Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ àti Àwọn Ìlànà Kristẹni Wọ́n Ha Bára Mu bí?
A YAN Stephen, Ẹlẹ́rìí kan láti ìhà Àríwá Yúróòpù láti lọ ṣe míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà kan. Nígbà tí òun pẹ̀lú arákùnrin kan ládùúgbò náà jọ ń rìn lọ láàárín ìlú, ó yà á lẹ́nu nígbà tí arákùnrin náà dì í lọ́wọ́ mú.
Kí ọkùnrin di ọkùnrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ mú lórí ìrìn ní òpópónà tí èrò ń rìn lọ rìn bọ̀ ba Stephen lẹ́rù gidigidi. Ní àwùjọ tirẹ̀ irú àṣà bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé ẹnì náà jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀. (Róòmù 1:27) Àmọ́, lójú arákùnrin tó jẹ́ ará Áfíríkà, àmì ọ̀rẹ́ lásán ni dídi ọwọ́ ẹni mú jẹ́. Jíjáwọ́ ẹni gbà yóò sì túmọ̀ sí kíkọ̀ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹni.
Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ṣàníyàn nípa àwọn àṣà tí ó yàtọ̀ síra? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àwọn ènìyàn Jèhófà ń hára gàgà láti ṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn láti “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Láti ṣàṣepé iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí, àwọn kan ti ṣí lọ sí àwọn ibi tí a ti nílò àwọn òjíṣẹ́ lójú méjèèjì. Láti lè ṣàṣeyọrí ní àyíká wọn tuntun, àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ mọ àwọn àṣà tí ó yàtọ̀ tí wọn yóò bá pàdé níbẹ̀, kí wọ́n sì mú ara wọn bá a mu. Ìgbà náà ni wọn tó lè bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀, wọn yóò sì tún jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba.
Síwájú sí i, nínú ayé onírúkèrúdò yìí, ọ̀ràn òṣèlú tàbí ti ọrọ̀ ajé ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn sá kúrò ní ilẹ̀ wọn tí rògbòdìyàn wà, wọ́n sì ti lọ fìdí kalẹ̀ sí orílẹ̀-èdè mìíràn. Nítorí náà, a lè wá rí i ní tòótọ́ pé nígbà tí a bá ń wàásù fún àwọn aládùúgbò tuntun wọ̀nyí, a ń bá àwọn àṣà tuntun pàdé. (Mátíù 22:39) Onírúurú ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ lè mú kí àwọn àṣà tuntun náà dà wá lọ́kàn rú.
Àwọn Ọ̀ràn Tí Ó Ṣe Kedere
Àṣà jẹ́ apá kan àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Nítorí náà, ẹ wo bí yóò ti jẹ́ wàhálà lásán tó láti di “olódodo àṣelékè,” kí a sì máa wádìí àṣà ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan bóyá ó bá ìlànà Bíbélì mu!—Oníwàásù 7:16.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí ó ṣe kedere pé wọn tako ìlànà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ní gbogbo gbòò, ìyẹn kò ṣòro, níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó “fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà.” (2 Tímótì 3:16) Bí àpẹẹrẹ, níní aya púpọ̀ jẹ́ àṣà ní àwọn ilẹ̀ kan, ṣùgbọ́n fún àwọn Kristẹni tòótọ́, ìlànà Ìwé Mímọ́ ni pé ọkùnrin kan kò gbọ́dọ̀ ní ju aya kan ṣoṣo lọ.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 1 Tímótì 3:2.
Bákan náà, àwọn àṣà ìsìnkú kan tí a gbé kalẹ̀ láti lé ẹ̀mí búburú dànù, tàbí tí a gbé ka ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn, yóò jẹ́ ohun tí Kristẹni tòótọ́ kan kò ní tẹ́wọ́ gbà rárá. Àwọn kan máa ń sun tùràrí tàbí kí wọ́n gbàdúrà láti lè lé àwọn ẹ̀mí búburú dànù. Àwọn mìíràn máa ń ṣe àìsùn òkú tàbí ìsìnkú ẹlẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú èrò ríran ẹni tó ti kú náà lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún gbígbé ‘ayé mìíràn.’ Ṣùgbọ́n Bíbélì kọ́ni pé, nígbà tí ẹnì kan bá kú, òun “kò mọ nǹkan kan rárá” nípa bẹ́ẹ̀ kò lè ṣe ẹnikẹ́ni lóore tàbí kí ó pa á lára.—Oníwàásù 9:5; Sáàmù 146:4.
Àmọ́ ṣáá o, ọ̀pọ̀ àṣà wà tí ó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Ẹ wo bí ó ti ń tuni lára tó nígbà tí a bá dé àwọn àdúgbò tí àṣà fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn ṣì wọ́pọ̀, níbi tí ó ti jẹ́ àṣà láti fi ọ̀yàyà kí àlejò káàbọ̀, tí ó bá sì pọndandan, wọn yóò gbà á sílé! Nígbà tí a hu irú ìwà yìí sí ọ, a kò ha sún ọ láti tẹ̀ lé irú àpẹẹrẹ yìí bí? Bí a bá sún ọ ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé yóò mú kí àkópọ̀ ìwà Kristẹni rẹ̀ sunwọ̀n sí i.—Hébérù 13:1, 2.
Ta ni nínú wa tí ń fẹ́ kí a fojú òun sọ́nà fún ìgbà pípẹ́? Ní àwọn ilẹ̀ kan èyí kì í sábà ṣẹlẹ̀ nítorí wọ́n ka dídé lákòókò sí ohun pàtàkì. Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Nítorí náà, ó ti dá “ọjọ́ àti wákàtí” láti fòpin sí ìwà burúkú, ó sì mú un dá wa lójú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí “kì yóò pẹ́.” (Mátíù 24:36; Hábákúkù 2:3) Àṣà tí ń gbé dídé lákòókò tí ó yẹ lárugẹ ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà létòlétò, yóò sì ṣèrànwọ́ láti bọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún àwọn ènìyàn mìíràn àti láti má ṣe fi àkókò wọn ṣòfò, èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́.—1 Kọ́ríńtì 14:40; Fílípì 2:4.
Àwọn Àṣà Tí Kò Lè Pani Lára Ńkọ́?
Bí ó tilẹ̀ hàn gbangba pé àwọn àṣà kan bá ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni mu, àwọn mìíràn kò bá a mu. Ṣùgbọ́n àwọn àṣà tí a kò lè sọ pé ó dára tàbí pé ó burú ńkọ́? Ọ̀pọ̀ àṣà jẹ́ èyí tí kò lè pani lára, ẹ̀mí ìrònú wa nípa wọn sì lè fi hàn bí a ṣe wà déédéé nípa tẹ̀mí tó.
Bí àpẹẹrẹ, onírúurú ìkíni ni ó wà—bíbọnilọ́wọ́, títẹríba, fífẹnukonu, tàbí gbígbánimọ́ra pàápàá. Bákan náà, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àṣà ni ó wà tí ó ń darí ọ̀nà ìgbà-jẹun. Ní àwọn ilẹ̀ kan inú àwo ńlá tàbí àwo pẹrẹsẹ ni wọ́n ti máa ń jẹun. A fàyè gba gígùnfẹ̀—a tilẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i pàápàá—ó jẹ́ ọ̀nà ìgbàfìmọrírì hàn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, nígbà tó sì jẹ́ pé ní àwọn ilẹ̀ mìíràn wọn kò fẹ́ ẹ rárá, ìwà ọ̀bùn gbáà ni wọ́n kà á sí.
Kàkà tí ìwọ yóò fi máa pinnu èyí tí o fẹ́ tàbí èyí tí o kò fẹ́ nínú àwọn àṣà tí kò pani lára wọ̀nyí, pọkàn pọ̀ sórí níní ẹ̀mí rere nípa wọn. Ìmọ̀ràn tí ó bá gbogbo ìgbà mu tí a rí nínú Bíbélì dámọ̀ràn fún wa pé kí a má ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí a máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Fílípì 2:3) Bákan náà, Eleanor Boykin, nínú ìwé rẹ̀ This Way, Please—A Book of Manners, sọ pé: “Ohun tí o kọ́kọ́ nílò ni ọkàn rere.”
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yìí kò ní jẹ́ kí a máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àṣà àwọn ẹlòmíràn. A óò sún wa láti lo àtinúdá wa, kí a sì fẹ́ láti kọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn, kí a kọ́ àṣà wọn, kí a sì tọ́ oúnjẹ wọn wò dípò tí a ó fi máa fà sẹ́yìn tàbí fura sí ohun gbogbo tó bá ti yàtọ̀ sí tiwa. Nípa níní ọkàn rere, tí a sì múra tán láti gbìyànjú àwọn ọ̀nà tuntun, a ń bọlá fún àwọn tí ó gbà wá lálejò tàbí àwọn aládùúgbò wa tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ òkèèrè. Àwa pẹ̀lú ń jàǹfààní bí a ti ń “gbòòrò síwájú” nínú ọkàn-àyà wa àti ìmòye wa.—2 Kọ́ríńtì 6:13.
Bí Àṣà Bá Ń Jin Ìtẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí Lẹ́sẹ̀
Ká ní a dojú kọ àwọn àṣà tí kò lòdì sí Ìwé Mímọ́ rárá, síbẹ̀ tí kò yọ̀ǹda fún ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn ènìyàn lè ní ìtẹ̀sí láti máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la. Gbígbé ìgbésí ayé tẹ̀ẹ́-jẹ́jẹ́ yìí lè dín másùnmáwo kù, ṣùgbọ́n ó lè mú kí ó túbọ̀ nira sí i fún wa láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa “ní kíkún.”—2 Tímótì 4:5.
Báwo ni a ṣe lè fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti yẹra fún títi àwọn ohun pàtàkì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan títí di “ọ̀la”? Rántí pé “ohun tí o kọ́kọ́ nílò ni ọkàn rere.” Bí ìfẹ́ bá sún wa, a lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, kí a sì fi ọkàn rere ṣàlàyé àǹfààní ṣíṣàì fi ohun tó yẹ ká ṣe lónìí sílẹ̀ di ọ̀la. (Oníwàásù 11:4) Lọ́wọ́ kan náà, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe tìtorí ohun tí a fẹ́ ṣe kí a wá fojú kéré ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìfọkàntẹ̀ tí a ní nínú ara wa lẹ́nì kíní kejì. Bí àwọn mìíràn kò bá tẹ́wọ́ gba àbá wa lójú ẹsẹ̀, a kò ní jẹ olúwa lé wọn lórí tàbí kí a bínú sí wọn. Nígbà gbogbo, ìfẹ́ ni a gbọ́dọ̀ fi ṣáájú ìjáfáfá.—1 Pétérù 4:8; 5:3.
Gbígbé Ohun Tí Wọ́n Fẹ́ Ládùúgbò Yẹ̀ Wò
A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìmọ̀ràn èyíkéyìí tí a bá fúnni múná dóko, kì í kàn ṣe pé a fẹ́ fipá gbé èrò tiwa ka àwọn ẹlòmíràn lórí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà ìwọṣọ wà lónírúurú. Ní ọ̀pọ̀ àgbègbè, ó bójú mu fún ọkùnrin kan tí ó ń wàásù ìhìn rere láti di táì, ṣùgbọ́n ní àwọn orílẹ̀-èdè olóoru kan, a lè kà á sí ìmúra tí ó ṣe kakaaka jù. Ríronú lórí ohun tí a kà sí ìmúra tí ó bójú mu fún amọṣẹ́dunjú kan tí ń ṣiṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn yóò fìgbà gbogbo jẹ́ amọ̀nà kan tí ó lè ṣèrànwọ́. “Ìyèkooro èrò inú” jẹ́ ohun tí ó ṣe kókó nígbà tí a bá dojú kọ ọ̀ràn tó gba ọgbọ́n irú bíi ti ìwọṣọ.—1 Tímótì 2:9, 10.
Bí àṣà kan kò bá wù wá ńkọ́? Ǹjẹ́ ó yẹ ká kọ̀ ọ́ lójú ẹsẹ̀? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Àṣà kí ọkùnrin máa di ọkùnrin lọ́wọ́ mu, tí a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan ni a tẹ́wọ́ gbà dáradára ni àwùjọ àwọn ará Áfíríkà yẹn. Nígbà tí míṣọ́nnárì náà rí i pé àwọn ọkùnrin yòókù ń dira wọn lọ́wọ́ mu bí wọ́n bá ń rìn káàkiri, ara rẹ̀ túbọ̀ balẹ̀.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn ìjọ tí àwọn mẹ́ńbà wọn wá láti ipò àtilẹ̀wá onírúurú wò nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ gbígbòòrò. Kò sí àní-àní pé, àwọn àṣà tí ó yàtọ̀ síra wọ́pọ̀ nígbà yẹn. Nípa báyìí, bí Pọ́ọ̀lù ti ń mú ara rẹ̀ bá àṣà èyíkéyìí tí ó lè fara mọ́ mu, bẹ́ẹ̀ ni ó ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì. Ó wí pé: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.”—1 Kọ́ríńtì 9:22, 23; Ìṣe 16:3.
Àwọn ìbéèrè pàtàkì mélòó kan yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bí ó ṣe yẹ kí a hùwà padà sí àwọn àṣà tuntun. Nípa ṣíṣàmúlò àṣà kan pàtó—tàbí kíkọ̀ láti ṣàmúlò rẹ̀—èrò wo ni a ń gbìn sí àwọn tí ń wò wá lọ́kàn? Wọn yóò ha nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà nítorí pé wọ́n lè rí i pé a ń gbìyànjú láti mú àṣà wọn lò bí? Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí a kò bá ṣàmúlò àṣà àdúgbò, ǹjẹ́ ‘wọn kò ní rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?’—2 Kọ́ríńtì 6:3.
Bí a bá fẹ́ láti di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” a lè ní láti ṣàyípadà àwọn èrò kan tí ó ti mọ́ wa lára ní ti ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà “tí ó tọ́” àti “èyí tí kò tọ́” láti ṣe nǹkan sinmi lórí ibi tí a ń gbé. Nípa báyìí, ní orílẹ̀-èdè kan, kí àwọn ọkùnrin máa dira wọn lọ́wọ́ mú jẹ́ ìfihàn pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ibòmíràn, yóò wulẹ̀ mú kí a bu ẹnu àtẹ́ lu ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ni.
Ṣùgbọ́n, àwọn àṣà mìíràn wà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà ní àwọn àgbègbè tí ó yàtọ̀ síra, tí ó sì lè tọ́ lójú àwọn Kristẹni pàápàá; ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra.
Ṣọ́ra fún Kíkọjá Ààlà!
Jésù Kristi sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kúrò nínú ayé, wọ́n ní láti wà ‘láìjẹ́ apá kan ayé.’ (Jòhánù 17:15, 16) Ṣùgbọ́n, nígbà mìíràn kò rọrùn láti mọ ààlà jíjẹ́ apá kan ayé Sátánì àti ohun tí ó jẹ́ àṣà lásán. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ ni orin àti ijó wà, ṣùgbọ́n a kà á sí ohun pàtàkì ní àwọn ilẹ̀ kan ju òmíràn lọ.
Ó rọrùn fún wa láti dórí ìpinnu kan—tí a gbé ka ipò àtilẹ̀wá wa dípò gbígbé e ka èrò yíyèkooro tí ó wá láti inú Ìwé Mímọ́. Alex, arákùnrin kan tí ó jẹ́ ará Germany, gba iṣẹ́ àyànfúnni kan ní Sípéènì. Ní àgbègbè rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ijó jíjó kò wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ní Sípéènì ó jẹ́ apá kan àṣà wọn. Nígbà tí ó kọ́kọ́ rí arákùnrin àti arábìnrin kan tí wọ́n ń jó ijó ìbílẹ̀ àfi-gbogbo-ara-jó, ó tojú sú u. Ṣe ijó yìí burú ni àbí ó jẹ́ ti ayé? Bí ó bá tẹ́wọ́ gba àṣà yìí, ǹjẹ́ kò ní túmọ̀ sí pé ó rẹ ọ̀pá ìdiwọ̀n Kristẹni rẹ̀ sílẹ̀? Alex wá mọ̀ pé bí orin àti ijó náà tilẹ̀ yàtọ̀, kò sí ìdí kankan fún òun láti rò pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun tí wọ́n jẹ́ ará Sípéènì ń rẹ ọ̀pá ìdiwọ̀n Kristẹni sílẹ̀. Ohun tí ó tojú sú u náà rí bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn àṣà.
Àmọ́ ṣá o, Emilio, arákùnrin kan tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ijó ìbílẹ̀ àwọn ará Sípéènì, mọ̀ pé ó léwu. Ó ṣàlàyé pé: “Mo ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ijó jíjó jẹ́ èyí tí ọkùnrin àti obìnrin ti máa ń wà mọ́ra. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò tíì gbéyàwó, mo mọ̀ pé èyí lè nípa lórí ìmọ̀lára ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn méjèèjì. Nígbà mìíràn, o lè lo ijó jíjó láti fi ìfẹ́ hàn sí ẹnì kan tí ó wù ọ́. Rírí i dájú pé orin náà gbámúṣé àti pé ìfarakanra mọ níwọ̀nba lè jẹ́ ààbò. Síbẹ̀síbẹ̀, mo gbà pé nígbà tí àwùjọ àwọn àpọ́nkùnrin àti obìnrin tí kò tíì lọ́kọ bá pagbo ijó, ó máa ń ṣòro láti ṣe nǹkan lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run.”
Dájúdájú, a kò ní fẹ́ lo àṣà wa gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún kíkówọ inú ìwà ayé. Orin kíkọ àti ijó jíjó ní àyè kan nínú àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà tí a sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì nípa líla Òkun Pupa kọjá, ayẹyẹ wọn mú orin àti ijó lọ́wọ́. (Ẹ́kísódù 15:1, 20) Àmọ́ ṣá o, irú orin àti ijó tiwọn yàtọ̀ sí ti ayé Kèfèrí tí ó yí wọn ká.
Ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà tí wọ́n ń dúró de Mósè láti padà láti Òkè Sínáì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní sùúrù, wọn yá ère ọmọ màlúù oníwúrà, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n sì mu tán “wọ́n dìde láti gbádùn ara wọn.” (Ẹ́kísódù 32:1-6) Nígbà tí Mósè àti Jóṣúà gbọ́ ohùn orin, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú. (Ẹ́kísódù 32:17,18) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọjá “ààlà” náà, irú orin tí wọ́n ń kọ àti ijó tí wọ́n ń jó sì wá gbé ìwà ayé kèfèrí tí ó wà yíká wọn yọ.
Bákan náà lónìí, orin àti ijó lè jẹ́ ohun tí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gbà ní àdúgbò wa, ó sì lè má da ẹ̀rí-ọkàn àwọn ẹlòmíràn láàmú. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ iná yẹ́ríyẹ́rí ni a tàn, tí a tún fi èyí tí ń bù yẹ̀rìyẹ̀rì síbẹ̀, tàbí tí a gbé àwo orin tí ọ̀rọ̀ wọn yàtọ̀ lọ́nà kan ṣáá sí i, ohun kan tí a tẹ́wọ́ gbà tẹ́lẹ̀ lè wá fi ẹ̀mí ayé hàn nísinsìnyí. A lè jiyàn pé: “Àṣà tiwa nìyẹn kẹ̀.” Áárónì lo irú àwáwí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó tẹ́wọ́ gba oríṣi eré ìnàjú àti ìjọsìn kèfèrí, tí ó sì fàṣìṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àjọyọ̀ fún Jèhófà.” Àwáwí yìí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Họ́wù, a tilẹ̀ ka ìwà wọn sí “[ojútì] láàárín àwọn alátakò wọn.”—Ẹ́kísódù 32:5, 25.
Àṣà Ní Àyè Tirẹ̀
Àwọn àṣà tí ó ṣàjèjì lè kọ́kọ́ yà wá lẹ́nu, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn náà ni kò dára. Pẹ̀lú ‘kíkọ́ tí a kọ́ agbára ìwòye’ wa, a lè pinnu àṣà wo ni ó bá àwọn ìlànà Kristẹni mu àti èyí tí kò bá a mu. (Hébérù 5:14) Nígbà tí a bá fi ọkàn rere tí ó kún fún ìfẹ́ hàn sí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, a óò hùwà padà lọ́nà yíyẹ nígbà tí a bá dojú kọ àwọn àṣà tí kò lè pani lára.
Bí a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn ènìyàn ní àgbègbè wa tàbí ní ibi tí ó jìnnà réré sí ilẹ̀ wa, wíwà déédéé nínú ọwọ́ tí a fi ń mú onírúurú àṣà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” Kò sì sí àní-àní pé a óò rí i pé bí a ti ń tẹ́wọ́ gba onírúurú àṣà, yóò mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, kí ó wuni, kí ó sì fani mọ́ra.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí ó tọ́ ni a lè gbà fi ìkíni Kristẹni hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ojú ìwòye tí ó wà déédéé ní ti onírúurú àṣà lè yọrí sí ìgbésí ayé tí ó nítumọ̀, tí ó sì wuni