ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 28-29
  • Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Àwọn Àṣà Olókìkí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Àwọn Àṣà Olókìkí
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Àṣà Ìbílẹ̀?
  • Ohun Táwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Ronú Lé Lórí
  • Máa Wá Ire Ọmọnìkejì Rẹ
  • Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ àti Àwọn Ìlànà Kristẹni Wọ́n Ha Bára Mu bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọrun!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 28-29

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Àwọn Àṣà Olókìkí

“KÒ SÍ ÀṢÀ NÁÀ TÍ WỌN Ò TÍÌ BẸNU ÀTẸ́ LÙ RÍ, BÓYÁ NÍGBÀ KAN TÀBÍ NÍBÌ KAN, Ó SÌ LÈ JẸ́ ÀÌGBỌ́DỌ̀MÁṢE NÍGBÀ KAN TÀBÍ NÍBÌ KAN.”

Ọ̀RỌ̀ yìí, tí William Lecky, òpìtàn ará Ireland, sọ fi hàn pé èèyàn ò dúró sójú kan rárá. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún kan àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó ti wà lóríṣiríṣi. Àní àwọn àṣà kan wà láyé àtijọ́ tó jẹ́ pé àìgbọ́dọ̀máṣe làwọn èèyàn kà wọ́n sí, àmọ́ nígbà tó ṣe, ó wá di ohun táwọn èèyàn ń bẹnu àtẹ́ lù. Èyí kò yani lẹ́nu, nítorí gẹ́gẹ́ bí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti wí, “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.”—1 Kọ́ríńtì 7:31.

Bẹ́ẹ̀ ni, àtòrì layé, tó bá lò síwájú, á tún lò sẹ́yìn. Èyí sábà máa ń hàn nínú báyé ṣe ń lọ tó ń bọ̀ lórí ọ̀ràn ìṣarasíhùwà àti ìṣesí tí wọ́n gbà pé ó bójú mu láwùjọ. Àwọn Kristẹni “kì í ṣe apá kan ayé”—èyíinì ni pé, wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Àmọ́, Bíbélì gbà pé àwọn Kristẹni ṣì wà “ní ayé,” nítorí náà kò pa á láṣẹ pé ká di anìkàngbé, ká wá di àbàtà tó ta kété bí ẹni tí kò bódò tan. Fún ìdí yìí, a gbọ́dọ̀ ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa àwọn àṣà ìbílẹ̀.—Jòhánù 17:11, 14-16; 2 Kọ́ríńtì 6:14-17; Éfésù 4:17-19; 2 Pétérù 2:20.

Kí Ni Àṣà Ìbílẹ̀?

Àṣà ìbílẹ̀ jẹ́ àwọn nǹkan táà ń ṣe láwùjọ kan, tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará ibì kan tàbí ìṣọ̀wọ́ àwọn èèyàn kan. Ohun tó pàdí àwọn àṣà kan, bí ọ̀nà ìgbàjẹun àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe táa bá ń jẹun lọ́wọ́, lè jẹ́ tìtorí àtimọ irú ìwà tó bójú mu nígbà táa bá wà láàárín àwọn èèyàn, kí kálukú lè mọ ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí tó sì yẹ́ni sí láwùjọ. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, a lè fi ìwà rere láàárín ẹgbẹ́ wé iṣẹ́ tí epo ń ṣe nínú ẹ̀rọ, nítorí pé ìwà rere máa ń jẹ́ kí àjọṣepọ̀ ẹ̀dá máa lọ geerege.

Ẹ̀sìn ti ní ipa pàtàkì lórí àṣà ìbílẹ̀. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ àṣà ló wá látinú àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ayé àtijọ́ àti ìgbàgbọ́ tí kò bá Bíbélì mu. Fún àpẹẹrẹ, ó jọ pé inú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni àṣà fífún àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ní òdòdó ti wá.a Ní àfikún, àwọ̀ búlúù—táwọn èèyàn máa ń lò fún ọmọkùnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí—jẹ́ láti fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù dà nù. Tìróò ni wọ́n sọ pé wọ́n fi ń dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ojú burúkú, wọ́n sì máa ń fi ìtọ́tè lé àwọn ẹ̀mí èṣù dà nù kí wọ́n má bàa wọ ẹnu obìnrin, kí wọ́n sì sọ ọ́ di òǹdè. Àní àṣà kéèyàn tiẹ̀ bo ẹnu lásán nígbà tó bá ń yán, lè jẹ́ àbárèbábọ̀ èrò pé kí ọkàn ẹni má bàa gba ẹnu fò jáde ni. Àmọ́, bí ọdún ti ń gorí ọdún, àwọn èèyàn ò so ìṣe àti àṣà wọ̀nyí pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ la ọ̀ràn ẹ̀sìn lọ mọ́.

Ohun Táwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Ronú Lé Lórí

Nígbà tó bá di dandan kí Kristẹni kan pinnu bóyá kóun tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ kan tàbí kóun má tẹ̀ lé e, ohun tó yẹ kó ronú lé lórí ni pé, Kí ni ojú ìwòye Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Bíbélì? Láyé ìgbàanì, Ọlọ́run kórìíra àwọn àṣà kan tó lè ṣàì burú lójú àwọn ará àdúgbò kan. Lára irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ni fífi ọmọ rúbọ, àṣìlò ẹ̀jẹ̀, àti onírúurú ìṣekúṣe láàárín takọtabo. (Léfítíkù 17:13, 14; 18:1-30; Diutarónómì 18:10) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó dájú pé àwọn àṣà kan tó wọ́pọ̀ lóde òní lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì. Irú ìwọ̀nyí ni àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Bíbélì mu, táwọn èèyàn ti sọ di ọdún ẹ̀sìn, àwọn ọdún bíi Kérésìmesì àti Àjíǹde tàbí àwọn àṣà ìbẹ́mìílò tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán.

Ṣùgbọ́n àwọn àṣà tó ti fìgbà kan rí jẹ́ àṣà tí ń kọni lóminú, ṣùgbọ́n lónìí tó ti di ìlànà ìwà híhù láwùjọ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àṣà tó wọ́pọ̀ nígbà ìgbéyàwó—títí kan gbígba òrùka àti jíjẹ kéèkì—ó jọ pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ló ti wá. Ṣé ohun táa wá ń sọ ni pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀? Ṣé dandan ni kí àwọn Kristẹni yẹ àṣà ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan wò fínnífínní láti rí i bóyá ó ti lòdì níbì kan tàbí nígbà kan rí?

Pọ́ọ̀lù sọ pé “níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17; Jákọ́bù 1:25) Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa fi òmìnira yìí tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa lọ́rùn, ṣùgbọ́n ó fẹ́ ká lò ó láti fi kọ́ agbára ìwòye wa láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Gálátíà 5:13; Hébérù 5:14; 1 Pétérù 2:16) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tó bá jẹ́ ọ̀ràn tí kò tako ìlànà Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe òfin dan-in dan-in. Kàkà bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù Kristẹni ló máa gbé ipò tó yí i ká yẹ̀ wò, tí yóò sì fúnra rẹ̀ ṣèpinnu.

Máa Wá Ire Ọmọnìkejì Rẹ

Ṣé ohun táa wá ń sọ ni pé níwọ̀n bí àṣà kan kò bá ti lòdì sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, kò sóhun tó burú nínú mímú un lò? Rárá o. (Gálátíà 5:13) Ohun táà ń sọ kọ́ yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé kò dáa kí Kristẹni máa wá ire tara rẹ̀ nìkan “bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn.” Ńṣe ló yẹ kó “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run,” kó má sì di okùnfà ìkọ̀sẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:31-33) Fún ìdí yìí, ẹni tó bá ń wá ojú rere Ọlọ́run yóò bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo àṣà yìí? Ǹjẹ́ ó ní ìtumọ̀ òdì kankan lójú àwọn ará àdúgbò? Ṣé títẹ̀lé àṣà yìí kò ní fi hàn pé inú mi dùn sáwọn àṣà tàbí èròǹgbà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí?’—1 Kọ́ríńtì 9:19, 23; 10:23, 24.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣà kan kò burú, ọwọ́ táwọn ará àdúgbò fi mú un lè jẹ́ kó lòdì sáwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ní àwọn àkókò kan, fífúnni ní òdòdó lè ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ tó lòdì sáwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nítorí náà, kí ló yẹ kó jẹ́ olórí àníyàn Kristẹni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kéèyàn ṣàyẹ̀wò ibi tí àṣà kan ti ṣẹ̀ wá, nígbà míì ohun tó ṣe pàtàkì jù ni láti ronú lórí ojú táwọn èèyàn fi ń wo àṣà náà lọ́wọ́lọ́wọ́ níbi téèyàn ń gbé. Bí àṣà kan bá gbé ìtumọ̀ tó lòdì sí Ìwé Mímọ́ tàbí ìtumọ̀ òdì rù ní àkókò kan pàtó lọ́dún tàbí lábẹ́ àwọn ipò kan pàtó, á bọ́gbọ́n mu káwọn Kristẹni yẹra fún un lákòókò yẹn.

Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé káwọn Kristẹni máa bá a lọ ní jíjẹ́ kí ìfẹ́ wọn máa pọ̀ sí i pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún. Bí àwọn Kristẹni bá ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa àwọn àṣà olókìkí, wọ́n á “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí [wọ́n] lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí [wọ́n] má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀.” (Fílípì 1:9, 10) Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọn yóò jẹ́ kí “ìfòyebánilò [wọn] di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ènìyàn sọ pé, tẹ́lẹ̀ rí wọ́n máa ń fi òdòdó rúbọ fáwọn òkú nígbà míì, kí wọ́n má bàa máa yọ sí àwọn alààyè.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan tó ti wà látayébáyé, irú bíi bíbo ẹnu nígbà táa bá ń yán àti àṣà fífún àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ní òdòdó, ti gbé ìtumọ̀ míì rù báyìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́