ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/15 ojú ìwé 21-23
  • “Ẹnu Ni Kí O Bọ́, Kìí Ṣe Ẹsẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹnu Ni Kí O Bọ́, Kìí Ṣe Ẹsẹ̀”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àṣà Ìsìnkú Àtọwọ́dọ́wọ́
  • Àwọn Ìgbàgbọ́ Àtọwọ́dọ́wọ́ Africa
  • Ohun tí Bibeli Sọ
  • Kí Ni Ìdí Fún Mímú Ìdúró tí Ó Yàtọ̀?
  • Ó Ha Yẹ Kí A Bọlá fún Òkú Bí?
    Jí!—1999
  • Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/15 ojú ìwé 21-23

“Ẹnu Ni Kí O Bọ́, Kìí Ṣe Ẹsẹ̀”

Ṣíṣàyẹ̀wò Àṣà Ìsìnkú Àtọwọ́dọ́wọ́ Africa

“WỌN kìí sin òkú wọn!” Èyí jẹ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tí a sábà máa ń sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa. Síbẹ̀, a mọ̀ nílé-lóko pé àwọn Ẹlẹ́rìí a máa sin òkú wọn níti tòótọ́.

Èéṣe tí àwọn ènìyàn fi máa ń sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí ṣin òkú wọn? Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí kìí pa púpọ̀ lára àwọn àṣà ìsìnkú tí ó gbajúmọ̀ ní àdúgbò mọ́.

Àwọn Àṣà Ìsìnkú Àtọwọ́dọ́wọ́

Aliu ń gbé ní abúlé kékeré kan ní Àárín-Gbùngbùn Nigeria. Nígbà tí ìyá rẹ̀ kú, ó sọ fún àwọn ẹbí nípa ikú rẹ̀ ó sì ṣètò lẹ́yìn náà pé kí a sọ ọ̀rọ̀-àsọyé Ìwé Mímọ́ ní ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀-àsọyé náà tí alàgbà kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àdúgbò sọ, pa àfiyèsí pọ̀ sórí ipò àwọn òkú àti ìrètí àjíǹde tí ń múnilọ́kànyọ̀ èyí tí Bibeli tọ́kasí. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀-àsọyé náà, ìyá Aliu ni a sin.

Inú bí àwọn ẹbí gidigidi. Ní tiwọn ìsìnkú kò tíì pé láìṣe àìsùn-òkú, èyí tí wọ́n sábà máa ń ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kejì tí ẹni náà bá kú. Láàárín àwùjọ àwọn ènìyàn tí Aliu ń gbé àìsùn-òkú jẹ́ àkókò ayẹyẹ, kìí ṣe ti ọ̀fọ̀. Wọn yóò wẹ òkú náà, wọn yóò wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, wọn yóò sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn. Àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ á pe olórin, wọ́n yóò ra páálí ọtí bíà àti kèrègbè ẹmu rẹpẹtẹ, wọn yóò sì ṣètò fún màlúù tàbí ewúrẹ́ kan tí a ó fi rúbọ. Lẹ́yìn náà àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ a dé láti kọrin, láti jó, jẹun, kí wọ́n sì mẹmu tàbí ọtí títí di ìdájí ọjọ́ kejì.

Nígbà tí àjọyọ̀ yìí bá ń lọ lọ́wọ́, wọn yóò gbé oúnjẹ sí ẹsẹ̀ òkú náà. Apákan lára irun orí, èékánná ọwọ́, àti èékánná ẹsẹ̀ òkú náà ni wọn yóò gé tí wọn yóò sì fi pamọ́ fún ṣíṣe “òkú ẹ̀gbẹ.” Ó máa ń wáyé ní ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀, tàbí ọdún pàápàá lẹ́yìn náà.

Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé àìsùn-òkú, wọn yóò sin òkú náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ayẹyẹ ààtò-ìsìnkú yóò máa báa lọ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà ni ṣíṣe òkú ẹ̀gbẹ yóò tó wáyé. Apákan irun orí, èékánná ọwọ́, àti èékánná ẹsẹ̀ náà ni wọn yóò dì sínú aṣọ funfun kan, tí wọ́n so mọ́ ọ̀pá onígi tí ó gùn tó 1.5 sí 1.8 mítà, Ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn ènìyàn tí ń kọrin tí wọ́n sì ń jó, yóò gbé igi náà lọ sí ibi tí sàréè wà wọn a sì sin ín sí ẹ̀bá ẹni tí ó ṣojú fún. Lẹ́ẹ̀kan síi, orin, ọtí mímu, àti àjọyọ̀ rẹpẹtẹ tún máa ń wà. Láti mú ṣíṣe ààtò-ìsìnkú náà wá sí ìparí, wọn a yin ìbọn ṣakabùlà kan sí ojú òfuurufú.

Níwọ̀n bí Aliu kò ti gba èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí láyè, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní ọ̀wọ̀ fún òkú náà àti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ń bọlá fún wọn. Ṣùgbọ́n èéṣe tí Aliu, Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, fi kọ̀ láti faramọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́? Nítorí pé ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kò gbà fún un láti tẹ́wọ́gba àwọn èrò ìsìn náà lórí èyí tí a gbé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí kà.

Àwọn Ìgbàgbọ́ Àtọwọ́dọ́wọ́ Africa

Jákèjádò Africa, àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn wá láti ilẹ̀-ọba ẹ̀mí àti pé wọn yóò padà síbẹ̀. Àwọn Yoruba ní Nigeria máa ń sọ pé: “Ayé lọjà ọ̀run nilé.” Àṣàyàn ọ̀rọ̀ ti àwọn Igbo sì ni pé: “Gbogbo ẹni wá sáyé ni yóò padà relé dandan, bí ó ti wù kí ẹnìkan pẹ́ láyé tó.”

Ṣàgbéyẹ̀wò àṣà tí a mẹ́nukàn ṣáájú. Ète àìsùn-òkú náà ni láti fún ẹ̀mí náà ní ìdágbére tí ó dára. Aṣọ funfun ni wọ́n kà sí ẹ̀wù yíyẹ fún ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Gbígbé oúnjẹ sí ẹsẹ̀ òkú ni wọ́n sopọ̀ mọ́ èrò náà pé òkú ń gba ẹsẹ̀ jẹun a sì gbọ́dọ̀ bọ́ ọ kí ebi má baà pa á lójú ọ̀nà ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ àwọn babańlá.

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ènìyàn náà lápapọ̀ gbàgbọ́ pé nígbà tí ẹ̀mí bá fi ara sílẹ̀, ó ń pààrà ọ̀dọ̀ àwọn tí ó wàláàyè kìí sìí padà lọ sọ́dọ̀ àwọn babańlá títí di ìgbà tí a bá yọ̀ǹda rẹ̀ nípasẹ̀ ṣíṣe òkú ẹ̀gbẹ. Àyàfi bí a bá ṣe òkú ẹ̀gbẹ, àwọn ènìyàn bẹ̀rù pé inú yóò bí ẹ̀mí náà yóò sì fi àìsàn tàbí ikú bá àwọn tí ó wàláàyè jà. Yíyin ìbọn jẹ́ láti “rán ẹ̀mí náà jáde lọ” sí ọ̀run.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣà ààtò-ìsìnkú yàtọ̀síra lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn ní Africa, èrò pàtàkì náà sábà máa ń jẹ́ pé ẹ̀mí a máa wàláàyé lẹ́yìn ikú ara. Olórí ète fún àwọn ààtò-àṣà náà ni láti ran ẹ̀mí náà lọ́wọ́ láti dáhùnpadà sí “ìpè-⁠padà-relé.”

Àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà wọ̀nyí ni ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Kristẹndọm nípa àìlèkú ọkàn ènìyàn àti ìjọsìn “àwọn ẹni mímọ́” ti fún níṣìírí. Àpẹẹrẹ kan nípa èyí ni ti àlàyé àlùfáà ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ní Swaziland tí ó sọ pé Jesu wá, kìí ṣe láti pa àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ run, ṣùgbọ́n láti mú wọn ṣẹ kí ó sì fìdí wọn múlẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti máa ń ṣàbójútó àwọn ọ̀nà tí a ń gbà sìnkú, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ronú pé Bibeli ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àti àwọn àṣà tí ó tí inú wọn jáde wá.

Ohun tí Bibeli Sọ

Bibeli ha ti àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn bí? Nípa ipò àwọn òkú, Oniwasu 3:20 sọ pé: “Níbì kan-náà ni gbogbo wọn [àti ènìyàn àti ẹranko] ń lọ; láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tún padà di erùpẹ̀.” Ìwé Mímọ́ tún sọ síwájú síi pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Ìfẹ́ wọn pẹ̀lú, àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí . . . Kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.”​—⁠Oniwasu 9:​5, 6, 10.

Ìwọ̀nyí àti àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mìíràn mú kí ó ṣe kedere pé àwọn òkú kò lè rí wa tàbí gbọ́ wa tàbí ràn wá lọ́wọ́ tàbí pa wá lára. Èyí kò ha wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí ìwọ ti kíyèsí bí? Ìwọ lè mọ̀ nípa gbajú-gbajà ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí ó ti kú tí àwọn ìdílè rẹ̀ sì ti jìyà lẹ́yìnwá ìgbà náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe gbogbo ayẹyẹ ààtò-ìsìnkú tí ó bá àṣà mu. Bí ọkùnrin yẹn bá wàláàyè nínú ilẹ̀-ọba ẹ̀mí, èéṣe tí kò fi ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́? Kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé òtítọ́ ni ohun tí Bibeli sọ​—⁠kò sí ìwàláàyè nínú àwọn òkú níti tòótọ́, wọ́n jẹ́ “aláìlágbára pàápàá nínú ikú,” àti nítorí náà wọn kò lè ran ẹnikẹ́ni lọ́wọ́.​—⁠Isaiah 26:⁠14, NW.

Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, mọ èyí sí òtítọ́. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Lasaru. Bibeli sọ pé: “Ó [Jesu] sì wí fún wọn [àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀] pé, Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú oorun rẹ̀. Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Oluwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn. Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀.”​—⁠Johannu 11:​11-⁠13.

Ṣàkíyèsí pé Jesu fi ikú wé oorun, láti rẹjú. Nígbà tí ó dé Betani, ó tu àwọn arábìnrin Lasaru, Maria àti Marta nínú. Bí a ti sún un nípasẹ̀ ìyọ́nú, Jesu sọkún. Síbẹ̀, òun kò ṣe tàbí sọ ohunkóhun lọ́nà èyíkéyìí tí ó dámọ̀ràn pé Lasaru ní ẹ̀mí kan tí ó ṣì wàláàyè tí ó sì ń wá ìrànlọ́wọ́ láti dé ilẹ̀ àwọn babańlá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jesu ṣe ohun tí ó sọ pé òun yóò ṣe. Ó jí Lasaru dìde kúrò nínú oorun ikú nípasẹ̀ àjíǹde. Èyí fi ẹ̀rí hàn pé Ọlọrun yóò lo Jesu ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ láti jí gbogbo àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú ibojì ìrántí dìde.​—⁠Johannu 11:17-⁠44; 5:28, 29.

Kí Ni Ìdí Fún Mímú Ìdúró tí Ó Yàtọ̀?

Ohun kan ha wà tí ó burú nínú fífaramọ́ àwọn àṣà ìsìnkú tí a gbékarí àwọn ìgbàgbọ́ tí kò bá ìwé mímọ́ mu bí? Aliu àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mìíràn gbàgbọ́ pé ó wà. Wọ́n mọ̀ pé ó lòdì​—⁠ó jẹ́ àgàbàgebè pàápàá​—⁠fún wọn láti kọ́wọ́ti àṣà èyíkéyìí tí ó ṣe kedere pé a gbékarí àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ èké tí ń ṣinilọ́nà. Wọn kò fẹ́ láti dàbí àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi, tí Jesu dálẹ́bi nítorí àgàbàgebè ìsìn.​—⁠Matteu 23:​1-⁠36.

Aposteli Paulu kìlọ̀ fún Timoteu alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀mí ń tẹnumọ́ ọn pé, ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn óò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù; nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké.” (1 Timoteu 4:​1, 2) Ǹjẹ́ ìpìlẹ̀-èrò náà pé òkú aráyé wàláàyè nínú ilẹ̀-ọba ẹ̀mí ha jẹ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù bí?

Bẹ́ẹ̀ni, ó jẹ́ bẹ́ẹ̀. Satani Eṣu, “baba èké,” sọ fún Efa pé òun kì yóò kú, ní títọ́ka síi pé yóò máa wàláàyè nìṣó nínú ẹran-ara. (Johannu 8:44; Genesisi 3:​3, 4) Ìyẹn kìí ṣe ohun kan-náà bíi sísọ pé ọkàn àìlèkú kan ń wàláàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ara. Bí ó ti wù kí ó rí, Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ làkàkà láti yí àwọn ènìyàn kúrò nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nípa ìgbélárugẹ èrò náà pé ìwàláàyè ń báa lọ lẹ́yìn ikú. Nítorí pé wọ́n gba ohun tí Ọlọrun sọ nínú Bibeli gbọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò ṣàjọpín kankan nínú àwọn ojú-ìwòye àti àṣà tí ó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn irọ́ Satani.​—⁠2 Korinti 6:​14-⁠18.

Nípa yíyẹra fún àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá ìwé mímọ́ mú, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti rí ìkannú àwọn kan tí kò ṣàjọpín ojú-ìwòye wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ni a ti fi ogún dù. Àwọn mìíràn ni àwọn ìdílé wọn ti tanù. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́ wọn mọ̀ pé ìfòtítọ́ ṣègbọràn sí Ọlọrun ń mú ìkannú ayé wá. Bíi ti àwọn olùṣòtítọ́ aposteli Jesu Kristi, wọ́n ti pinnu láti “gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.”​—⁠Iṣe 5:⁠29; Johannu 17:⁠14.

Nígbà tí wọ́n ṣìkẹ́ rírántí àwọn olólùfẹ́ wọn tí ó ti sùn nínú ikú, àwọn Kristian tòótọ́ ń làkàkà láti fi ìfẹ́ hàn fún àwọn alààyè. Fún àpẹẹrẹ, Aliu ti mú ìyá rẹ̀ sọ́dọ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú ó sì ti ń bọ́ ọ ó sì ń bìkítà fún un fún ìyókù ìgbésí-ayé rẹ̀. Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn sọ pé Aliu kò bìkítà fún ìyá rẹ̀ tó nítorí pé kò sin ín ní ìbámu pẹ̀lú àṣà tí ó gbajúmọ̀, ó tọ́kasí òwé yìí tí a sábà máa ń pa láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Ẹnu mi ni kí o kọ́kọ́ bọ́, kí o tó bọ́ ẹsẹ̀ mi.” Bíbọ́ ẹnu, tàbí bíbìkítà fún ènìyàn kan nígbà tí ẹni náà ṣì wàláàyè, ṣe pàtàkì gidigidi ju bíbọ́ ẹsẹ̀, àṣà tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ ṣáájú tí ó sì wépọ̀ mọ́ àìsùn-òkú lẹ́yìn tí ẹni náà ti kú tán. Nítòótọ́, bíbọ́ ẹsẹ̀, kò ṣàǹfààní fún ẹni tí ó kú náà rárá.

Aliu bi àwọn tí ń ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ léèrè pé, ‘Èwo ni ìwọ yóò fẹ́ jù​—⁠pé kí àwọn ìdílé rẹ̀ bójútó ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ tàbí kí wọ́n ṣe ayẹyẹ ńlá fún ọ lẹ́yìn tí o bá kú?’ Ọ̀pọ̀ yàn pé kí a bójútó wọn nígbà tí wọ́n ṣì wàláàyè. Wọ́n tún mọrírì mímọ̀ pé bí ó bá sẹlẹ̀ pé awọn kú, àwọn yóò ní ìsìn ìrántí wíwuyì àti ìsìnkú yíyẹ tí a gbékarí Bibeli.

Èyí ni ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń sakun láti ṣe fún àwọn olólùfẹ́ wọn. Ẹnu ni wọ́n ń bọ́, kìí ṣe ẹsẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́