Bibeli Ha Jẹ́ Ẹbun Kan Lati Ọdọ Ọlọrun Nitootọ Bi?
“MO GBAGBỌ pe Bibeli ni ẹbun didara julọ ti Ọlọrun tíì fi fun eniyan rí.” Ọrọ yẹn ni a sọ lati ẹnu Abraham Lincoln, ààrẹ 16 ti orilẹ-ede United States.a Kò dánìkan wà ninu ifimọriri han rẹ̀ fun iwe atọjọmọjọ yii.
Àgbà oselu ara Britain ti ọrundun 19 naa William E. Gladstone sọ pe: “A mọ̀ nipa Bibeli pé ó ni Orisun Akanṣe kan, alafo kan ti a kò lè diwọn rẹ̀ ni o sì yà á sọtọ kuro lara awọn alabaadije rẹ̀.” Lọna kan naa, àgbà oṣelu ara America naa ti ọrundun 18 Patrick Henry sọ pe: “Bibeli niyelori tó apapọ gbogbo awọn iwe ti a tii tẹ̀ rí.” Niti pe Iwe Mimọ wú u lori dajudaju, olu-ọba France naa Napoléon Bonaparte sọrọ akiyesi pe: “Bibeli kii wulẹ ṣe iwe kan lasan, ṣugbọn Ẹ̀dá Alààyè kan ni, pẹlu agbara ti ń ṣẹgun gbogbo ohun ti o bá tako o.”
Fun awọn kan, Bibeli ti jẹ́ orisun iranlọwọ ati ìtùnú. Ọgagun àgbà ti Imulẹ Apapọ Ijọba Guusu America naa Robert E. Lee ṣalaye pe: “Ninu gbogbo idaamu ati ipọnju mi, Bibeli kò tii kuna rí lati fun mi ni imọlẹ ati okun.” Ati nitori imọriri rẹ̀ fun iwe yii, ààrẹ ilẹ U.S. naa John Quincy Adams sọ pe: “Fun ọpọlọpọ ọdun ni mo ti sọ ọ di àṣà lati ka Bibeli jálẹ̀ lẹẹkan lọdọọdun.”
Bi Ọga Ogo Julọ bá ti fi Bibeli fun araye, ẹri gbọdọ wà pe a mí sí i latọrunwa. O gbọdọ tayọlọla ju iwe eyikeyii miiran lọ. Ati fun Bibeli lati jẹ́ orisun tootọ fun okun ati itọni, ó gbọdọ ṣee gbáralé patapata. eayi o, nigba naa, ibeere naa wà sibẹ pe, Bibeli ha jẹ́ ẹbun kan lati ọdọ Ọlọrun nitootọ bi? Jẹ ki a ṣawari idahun si ibeere naa tẹ̀le eyi.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Niti tootọ, ẹbun titobi ju miiran kan wà—Jesu Kristi.—Johanu 3:16.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
William. E. Gladstone
[Credit Line]
U.S. National Archives photo
Abraham Lincoln
[Credit Line]
U.S. National Archives photo
Patrick Henry
[Credit Line]
Harper’s U.S. History
Napoléon Bonaparte
[Credit Line]
Ti A Yà Lati Ọwọ E. Ronjat
John Quincy Adams
[Credit Line]
Harper’s U.S. History
Robert E. Lee
[Credit Line]
U.S. National Archives photo