Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ọkàn Nígbà Ikú?
“Ẹ̀kọ́ ti pé ọkàn ènìyàn jẹ́ aláìleèkú àti pé ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti kú tí ara rẹ̀ sì ti jẹrà, jẹ́ ọ̀kan nínú ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí àti ti ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni.”—ÌWÉ AGBÉDÈGBẸ́YỌ̀ “NEW CATHOLIC ENCYCLOPEDIA.”
1. Kí ni ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia gbà ní ti pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú?
ṢÙGBỌ́N, ìwé tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí, gbà pé “èrò ti pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú kò rọrùn láti rí nínú Bíbélì.” Kí wá ni Bíbélì fi kọ́ni ní ti gidi nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú?
Òkú Kò Mọ Ohunkóhun
2, 3. Ipò wo ni àwọn òkú wà, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó sì fi èyí hàn?
2 A mú ipò tí àwọn òkú wà ṣe kedere nínú Oníwàásù 9:5, 10, níbi tí a ti kà á pé: “Òkú kò mọ nǹkan kan . . . Kò sí ìlépa ohunkóhun, kò sí ìpète, kò sí ìmọ̀ tàbí làákàyè kankan nínú ibojì.” (Moffatt) Nítorí náà, ikú jẹ́ ipò àìsí níbikíbi. Onísáàmù kọ̀wé pé nígbà tí ènìyàn bá kú, “ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.
3 Nípa bẹ́ẹ̀, òkú kò mọ ohunkóhun, kò lè ṣe ohunkóhun. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ Ádámù, ó sọ pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ádámù kò sí níbikíbi kí Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú ekuru ilẹ̀ tí ó sì fún un ní ìwàláàyè. Nígbà tí Ádámù sì kú, ipò yẹn náà ni ó sì padà sí. Ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—kì í ṣe ìpapòdà sí àgbègbè mìíràn.
Ọkàn Lè Kú
4, 5. Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ láti inú Bíbélì, tí ó fi hàn pé ọkàn lè kú.
4 Nígbà tí Ádámù kú, kí ní ṣẹlẹ̀ sí ọkàn rẹ̀? Wàyí o, rántí pé nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” sábà máa ń wulẹ̀ tọ́ka sí ènìyàn. Nítorí náà, nígbà tí a sọ pé Ádámù kú, ohun tí a ń sọ ni pé ọkàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ádámù kú. Èyí lè ṣàjèjì sí ẹni tí ó bá gba àìleèkú ọkàn gbọ́. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Léfítíkù 21:1 sọ̀rọ̀ nípa “ọkàn tí ó ti di olóògbé” (“òkú,” Jerusalem Bible). A sì sọ fún àwọn Násírì pé wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ “òkú ọkàn èyíkéyìí” (“òkú,” Lamsa).—Númérì 6:6.
5 A rí ìtọ́ka nípa ọkàn tí ó jọ ìwọ̀nyí nínú 1 Àwọn Ọba 19:4. Èlíjà tí wàhálà ti bá gidigidi “bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé kí ọkàn òun kú.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jónà “ń bá a nìṣó láti béèrè pé kí ọkàn òun kú, ó sì ń sọ léraléra pé: ‘Kí n kú dànù sàn ju kí n wà láàyè.’” (Jónà 4:8) Jésù sì lo gbólóhùn náà ‘láti pa ọkàn,’ èyí tí Bíbélì The Bible in Basic English pè ní “láti ṣekú pa.” (Máàkù 3:4) Nítorí náà, ikú ọkàn wulẹ̀ túmọ̀ sí ikú ẹni náà.
Ó “Ń Jáde Lọ” Ó sì ‘Ń Padà’
6. Kí ni Bíbélì ń wí nígbà tí ó sọ pé ọkàn Rákélì ń “jáde lọ”?
6 Ikú ìbànújẹ́ tí Rákélì kú, èyí tí ó ṣẹlẹ̀ bí ó ṣe ń bí ọmọ rẹ̀ kejì, ńkọ́? Nínú Jẹ́nẹ́sísì 35:18, a kà á pé: “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń jáde lọ (nítorí pé ó kú) ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ónì; ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pè é ní Bẹ́ńjámínì.” Ṣé àyọkà yìí fẹ́ fi yé wa pé Rákélì ní ẹ̀dá inú kan tí ó jáde lọ nígbà tí ó kú ni? Rárá o. Rántí pé ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” tún lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ènìyàn ní. Nítorí náà, nínú ọ̀ràn yìí, “ọkàn” Rákélì wulẹ̀ túmọ̀ sí “ìwàláàyè” rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwọn Bíbélì mìíràn fi tú gbólóhùn náà “ọkàn rẹ̀ . . . ń jáde lọ” sí “ìwàláàyè rẹ̀ ń tán lọ” (Knox), “ó mí èémí àmíkẹ́yìn” (Jerusalem Bible), àti “ìwàláàyè rẹ̀ kúrò lára rẹ̀” (Bible in Basic English). Kò sí ohun tí ó fi hàn pé ẹ̀ka àràmàǹdà kan wà nínú Rákélì tí ó ṣì wà láàyè lẹ́yìn ikú rẹ̀.
7. Lọ́nà wo ni ó gbà fi jẹ́ pé ọkàn ọmọ opó náà “padà sínú rẹ̀”?
7 Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú àjíǹde ọmọ opó kan, tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú 1 Àwọn Ọba orí 17. Ní 1Ọb 17 ẹsẹ 22, a kà á pé bí Èlíjà ti ń gbàdúrà lé ọ̀dọ́mọkùnrin náà lórí, “Jèhófà fetí sí ohùn Èlíjà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ náà padà sínú rẹ̀, ó sì wá sí ìyè.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” túmọ̀ sí “ìyè.” Nípa báyìí, Bíbélì New American Standard Bible kà pé: “Ìwàláàyè ọmọ náà padà sínú rẹ̀ ó sì sọjí.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìwàláàyè ni ó padà sínú ọmọkùnrin náà, kì í ṣe ohun kan tí ó dà bí òjìji. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Èlíjà sọ fún ìyá ọmọ náà, pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ [ọmọ náà lódindi] yè.”—1 Àwọn Ọba 17:23.
Ìṣòro “Ipò Agbedeméjì”
8. Kí ni ọ̀pọ̀ afẹnujẹ́ Kristẹni gbà gbọ́ pé yóò ṣẹlẹ̀ nígbà àjíǹde?
8 Ọ̀pọ̀ àwọn afẹnujẹ́ Kristẹni gbà gbọ́ pé àjíǹde kan ń bẹ lọ́jọ́ iwájú, pé ìgbà yẹn ni a ó so àwọn ara ìyára pọ̀ mọ́ àwọn ọkàn aláìleèkú. Nígbà náà, àwọn tí a jí dìde yóò wá gba èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn—bóyá láti fi èrè fún àwọn tí ó gbé ìgbé ayé rere tàbí láti sẹ̀san fún olubi.
9. Kí ni gbólóhùn náà “ipò agbedeméjì” túmọ̀ sí, kí sì ni àwọn kan sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn láàárín àkókò yìí?
9 Èrò náà jọ ohun tí ó rọrùn. Ṣùgbọ́n ó ṣòro fún àwọn tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ti pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú láti ṣàlàyé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn láàárín ìgbà ikú àti ìgbà àjíǹde. Ní tòótọ́, “ipò agbedeméjì” yìí, bí a ti sábà máa ń pè é, ti fa onírúurú ìméfò fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àwọn kan sọ pé pọ́gátórì ni ọkàn máa ń lọ ní àkókò yẹn, níbi tí a óò ti fọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mọ́ kúrò lára rẹ̀ kí ó bàa lè di ẹni tí ó lè wọ ọ̀run.a
10. Èé ṣe tí kò fi bá Ìwé Mímọ́ mu láti gbà gbọ́ pé àwọn ọkàn máa ń dúró díẹ̀ ní pọ́gátórì lẹ́yìn ikú, báwo sì ni ìrírí Lásárù ṣe fẹ̀rí èyí múlẹ̀?
10 Àmọ́, bí a ti ṣe rí i, ènìyàn gan-an ni ọkàn. Bí ènìyàn bá ti kú, ọkàn kú nìyẹn. Nítorí náà, kò sí ìwàláàyè tí ènìyàn ti ń mọ ohunkóhun lẹ́yìn ikú. Ní ti gidi, nígbà tí Lásárù kú, Jésù Kristi kò sọ pé ó wà ní pọ́gátórì, Líḿbò, tàbí “ipò agbedeméjì” kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù kàn sọ pé: “Lásárù ti sùn.” (Jòhánù 11:11, New English Bible) Ní kedere, Jésù, tí ó mọ òtítọ́ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú, gbà gbọ́ pé Lásárù kò mọ ohunkóhun, kò sí níbikíbi.
Kí Ni Ẹ̀mí?
11. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí,” kò fi lè tọ́ka sí apá kan lára ẹni, tí ó bọ́ agọ̀ ara sílẹ̀, tí ó sì ń bá a lọ láti wà láàyè lẹ́yìn ikú?
11 Bíbélì sọ pé nígbà tí ènìyàn bá kú, “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀.” (Sáàmù 146:4) Èyí ha túmọ̀ sí pé ṣe ni ẹ̀mí kan tí ó bọ́ agọ̀ ara sílẹ̀ jáde lọ ní ti gidi tí ó sì ń bá a lọ láti wà láàyè lẹ́yìn ikú ènìyàn bí? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí onísáàmù náà sọ tẹ̀ lé èyí pé: “Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé” (“gbogbo inú rírò rẹ̀ dópin,” NEB). Kí wá ni ẹ̀mí yẹn, báwo sì ni ó ṣe ń “jáde lọ” kúrò lára ènìyàn nígbà tí ẹni náà bá kú?
12. Kí ni ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” nínú Bíbélì túmọ̀ sí?
12 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” (Hébérù, ruʹach; Gíríìkì, pneuʹma) wulẹ̀ túmọ̀ sí “èémí.” Nípa báyìí, dípò “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ,” ìtumọ̀ ti R. A. Knox lo gbólóhùn náà “èémí rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.” (Sáàmù 145:4, Knox) Àmọ́ o, ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ju kìkì ọ̀ràn mímí lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jẹ́nẹ́sísì 7:22 ń ṣàlàyé bí ìwàláàyè ènìyàn àti tàwọn ẹranko ṣe pa run nígbà Àkúnya kárí ayé, ó sọ pé: “Ohun gbogbo tí èémí ipá [tàbí ẹ̀mí; Hébérù, ruʹach] ìwàláàyè ń ṣiṣẹ́ ní ihò imú rẹ̀ kú, èyíinì ni, gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” Nítorí náà, “ẹ̀mí” lè tọ́ka sí ipá ìwàláàyè tí ń ṣiṣẹ́ nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè, àtènìyàn àtẹranko, èyí tí mímí tí a ń mí sì gbé ró.
13. Lọ́nà wo ni a lè gbà fi ẹ̀mí wé agbára iná mànàmáná?
13 Bí àpèjúwe: Agbára iná mànàmáná ń gbé ohun ìlò kan ṣiṣẹ́. Bí agbára iná mànàmáná náà bá dáwọ́ dúró, ohun ìlò náà kò ní ṣiṣẹ́ mọ́. Agbára iná mànàmáná náà kò sì ní lọ bẹ̀rẹ̀ sí dá wà fúnra rẹ̀. Bákan náà, nígbà tí ẹnì kan bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ a dáwọ́ mímú tí ó ń mú kí àwọn ohun tíntìntín ara ṣiṣẹ́ dúró. Kì í fi ara sílẹ̀ lọ sí àgbègbè mìíràn.—Sáàmù 104:29.
14, 15. Báwo ni ẹ̀mí ṣe ń padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà ikú?
14 Nígbà náà, èé ṣe tí Oníwàásù 12:7 fi sọ pé nígbà tí ènìyàn bá kú, “ẹ̀mí yóò . . . padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni”? Èyí ha túmọ̀ sí pé ṣe ni ẹ̀mí máa ń gba òfuurufú lọ bá Ọlọ́run ní ti gidi bí? Ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò wáyé rárá. Rántí, ẹ̀mí jẹ́ ipá ìwàláàyè. Tí ipá ìwàláàyè yẹn bá ti lọ pẹ́nrẹ́n, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó lè dá a padà. Nítorí náà, ẹ̀mí “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́” ní ti pé, ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ni ìrètí èyíkéyìí pé ẹni náà máa wà láàyè lọ́jọ́ iwájú wà.
15 Ọlọ́run nìkan ni ó lè dá ẹ̀mí, tàbí ipá ìwàláàyè padà, ní mímú kí ènìyàn padà wà láàyè. (Sáàmù 104:30) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ha pète láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ṣe wí, “kedere ni àwọn Baba [Ṣọ́ọ̀ṣì] ní gbogbogbòò ń jẹ́rìí sí wíwà pọ́gátórì.” Síbẹ̀, ìwé kan náà yìí gbà pé “orí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni a gbé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì náà, pọ́gátórì, kà kì í ṣe Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìrántí Ayé Tí A Ti Gbé Ṣáájú
BÍ KÒ bá sí ohunkóhun tí ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú ara, báwo wá ni ti rírántí tí àwọn kan sọ pé àwọn ń rántí ayé tí àwọn tí gbé rí ṣe jẹ́?
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Híńdù náà, Nikhilananda, sọ pé ‘àwọn ìrírí lẹ́yìn ikú ni a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání.’ Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan, Hans Küng, sọ nínú àsọyé rẹ̀ “Àwọn Àwòṣe Ìgbàgbọ́ Nínú Wíwà Títí Ayérayé Nínú Àwọn Ẹ̀sìn,” pé: “Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ìròyìn—tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ ń ti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé wá tàbí kí ó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó gba àtúnwáyé gbọ́—nípa ìrántí ayé tí ẹnì kan ti gbé rí tí a lè fi ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́.” Ó fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn [olùwádìí tí ń fi aápọn àti ọ̀nà ti sáyẹ́ǹsì ṣiṣẹ́ lórí kókó yìí] gbà pé àwọn ìrírí tí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ kò pèsè ìpìlẹ̀ fún ẹ̀rí tí ó dáni lójú nípa títún ìgbésí ayé gbé lórí ilẹ̀ ayé.”
Bí o bá rò pé o ń rántí ayé tí o ti gbé ṣáájú ńkọ́? Onírúurú nǹkan ló lè fa irú ìrònú bẹ́ẹ̀. Èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ìsọfúnni tí a ń rí gbà ni a máa ń kó pa mọ́ síbì kan tí a kì í sábà lò nínú ọpọlọ wa nítorí pé a kò nílò rẹ̀ ní tààràtà tàbí lójú ẹsẹ̀. Nígbà tí a bá rántí àwọn ìrírí wa tí a ti gbàgbé, àwọn kan a túmọ̀ ìwọ̀nyí sí ẹ̀rí pé àwọn ti gbé ayé ṣáájú. Àmọ́ ṣá, òkodoro ọ̀rọ̀ náà ni pé kò sí àwọn ìrírí ayé mìíràn tí ẹ̀rí rẹ̀ ṣeé fi múlẹ̀ yàtọ̀ sí ti èyí tí a ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ni kò lè rántí pé àwọn ti gbé láyé rí; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ti gbé ayé rí.