awọn Ọṣọ Ti Ibọriṣa Bi?” ninu Ji! ti August 8, 1977.
b Ifẹ idile naa ni a nilati gbeyẹwo, nitori awọn kan sọ ọ di mimọ pe ẹnikẹni ti o ba fẹ lati fi òdòdó ranṣẹ nilati ṣe idawo sinu ijọ dipo bẹẹ tabi sinu eto-ajọ onitọrẹ aanu kan bayii.