ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 12/8 ojú ìwé 14-15
  • Wọ́n Ṣí Ibi Àkójọ Ìwé Àṣírí Fáráyé Wọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ṣí Ibi Àkójọ Ìwé Àṣírí Fáráyé Wọ̀
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Wà Nínú Wọn?
  • Ìṣelámèyítọ́
  • ‘Kò Sí Àṣírí Tí Kì Yóò Di Mímọ̀’
  • Gbígbẹ́jọ́ “Aládàámọ̀” Kan Àti Pípa á
    Jí!—1997
  • Àwọn Irin Iṣẹ́ Ìdálóró Tí Kò Ṣeé Finú Wòye
    Jí!—1998
  • Bibeli Ha Jẹ́ Ẹbun Kan Lati Ọdọ Ọlọrun Nitootọ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ija-ogun Bibeli Ledee Spanish fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Jí!—1998
g98 12/8 ojú ìwé 14-15

Wọ́n Ṣí Ibi Àkójọ Ìwé Àṣírí Fáráyé Wọ̀

LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ

“A ṣí ibi àkójọ ìwé Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ Fáráyé Wọ̀.” Èyí ni ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sọ nípa bí Ibùjókòó Ìjọba Póòpù ṣe gba àwọn ọ̀mọ̀wé láyè láti dé ibi tí Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Tí Ń Rí Sí Ìgbàgbọ́ Ẹ̀sìn Kátólíìkì, tí a mọ̀ sí Ọ́fíìsì Mímọ́ títí di ọdún 1965, ń tọ́jú àwọn ìwé rẹ̀ sí.

WỌ́N sọ pé kí a fojú wo ìgbésẹ̀ náà “bí apá kan ìlànà àtúnṣe àtọjọ́mọ́jọ́ tí ó wà nínú ìtàn, tí a sì ṣètò dáradára, tí John Paul Kejì fẹ́ parí kí ó tó di ọdún 2000.”a Kí ló fà á tí a lọ́kàn ìfẹ́ tó bẹ́ẹ̀ nínú àkójọ ìwé wọ̀nyí? Àwọn àṣírí wo ni a lérò pé ó wà nínú wọn?

Póòpù Paul Kẹta ló gbé Ọ́fíìsì Mímọ́ náà kalẹ̀ ní 1542. A tún ń pe ohun tí póòpù lò láti fipá kápá “àdámọ̀” yìí ní Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti Róòmù, láti fìyàtọ̀ sáàárín òun àti Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti Sípéènì tí wọ́n ṣe ní 1478.b Adriano Prosperi, tí ó jẹ́ abẹnugan lórí ọ̀ràn àdámọ̀, sọ pé, ẹgbẹ́ àwọn kádínà tí a gbé kalẹ̀ ní 1542 ni yóò “máa bójú tó ọ̀ràn nípa àdámọ̀ nínú gbogbo ẹ̀sìn Kristẹni.” Nínú gbogbo Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ tí a ṣe láàárín ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti Róòmù nìkan ló ṣì ń bá iṣẹ́ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti yí orúkọ rẹ̀ padà, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ mìíràn ló ń gbé ṣe.

A kó àwọn àkọsílẹ̀ nípa Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ jọ. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n wá di àkójọ ìwé àṣírí Ọ́fíìsì Mímọ́ náà. Àwọn kan lára àwọn ará Róòmù tí a kà sí olórí alágbàwí Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti Róòmù, tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ láti “ṣayẹyẹ” òkú Póòpù Paul Kẹrin, tú ibi àkójọ ìwé náà látòkè délẹ̀ ní ọdún 1559. Lẹ́yìn tí Napoléon Kìíní ṣẹ́gun Róòmù ní 1810, ó kó àwọn ìwé náà lọ sí Paris. Ọ̀pọ̀ àwọn àkójọ ìwé ló sọnù tàbí kí wọ́n bà jẹ́ nígbà yẹn àti ìgbà tí a kó wọn padà lọ sọ́dọ̀ póòpù lẹ́yìn náà.

Kí Ló Wà Nínú Wọn?

Àwọn ìwé tó lé ní ẹ̀ẹ́dégbèjìlélógún [4,300] tó para pọ̀ jẹ́ àkójọ ìwé náà kún iyàrá méjì nítòsí Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ti Pétérù Mímọ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kádínà Joseph Ratzinger—olórí ibùdó Ibùjókòó Ìjọba Póòpù—àwọn ọ̀ràn tó wà nínú àkójọ ìwé náà kò ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn ìṣèlú ní tààràtà, àmọ́ “wọ́n jẹ́ ti ìsìn.”

Àwọn òpìtàn fohùn ṣọ̀kan pé a kò lè retí kí àkójọ ìwé náà ṣí ohun púpọ̀ payá. Ọ̀jọ̀gbọ́n Prosperi ṣàlàyé pé àkọsílẹ̀ ìjíròrò ni àwọn ìpàdé Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti Róòmù wà níbẹ̀, àmọ́ ṣá “àwọn àlàyé tí a kọ fún àgbéyẹ̀wò, àwọn àkọsílẹ̀ ìgbẹ́jọ́, àti ọ̀pọ̀ jù lọ àkọsílẹ̀ nípa bí gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ ni kò sí níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni Bíṣọ́ọ̀bù Marino Marini, tí wọ́n rán láti Róòmù pé kí ó lọ gba àwọn ìwé tí Napoléon kó níbẹ̀ padà, pàṣẹ pé kí a bà jẹ́ láàárín ọdún 1815 sí 1817 ní Paris.”

Ibùjókòó Ìjọba Póòpù ti fún àwọn ọ̀mọ̀wé ní àǹfààní láti wọ ibẹ̀ lọ wo àwọn ìwé tí a ti kó jọ kí Leo Kẹtàlá tó kú ní July 1903. Kí àwọn olùwádìí tó lè wọ ibẹ̀, wọ́n ní láti gba lẹ́tà tí ń ṣàlàyé nípa wọn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí ìsìn tàbí àwọn ọ̀mọ̀wé onípò gíga.

Ìṣelámèyítọ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kan sáárá sí ìròyìn nípa ṣíṣí ibi àkójọ ìwé náà fáráyé wọ̀, àwọn ènìyàn ṣì ṣe lámèyítọ́ rẹ̀. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì náà, Hans Küng, ń ronú nípa ìdí tó fi jẹ́ kìkì àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà ṣáájú ọdún 1903 ni a kó jáde fáráyé rí, ló bá béèrè pé: “Ṣé pé ọdún 1903 gangan ni àwọn àkọsílẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í di ohun tí ń pe àfiyèsí, nítorí pé lọ́dún yẹn ni Póòpù Pius Kẹwàá, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ joyè póòpù, bẹ̀rẹ̀ ìgbétásì láti gbógun ti àwọn Elérò Ìgbàlódé, tí ó fi pète láti gbá ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan mú, kí ó sì dá ìṣòro sílẹ̀ fún àwọn bíṣọ́ọ̀bù Ítálì, ilẹ̀ Faransé, àti Germany, tí ó sì mú kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn pa ṣọ́ọ̀ṣì tì ni?”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yí orúkọ ibi àkójọ ìwé náà padà, tí wọ́n sì ṣí i fáráyé wọ̀, lójú òpìtàn Italo Mereu, “iṣẹ́ tí [Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Tí Ń Rí Sí Ìgbàgbọ́ Ẹ̀sìn Kátólíìkì] ń ṣe kò yàtọ̀ sí ti Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti tẹ́lẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà ògbólógbòó tó gbà ṣe é,” bíi ṣíṣàì jẹ́ kí àwọn tí a ń wádìí nípa wọ́n rí àwọn ìwé ìgbẹ́jọ́ wọn.

‘Kò Sí Àṣírí Tí Kì Yóò Di Mímọ̀’

Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn òpìtàn kì í gbà gbọ́ pé àwọn yóò rí àwọn ohun bàbàrà kankan nínú “àkójọ ìwé Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ náà.” Síbẹ̀, ó ṣì ṣe pàtàkì pé Ìjọ Kátólíìkì kà á sí àìgbọdọ̀máṣe láti fara mọ́ ìdájọ́ tí a gbé karí èrò àwọn aráàlú.

Àmọ́, èrò Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù. Láìpẹ́ láìjìnnà, yóò ṣe ìdájọ́ ìsìn tó ní òun jẹ́ ìsìn Kristẹni, àmọ́ tó jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ ló ti ń rú òfin Ọlọ́run, tí ó sì ń ba ìjẹ́pàtàkì ẹ̀kọ́ Jésù jẹ́ nípa ṣíṣe Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ lọ́nà rírorò. A ti dá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lóró, tí a sì ti pa wọ́n nípakúpa nínú ìwádìí wọ̀nyí, kìkì nítorí pé wọn kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìjọ náà àti àwọn ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan.—Mátíù 26:52; Jòhánù 14:15; Róòmù 14:12.

Kò sí bí àyẹ̀wò tí àwọn ọ̀mọ̀wé ń ṣe lórí àkójọ ìwé náà ṣe lè kún tó, kò lè pé láé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, “kò . . . sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú [Ọlọ́run], ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó ń sọ nípa àwọn aṣáájú ìsìn tí ń ṣòdì sí i pé: “Ẹ má bẹ̀rù wọn; nítorí kò sí nǹkan kan tí a bò mọ́lẹ̀ tí kì yóò di títú síta, kò sì sí àṣírí tí kì yóò di mímọ̀.”—Mátíù 10:26.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́, March 1, 1998, ojú ìwé 3 sí 7.

b Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tí àjọ méjèèjì ń gbà ṣiṣẹ́ àti ìyọrísí iṣẹ́ wọn yàtọ̀ díẹ̀, àjọ tuntun ni wọ́n jẹ́ bí a bá fi wọ́n wé Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní sànmánì agbedeméjì tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1231 ní Ítálì àti ilẹ̀ Faransé.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ilé ńlá tí Ọ́fíìsì Mímọ́ náà wà ní Róòmù, Ítálì

Àwọn àwòrán: Láti inú ìwé Bildersaal deutscher Geschichte

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́