Àwọn Irin Iṣẹ́ Ìdálóró Tí Kò Ṣeé Finú Wòye
ÀWỌN ọ̀rọ̀ náà, “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀,” “ìdálóró,” àti “ìṣekúpani” ha ń mú ọ wá rìrì bí? Wọ́n jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gidi tí kò bára dé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n jìyà Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ àti ìgbẹ́jọ́ àwọn tí a pè ní àjẹ́ ní Yúróòpù (láàárín ọ̀rúndún kẹtàlá sí ìkọkàndínlógún). Àwọn irin iṣẹ́ tí a fi hàn níhìn-ín, tí wọ́n jẹ́ tí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan ní ìlú Rüdesheim lórí odò Rhine, ní Germany, jẹ́ ti ìgbà yẹn. Wọ́n fún wa ní ìṣọfúnni ráńpẹ́ nípa irú ìyà tí ó jẹ àwọn ènìyàn náà.
Òjìyà aláìlólùràn-lọ́wọ́ náà fimú danrin ìrora tí kò ṣeé ṣàpèjúwe nígbà tí ó jókòó níhòòhò fún ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò lórí àga Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀, tí wọ́n da ẹ̀gún tí ẹnu rẹ̀ ṣe ṣóńṣó dáadáa lé. Àwọn ìdè orúnkún ya apá, ẹsẹ̀, tàbí àwọn oríkèé ara òjìyà náà jálajàla tàbí kí ó bà wọ́n jẹ́. Wọ́n fi èékánná ológbò la awọ ara rẹ̀ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́; wọn kò dá apá kan lára rẹ̀ sí. Ẹ̀wọ̀n àgbékọ́rùn ẹlẹ́gùn-ún mú kí ọrùn, èjìká, àti párì òjìyà náà máa kẹ̀ fún egbò, tí ó tètè fa kòkòrò àrùn tí ń gbógun ti ìṣàn ẹ̀jẹ̀ àti ikú.
Àwọn Olùṣèwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ tí Ìjọ Roman Kátólíìkì yanṣẹ́ fún lo àwọn irin iṣẹ́ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn tí ó jọ wọ́n láti fìyà jẹ àwọn oníyapa—tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ènìyàn gbáàtúù tí wọ́n ti fi bú, tí wọ́n ti wá fipá mú wọn ṣe “ìjẹ́wọ́” wọn nípasẹ̀ ìdálóró. Ní gidi, nígbà Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ tí póòpù ṣe fún Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, wọ́n tilẹ̀ fi omi mímọ́ wọ́n àwọn irin iṣẹ́ ìdálóró.
Kirisẹ́ńdọ̀mù ru ẹrù ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo nítorí Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ náà. Òpìtàn Walter Nigg ṣàlàyé pé: “Kirisẹ́ńdọ̀mù kì yóò tún rí ìbùkún gbà mọ́ àyàfi tí ó bá pàpà jẹ́wọ́—ní gbangba àti pẹ̀lú ìdánilójú tí ó jinlẹ̀—àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nínú Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ náà, láìṣàbòsí, kí ó sì jáwọ́ pátápátá nínú onírúurú ìwà ipá tí ó ń hù, lórúkọ ìsìn.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àga Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀
Ìdè orúnkún
Èékánná ológbò
Ẹ̀wọ̀n àgbékọ́rùn ẹlẹ́gùn-ún
[Credit Line]
Gbogbo àwòrán: Mittelalterliches Foltermuseum Rüdesheim/Rhein