ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ol apá 4 ojú ìwé 12-14
  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?
  • Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọkàn àti Ẹ̀mí
  • Ipò Tí Àwọn Òkú Wà
  • Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?
    Jí!—2009
  • Awọn Ẹmi Ko Gbe Ki Wọn si Kú Rí Lori Ilẹ Aye
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ọkàn Nígbà Ikú?
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
ol apá 4 ojú ìwé 12-14

APÁ 4

Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?

Ọkùnrin kan ń wo àwòrán àwọn baba ńlá rẹ̀

1, 2. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nípa àwọn tó ti kú?

ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ní ilẹ̀ Áfíríkà gbà gbọ́ pé ikú kì í ṣe òpin ìwàláàyè ẹni, pé ìpapòdà lásán ni, pé ńṣe lèèyàn ń ṣípò padà tó lọ ń gbé níbòmíràn. Ọ̀pọ̀ ronú pé ńṣe làwọn baba ńlá wọn tó ti kú ṣí kúrò nínú ayé téèyàn lè fojú rí lọ sínú ayé téèyàn ò lè fojú rí, ìyẹn láti ayé ẹ̀dá èèyàn lọ sí ayé àwọn ẹ̀mí àìrí.

2 Àwọn baba ńlá tàbí àwọn ìṣẹ̀run ẹni yìí ni àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé wọ́n máa ń bójú tó àwọn ìdílé wọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà, kí wọ́n sì láásìkí. Ní ìbámu pẹ̀lú èrò yìí, wọ́n ronú pé àwọn ìṣẹ̀run ẹni jẹ́ àtàtà ọ̀rẹ́, tó lè mú kí ìkórè dára, kí nǹkan ṣẹnuure, kí wọ́n sì dáàbò boni lọ́wọ́ ewu. Béèyàn ò bá kà wọ́n sí tàbí béèyàn bá mú wọn bínú, wọ́n sọ pé wọ́n lè ṣeni ní jàǹbá nípa fífi àìsàn ṣeni, wọ́n lè fi òṣì tani, wọ́n sì lè ṣeni léṣe.

3. Báwo làwọn èèyàn kan ṣe ń jọ́sìn àwọn baba ńlá?

3 Àwọn tó wà láàyè máa ń ṣe àwọn ààtò kan láti bọlá fún ìṣẹ̀run wọn àti láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú wọn. Wọ́n sábà máa ń gbé irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ lárugẹ nígbà ààtò ìsìnkú, irú bíi ṣíṣe àìsùn òkú àti ṣíṣe òkú ẹ̀gbẹ. Ìjọsìn àwọn baba ńlá tún máa ń wáyé láwọn ọ̀nà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan wà tó jẹ́ pé kí wọ́n tó mu ọtí, wọ́n máa ń ta díẹ̀ lára rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn baba ńlá. Síwájú sí i, lẹ́yìn tí wọ́n bá se oúnjẹ tán, wọ́n á ṣẹ́ oúnjẹ kù sínú ìkòkò kí ó lè jẹ́ pé bí àwọn baba ńlá bá wá, wọ́n á rí oúnjẹ jẹ.

4. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nípa ọkàn?

4 Àwọn èèyàn mìíràn gbà pé àwọn tó wà láàyè ní ọkàn tí kì í kú nígbà tí ara bá kú. Wọ́n sọ pé béèyàn bá gbélé ayé ṣe rere, ọkàn rẹ̀ á lọ sọ́run tàbí sí párádísè, ṣùgbọ́n béèyàn bá ṣe búburú, wọ́n gbà pé ọ̀run àpáàdì ni yóò lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń pa èrò yìí pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ti ẹ̀sìn àbáláyé. Bí àpẹẹrẹ, tí ìwé ìròyìn bá ń kéde ètò ìsìnkú tí wọ́n á ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì, nígbà mìíràn wọ́n á fi kún un pé ẹni náà ti “jáde láyé” tàbí pé “ó ti rebi àgbà á rè.” Gbogbo irú ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ni wọ́n gbé karí èrò náà pé ọkàn tàbí ẹ̀mí kì í kú nígbà tí ara bá kú. Kí ni Bíbélì sọ nípa èyí?

Ọkàn àti Ẹ̀mí

5, 6. Ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, kí ni ọkàn?

5 Bíbélì fi hàn pé ọkàn tí à ń sọ yìí kì í ṣe ohun kan tó wà nínú èèyàn; ẹni náà gan-an ni ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù, “ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Kì í ṣe pé Ọlọ́run fún Ádámù ní ọkàn; ọkàn ni òun fúnra rẹ̀ jẹ́, odindi èèyàn ni.

6 Ìdí nìyẹn tí a fi máa ń rí i kà pé wọ́n bí ọkàn. (Jẹ́nẹ́sísì 46:18) Ọkàn lè jẹun, ó sì lè gbààwẹ̀. (Léfítíkù 7:20; Sáàmù 35:13) Ọkàn máa ń sunkún, àárẹ̀ sì máa ń mú un. (Jeremáyà 13:17; Jónà 2:7) Wọ́n lè jí ọkàn gbé, wọ́n lè lépa rẹ̀, wọ́n sì lè fi ọkàn sínú ẹ̀wọ̀n irin. (Diutarónómì 24:7; Sáàmù 7:5; 105:18) Àwọn Bíbélì kan tú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí “ọkàn” nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, nígbà tí àwọn Bíbélì mìíràn lo ọ̀rọ̀ náà, “ohun alààyè,” “ẹ̀dá” tàbí “èèyàn.” Nǹkan kan náà ni gbogbo wọn túmọ̀ sí.

7. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló fi hàn pé ọkàn lè kú?

7 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni náà ni ọkàn, bí èèyàn bá kú, ọkàn náà ló kú yẹn. Ìsíkíẹ́lì 18:4 sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” Síwájú sí i, Ìṣe 3:23 sọ pé: “Ọkàn [tàbí èèyàn] èyíkéyìí tí kò bá fetí sí Wòlíì yẹn ni a ó pa run pátápátá kúrò láàárín àwọn ènìyàn.” Nítorí náà, ọkàn kì í ṣe ohun kan tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú tán.

8. Kí ni ẹ̀mí tó wà nínú èèyàn jẹ́?

8 Ẹ̀mí àti ọkàn kì í ṣe ohun kan náà. Nínú èèyàn, ẹ̀mí ni agbára ìwàláàyè tó ń jẹ́ kí ara lè máa ṣiṣẹ́. Ńṣe ni ẹ̀mí dà bí iná mànàmáná. Iná mànàmáná lè mú kí fáànù tàbí fíríìjì ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ kò lè fẹ́ afẹ́fẹ́ bíi ti fáànù tàbí kí ó mú kí nǹkan tutù bíi ti fíríìjì. Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí wa ló ń jẹ́ ká lè ríran, òun ló ń jẹ́ ká lè gbọ́ràn, òun ló sì ń jẹ́ ká lè ronú. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí fúnra rẹ̀ kò lè ṣe èyíkéyìí lára nǹkan wọ̀nyẹn láìsí ojú, etí tàbí ọpọlọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ nípa èèyàn pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.

9. Kí ni ọkàn àti ẹ̀mí kì í ṣe?

9 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ọkàn kì í fi ara sílẹ̀ láti lọ máa gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí nígbà téèyàn bá kú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí kì í lọ gbé níbì kankan pẹ̀lú.

Ipò Tí Àwọn Òkú Wà

10. Kí ni Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn òkú wà?

10 Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ipò wo ni àwọn òkú wà? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló dá èèyàn, òun náà ló mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ni pé àwọn òkú kò sí láàyè, wọn kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀, wọn kò lè ríran, wọn kò lè sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè ronú ohunkóhun. Bíbélì sọ pé:

  • “Àwọn òkú . . . kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.

  • “Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé nísinsìnyí.”—Oníwàásù 9:6.

  • “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní [sàréè], ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:10.

11. Lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, kí ni Jèhófà sọ fún un?

11 Ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Ádámù, baba ńlá wa àkọ́kọ́. Jèhófà ṣẹ̀dá Ádámù “láti inú ekuru ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ká ní Ádámù ṣègbọràn sí òfin Jèhófà ni, ì bá wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò sì máa láyọ̀ nìṣó. Ṣùgbọ́n, Ádámù ṣàìgbọràn sí òfin Jèhófà, ikú sì ni ìjìyà rẹ̀. Ibo ni Ádámù lọ nígbà tó kú? Ọlọ́run sọ fún un pé: “Ìwọ yóò . . . padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù nígbà tó kú?

12 Ibo ni Ádámù wà ṣáájú kí Jèhófà tó ṣẹ̀dá rẹ̀ látinú ekuru? Kò sí ní ibì kankan. Kò wà rárá. Nítorí náà, nígbà tí Jèhófà sọ pé Ádámù yóò “padà sí ilẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé Ádámù yóò tún padà di ẹni tí kò sí láàyè mọ́, gẹ́gẹ́ bí ekuru kò ṣe sí láàyè. Kì í ṣe pé Ádámù ń wà láàyè nìṣó nínú ayé ẹ̀mí àìrí. Kò “jáde láyé” lọ dàpọ̀ mọ́ àwọn ìṣẹ̀run yòókù. Kò lọ sí ọ̀run rere tàbí ọ̀run àpáàdì. Ńṣe ló bọ́ sí ipò kan tí kò ti wà láàyè mọ́; ó pa rẹ́ pátápátá láìsí níbikíbi.

13. Nígbà ikú, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn àti ẹranko?

13 Ǹjẹ́ ohun kan náà yìí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ènìyàn? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé: “Ibì kan náà ni [èèyàn àti ẹranko] ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.”—Oníwàásù 3:19, 20.

14. Ìrètí wo ló wà fún àwọn òkú?

14 Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde sí ìyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ṣùgbọ́n ìyẹn ṣì di ọjọ́ iwájú. Ní báyìí ná, wọ́n ṣì ń sùn nínú ikú ni. (Jòhánù 11:11-14) Kò yẹ ká bẹ̀rù wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ ká jọ́sìn wọn nítorí pé wọn kò lè ràn wá lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè pa wá lára.

15, 16. Báwo ni Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn òkú kò kú ní ti gidi?

15 Èrò náà pé a kì í kú ní ti gidi jẹ́ irọ́ tí Sátánì Èṣù tàn kálẹ̀. Káwọn èèyàn lè gba irọ́ yìí gbọ́, òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa ń gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn ronú pé ẹ̀mí àwọn òkú ló máa ń fa àìsàn àtàwọn ìṣòro mìíràn. Òótọ́ ni pé àwọn ẹ̀mí èṣù fúnra wọn máa ń fa àwọn ìṣòro kan. Òótọ́ sì tún ni pé àwọn ìṣòro kan wà tí kì í ṣe àwọn ẹ̀mí àìrí ló ń fà wọ́n. Ṣùgbọ́n irọ́ gbuu ni pé àwọn tó ń sùn nínú ikú lè pa wá lára.

16 Ọ̀nà mìíràn ṣì tún wà táwọn ẹ̀mí èṣù fi ń mú káwọn èèyàn ronú pé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn òkú kò tọ̀nà. Wọ́n máa ń fi ẹ̀tàn mú kí àwọn èèyàn ronú pé àwọn rí òkú tàbí pé àwọn bá òkú sọ̀rọ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lo ìran, àlá, àwọn abẹ́mìílò tàbí àwọn ọ̀nà mìíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe òkú ni èèyàn ń bá sọ̀rọ̀ bí kò ṣe àwọn ẹ̀mí èṣù tó máa ń gbé agọ̀ ẹni tó ti kú wọ̀ ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi dẹ́bi gidigidi fún àwọn abẹ́mìílò àti àwọn tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.—Diutarónómì 18:10-12; Sekaráyà 10:2.

Àwọn Òkú Ò Lè Ràn Wá Lọ́wọ́

Olóyè pàtàkì kan kú ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà lọ́dún 1990. Ó ní ìyàwó márùn-ún àti ọ̀pọ̀ ọmọ. Ó ní okòwò méjì tó máa ń mú owó jaburata wọlé.

Nígbà tí olóyè yìí kú, ìdílé rẹ̀ fara balẹ̀ ṣe gbogbo ààtò tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó jẹ́ àṣẹ̀yìndè òkú rẹ̀. Àwọn ìyàwó rẹ̀ wọ aṣọ dúdú, wọ́n da irun wọn rú, wọ́n febi panú, wọn kò sì wẹ̀. Wọ́n sunkún, wọ́n sì fi ọjọ́ méje ṣọ̀fọ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ibẹ̀, gbogbo ìdílé rẹ̀ àti àwọn mọ̀lẹ́bí pé jọ, wọ́n sì ṣayẹyẹ àṣekágbá fún ìsìnkú rẹ̀. Wọ́n se àsè, wọ́n mutí, wọ́n sì jó níbi ayẹyẹ àṣekágbá náà.

Dájúdájú, ká ní olóyè náà lágbára rẹ̀ ni, ì bá dáàbò bo ìdílé rẹ̀ ọ̀wọ́n, ì bá sì bù kún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀! Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Okòwò rẹ̀ forí ṣánpọ́n. Àwọn ará ilé rẹ̀ bá ara wọn jà nítorí ogún, olúkúlùkù wọn sì wábi gbà lọ níkẹyìn. Ní báyìí, èèyàn díẹ̀ ló kù nínú agbo ilé ńlá yìí tó jẹ́ pé fọ́fọ́ làwọn èèyàn máa ń kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Àwọn Òkú Kò Lè Pa Wá Lára

Ọkùnrin kan wà ní ibi sàréè

Ní abúlé kan ní Nàìjíríà, ọkùnrin kan kú, wọ́n sì sin ín. Nígbà tó yá, ìyàwó rẹ̀ rí i lójú àlá pé ọkọ òun fẹ́ gba aago rẹ̀. Ni obìnrin yìí bá mú aago ọ̀hún, ó sì lọ rì í mọ́lẹ̀ síbi oórì ọkọ rẹ̀.

Ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dunikan rọra lọ wú aago ọ̀hún níbẹ̀, ó sì lò ó fún ọ̀pọ̀ ọdún títí tí aago náà fi gbó. Ohunkóhun kò ṣe ọmọkùnrin náà. Ká ní ọkùnrin tó kú náà ní agbára láti ṣe alààyè ní nǹkan, ó dájú pé ì bá ti fìyà jẹ olè tó lórí láyà wá jí aago níbi sàréè rẹ̀!

Àpótí: Ìrírí wo ló fi hàn pé àwọn òkú kò lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa wá lára?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́