Wíwó Ògiri Palẹ̀ Láti Fi Kọ́ Afárá
A KÒ yan ìdílé tàbí orílẹ̀-èdè tí a bí wa sí, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò pinnu àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó ní láti darí ìrònu wa. A kò ní agbára láti ṣàkóso kankan lórí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Gbogbo wá wà lábẹ́ ìgbà àti èèṣì. Ṣùgbọ́n a lè ṣàkóso ojú tí a fi ń wo àwọn ẹlòmíràn àti bí a ṣe ń hùwà sí wọn.
Bíbélì ṣàpèjúwe bí a ṣe lè ṣe ìyẹn. Ṣàgbéyẹ̀wo àwọn ìlànà díẹ̀ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ afárá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n lè ní ipò àtẹ̀yìnwá tí ó yàtọ̀ sí tiwa.
“Ọlọ́run náà tí ó ṣe ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínu rẹ̀ . . . Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:24, 26) Gbogbo wa pátá jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kan náà, a sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó jọra. Fífiyè sí àwọn ohun tí a fi jọra ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ túbọ̀ rọrùn. Gbogbo wa ń fẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rere, a sì fẹ́ láti nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ wa, a sì bọ̀wọ̀ fún wa. Olúkúlùkù ń fẹ́ láti yẹra fún ìrora ti ara ìyára àti ti èrò ìmọ̀lára. Àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ fẹ́ràn orin àti iṣẹ́ ọnà, wọ́n ń ṣàwàdà, wọ́n gbà gbọ́ nínú híhùwà ọmọlúwàbí sí àwọn ẹlòmíràn, wọ́n sì ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè láyọ̀.
‘Ẹ má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’ (Fílípì 2:3) Èyí kò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ ka àwọn ẹlòmíràn sí ẹni tí ó lọ́lá jù wá lọ nínú ohun gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé, ní àwọn apá kan nínú ìgbésí ayé, àwọn mìíràn lọ́lá jù wá lọ. A kò gbọdọ̀ fìgbà kankan ronú láé pé àwa tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa nìkan ni ó ní gbogbo ohun tí ó dára.
“Ní ti gidi, nígbà naa, níwọ̀n ìgbà tí àwá bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Wíwulẹ̀ lo ìdánúṣe láti jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ tí ó sì wúlò fún àwọn ẹlòmíràn, láìka àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sí, lè ṣe púpọ̀ láti dí àlàfo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.
“Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Olúkúlùkù ènìyán gbọ́dọ̀ yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nipa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Àwọn alájùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rere gbọ́dọ̀ ṣe ju sísọ̀rọ̀ lásán lọ; wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ agbatẹnirò.
“Ìmọ̀ nínú ọkàn ènìyán dà bí omi jíjìn; ṣùgbọ́n amòye ènìyàn níí fà á jáde.” (Òwe 20:5) Wà lójúfò láti fòye mọ àwọn ìmọ̀lára àti kókó ọ̀ràn tí ó wà lẹ́yìn ìhùwàsí òde ẹnì kan. Túbọ̀ mọ àwọn ènìyàn dáradára sí i.
“Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Jẹ́ agbatẹnirò nípa bíbojú wo àwọn ọ̀ràn láti ojú ìwòye ẹnì kejì. Má ṣe mọ tara rẹ nìkan.
Àìdọ́gba Àṣà Ìbílẹ̀ Láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
A rí ẹ̀rí pé àwọn ìlànà wọ̀nyí gbéṣẹ́ ní tòótọ́ nínú ìṣọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ń ṣiṣẹ́ ní 232 orílẹ̀-èdè ayé. Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ó wá láti “inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n,” tí wọ́n sì ti pinnu láti mú ara wọn bá àwọn ìdarísọ́nà onífẹ̀ẹ́ Jèhófà mu nínú ohun gbogbo.—Ìṣípayá 7:9; Kọ́ríńtì Kìíní 10:31-33.
Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan kì í pẹ̀gàn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí ó di Ẹlẹ́rìí kì í kọ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí a bí wọn sí sílẹ̀, àyàfi bí ó bá lòdì sí àwọn ìlànà inú Bíbélì. Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, wọ́n ń yí ìgbésí ayé wọn padà. Wọ́n mọ̀ pé àwọn apá ẹ̀ka tí ó wuyì ń bẹ nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti pé a túbọ̀ ń gbé àwọn wọ̀nyí yọ lára àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́.
Wọ́n ń tiraka láti bojú wo pílánẹ́ẹ̀ti wa bí ó ti yẹ kí Ọlọ́run rí i—ní dídán yanran, mímọ́ gaara, tí ó sì rẹwà—tí ń yí biiri la gbalasa òfuurufú já. Ó jẹ́ pílánẹ́ẹ̀tì kan tí ó ní àgbàyanu onírúurú ènìyàn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fojú sọ́nà fún àkókò náà, nígbà tí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò gbádùn ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí a so pọ̀ ṣọ̀kan ní tòótọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ láti wó àwọn ìdènà àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ palẹ̀