Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mo Bá Lọ Gbé Nílùú Tí Àṣà Tàbí Èdè Wọn Yàtọ̀ Sí Tèmi?
“Ará Ítálì làwọn òbí mi, wọ́n lọ́yàyà wọ́n sì máa ń kóni mọ́ra. Àmọ́ orílẹ̀-èdè Britain là ń gbé báyìí. Àwọn mètò ní tiwọn, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo nǹkan fínnífínní. Kò dà bíi pé mo rí èyí tó bá mi lára mu nínú àṣà méjèèjì. Mi ò fi taratara jọ àwọn ará Ítálì, mi ò sì lè ṣe bíi tàwọn ará Britain.”—Giosuè, láti orílẹ̀-èdè England.
“Nílé ìwé, olùkọ́ mi sọ fún mi pé ojú òun ni kí n máa wò tóun bá ń bá mi sọ̀rọ̀. Àmọ́, bí mo bá ń wo bàbá mi lójú nígbà tí wọ́n bá ń bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n á ní mo bà jẹ́. Mi ò mèyí tí ǹ bá fara mọ́ nínú àṣà ìbílẹ̀ méjèèjì.”—Patrick, tó ti orílẹ̀-èdè Algeria lọ gbé ní ilẹ̀ Faransé.
Ṣé orílẹ̀-èdè míì ni bàbá tàbí màmá rẹ ń gbé?
◻ Bẹ́ẹ̀ ni ◻ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Ṣé èdè tí wọ́n ń sọ nílé ìwé yín tàbí àṣà ìbílẹ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ ń relé ìwé yàtọ̀ sí tàwọn òbí ẹ?
◻ Bẹ́ẹ̀ ni ◻ Bẹ́ẹ̀ kọ́
ÀRÀÁDỌ́TA Ọ̀KẸ́ èèyàn ló ń lọ gbé lórílẹ̀-èdè míì lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ wọn ló sì ń kojú àwọn ìṣòro kàǹkà kàǹkà. Kì í pẹ́ tí wọ́n fi máa ń bára wọn láàárín àwọn èèyàn tí èdè, àṣà ìbílẹ̀ àti aṣọ wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Nítorí èyí, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Noor kíyè sí i pé àwọn tó bá lọ gbé lórílẹ̀-èdè míì kì í pẹ́ dẹni táwọn èèyàn fi ń ṣe yẹ̀yẹ́. Láti orílẹ̀-èdè Jordan ni ọmọbìnrin yìí àtàwọn òbí ẹ̀ ti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé aṣọ wa yàtọ̀. Àwàdà táwọn ará Amẹ́ríkà máa ń ṣe kì í sì í yé àwa ní tiwa.”
Bí ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Nadia ṣe rí tún yàtọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n bí mi sí. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ará Ítálì làwọn òbí mi, ó máa ń hàn nínú bí mo ṣe ń sọ èdè Jámánì, àwọn ẹlẹgbẹ́ mi nílé ìwé sì máa ń pè mí ní ‘ará ìlú òkè lásán.’ Àmọ́ bí mo bá lọ sí Ítálì, mo tún máa ń rí i pé Jámánì máa ń hàn nínú èdè Ítálì tí mò ń sọ. Nítorí náà, mi ò mọ ọmọ ibi tí mi ò bá sọ pé mo jẹ́ nínú méjèèjì. Àjèjì ni mo máa ń jẹ́ níbikíbi tí mo bá lọ.”
Ìṣòro míì wo làwọn ọmọ tí òbí wọn bá kó lọ sórílẹ̀-èdè míì tún máa ń kojú? Ọgbọ́n wo ni wọ́n sì lè dá sí i tí ò fi ní mu wọ́n lómi jù?
Èdè Kì Í Jọra bí Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Bá Yàtọ̀
Àwọn ọmọ táwọn òbí wọn kó lọ sórílẹ̀-èdè míì pàápàá tún lè rí i pé nǹkan kì í jọra nínú ilé. Kí ló máa ń fà á ná? Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tuntun máa ń tètè mọ́ àwọn ọmọdé lára ju àwọn òbí wọn lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Ana nígbà táwọn òbí ẹ̀ kó lọ sí ilẹ̀ England. Ó sọ pé: “Ní tèmi àti àbúrò mi, kò pẹ́ wa rárá tí àṣà wọn nílùú London fi mọ́ wa lára. Àmọ́ kò rọrùn fáwọn òbí mi tọ́jọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbé ní erékùṣù kékeré tó ń jẹ́ Madeira lórílẹ̀-èdè Potogí.” Voeun, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà táwọn òbí ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará Cambodia kó lọ sórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ibẹ̀ ò tètè mọ́ àwọn òbí mi lára. Kódà, bàbá mi tètè máa ń bínú bí mi ò bá ṣe ohun tí wọ́n ronú pó yẹ kí n ṣe.”
Bí àṣà ìbílẹ̀ bá yàtọ̀ síra kò ní jẹ́ kí èrò àwọn ọ̀dọ́ àti tàwọn òbí wọn ṣọ̀kan. Bó bá sì tún wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí ò lóye èdè táwọn ọmọ ń sọ, ńṣe ni àìṣọ̀kan tó wà nínú ìdílé á túbọ̀ máa gbòòrò sí i. Ohun tó sì sábà máa ń mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ọmọdé ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń gbédè tuntun káwọn òbí wọn tó gbọ́ ọ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, èdè tuntun náà á mú kí wọ́n máa gbàgbé èdè àwọn òbí wọn, bá á ṣe di pé àwọn òbí wọn ò ní lè báwọn sọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ mọ́ nìyẹn.
Ian, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá báyìí rí i pé irú àìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ wáyé láàárín òun àtàwọn òbí òun lẹ́yìn tí wọ́n ti orílẹ̀-èdè Ecuador kó lọ sí ìpínlẹ̀ New York. Ó wá sọ pé: “Ní báyìí, mo mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ ju èdè Sípáníìṣì lọ. Èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn olùkọ́ mi nílé ìwé ń sọ, òun làwọn ọ̀rẹ́ mi ń sọ, òun náà sì lèmi àtàwọn àbúrò mi máa ń sọ síra wa. Mo túbọ̀ ń lóye èdè Gẹ̀ẹ́sì, mo sì ń gbàgbé èdè Sípáníìṣì tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀.”
Ṣé ọ̀rọ̀ tìẹ àti ti Ian jọra? Báwọn òbí ẹ bá kó lọ síbòmíràn nígbà tó o wà lọ́mọdé, o lè má mọ̀ pé èdè àwọn òbí ẹ ṣì máa wúlò fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, o lè ti jẹ́ kó kúrò lọ́pọlọ ẹ. Noor, tá a ti kọ́kọ́ fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ sọ pé: “Bàbá mi gbìyànjú gidigidi pé ká máa sọ èdè táwọn gbọ́ nínú ilé, àmọ́ kò wù wá láti máa sọ èdè Lárúbáwá. Wàhálà làwa ka kíkọ́ èdè Lárúbáwá sí. Èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn ọ̀rẹ́ wa ń sọ. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń lò nínú àwọn ètò tá à ń gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n. Kí la wá fẹ́ fi èdè Lárúbáwá ṣe?”
Àmọ́, bó o bá ṣe ń dàgbà sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í mọrírì àwọn àǹfààní tó wà nínú sísọ èdè àwọn òbí ẹ. Àmọ́, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń tètè rántí tẹ́lẹ̀. Michael, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá táwọn òbí ẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Ṣáínà lọ gbé ní ilẹ̀ England sọ pé: “Mo máa ń ṣi èdè méjèèjì mú síra wọn.” Ornelle, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tó ti orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa) kó lọ sí ìlú London sọ pé: “Mò ń gbìyànjú láti sọ ohun kan fún màmá mi lédè Lingala, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún mi nítorí pé ó ti mọ́ mi lára láti máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.” Orílẹ̀-èdè Cambodia làwọn òbí Lee ti wá, àmọ́ ilẹ̀ Ọsirélíà ni wọ́n bí i sí. Ó máa ń dùn ún pé kò mọ èdè àwọn òbí ẹ̀ sọ dáadáa. Ó wá ṣàlàyé pé: “Bí mo bá ń báwọn òbí mi sọ̀rọ̀, tí mo sì fẹ́ ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ọ̀ràn kan ṣe rí lára mi, mo máa ń rí i pé mi ò lè sọ èdè wọn dáadáa.”
Ìdí Tó Fi Yẹ Kérò Àwọn Òbí Àtàwọn Ọmọ Ṣọ̀kan
Bó bá dà bíi pé o ò gbọ́ èdè àwọn òbí ẹ mọ́, má ṣe banú jẹ́ torí pé o ṣì lè padà gbọ́ ọ. Àmọ́, àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yé ẹ kedere. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní náà? Giosuè, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo kọ́ èdè táwọn òbí mi ń sọ torí pé mo fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa yéra wa, àti ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo fẹ́ kí èmi àtàwọn jọ máa sin Jèhófà. Kíkọ́ tí mo kọ́ èdè wọn ló jẹ́ kí n lóye bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tèmi náà túbọ̀ máa yé wọn.”
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ ló túbọ̀ ń kọ́ èdè táwọn òbí wọn ń sọ nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn míì tí wọ́n ń ti orílẹ̀-èdè kan kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Salomão, táwọn òbí ẹ kó lọ sí ìlú London nígbà tó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún sọ pé: “Àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé mo lè lo èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́! Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé èdè àwọn òbí mi tán, àmọ́ léyìí tí mo ti wá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Potogí báyìí, mo ti mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Potogí sọ dáadáa.” Oleg, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé báyìí sọ pé: “Inú mi máa ń dùn pé mo lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Mo lè ṣàlàyé Bíbélì fáwọn tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà, èdè Faransé, tàbí èdè Moldova.” Noor rí i pé àwọn tó ń sọ èdè Lárúbáwá nílò àwọn tó máa wàásù ìhìn rere fún wọn gan-an ni. Ó sọ pé: “Ní báyìí, mo ti ń tún èdè náà kọ́ kí n bàa lè máa sọ ọ́ dáadáa. Ojú tí mo fi ń wo èdè ti yí padà. Ẹni tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n sọ dáadáa ni mò ń wá báyìí.”
Kí lo lè ṣe kó o bàa lè padà mọ èdè àwọn òbí ẹ sọ dáadáa? Àwọn ìdílé kan ti rí i pé báwọn bá fi dandan lé e pé káwọn máa sọ èdè ìbílẹ̀ nìkan nígbà táwọn bá wà nílé, á ṣeé ṣe fáwọn ọmọ láti gbọ́ èdè méjèèjì dáadáa.a O sì tún lè ní káwọn òbí ẹ kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń kọ èdè náà sílẹ̀. Stelios, tí wọ́n tọ́ dàgbà lórílẹ̀-èdè Jámánì, tó jẹ́ pé Gíríìkì lèdè ìbílẹ̀ àwọn òbí ẹ̀, sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì kan pẹ̀lú mi lójoojúmọ́. Wọ́n máa ń kà á sókè ketekete, èmi á sì máa kọ ọ́ sílẹ̀. Mo ti wá mọ bí wọ́n ṣe ń ka èdè Gíríìkì àti èdè Jámánì báyìí, mo sì tún lè kọ méjèèjì sílẹ̀.”
Dájúdájú, bó o bá mọ̀ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ méjì tó o sì lè sọ èdè méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àǹfààní ńlá lo ní o. Bó o bá mọ̀ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ méjì, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún ẹ láti lóye báwọn èèyàn ṣe ń ronú, á sì yá ẹ lára láti lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọn nípa Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ń yọ̀ nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23) Ọmọ orílẹ̀-èdè Íńdíà làwọn òbí Preeti, àmọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n bí i sí. Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí pé mo lóye àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ méjì tó yàtọ̀ síra, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí mo bá wà lóde ẹ̀rí. Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ń gbà lóye àwọn èèyàn. Mo máa ń lóye ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hùwà.”
“Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú”
Bí àṣà tàbí èdè àwọn míì bá yàtọ̀ sí tìẹ, má ṣe jẹ́ kíyẹn káàárẹ̀ bá ẹ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ dà bíi tàwọn kan nínú Bíbélì nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, láti kékeré ni wọ́n ti mú Jósẹ́fù kúrò láàárín àwọn Hébérù bíi tiẹ̀ lọ síbi tí àṣà ìbílẹ̀ wọn ti yàtọ̀ nílùú Íjíbítì, ibẹ̀ ló sì gbé títí dọjọ́ ikú ẹ̀. Síbẹ̀, ó dájú pé kò gbàgbé èdè ìbílẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 45:1-4) Nítorí èyí, ó ṣeé ṣe fún un láti ran àwọn ìbátan rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.—Jẹ́nẹ́sísì 39:1; 45:5.
Tímótì bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gíríìkì ni bàbá rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Júù. (Ìṣe 16:1-3) Bó bá wo ti irú ilé tó ti jáde wá ni, ì bá nira fún un, àmọ́ ńṣe ló lo òye tó ní nípa àṣà tó yàtọ̀ síra láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nípa ṣíṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì.—Fílípì 2:19-22.
Ṣé ìwọ náà lè wo ipò tó o bá bára ẹ gẹ́gẹ́ bí àǹfààní tó o lè fi ṣe púpọ̀ sí i dípò kó o máa wò ó gẹ́gẹ́ bí ìdílọ́wọ́? Rántí pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, kì í ṣe nítorí ibi tó o ti wá, bí kò ṣe nítorí irú ẹni tó o jẹ́. Bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níbí yìí, ṣe ìwọ náà lè lo òye àti ìrírí tó o ní láti fi ran àwọn tẹ́ ẹ jọ ti ibì kan náà wá lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run wa tí kì í ṣe ojúṣàájú? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá ní ojúlówó ayọ̀!—Ìṣe 20:35.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá tún ń fẹ́ àwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Títọ́ Ọmọ Nílẹ̀ Òkèèrè Ìpèníjà àti Èrè Tó Wà Ńbẹ̀,” tá a tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2002.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ni èdè àti àṣà tí ò jọra ń fojú ẹ rí?
◼ Kí lo lè ṣe sí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí èdè àti àṣà tí kò jọra máa ń fà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Bó o bá ń sọ èdè àwọn òbí rẹ, ẹ máa wà ní ìṣọ̀kan