Àwọn Ògiri Ìdènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
ROBERT jẹ́ míṣọ́nnárì Watch Tower tí ń gbé ní Sierra Leone, ní Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà. Lọ́jọ́ kan, láìpẹ́ tó dé orílẹ̀-èdè náà, bí ó ti ń lọ ní pópó, ó ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọdé àdúgbò ń kọrin pé: “Òyìnbó! Òyìnbó!” Robert, tí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú, ọmọ ilẹ̀ America wò yí ká láti rí òyìnbó aláwọ̀ funfun kan, ṣùgbọ́n kò sí ẹlòmíràn kankan níbẹ̀. Ó wáá mọ̀ nígbà náà pé òun ni àwọn ọmọdé náà ń pariwo wọn lé lórí!
Ariwo yẹn kò ní ẹ̀tanú kankan nínú. Àwọn ọmọdé náà wulẹ̀ ń fi hàn pé àwọ́n mọ̀ pé Robert kì í ṣe ara ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ni. Pípe Robert ní òyìnbó ni ọ̀nà dídára jù lọ tí wọ́n lè ronú kàn láti fi ìyàtọ̀ yẹn hàn.
Bí Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Ṣe Ń Nípa Lórí Irú Ẹni Tí A Jẹ́
A ti túmọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, lọ́nà gbígbòòrò, gẹ́gẹ́ bí “ọ̀wọ́ àjùmọ̀ní èròǹgbà, . . . àṣà ìbílẹ̀, ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ tí ó jẹ́ àbùdá ọ̀nà ìgbé ayé kan.” A ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ṣíṣeyebíye nínú àṣà ìbílẹ̀ kan nípasẹ̀ ìkọ́ni ní tààràtà, ṣùgbọ́n a tún ń gba àwọn mìíràn mọ́ra láìfiyè sí i. Olùṣèwádìí kan sọ pé: “Láti ìgbà ìbí [ọmọ kan] ni àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí a bí i sí ti ń nípa lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbé ayé àti ìwà rẹ̀. Nígbà tí ó bá fi lè sọ̀rọ̀, ó jẹ́ ẹ̀dá kékeré kan tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ mú jáde, nígbà tí ó bá sì fi dàgbà, tí ó sì lè kópa nínú ìgbòkègbodò àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ náà, àwọn àṣà ìhùwa rẹ̀ ti di tirẹ̀, àwọn ìgbàgbọ rẹ̀ ti di tirẹ̀, àwọn àìlèṣeéṣe rẹ̀ ti di tirẹ̀.”
Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń mú ìgbé ayé túbọ̀ rọrùn fún wa lọ́nà púpọ̀. Bí àwọn ọmọdé, a ń yára kọ́ bí a ṣe lè tẹ́ àwọn òbí wa lọ́rùn. Mímọ àwọn ohun tí a tẹ́wọ́ gbà tàbí tí a kò tẹ́wọ́ gbà nínú àwùjọ wa ń tọ́ wa sọ́nà nínú ṣíṣe ìpinnu nípa bí a ṣe ní láti hùwà, ohun tí ó yẹ kí a wọ̀, àti irú àjọṣe tí ó yẹ kí a ní pẹ̀lú àwọn mìíràn.
Ó dájú pé, ohun tí a jẹ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kò wulẹ̀ dá lérí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa ṣáá. Láàárín ẹgbẹ́ àwùjọ kọ̀ọ̀kan, àìbáradọ́gba wà láàárín àwọn ènìyàn. A tún ń pinnu ohun tí a jẹ́ nípasẹ̀ apilẹ̀ àbùdá, ìrírí wa nínú ìgbé ayé, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn kókó mìíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa ń nípa lórí ojú tí a fi ń wo àgbáyé tí ó yí wa ká.
Fún àpẹẹrẹ, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa kò wulẹ̀ ń pinnu èdè tí a ń sọ lásán, ṣùgbọ́n ó ń pinnu bí a ṣe ń sọ ọ́ pẹ̀lú. Ní àwọn apá kan ní ìhà Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé, àwọn ènìyàn ń fojú iyebíye wo ṣíṣàlàyé ara ẹni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀, àwítúnwí àti àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́. Ní ìyàtọ̀ gédégédé, àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Jíjìnnà ń fi ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́rọ̀ ẹnu mọ sí ìwọ̀nba ṣókí. Òwe àwọn ará Japan kan fi ojú ìwòye yìí hàn pé: “Ẹnù rẹ ní ó pa ọ́.”
Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa ń pinnu ojú tí a fi ń wo àkókò. Ni Switzerland, bí o bá fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá pẹ́ kọjá àkókò àdéhùn, o gbọ́dọ̀ tọrọ gáfárà. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, o lè fi wákàtí kan tàbí méjì pẹ́, tí a kò sì níí retí pé kí o tọrọ gáfárà.
Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa tún ń kọ́ni ní ohun ṣíṣeyebíye. Ronú lórí bí ìmọ̀lára rẹ yóò ti rí, bí ẹnì kán bá sọ fún ọ pé: “O mà ń yọkùn o. O ń sanra ní ti gidi!” Bí o bá wá láti inú ẹgbẹ́ àwùjọ ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tí a ti ka ìsíngbọnlẹ̀ sí pàtàkì, ọ̀rọ̀ àkíyèsí náà yóò mú ọ láyọ̀. Ṣùgbọ́n bí o bá wá láti inú ẹgbẹ́ àwùjọ Ìwọ̀ Oòrùn Ayé, níbi tí a ń fi ojú ìjẹ́pàtàkì wo jíjẹ́ ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, ọ̀rọ̀ àkíyèsí tí ń sọ ojú abẹ níkòó bẹ́ẹ̀ lè bí ọ nínú.
‘Tiwa Ló Dára Jù!’
Ohun tí ó sábà ń ṣèdènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ́n yàtọ̀ síra ni pé, àwọn ènìyàn níbi gbogbó nítẹ̀sí láti gbà pé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tiwọn ló sàn jù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wa la ń rò pé àwọn ìgbàgbọ́, ìjẹ́pàtàkì, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ọ̀nà ìmúra, àti èro tiwa nípa ohun tí ó rẹwà ni ó tọ̀nà, tí ó yẹ, tí ó sì sàn ju èyíkéyìí mìíràn lọ. A tún ní ìtẹ̀sí láti máa ṣèdájọ́ àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwùjọ tiwá kà sí pàtàkì. Irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ni a ń pè ní ìgbéraga ẹ̀yà ìran. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “A lè sọ pé ìgbéraga ẹ̀yà ìran . . . fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ nǹkan tí ó kárí ayé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ nínú gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àgbáyé ni àwọn mẹ́ḿbà ọ̀kọ̀ọ̀kan ti ń wo ọ̀nà ìgbé ayé tiwọn bí èyí tí ó sàn ju ti àwọn aládùúgbò tí ó sún mọ́ wọn pàápàá lọ.”
Ní 200 ọdún sẹ́yìn, aláṣẹ ìlú kán sọ ọ́ ní ṣàkó pé: “[Láti inú ohun tí] mo rí, òmùgọ̀ ní àwọn àjèjì.” Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe ìwé àwọn àyọlò tí a ti rí ọ̀rọ̀ yìí kọ ọ́ pé: “[Èyí] ní láti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìmọ̀lára gbogbogbòò tí a tí ì sọ jáde rí.”
Àwọn àpẹẹrẹ àìráragbaǹkansí tí a fi hàn sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn pọ̀ yanturu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òǹkọ̀wé ìtàn àròsọ kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany, ni ó kọ ọ́ sílẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, àyọlò tí ó tẹ̀ lé e yìí ni a sábà ń tọ́ka sí bí ọ̀rọ̀ aṣíwájú ìjọba Nazi, Hermann Göring, pé: “Nígbà tí mo bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, mo máa ń nawọ́ mú ìbọn mi ni.”
Àwọn ojú ìwòye ìgbéraga ẹ̀yà ìran lílágbára lè ṣamọ̀nà sí ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ó lè yọrí sí ìkóguntini àti ìforígbárí lẹ́yìn náà. Richard Goldstone ni olùpẹ̀jọ́ fún Ìgbìmọ̀ Àgbáyé fún Ìwádìí Ìwà Ọ̀daràn tí ń ṣèwádìí lórí ìwà ọ̀daràn ìgbà ogun ní Rwanda àti Yugoslavia àtijọ́. Nípa ìwà àìlọ́làjú tí ó wáyé nínú ìforígbárí méjèèjì, ó wí pé: “Irú nǹkan báyìí lè ṣẹlẹ̀ níbikíbi. Àwọn orílẹ̀-èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìtan wọ́n yàtọ̀ síra nìyí, síbẹ̀, ìwà ìkà òǹrorò jíjọra [ni] àwọn aládùúgbò ń hù sí aládùúgbò wọn níbẹ̀. Irú ogun ẹ̀yà ìran tàbí ti ìsìn lọ́nà oníkà báyìí wulẹ̀ jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó jinlẹ̀ dé ìpele ìwà ipá. Àwọn tí a fìyà jẹ ni a ń fi hàn bí àwọn tí kò ní ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó yẹ fún oríyìn tàbí tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù. Bí a bá ti gbin èrò yìí sí àwọn ènìyàn lọ́kàn, ó tú àwọn gbáàtúù ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò ìwà rere tí ó yẹ kí ó dí wọn lọ́wọ́ [nínu] ṣíṣe àwọn nǹkan bíbani lẹ́rù bẹ́ẹ̀.”
Mímú Ojú Ìwòye Wa Gbòòrò
Àwọn ènìyàn tí a sábà máa ń yàn bí ọ̀rẹ́ wa ni àwọn tí wọ́n jọ àwa fúnra wa gan-an, àwọn tí ẹ̀mí ìrònú àti èrò ìjẹ́pàtàkì wọ́n bá tiwa mu. A ń gbọ́kàn lé wọn, a sì ń lóye wọn. Ará máa ń tù wá bí a bá wà pẹ̀lu wọn. Bí a bá ka ìhùwàsí ẹnì kan sí èyí tí kò bẹ́gbẹ́ mu tàbí tí kò dára, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀rẹ wá gbà pẹ̀lú wa, nítorí àwọn ọ̀rẹ wá máa ń ṣàjọpín ẹ̀tanú wa.
Nígbà náà, kí ni a lè jàǹfààní rẹ̀ nípa jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn, tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ́n yàtọ̀ sí tiwa? Lọ́nà kan, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí àwọn mìíràn fi ń ronú, tí wọ́n sì ń hùwà bí wọ́n ṣe ń ṣe. Kúnlé, ọmọ ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà kán, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọmọdé nílẹ̀ Áfíríkà ni a ti kìlọ̀ fún tagbáratagbára láti má ṣe sọ̀rọ̀ nídìí oúnjẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Europe, a ń fún sísọ̀rọ̀ nídìí oúnjẹ níṣìírí. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ará Europe bá ń jẹun pọ̀ pẹ̀lú ará Áfíríkà? Ará Europe náà yóò máa ṣe kàyéfì lórí ìdí tí ará Áfíríkà fi pọkàn pọ̀ sórí oúnjẹ rẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Nígbà kan náà, ará Áfíríkà náà yóò máa ṣe kàyéfì lórí ìdí tí ará Europe náà fi ń sọ̀rọ̀ wótòwótò bí ẹyẹ!” Lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ó ṣe kedere pé, jíjùmọ̀ lóye àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹnì kejì lè ṣe púpọ̀ láti mú ẹ̀tanú àjùmọ̀ṣepọ̀ kúrò.
Bí a ti wá ń mọ àwọn ènìyàn láti inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn, a kò wulẹ̀ máa lóye wọn lọ́nà sísàn jù sí i, ṣùgbọ́n a ń lóye ara àwa fúnra wa dáradára sí i. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn kán kọ̀wé pé: “Ohun tí ẹ̀dá tí ń gbé ìsàlẹ̀ òkun kan yóò mọ̀ nípa rẹ̀ kẹ́yìn ni omi. Yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé omí wà, nígbà tí ìjàm̀bá kan bá mú un jáde sí gbangba, tí ó sì gbé e sọ sáfẹ́fẹ́. . . . Ṣíṣeé ṣe náà láti rí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ ẹni lódindi . . . ń béèrè ìwọ̀n wíwà láìṣègbè, èyí tí ó ṣọ̀wọ́n gan-an bí ó bá tilẹ̀ wà rárá.” Síbẹ̀síbẹ̀, nípa ṣíṣí ara wa payá sí àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn, a dà bí olùgbé inú òkun tí a mú mọ afẹ́fẹ́; a wáá mọ̀ nípa “àwọn omi” àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí a ń gbé inú rẹ̀. Òǹkọ̀wé Thomas Abercrombie sọ ọ̀rọ̀ náà dáradára pé: “Ẹnì kan tí kò ì nírìírí ìfanimọ́ra àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣàjèjì kò lè lóye àwọn ipá tí ń pààlà sí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tirẹ̀.”
Ní àkópọ̀, mímọyì àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn lè sọ ìgbé ayé wa di ọlọ́ràá nípa mímú ojú ìwòye wa gbòòrò, tí a sì lè tipa bẹ́ẹ̀ lóye ara wa àti àwọn mìíràn pẹ̀lú. Nígbà tí àjogúnbá ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìrònú ìgbéraga ẹ̀yà ìrán lè jẹ́ adènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, kò yẹ kí wọ́n jẹ́ bẹ́ẹ̀. A lè bi àwọn ògiri wọ̀nyẹn lulẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ nínú gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àgbáyé ni àwọn mẹ́ḿbà ọ̀kọ̀ọ̀kán ti ń wo ọ̀nà ìgbé ayé tiwọn bí èyí tí ó sàn ju ti àwọn aládùúgbò tí ó sún mọ́ wọn pàápàá lọ.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀—The New Encyclopædia Britannica
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A lè kọ́ láti gbádùn àwọn ohun rere inú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
Globe: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.