Iwọ Ha Ranti Bi?
Iwọ ha ti fun awọn itẹjade Ilé-ìṣọ́nà ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yii ni ironu afarabalẹ ṣe bi? Bi o ba ri bẹẹ, o ṣeeṣe ki o ru ọ soke lati ranti awọn ohun ti wọn tẹle e yii:
◻ Bawo ni akọsilẹ Bibeli nipa awọn ija ogun Jehofa ṣe fun wa ni igbọkanle nipa kikoju “ipọnju nla” naa? (Matiu 24:21)
Bi o ti jẹ pe oun nṣakoso nigba gbogbo, Jehofa le ronu tayọ ti awọn ọta rẹ̀ ki o sì dari awọn ipo fun igbala awọn eniyan rẹ̀.—8/15, oju-iwe 27.
◻ Ki ni awọn obi gbọdọ muratan lati ṣe lati pa ijumọsọrọpọ mọ laaarin awọn ati awọn ọmọ wọn?
Awọn obi gbọdọ lo akoko pẹlu awọn ọmọ wọn. Wọn tun gbọdọ muratan lati ṣe awọn irubọ nititori awọn ọmọ wọn fun idagba wọn niti ero ori, ara ìyára, ati tẹmi.—9/1, oju-iwe 22.
◻ Itumọ wo ni ipalarada Jesu ní fun wa loni? (Maaku 9:2-4)
Ipalarada naa lè gbé igbagbọ ró ninu ọrọ asọtẹlẹ Jehofa ó sì fun igbagbọ wa lokun ninu Jesu Kristi gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun ati Mesaya ti a ṣeleri naa. Ó lè tubọ fun igbagbọ wa ninu ajinde Jesu si iwalaaye tẹmi lokun ki o sì tun mu igbagbọ wa pọ sii ninu iṣakoso Ọlọrun.—9/15, oju-iwe 23.
◻ Ki ni itumọ “fun igba diẹ” ninu Aisaya 11:6?
Itumọ afarabalẹ ṣe ti ẹsẹ yii fihan pe ikooko ati ọdọ agutan ki yoo maa figba gbogbo wà layiika araawọn ninu aye titun. Ó lè ṣeeṣe pe iru awọn ẹranko bẹẹ ṣì lè ni ibugbe yiyatọ ki wọn sì tori bẹẹ wà labẹ isọwọ ‘ẹran ọsin ati ẹranko ẹhanna’ bi o ti wà ni Paradise ipilẹṣẹ. (Jẹnẹsisi 1:24) Bi o ti wu ki o ri, awọn ẹranko yoo wà ni alaafia pẹlu araawọn, wọn yoo sì lè wà layiika araawọn laisi ewu.—9/15, oju-iwe 31.
◻ Ki ni kọkọrọ si isin Kristẹni tootọ?
Ifẹ ni kọkọrọ naa si isin Kristẹni tootọ. Igbagbọ, awọn iṣẹ, ati ibakẹgbẹpọ titọna jẹ koṣeemani, ṣugbọn laisi ifẹ iniyelori wọn ni a kò lè ri. Eyi ri bẹẹ nitori pe Jehofa jẹ Ọlọrun ifẹ lọna ti ó ga julọ. (1 Kọrinti 13:1-3; 1 Johanu 4:8)—10/1, oju-iwe 20.
◻ Njẹ ọrọ naa “igba bibini, ati igba kiku” ni Oniwaasu 3:2 ti ero naa lẹhin pe Ọlọrun ti pinnu akoko iku wa ṣaaju?
Bẹẹkọ. Solomọni wulẹ njiroro bibaa niṣo iyipo akoko iwalaaye ati iku ti ńpọ́n iran araye alaipe loju ni. Oniwaasu 7:17 wi pe: “Iwọ ma ṣe buburu aṣeleke, bẹẹ ni ki iwọ ki ó ma ṣiwere; nitori ki ni iwọ yoo ṣe ku ki ọjọ rẹ ki o to pe?” Ọgbọn wo ni yoo wà ninu imọran yii bi akoko iku ẹnikan bá jẹ́ eyi ti a ti pinnu ṣaaju lọna ti kò ṣee yipada?—10/15, oju-iwe 5-6.
Ki ni ó tako ero naa pe apọsiteli Peteru jẹ biṣọobu Roomu akọkọ?
Ko si ẹ̀rí kankan pe Peteru tilẹ ṣebẹwo si ilu nla Roomu; bẹẹ si ni Peteru kò fi igbakanri tọka si araarẹ gẹgẹ bi ẹlomiran ju apọsiteli Kristi lọ. (2 Peteru 1:1)—10/15, oju-iwe 8.
◻ Ó ha tọna fun awọn Kristẹni lati fi òdòdó ranṣẹ fun isinku kan?
Bi a bá mọ̀ ọ́n daradara pe aṣa kan (tabi iṣẹ ọna kan, iru bii agbelebuu) ni itumọ isin èké ni agbegbe ẹni ni lọwọlọwọ, a gbọdọ yẹra fun un. Nitori naa Kristẹni ki yoo maa tipa bayii fi òdòdó ranṣẹ ni irisi agbelebuu kan tabi lò wọn ni ọna eto aṣa kan ti o daju pe o ni itumọ isin èké. Bi o ti wu ki o ri, ni akoko yii ni ọpọlọpọ ilẹ, aṣa pipese òdòdó laisi isopọ ti isin jẹ́ eyi ti ó wọpọ. Awọn Kristẹni kan ti fi òdòdó ranṣẹ lati fi imoriyagaga kún iṣẹlẹ bibanininujẹ kan ati lati fi ibanikẹdun ati idaniyan han.—10/15, oju-iwe 31.
◻ Ki ni awọn itumọ ti o ni aṣẹ mu ṣe kedere nipa Mẹtalọkan?
Wọn mu un ṣe kedere pe ẹkọ Mẹtalọkan kii ṣe ero ti ó rọrun kan. Kaka bẹẹ, ó jẹ atojọ ero didiju kan ti a ti so papọ la ọpọlọpọ ọrundun kọja ti a sì ti wépọ̀ mọ araawọn. Pupọ awọn ọmọwe, eyi ti ó ni ninu awọn ti ó gbagbọ ninu Mẹtalọkan, gbà pe Bibeli niti gidi kò ni ẹkọ Mẹtalọkan ninu.—11/1, oju-iwe 21, 22.
◻ Eeṣe ti 29 C.E. fi jẹ deeti pataki ninu itan Bibeli?
Nitori pe ni pipa awọn isọfunni Bibeli ti ó ṣe pato pọ̀ mọ kika deeti ti ayé nipa iṣakoso Tiberiu, awọn akẹkọọ Bibeli lè ṣiro pe iṣẹ-ojiṣẹ Johanu bẹrẹ ni igba iruwe 29 C.E. ati pe oṣu mẹfa lẹhin naa, ni igba iwọwe 29 C.E., Johanu bamtisi Jesu.—11/15, oju-iwe 31.
◻ Ki ni “ijọsin” tumọsi fun awọn eniyan ti wọn nsọ èdè Heberu, bawo si ni eyi ṣe kan awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii?
Ọrọ Heberu naa ti ó ṣe deedee pẹlu ọrọ naa “ijọsin” ni a lè tumọsi “iṣẹ-isin.” Nitori naa, ninu ero inu Heberu, ijọsin tumọsi iṣẹ-isin. Ohun ti ó tumọsi niyii fun awọn eniyan Jehofa lonii, nitori naa ami kan ti ó ṣe pataki ti isin tootọ ni iṣẹ-isin oniwa-bi-Ọlọrun ti wiwaasu.—12/1, oju-iwe 19.