Ìrànlọ́wọ́ Fáwọn Èèyàn Tí Wọ́n Dá Lóró
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ DENMARK
“Ó RỌRÙN LÁTI TO EEGUN TÓ ṢẸ́ JU LÁTI WO ỌKÀN TÓ GBỌGBẸ́ SÀN.”—Dókítà Inge Genefke.
Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN kan ń rin ìrìn gbẹ̀fẹ́ ládùúgbò kan tó parọ́rọ́ nílùú kan ní Yúróòpù, ó sì ní kóun kàn sáà wo àwọn ọjà tí wọ́n tò sójú fèrèsé kan. Lójijì, ṣe ni ọwọ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Eékún rẹ̀ sì ń gbọ̀n. Ó ń tẹ ọ̀fun bí ẹni pé kò lè mí dáadáa mọ́. Ohun tó rí lójú fèrèsé yẹn ni òjìji ọlọ́pàá méjì tó wọṣọ. Kì í kúkú ṣe pé ọ̀dọ́mọkùnrin náà rúfin, kò sì yẹ kó bẹ̀rù. Ṣùgbọ́n, kìkì pé ó rí àwọn tó wọṣọ ọlọ́pàá mú un rántí ibì kan tó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà síbi tó wà, níbi tí wọ́n ti dá a lóró lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
Ohun kan náà sì lè máa ṣẹlẹ̀ sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé pàápàá. Ó lè máa ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan tóo mọ̀. Ẹni tí wọ́n hàn léèmọ̀ lè jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi tàbí ará ilẹ̀ òkèèrè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sádùúgbò yín. Bóyá iléèwé kan náà lọmọ tiẹ̀ àtọmọ tìẹ jọ ń lọ. Bóyá o kà á séèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àti ẹni pẹ̀lẹ́, tí kì í ṣaápọn, tó rọra ń lọ nílọ tiẹ̀. Àmọ́ ìrísí lè tanni jẹ; ìrísí lè bo pákáǹleke inú lọ́hùn-ún tó ń bá onítọ̀hún fínra mọ́lẹ̀, bó ti ń jà raburabu láti gbàgbé ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn tó ti ní sẹ́yìn. Ohunkóhun tó bá rí—tàbí ìró èyíkéyìí tó bá gbọ́—lè mú un rántí ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àtẹ̀yìnwá. Ẹnì kan tí irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí sọ pé: “Ìgbàkigbà tí mo bá gbọ́ tí ọmọ ọwọ́ ń ké ni mo máa ń rántí àwọn tí mo gbọ́ tí wọ́n ń ké nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìgbàkigbà tí mo bá gbọ́ tí nǹkan kan ń dún fàì-fàì ni mo máa ń rántí ẹgba tó ń lọ sókè sódò—bó ṣe máa ń dún kó tó balẹ̀ sí mi lára.”
Àwọn jàǹdùkú olóṣèlú àti ẹgbẹ́ àwọn apániláyà nìkan kọ́ ló ń dáni lóró. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ológun àti ọlọ́pàá máa ń dáni lóró. Nítorí kí ni? Ìdánilóró lè jẹ́ ọ̀nà tó yá, tó sì gbéṣẹ́ láti fi wádìí nǹkan lẹ́nu èèyàn, láti fi túláàsì mú káwọn èèyàn jẹ́wọ́, láti fi kó àwọn ẹlòmíì sí yọ́ọ́yọ́, tàbí láti fi ránró. Dókítà Inge Genefke, ará Denmark, tó tún jẹ́ òléwájú nínú àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀ràn ìdánilóró, sọ pé nígbà míì àwọn ìjọba tó wà lórí àlééfà “ohun tó gbé wọn débẹ̀, tí wọ́n sì fi lè máa ṣèjọba nìṣó ni dídá àwọn èèyàn lóró.” Ẹnì kan tí wọ́n dá lóró sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Wọ́n fẹ́ kí n bọ́hùn, kí àwọn ẹlòmíì lè rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá bẹnu àtẹ́ lu ìjọba.”
Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìgbà tójú ò tíì là nìkan làwọn èèyàn ń dá èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lóró. Ṣebí láti ọdún 1948 ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fọwọ́ sí Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé, tó sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lóró tàbí hàn án léèmọ̀, tàbí hùwà ìkà sí i tàbí ṣe é ṣúkaṣùka.” (Ẹ̀ka karùn-ún) Àmọ́, àwọn ògbógi kan sọ pé iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi táwọn èèyàn ń dá lóró tó ìpín márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún. Kí ló fà á tí ìdánilóró fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ipa wo ló ń ní lórí àwọn tí wọ́n ń dá lóró, kí sì ni a lè ṣe láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́?
Ìyọrísí Rẹ̀
Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dá lóró fi máa ń sá kúrò ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn láti lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun níbòmíì. Àmọ́ bí àyíká tilẹ̀ yí padà, ìrora náà—ti ara ìyára àti ti èrò orí—ṣì ń bá a lọ. Fún àpẹẹrẹ, onítọ̀hún lè máa rò pé òun ló lẹ̀bi àìlègba àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ òun lọ́wọ́ ìyà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó lè máà gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹlòmíì mọ́, ó lè máa bẹ̀rù pé amí ni gbogbo àwọn tóun ń bá pàdé. Òǹkọ̀wé nì, Carsten Jensen, sọ pé: “Àjèjì ayérayé ni ẹni tí wọ́n dá lóró máa ń dà. Kò ní gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni mọ́ láé.”
Ohun tó máa ń fà ni ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà tó lè kó ìdààmú bá àtòun àtàwọn tó ń gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́. Ó lè rọrùn láti wá nǹkan ṣe sí ìrora, ṣùgbọ́n ẹ̀dùn ọkàn ṣòroó wò. Dókítà Genefke sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, a máa ń ronú pé, ‘Ṣebí ìrora lásán ni, ìyẹn ò le kẹ̀, àá wọ́gbọ́n dá sí i—kíá lara wọn máa le.’ Àmọ́, kì í pẹ́ táa fi máa ń rí i pé ẹ̀dùn ọkàn gan-an lohun tó ń jàrábà wọn.” Ṣùgbọ́n o, Dókítà Genefke sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ó ṣeé ṣe láti mú ìtura bá wọn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́, kódà bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tiẹ̀ ti kọjá.”
Ní 1982, ní Ọsibítù Ìjọba Nílùú Copenhagen, Dókítà Genefke pẹ̀lú àwọn oníṣègùn ará Denmark mìíràn, gbé ẹ̀ka kékeré kan kalẹ̀ fún títọ́jú àwọn olùwá-ibi-ìsádi táwọn èèyàn dá lóró. Nǹkan tó bẹ̀rẹ̀ ní kékeré yẹn ló ti wá di ètò kárí ayé báyìí lábẹ́ orúkọ náà Ẹgbẹ́ Tí Ń Tọ́jú Àwọn Táwọn Ẹlòmíì Dá Lóró Lágbàáyé. Láti oríléeṣẹ́ rẹ̀ tó wà nílùú Copenhagen ni ẹgbẹ́ yìí ti ń darí iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ láwọn ibùdó tó ju ọgọ́rùn-ún lọ lágbàáyé. Láàárín ọdún wọ̀nyí, ẹgbẹ́ náà ti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn táwọn ẹlòmíì dá lóró.
Báa Ṣe Lè Ṣètìlẹyìn
Ó sábà máa ń ṣèrànwọ́ bí àwọn tí wọ́n dá lóró bá sọ ohun tójú wọ́n rí. Ìwé ìsọfúnni kan látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣètọ́jú yìí sọ pé: “Ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, ìyà ọ̀nà méjì ló ń jẹ àwọn táwọn ẹlòmíì ń dá lóró. Èkínní, ìyà ń jẹ wọ́n nípa tara àti nípa ti èrò orí, àti èkejì, àìlèsọ̀rọ̀ síta tún ń fìyà jẹ wọ́n.”
Òtítọ́ ni pé ọ̀rọ̀ nípa ìdálóró kì í ṣọ̀rọ̀ tó dùn-ún sọ. Àmọ́, bí ẹni tí wọ́n dá lóró bá fẹ́ finú han ọ̀rẹ́, tí ọ̀rẹ́ sì kọ̀ láti gbọ́, èyí lè dá kún ẹ̀dùn ọkàn onítọ̀hún. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a fi onítọ̀hún lọ́kàn balẹ̀ pé ẹnì kan tó bìkítà wà. Èyí ò wá ní kéèyàn di alátojúbọ̀ o. Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ọwọ́ ẹni tí wọ́n dá lóró ni ìpinnu wà ní ti bóyá òun yóò finú han ẹnikẹ́ni, àti ẹni tí òun yóò finú hàn, àti ìgbà tí òun yóò finú hàn án.—Òwe 17:17; 1 Tẹsalóníkà 5:14.
Ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ògbógi dámọ̀ràn ni pé kéèyàn ronú nípa ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn tí ìdánilóró ń fà. Fún àwọn kan, wọ́n ní láti lọ gba ìrànlọ́wọ́ àwọn ògbógi kí ara wọ́n tó lè padà bọ̀ sípò. Ìtọ́jú tí a ń fún wọn wé mọ́ ìgbòkègbodò tí ń mú kí wọ́n lè mí láìsíṣòro kí wọ́n sì lè bá èèyàn sọ̀rọ̀ láìsí wàhálà.a Ìṣòro ìtìjú sábà máa ń wà lára nǹkan tí wọ́n ní láti kọ́kọ́ yanjú. Olùtọ́jú kan sọ fún obìnrin tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ léraléra, tí wọ́n sì lù, pé: “Ojú tó ń tì ẹ́ kò ṣàjèjì, ó sì bá ìwà ẹ̀dá mu. Ṣùgbọ́n rántí pé ìwọ kọ́ lo ṣe nǹkan ìtìjú. Àwọn tó ṣe eléyìí sí ẹ ló yẹ kójú tì.”
Àwọn Tó Yè Bọ́ Nínú Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ojú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn rí màbo nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Hitler. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí pé wọn ò kọ ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da irú àdánwò burúkú bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo?
Tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó ju àwọn Kristẹni wọ̀nyí sẹ́wọ̀n ni wọ́n ti ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Fún ìdí yìí, àdánwò náà kò bá wọn lábo, wọn ò sì bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́bi fún Ọlọ́run nígbà tí ìyà náà kò tètè dópin. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí ti mọ̀dí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti bí yóò ṣe fòpin sí i nígbà tó bá tákòókò lójú rẹ̀. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo” ni Jèhófà àti pé ọkàn rẹ̀ máa ń gbọgbẹ́ nígbà táwọn èèyàn bá ń fojú èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn gbolẹ̀.—Sáàmù 37:28; Sekaráyà 2:8, 9.
Àmọ́ o, ó ti di dandan fún ọ̀pọ̀ lára àwọn tó la àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já wọ̀nyí láti fara da ìròbìnújẹ́ tó ń jẹ yọ láti inú ohun tójú wọ́n rí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ti jèrè okun ńláǹlà nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fimú dánrin nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Róòmù, ipò tó ṣeé ṣe kí ó kó àníyàn ńlá bá a, ó kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 1:13; 4:6, 7.
Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ wọ̀nyí mọ̀ pé Ọlọ́run ti ṣèlérí láti sọ ilẹ̀ ayé di párádísè, níbi tí kì yóò ti sí àròdùn mọ́ nítorí ìwà ìfojú-ẹni-gbolẹ̀, bíi ìdánilóró.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàjọpín ìrètí yìí tó bá Bíbélì mu pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn ní igba ó lé ọgbọ̀n ilẹ̀. Rúkèrúdò kárí ayé ń jẹ́ kí wọ́n rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí ojú ti pọ́n nítorí ìwà ìkà táwọn èèyàn ti hù sí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá ṣalábàápàdé àwọn táwọn èèyàn ti dá lóró, wọ́n máa ń ṣàjọpín ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn èèyàn yìí. Ẹ wo bí inú wọn ti ń dùn tó láti wàásù ìhìn ayọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la kan nígbà tí ìdánilóró yóò di ohun àtijọ́!—Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jí! ò yan ìtọ́jú èyíkéyìí láàyò. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ gbà kò lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
“A Ò GBỌ́DỌ̀ DÁ ẸNIKẸ́NI LÓRÓ TÀBÍ HÀN ÁN LÉÈMỌ̀, TÀBÍ HÙWÀ ÌKÀ SÍ I TÀBÍ ṢE É ṢÚKAṢÙKA.”—Ẹ̀ka Karùn-ún, Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
BÓO ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́
BÓO BÁ MỌ ẸNÌ KAN TÓ ṢẸ̀ṢẸ̀ Ń BỌ́ LỌ́WỌ́ ÀKÓBÁ TÍ ÌDÁNILÓRÓ ṢE FÚN UN, ÀWỌN ÀBÁ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ LÈ ṢÈRÀNWỌ́:
● Ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. O lè sọ pé: “Mo mọ̀ pé wàhálà pọ̀ ní orílẹ̀-èdè tóo ti wá. Báwo ni gbogbo nǹkan ṣe ń lọ?”—Mátíù 7:12; Róòmù 15:1.
● Má yọjúràn, má sì fi tipátipá pèsè ìrànlọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ onínúure àti olùgbatẹnirò. Jẹ́ kí onítọ̀hún mọ̀ pé elétíi-gbáròyé ni ẹ́.—Jákọ́bù 1:19.
● Aájò ò gbọ́dọ̀ pọ̀ jù. Fi ọ̀wọ̀ onítọ̀hún wọ̀ ọ́, má sì kọjá àyè ẹ. O fẹ́ ràn án lẹ́rù ni, kò sì yẹ kí gbà-ràn-mí rẹ dẹlẹ́rù.