ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 26-27
  • Àwọn Ìyá Tó Ní Àrùn Éèdì Ko Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìyá Tó Ní Àrùn Éèdì Ko Ìṣòro
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìṣòro Dídíjú Tó Ń Dènà Ojútùú Rírọrùn
  • Àwọn Oògùn Tí Ń Bá Àrùn Éèdì Jà Ńkọ́?
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 26-27

Àwọn Ìyá Tó Ní Àrùn Éèdì Ko Ìṣòro

CYNTHIA,a obìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè West Indies, ní yíyàn méjì, yálà kó fi ọmú bọ́ ọmọ rẹ̀ tàbí kó fi oúnjẹ inú agolo bọ́ ọ. Èèyàn lè rò pé ìpinnu tó rọrùn-ún ṣe ni. Ṣebí ọjọ́ ti pẹ́ táwọn tó mọ̀ nípa ọ̀ràn ìlera ti ń ké gbàjarè pé wàrà ìyá ni “oúnjẹ aṣaralóore jù lọ” fáwọn ọmọ ọwọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ní àwọn ilẹ̀ tálákà, ó jọ pé àrunṣu lè pa àwọn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n fi oúnjẹ inú agolo bọ́ ní ìlọ́po mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ju àwọn tí wọ́n fún lọ́mú. Àní sẹ́, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) ròyìn pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọmọdé ló ń kú lọ́dọọdún nítorí ewu àwọn oúnjẹ míì táwọn èèyàn fi ń rọ́pò ọmú ìyá.

Àmọ́ ní ti Cynthia, ìpinnu láti fọ́mọ lọ́mú tún wé mọ́ ewu míì lọ́tọ̀. Ó ti kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn lára ọkọ rẹ̀, fáírọ́ọ̀sì yìí ló sì máa ń fa éèdì. Lẹ́yìn tí Cynthia bímọ ni wọ́n wá sọ fún un pé ọ̀kan nínú méje àwọn ọmọ tí ìyá tó ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn bá bí, ló máa ń kó fáírọ́ọ̀sì náà látinú wàrà ìyá wọn.b Nípa báyìí, ìpinnu tó le koko ló dojú kọ ọ́: yálà kó fẹ̀mí ọmọ rẹ̀ wewu nípa fífún un lọ́mú, tàbí kó fi í sínú ewu míì nípa fífi oúnjẹ inú agolo bọ́ ọ.

Ní àwọn apá ibi tí àjàkálẹ̀ àrùn éèdì ti gbilẹ̀ jù lọ láyé, méjì sí mẹ́ta lára gbogbo aboyún mẹ́wàá ló ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn. Lórílẹ̀-èdè kan, èèràn ti ran àwọn tó lé ní ìdajì lára àwọn aboyún tí wọ́n yẹ̀ wò. Rédíò àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé: “Ìṣírò tí ń kó ìdágìrì báni yìí ló ń lé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ léré láti tètè wá nǹkan ṣe sọ́ràn náà.” Láti kojú ìpèníjà yìí, àjọ mẹ́fà látinú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti pa ìrírí, ìsapá, àti agbára wọn pọ̀, láti dá àjọ kan sílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Ètò Tí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Pawọ́ Pọ̀ Ṣe Lórí Fáírọ́ọ̀sì Tó Ń Pa Agbára Ìdènà Àrùn àti Éèdì, ìkékúrú orúkọ àjọ yìí ni UNAIDS.c Ṣùgbọ́n UNAIDS ti rí i pé wíwá ojútùú sí ìṣòro éèdì kò rọrùn rárá.

Àwọn Ìṣòro Dídíjú Tó Ń Dènà Ojútùú Rírọrùn

Edith White, tó mọwámẹ̀yìn nípa ọ̀ràn fífọ́mọlọ́mú àti bí ìyá ṣe ń kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn ran ọmọ, sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n jẹ mọ́ ọ̀ràn ìlera ti ń kìlọ̀ fáwọn obìnrin tó ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà pé kí wọ́n má ṣe fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú, níwọ̀n bí èyí ti máa ń dá kún ewu pé ọmọ náà lè kó fáírọ́ọ̀sì. Lílo wàrà oníyẹ̀fun ló jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti yíjú sí. Àmọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà—níbi tí àwọn àbá tí kò lè ṣẹ ti sábà máa ń já sí pàbó—ojútùú rírọrùn yìí máa ń ṣòroó mú lò.

Ọ̀kan lára ìṣòro náà jẹ́ ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣe pé fífọ́mọlọ́mú ló wọ́pọ̀, a lè sọ pé àwọn obìnrin tó ń fi oúnjẹ inú agolo bọ́ ọmọ wọn ń pariwo ara wọn síta pé àwọn ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn. Ẹ̀rù lè máa ba obìnrin kan pé táwọn èèyàn bá mọ ohun tó ń ṣe òun pẹ́nrẹ́n, ṣe ni wọ́n á máa dá òun lẹ́bi, tàbí kí wọ́n pa òun tì, tàbí kí wọ́n lu òun. Àwọn obìnrin kan tó bá ara wọn nínú ipò yìí ti pinnu pé kò sóhun táwọn lè ṣe ju pé kí àwọ́n máa fi ọmú bọ́ ọmọ àwọn, káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé àwọn alára ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn.

Àwọn ìṣòro míì tún wà o. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Margaret, tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún, yẹ̀ wò. Obìnrin yìí ò tíì lọ fún àyẹ̀wò rí láti mọ̀ bóyá òun ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn, bó sì ṣe rí nìyí láàárín ó kéré tán ìpín márùndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí ń gbé lábúlé ní Uganda. Ṣùgbọ́n kí Margaret má ṣàfira o. Nítorí pé ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́ ti kú, fòní-kú-fọ̀la-dìde sì ni ọmọ rẹ̀ kejì. Ìgbà mẹ́wàá ni Margaret ń fún ọmọ rẹ̀ kẹta lọ́mú lóòjọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí obìnrin yìí ti ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn. Ó sọ pé: “Mi ò lè fi wàrà inú agolo bọ́ ọmọ mi láé.” Kí ló dé? Margaret sọ pé iye téèyàn máa ná sórí fífi wàrà oníyẹ̀fun bọ́ ọmọ ti wọ́n jù, ó fi ìlọ́po kan àtààbọ̀ pọ̀ ju iye tí ń wọlé fún ìdílé kọ̀ọ̀kan lábúlé rẹ̀ lọ́dún kan gbáko. Ká tiẹ̀ sọ pé ọ̀fẹ́ ni wàrà ọ̀hún, kò síbi tí wọ́n á ti rí omi tó mọ́ tí wọ́n á fi pò ó láìjẹ́ pé àwọn ọmọdé tibẹ̀ kó àrùn míì.d

Àwọn ìṣòro yìí lè dín kù bí àwọn ìyá tó ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn bá ní ètò ìmọ́tótó tó yẹ, bí wọ́n bá ní òunjẹ inú agolo tó pọ̀ tó, àti bí wọ́n bá ni omi tó dáa. Ṣé nǹkan wọ̀nyí ò wọ́n jù báyìí? Ó jọ bẹ́ẹ̀ o. Àmọ́, ó yani lẹ́nu pé àtirówó ṣètò nǹkan wọ̀nyí kọ́ ló jà, bí kò ṣe ohun táa kà sí pàtàkì. Àní, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé owó tí àwọn kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ lágbàáyé ń ná lórí ọ̀ràn ogun jẹ́ ìlọ́po méjì owó tí wọ́n ń ná lórí ọ̀ràn ìlera àti ẹ̀kọ́.

Àwọn Oògùn Tí Ń Bá Àrùn Éèdì Jà Ńkọ́?

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń bá àjọ UN ṣiṣẹ́ ròyìn pé oògùn kan, tó rọrùn láti rí, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́n, tí wọ́n ń pè ní AZT, lè dènà kíkó táwọn ìyá ń kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn ran àwọn ọmọ. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àjọ UNAIDS, iye rẹ̀ kò ju àádọ́ta dọ́là lọ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn olùwádìí nípa àrùn éèdì kéde ní July 1999 pé oògùn kan tí wọ́n ń pè ní nevirapine, tí wọn óò máa fi tọ́jú àwọn ìyá tó ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn àtàwọn ọmọ wọn tuntun, kò lè náni ju dọ́là mẹ́ta péré lọ, wọ́n sì sọ pé ó tiẹ̀ jọ pé oògùn yìí tún ń ṣiṣẹ́ ju AZT ní dídènà ìtànkálẹ̀ fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn. Àwọn ògbógi nípa ọ̀ràn ìlera sọ pé nevirapine lè gba ogún ọ̀kẹ́ ọmọ tuntun lọ́wọ́ kíkó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn ní kùtùkùtù ìgbésí ayé wọn.

Ṣùgbọ́n o, àwọn kan tún ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn oògùn yẹn, wọ́n ní ṣebí kò lè ṣe ju wíwulẹ̀ dènà kí ìyá kó fáírọ́ọ̀sì náà ran ọmọ, wọ́n ní níwọ̀n ìgbà tí kò pa fáírọ́ọ̀sì náà lára ìyá, kò sígbà tí ìyá ọ̀hún ò ní kó àrùn éèdì, tí yóò sì kú fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. Àjọ UN wá dá wọn lóhùn pé a ò kúkú lè tìtorí èyí lajú sílẹ̀ ká wá jẹ́ kí àwọn ọmọ ọwọ́ máa kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn, ká jẹ́ kí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yìí wáyé ìyà, kí wọ́n sì kú ikú oró. Wọ́n tún sọ síwájú sí i pé ìyá tó bá ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn ṣì lè ṣe ọ̀pọ̀ ọdún láyé kó tó kú. Ẹ jẹ́ ká tún padà sórí ọ̀ràn Cynthia táa sọ níbẹ̀rẹ̀. Nígbà tó bí ọmọ rẹ̀ ní ọdún 1985 ni wọ́n sọ fún un pé ó ti kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn, àmọ́ ọdún mẹ́jọ kọjá kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà ní fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn nígbà tó bí i, nígbà tọ́mọ náà fi máa pé ọmọ ọdún méjì, kò ní in mọ́.

Ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi tù wá nínú ni pé, láìpẹ́ sígbà táa wà yìí, àyíká aláìléwu yóò dé lóòótọ́, ìṣòro àwọn àjàkálẹ̀ àrùn bí éèdì yóò sì yanjú pátápátá. (Ìṣípayá 21:1-4) Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí ayé tuntun níbi tí kì yóò ti “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fẹ́ láti sọ fún ẹ nípa ojútùú tí gbogbo ìṣòro náà máa ní. Bóo bá fẹ́ gbọ́ sí i nípa rẹ̀, jọ̀wọ́ kàn sí àwa táa ṣe ìwé ìròyìn yìí tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an nìyí.

b Àjọ UNICEF sọ pé lójoojúmọ́, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún sí méje àwọn ìkókó ló ń kó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn látinú wàrà ìyá wọn.

c Àwọn àjọ mẹ́fà náà ni UNICEF, Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Ìdàgbàsókè, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Iye Ènìyàn, Àjọ Ìlera Àgbáyé, Báǹkì Àgbáyé, àti Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ọdún 1995 ni wọ́n dá àjọ UNAIDS sílẹ̀.

d Ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí kan sọ pé lílo wàrà oníyẹ̀fun àti wàrà ìyá lè tún fi kún ewu kíkó fáírọ́ọ̀sì tó ń pa agbára ìdènà àrùn, àti pé wàrà ìyá lè ní àwọn èròjà tó lè gbógun ti fáírọ́ọ̀sì yìí. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, á jẹ́ pé fífọ́mọlọ́mú nìkan ló sàn jù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó léwu nínú. Àmọ́ o, èèyàn ò tíì lè fi gbogbo ara gbọ́kàn lé ìwádìí yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Àjọ WHO/E. Hooper

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́