ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/15 ojú ìwé 28-30
  • Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọrun!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọrun!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àṣà-Ìbílẹ̀ Ààtò-Ìsìnkú Tí Ó jẹ́ Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán
  • “Ìfọ̀mọ́” ti Ìbálòpọ̀
  • Ìṣẹ́nú àti Bíbí Ọmọ Lókùú
  • Yẹra fún Ìkonilójú, Ṣùgbọ́n Dúró Gbọn-in
  • Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Ẹnu Ni Kí O Bọ́, Kìí Ṣe Ẹsẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsìnkú Kristẹni—Kó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Kó Lọ́wọ̀, Kó Dára Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/15 ojú ìwé 28-30

Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọrun!

JESU KRISTI wí pé: “Òtítọ́ yoo sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Johannu 8:32) Bẹ́ẹ̀ni, ìsìn Kristian ń dá àwọn ènìyàn sílẹ̀ lómìnira—òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìsìnrú fún ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké àti ìrètí asán, òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìdè àwọn àṣà tí ń rẹni nípò sílẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àkókò ìgbàanì, àwọn Kristian lónìí sábà máa ń dojúkọ ìkìmọ́lẹ̀ láti padà sí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti àtẹ̀yìnwá. (Galatia 4:9, 10) Kì í ṣe pé gbogbo àwọn àṣà-ìbílẹ̀ tí ó lókìkí ni ó léwu. Ní tòótọ́, Kristian kan lè yàn láti tẹ̀lé àwọn àṣà-ìbílẹ̀ àdúgbò tí ó gbámúṣé tí ó sì lè ṣeni láǹfààní. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àṣà-ìbílẹ̀ bá forígbárí pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àwọn Kristian kì í juwọ́sílẹ̀. A ti tipa báyìí mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí-ẹni-mowó fún kíkọ̀ láti kópa nínú àwọn ayẹyẹ Keresimesi, ọjọ́-ìbí, àti àwọn àṣà-ìbílẹ̀ mìíràn tí ó forígbárí pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Ìdúró onígboyà yìí ti sábà yọrí sí ìfiniṣẹlẹ́yà púpọ̀ àti àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúlùmọ̀, aládùúgbò, àti àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́. Èyí ti rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní àwọn ilẹ̀ Africa kan, níbi tí a ti ń ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lọ́nà tí ó wọ́pọ̀ níbi ààtò-ìsìnkú, ìgbéyàwó, àti ìbímọ. Ìkìmọ́lẹ̀ náà láti fohùnṣọ̀kan lè páni láyà—tí ó sábà máa ń ní nínú ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣe oníwà-ipá. Báwo ni àwọn Kristian tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe lè mú ìdúró wọn gbọn-in-gbọn-in? Ó ha ṣeé ṣe láti yẹra fún ìkonilójú láì juwọ́sílẹ̀ bí? Láti lè dáhùn ìbéèrè náà, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn Kristian olùṣòtítọ́ ti ṣe yanjú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan tí kò bá ìwé mímọ́ mu.

Àwọn Àṣà-Ìbílẹ̀ Ààtò-Ìsìnkú Tí Ó jẹ́ Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán

Ní gúúsù Africa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ń bẹ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ààtò-ìsìnkú àti ìsìnkú. Àwọn tí ń kẹ́dùn sábà máa ń lo gbogbo òru—tàbí òru mélòókan—ni ilé ọ̀fọ̀, níbi tí iná yóò ti máa jó nígbà gbogbo. A kà á léèwọ̀ fún àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ láti dáná, gé irun wọn, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ wẹ̀ títí di ìgbà tí a bá tó sìnkú náà. Lẹ́yìn náà, wọn yóò wẹ ara wọn nínú àkànṣe àdàlù àgbo kan. A ha tẹ́wọ́gba irú àwọn àṣà-ìbílẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún àwọn Kristian bí? Rárá. Gbogbo wọn fi ìgbàgbọ́ nínú ọkàn àìleèkú àti ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì fún àwọn òkú hàn.

Oniwasu 9:5 sọ pé: “Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.” Mímọ òtítọ́ yìí dá ẹnì kan sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ níní ìbẹ̀rù ‘ẹ̀mí àwọn òkú.’ Ṣùgbọ́n kí ni Kristian kan níláti ṣe nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí ọlọ́kàn rere bá béèrè pé kí ó lọ́wọ́ nínú irú àwọn ààtò bẹ́ẹ̀?

Gbé ìrírí Ẹlẹ́rìí kan ní Africa yẹ̀wò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jane, ẹni tí bàbá rẹ̀ kú. Nígbà tí ó dé ilé tí wọn yóò ti ṣe ààtò-ìsìnkú náà, a sọ fún un lójú ẹsẹ̀ pé òun àti àwọn yòókù nínú ìdílé náà níláti jó yíká òkú náà ní gbogbo òru kí wọ́n baà lè tu ẹ̀mí olóògbé náà lójú. Jane sọ pé: “Mo sọ fún wọn pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, n kò lè lọ́wọ́ nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn ìsìnkú náà, àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà wí pé àwọn yóò wẹ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ààbò síwájú síi lòdì sí ẹ̀mí olóògbé náà. Lẹ́ẹ̀kan síi mo kọ̀ láti kópa. Ní àkókò kan náà, wọ́n fi Màmá nìkan pamọ́ sínú ilé kan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti rí i gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mu ohun mímu ọlọ́tí tí a ti pèsè sílẹ̀ fún ète náà.

“Mo kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú èyíkéyìí nínú èyí. Kàkà bẹ́ẹ̀ mo lọ sílé láti gbọ́ oúnjẹ díẹ̀, èyí tí mo gbé lọ sí ilé tí Màmá wà. Èyí já ìdílé mi kulẹ̀ gidigidi. Àwọn mọ̀lẹ́bí mi rò pé orí mi kò pé.” Ju ìyẹn lọ, wọ́n fi ṣẹlẹ́yà wọ́n sì gbé e ṣépè, ní sísọ pé: “Níwọ̀n bí o ti kọ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wa nítorí ìsìn rẹ, ẹ̀mí bàbá rẹ yóò dà ọ́ láàmú. Àní, o kò ní rí ọmọ bí.” Síbẹ̀, Jane kọ̀ láti jẹ́ kí a mú òun láyà pami. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ó sọ pé: “Ní àkókò náà mo ní ọmọ méjì. Nísinsìnyí mo ní mẹ́fà! Èyí ti dójú ti àwọn wọnnì tí wọ́n sọ pé n kò lè bímọ mọ́.”

“Ìfọ̀mọ́” ti Ìbálòpọ̀

Àṣà-ìbílẹ̀ mìíràn wémọ́ ìfọ̀mọ́ aláṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lẹ́yìn ikú alábàáṣègbéyàwó ẹni. Bí aya kan bá kú, ìdílé aya náà yóò mú àbúrò rẹ̀ tí ó jẹ́ obìnrin tàbí obìnrin mìíràn tí ó jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ aya náà wá fún ọkọ ẹni tí ó dolóògbé náà. Ọ̀ranyàn ni fún un láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kìkì nígbà náà ni ó tó lè fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú. Ohun kan náà ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkọ obìnrin kan bá kú. Wọ́n rò pé àṣà náà lè sọ alábàáṣègbéyàwó tí ó wàláàyè náà di mímọ́ kúrò lọ́wọ́ “ẹ̀mí” alábàáṣègbéyàwó rẹ̀ tí ó kú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti ṣe irú “ìfọ̀mọ́” bẹ́ẹ̀ ń fi rírí ìrunú àwọn mọ̀lẹ́bí ṣeré. Wọ́n lè dẹ́yẹ sí i kí wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà kí wọ́n sì ké ègbé lé e lórí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian kọ̀ láti tẹ̀lé àṣà-ìbílẹ̀ yìí. Wọ́n mọ̀ pé yàtọ̀ sí jíjẹ́ irú “ìfọ̀mọ́” kan, ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó jẹ́ ohun tí ń sọni di ẹlẹ́gbin lójú Ọlọrun. (1 Korinti 6:18-20) Síwájú síi, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ gbéyàwó “kìkì ninu Oluwa.”—1 Korinti 7:39.

Obìnrin ará Zambia kan tí ó jẹ́ Kristian tí a pe orúkọ rẹ̀ ni Violet pàdánù ọkọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn mọ̀lẹ́bí mú ọkùnrin kan wá fún un, wọ́n sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé ó gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Violet kọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìjìyà, a fòfindè é láti máṣe fa omi nínú kànga tí ó wà fún gbogbo ènìyàn. Wọ́n tún kìlọ̀ fún un kí ó máṣe rìn lójú pópó, kí ìjàm̀bá má baà dé bá a. Bí ó ti wù kí ó rí, ó kọ̀ láti jẹ́ kí a mú òun láyà pami yálà láti ọwọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń gbé abúlé.

Lẹ́yìn náà wọ́n pe Violet lẹ́jọ́ sí ilé-ẹjọ́ àdúgbò. Níbẹ̀ ni ó ti ṣàlàyé láìyẹhùn nípa àwọn ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún kíkọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ tí kò tọ́. Ilé-ẹjọ́ dá a láre, ní sísọ pé ilé-ẹjọ́ kò lè fipá mú un láti rọ̀ mọ́ àṣà-ìbílẹ̀ àdúgbò àti àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó lòdì sí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó dùn mọ́ni pé, kíkọ̀ jálẹ̀ rẹ̀ láti juwọ́sílẹ̀ ṣiṣẹ́ láti dín ìkìmọ́lẹ̀ lórí àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù tí wọ́n dojúkọ irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn náà ní abúlé náà kù.

Ẹlẹ́rìí kan ará Africa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Monika dojúkọ irú ìkìmọ́lẹ̀ kan náà lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú. Ìdílé ọkọ náà tẹpẹlẹ mọ́ fífún un ní ọkọ mìíràn. Monika sọ pé: “Mo kọ̀, mo pinnu láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí ó wà ní 1 Korinti 7:39.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkìmọ́lẹ̀ náà kò rọjú. Monika rántí pé: “Wọ́n halẹ̀ mọ́ mi. Wọ́n wí pé: ‘Bi o bá kọ̀, o kò ní lọ́kọ mọ́ láé.’ Wọ́n tilẹ̀ sọ pé àwọn kan lára àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ mi ni a ti fọ̀ mọ́ lọ́nà yìí gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Monika dúró gbọn-in-gbọn-in. Ó sọ pé: “Mo dúró láìlọ́kọ fún ọdún méjì, lẹ́yìn èyí tí mo tún ṣègbéyàwó lọ́nà ti Kristian.” Monika ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ìṣẹ́nú àti Bíbí Ọmọ Lókùú

Àwọn Kristian ní gúúsù Africa tún gbọ́dọ̀ bá àwọn àṣà-ìbílẹ̀ tí ó yí ìṣẹ́nú àti bíbí ọmọ lókùú ká lò. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbaninínújẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìyọrísí àìpé ẹ̀dá ènìyàn—kì í ṣe ìjìyà àtọ̀runwá. (Romu 3:23) Ṣùgbọ́n bí obìnrin kan bá ní ìṣẹ́nú, àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ará Africa kan béèrè pé kí a hùwà sí i gẹ́gẹ́ bí ẹni-ìṣátì fún sáà àkókò kan.

Obìnrin kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìṣẹ́nú láìpẹ́ yìí ni ẹnú ya gidigidi láti rí Ẹlẹ́rìí kan tí ń bọ̀ wá sí ilé rẹ̀. Bí ó ti súnmọ́ ibẹ̀, ó pariwo sí i pé: “Máṣe wá síhìn-ín! Gẹ́gẹ́ bí àṣà-ìbílẹ̀ wa, obìnrin kan tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìṣẹ́nú ni a kò retí pé kí a bẹ̀wò.” Bí ó ti wù kí ó rí, Ẹlẹ́rìí náà sọ fún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú ìhìn-iṣẹ́ Bibeli lọ fún onírúurú ènìyàn àti pé wọ́n kì í pa àwọn àṣà-ìbílẹ̀ àdúgbò mọ́ níti ìṣẹ́nú. Lẹ́yìn náà ó ka Isaiah 65:20, 23, fún un, ó sì ṣàlàyé pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun ìṣẹ́nú àti bíbí ọmọ lókùú kì yóò ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, obìnrin náà tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.

Àwọn àṣà-ìbílẹ̀ ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tún lè bá ìsìnkú àwọn ọmọ-ọwọ́ tí a bí lókùú rìn. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joseph lọ sí irú ibi ìsìnkú bẹ́ẹ̀, a sọ fún un pé gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀ gbọ́dọ̀ wẹ ọwọ́ wọn nínú àgbo kan kí wọ́n sì fi egbòogi náà pa àyà wọn. Èyí ni a sọ pé ó lè dènà kí “ẹ̀mí” ọmọ-ọwọ́ náà padà wá kí ó sì pa wọ́n lára. Joseph fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fà sẹ́yìn, ní mímọ ẹ̀kọ́ Bibeli pé àwọn òkú kò lè pa àwọn alààyè lára. Síbẹ̀, àwọn kan gbìyànjú láti sún un sínú lílo egbòogi náà. Joseph tún fà sẹ́yìn. Ní rírí ìdúró aláìbẹ̀rù tí Kristian yìí ní, àwọn mìíràn tí wọ́n pésẹ̀ kọ àgbo náà pẹ̀lú.

Yẹra fún Ìkonilójú, Ṣùgbọ́n Dúró Gbọn-in

Ìbẹ̀rù tí àwọn alààyè ní àti ìfòyà ti dídi ẹni-ìṣátì lè jẹ́ ipa alágbára fún jíjuwọ́sílẹ̀. Owe 29:25 sọ pé: “Ìbẹ̀rù ènìyàn ní í mú ìkẹ́kùn wá.” Àwọn ìrírí tí ó ṣáájú fi ìjótìítọ́ apá tí ó gbẹ̀yìn nínú ẹsẹ̀ yìí hàn: “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Oluwa ni a óò gbé lékè.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a lè yẹra fún ìkonilójú. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá késí Kristian kan síbi ààtò-ìsìnkú mọ̀lẹ́bí kan, òun kò níláti dúró títí di ìgbà tí ó bá rí ara rẹ̀ ní ipò kan tí ó lè mú kí ó juwọ́sílẹ̀. “Amòye ènìyàn rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́; ṣùgbọ́n àwọn òpè kọjá a sì jẹ wọ́n níyà.”—Owe 27:12.

Yóò jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti fi ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ béèrè àwọn àṣà-ìbílẹ̀ tí a óò tẹ̀lé. Bí àwọn wọ̀nyí bá lòdì, Kristian náà lè lo àǹfààní yìí láti ṣàlàyé ìdí tí òun kò fi lè kópa, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “pẹlu inú tútù ati ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Peteru 3:15) Nígbà tí Kristian kan bá ti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìdúró rẹ̀ tí a gbékarí Bibeli ṣáájú, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ yóò ní ìtẹ̀sí láti bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ wọ́n kì í sìí ní ìtẹ̀sí púpọ̀ láti lo ìhalẹ̀mọ́ni àti ìmáyàpami.

Ohun yòówù kí ó jẹ́ ìhùwàpadà àwọn mọ̀lẹ́bí, Kristian kan kò lè wulẹ̀ juwọ́sílẹ̀ nípa títẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò fi ọlá fún Ọlọrun—láìka ìhalẹ̀mọ́ni tàbí èébú tí wọ́n lè dà bò ó sí. A ti dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Aposteli Paulu rọni pé: “Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira. Nitori naa ẹ dúró ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ kí a tún há yín mọ́ inú àjàgà ìsìnrú.”—Galatia 5:1.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alárinà kí ó sì jíṣẹ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́